Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:1-7

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
    wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
    wọn ó máa gbé
Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
    ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
    tí wọn lè máa gbé

Saamu 107:33-37

33 Ó sọ odò di aginjù,
    àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
    nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀;
35 O sọ aginjù di adágún omi àti
    ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi
36 Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
    wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
    tí yóò máa so èso tí ó dára;

Joṣua 2:1-14

Rahabu àti àwọn Ayọ́lẹ̀wò

(A)Nígbà náà ni Joṣua ọmọ Nuni rán àwọn ayọ́lẹ̀wò méjì jáde ní àṣírí láti Ṣittimu. Ó sì wí pé, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá Jeriko.” Wọ́n sì lọ, wọ́n wọ ilé panṣágà kan, tí à ń pè ní Rahabu wọ́n sì dúró síbẹ̀.

A sì sọ fún ọba Jeriko, “Wò ó! Àwọn ará Israẹli kan wá ibí ní alẹ́ yìí láti wá yọ́ ilẹ̀ yí wò.” Ọba Jeriko sì ránṣẹ́ sí Rahabu pé: “Mú àwọn ọkùnrin nì tí ó tọ̀ ọ́ wá, tí ó wọ inú ilé rẹ jáde wá, nítorí wọ́n wá láti yọ́ gbogbo ilẹ̀ yìí wò ni.”

Ṣùgbọ́n obìnrin náà ti mú àwọn ọkùnrin méjì náà o sì fi wọ́n pamọ́. Ó sì wí pé, “lóòtítọ́ ní àwọn ọkùnrin náà wá sí ọ̀dọ̀ mi, ṣùgbọ́n èmi kò mọ ibi tí wọ́n ti wá. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, nígbà tí ó tó àkókò láti ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè, àwọn ọkùnrin náà sì jáde lọ. Èmi kò sì mọ ọ̀nà tí wọ́n gbà lọ. Ẹ lépa wọn kíákíá. Ẹ̀yin yóò bá wọn.” (Ṣùgbọ́n ó ti mú wọn gòkè àjà ó sì fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ pòròpòrò ọkà tó tò jọ sí orí àjà.) Àwọn ọkùnrin náà jáde lọ láti lépa àwọn ayọ́lẹ̀wò náà ní ọ̀nà tí ó lọ sí ìwọdò Jordani, bí àwọn tí ń lépa wọn sì ti jáde, wọ́n ti ìlẹ̀kùn ẹnu ibodè.

Kí àwọn ayọ́lẹ̀wò náà tó sùn ní alẹ́, ó gòkè tọ̀ wọ́n lọ lókè àjà. Ó sì sọ fún wọn, “Èmi mọ̀ pé Olúwa ti fún un yín ní ilẹ̀ yìí àti pé ẹ̀rù u yín ti sọ wá di ojo dé ibi pé ìdí gbogbo àwọn tí ó n gbé ilẹ̀ yìí ti di omi nítorí i yín. 10 Àwa ti gbọ́ bí Olúwa ti mú omi Òkun Pupa gbẹ níwájú u yín nígbà tí ẹ̀yin jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ohun tí ẹ̀yin ṣe sí Sihoni àti Ogu, àwọn ọba méjèèjì ti Amori ti ìlà-oòrùn Jordani, tí ẹ̀yin parun pátápátá. 11 Bí a ti gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ọkàn wa pami kò sì sí okun kankan fún wa mọ́ nítorí i yín, nítorí pé Olúwa Ọlọ́run yín ni Ọlọ́run ní òkè ọ̀run àti ní ayé. 12 Ǹjẹ́ nísinsin yìí, ẹ jọ̀wọ́ ẹ búra fún mi ní ti Olúwa pé ẹ̀yin yóò ṣe àánú fún ìdílé mi, nítorí pé mo ti ṣe yín ní oore. Ẹ̀yin yóò fún mi ní ààmì tó dájú: 13 pé ẹ̀yin yóò dá ẹ̀mí baba àti ìyá mi sí; arákùnrin mi àti arábìnrin mi, àti ohun gbogbo tí wọ́n ní, àti pé ẹ̀yin yóò gbà wá là lọ́wọ́ ikú.”

14 “Ẹ̀mí wa fún ẹ̀mí in yín!” àwọn ọkùnrin náà mú dá a lójú. “Tí ìwọ kò bá sọ ohun tí àwa ń ṣe, àwa yóò sì fi òtítọ́ àti àánú bá ọ lò nígbà tí Olúwa bá fún wa ní ilẹ̀ náà.”

2 Peteru 2:1-3

Àwọn olùkọ́ni èké àti ìparun wọn

(A)Ṣùgbọ́n àwọn wòlíì èké wà láàrín àwọn ènìyàn náà pẹ̀lú, gẹ́gẹ́ bí àwọn olùkọ́ni èké yóò ti wà láàrín yín. Wọn yóò yọ́ kẹ́lẹ́ mú ẹ̀kọ́ òdì àti ègbé tọ̀ yín wa, àní tí yóò sẹ́ Olúwa tí ó rà wọ́n padà, wọ́n ó sì mú ìparun ti o yára kánkán wá sórí ara wọn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yóò si máa tẹ̀lé ọ̀nà ìtìjú wọn, tí wọn yóò sì mú kí ọ̀nà òtítọ́ di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. Nínú ìwà wọ̀bìà wọn, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ òdì wọ̀nyí yóò máa rẹ́ ẹ yín jẹ nípa ìtàn asán. Ìdájọ́ ẹni tí kò falẹ̀ láti ìgbà yìí wá àti ìparun wọn tí kò sí tòògbé.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.