Revised Common Lectionary (Semicontinuous)
Saamu ti Dafidi. Nígbà tí ó wà nínú aginjù Juda.
63 Ọlọ́run, ìwọ ni Ọlọ́run mi,
nígbà gbogbo ni mo ń ṣàfẹ́rí rẹ,
òǹgbẹ rẹ ń gbẹ ọkàn mi,
ara mi fà sí ọ,
ní ilẹ̀ gbígbẹ àti ilẹ̀ tí ń ṣàárẹ̀
níbi tí kò sí omi.
2 Èmi ti rí ọ ní ibi mímọ́,
mo rí agbára àti ògo rẹ.
3 Nítorí ìfẹ́ rẹ dára ju ayé lọ,
ètè mi yóò fògo fún ọ.
4 Èmi ó yìn ọ́ níwọ̀n ìgbà tí mo wà láààyè,
èmi ó gbé ọwọ́ sókè, èmi ó sì pe orúkọ rẹ.
5 A ó tẹ́ ọkàn mi lọ́rùn bí ọlọ́ràá oúnjẹ;
pẹ̀lú ètè ìyìn, ẹnu mi yóò yìn ọ́.
6 Nígbà tí mo rántí rẹ lórí ibùsùn mi;
èmi ń ronú rẹ títí ìṣọ́ òru.
7 Nítorí ìwọ ni ìrànlọ́wọ́ mi,
mo kọrin níbi òjìji ìyẹ́ apá rẹ.
8 Ọkàn mí fà sí ọ:
ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbé mi ró.
Ògo Olúwa
34 (A)Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà. 35 Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.
36 Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli nígbàkúgbà tí a bá ti fa ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ; 37 ṣùgbọ́n tí àwọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè. 38 Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.
Ìṣubú Babeli
18 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo sì rí angẹli mìíràn, ó ń ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀ wá ti òun ti agbára ńlá; ilẹ̀ ayé sì ti ipa ògo rẹ̀ mọ́lẹ̀. 2 (A)Ó sì kígbe ní ohùn rara, wí pé:
“Babeli ńlá ṣubú! Ó ṣubú!
Ó sì di ibùjókòó àwọn ẹ̀mí èṣù,
àti ihò fún ẹ̀mí àìmọ́ gbogbo,
àti ilé fún ẹyẹ àìmọ́ gbogbo,
ilé fún ẹranko ìríra àti àìmọ́ gbogbo.
3 (B)Nítorí nípa ọtí wáìnì ìrunú àgbèrè rẹ̀ ni
gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ṣubú.
Àwọn ọba ayé sì ti bá a ṣe àgbèrè,
àti àwọn oníṣòwò ayé sì di ọlọ́rọ̀ nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọ̀bìà rẹ̀.”
4 (C)Mo sì gbọ́ ohùn mìíràn láti ọ̀run wá, wí pé:
“ ‘Ẹ ti inú rẹ̀ jáde, ẹ̀yin ènìyàn mi,’
kí ẹ ma bá a ṣe alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀,
kí ẹ ma bà á sì ṣe gbà nínú ìyọnu rẹ̀.
5 (D)Nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ga títí dé ọ̀run,
Ọlọ́run sì ti rántí àìṣedéédéé rẹ̀.
6 (E)San an fún un, àní bí òun tí san án fún ní,
kí ó sì ṣe e ni ìlọ́po méjì fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀
Nínú ago náà tí o ti kún, òun ni kí ẹ sì kún fún un ni méjì.
7 (F)Níwọ́n bí o ti yin ara rẹ̀ lógo tó,
tí ó sì hùwà wọ̀bìà,
níwọ̀n bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ dá a lóró kí ẹ sì fún un ní ìbànújẹ́;
nítorí tí ó wí ní ọkàn rẹ̀ pé,
‘Mo jókòó bí ọbabìnrin,
èmi kì sì í ṣe opó, èmí kì yóò sì rí ìbànújẹ́ láé.’
8 Nítorí náà, ní ọjọ́ kan ni ìyọnu rẹ̀ yóò dé,
ikú, àti ìbìnújẹ́, àti ìyàn;
a ó sì fi iná sun ún pátápátá:
nítorí pé alágbára ni Olúwa Ọlọ́run tí ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.
9 (G)“Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀. 10 Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
Babeli ìlú alágbára nì!
Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’
19 (A)Wọ́n sì kú ekuru sí orí wọn, wọ́n kígbe, wọ́n sọkún, wọn sì ń ṣọ̀fọ̀, wí pé:
“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
nínú èyí tí a sọ gbogbo àwọn tí ó ni ọkọ̀
ní Òkun di ọlọ́rọ̀ nípa ohun iyebíye rẹ̀!
Nítorí pé ni wákàtí kan, a sọ ọ́ di ahoro.’
20 (B)“Yọ̀ lórí rẹ̀, ìwọ ọ̀run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Ọlọ́run!
Ẹ yọ̀, ẹ̀yin aposteli mímọ́ àti wòlíì!
Nítorí Ọlọ́run ti gbẹ̀san yín lára rẹ̀
nítorí ìdájọ́ tí ó gbé ka orí rẹ.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.