Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Semicontinuous)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with sequential stories told across multiple weeks.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:1-7

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Wọ́n ń rìn káàkiri ní aginjù ní ibi tí ọ̀nà kò sí,
    wọn kò rí ọ̀nà lọ sí ìlú níbi tí
    wọn ó máa gbé
Ebi ń pa wọn, òǹgbẹ gbẹ wọ́n,
    ó sì rẹ ọkàn wọn nínú wọn.
Ní ìgbà náà, wọ́n kígbe sókè
    Olúwa nínú ìdààmú wọn,
ó sì yọ wọ́n kúrò nínú ìrora wọn
Ó fi ọ̀nà títọ́ hàn wọ́n sí ìlú
    tí wọn lè máa gbé

Saamu 107:33-37

33 Ó sọ odò di aginjù,
    àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
    nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀;
35 O sọ aginjù di adágún omi àti
    ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi
36 Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
    wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
    tí yóò máa so èso tí ó dára;

Joṣua 1:1-11

Olúwa pàṣẹ fún Joṣua

Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose: “Mose ìránṣẹ́ mi ti kú. Nísinsin yìí, ìwọ àti gbogbo àwọn ènìyàn wọ̀nyí, ẹ múra láti kọjá odò Jordani lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ó fi fún wọn fún àwọn ará Israẹli. Èmi yóò fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹsẹ̀ ẹ yín tẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe ìlérí fún Mose. Ilẹ̀ ẹ yín yóò fẹ̀ láti aginjù Lebanoni, àti láti odò ńlá, ti Eufurate—gbogbo orílẹ̀-èdè Hiti títí ó fi dé Òkun ńlá ní ìwọ̀-oòrùn. (A)Kì yóò sí ẹnikẹ́ni tí yóò le è dúró níwájú rẹ ní ọjọ́ ayé è rẹ gbogbo. Bí mo ti wà pẹ̀lú u Mose, bẹ́ẹ̀ ni Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, Èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Èmi kì yóò kọ̀ ọ́.

“Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn. Jẹ́ alágbára, kí o sì mú àyà le gidigidi. Kí o sì ṣọ́ra láti pa gbogbo òfin tí Mose ìránṣẹ́ mi fún ọ mọ́, Má ṣe yà kúrò nínú u rẹ̀ sí ọ̀tún tàbí sí òsì, kí ìwọ kí ó lè ṣe rere níbikíbi tí ìwọ bá ń lọ. Má ṣe jẹ́ kí Ìwé Ofin yìí kúrò ní ẹnu rẹ, máa ṣe àṣàrò nínú u rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru, kí ìwọ kí ó lè ṣọ́ra láti ṣe gbogbo nǹkan tí a kọ sí inú u rẹ̀. Nígbà náà ni yóò dára fún ọ, ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí. Èmi kò ha ti pàṣẹ fún ọ bí? Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le. Má ṣe bẹ̀rù, má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì, nítorí pé Olúwa à rẹ yóò wà pẹ̀lú rẹ ní ibikíbi tí ìwọ bá ń lọ.”

10 Báyìí ni Joṣua pàṣẹ fún olórí àwọn ènìyàn rẹ̀ 11 “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ”

Romu 2:17-29

Àwọn Júù àti òfin

17 Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 18 (A)tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19 tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn, 20 (B)Olùkọ́ àwọn aláìmòye, olùkọ́ àwọn ọmọdé, ẹni tí ó ní ètò ìmọ̀ àti òtítọ́ òfin lọ́wọ́, 21 (C)Ǹjẹ́ ìwọ tí o ń kọ́ ẹlòmíràn, ìwọ kò kọ́ ara rẹ? Ìwọ tí ó ń wàásù kí ènìyàn má jalè, ìwọ ha ń jalè bí? 22 Ìwọ tí o wí pé, kí ènìyàn má ṣe panṣágà, ìwọ ń ṣe panṣágà bí? Ìwọ tí o kórìíra òrìṣà, ìwọ ń ja tẹmpili ní olè bí? 23 Ìwọ ti ń ṣògo nínú òfin, ìwọ ha ń bu Ọlọ́run ni ọlá kù nípa rírú òfin? 24 (D)Nítorí gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́, “Orúkọ Ọlọ́run sá à di ìsọ̀rọ̀-òdì sí láàrín àwọn aláìkọlà nítorí yín.”

25 (E)Nítorí ìkọlà ní èrè nítòótọ́, bí ìwọ bá pa òfin mọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá jẹ́ arúfin, ìkọlà rẹ di àìkọlà. 26 (F)Nítorí náà bí àwọn aláìkọlà bá pa ìlànà òfin mọ́, a kì yóò ha kà wọ́n sí àwọn tí a kọ nílà bí? 27 (G)Aláìkọlà nípa àdánidá, bí ó bá pa òfin mọ́, yóò dá ẹ̀bi fún ìwọ tí ó jẹ́ arúfin nípa ti àkọsílẹ̀ òfin àti ìkọlà.

28 (H)Kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní òde ni Júù, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe èyí tí ó farahàn ní ara ni ìkọlà: 29 (I)Ṣùgbọ́n Júù ti inú ni Júù, àti ìkọlà sì ni ti ọkàn nínú ẹ̀mí tí kì í ṣe ti àkọsílẹ̀, ìyìn ẹni tí kò sí lọ́dọ̀ ènìyàn, bí kò ṣe lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.