Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Gẹ́gẹ́ bí ti ṣeminiti. Saamu ti Dafidi.
12 Ràn wá lọ́wọ́, Olúwa, nítorí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run kò sí mọ́;
Olóòtítọ́ tí pòórá kúrò láàrín àwọn ènìyàn.
2 Olúkúlùkù ń parọ́ fún aládùúgbò rẹ̀;
ètè èké wọn ń sọ ẹ̀tàn.
3 Kí Olúwa kí ó gé ètè èké wọn
àti gbogbo ahọ́n ìfọ́nnu
4 tí ó wí pé,
“Àwa ó borí pẹ̀lú ahọ́n wa;
àwa ní ètè wa: Ta ni ọ̀gá wa?”
5 “Nítorí ìnilára àwọn aláìlágbára àti ìkérora àwọn aláìní,
Èmi yóò dìde nísinsin yìí” ni Olúwa wí.
“Èmi yóò dáàbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn tí ń ṣe àrankàn wọn.”
6 Ọ̀rọ̀ Olúwa sì jẹ aláìlábùkù,
gẹ́gẹ́ bí fàdákà tí a yọ́ nínú ìléru amọ̀,
tí a sọ di mímọ́ nígbà méje.
7 Olúwa, ìwọ yóò pa wá mọ́
kí o sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí títí láé.
8 Àwọn ènìyàn búburú ń rin ìrìn fáàrí kiri
nígbà tí wọn ń bọ̀wọ̀ fún òsì láàrín àwọn ènìyàn.
17 Òkèlè gbígbẹ tòun tàlàáfíà àti ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ sàn
ju ilé tí ó kún fọ́fọ́ fún ẹran àti ìjà.
2 Ọlọ́gbọ́n ìránṣẹ́ yóò ṣàkóso adójútini ọmọ,
yóò sì pín ogún gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ.
3 Iná ni a fi fọ́ Fàdákà àti wúrà
Ṣùgbọ́n Olúwa ló ń dán ọkàn wò.
4 Ènìyàn búburú ń tẹ́tí sí ètè tí ń sọ ibi
òpùrọ́ a máa fetí sí ahọ́n búburú.
5 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sín olùpọ́njú jẹ, ó gan Ẹlẹ́dàá rẹ̀,
ẹnikẹ́ni tí ń yọ̀ sí ìyọnu kò ní lọ láìjìyà.
19 Bí mo ti jẹ́ òmìnira tí ń kò sì darapọ̀ mọ́ ẹnikẹ́ni, mo sọ ara mi di ẹrú lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, láti lè jèrè ọ̀pọ̀lọpọ̀ sí i. 20 (A)Nígbà tí mó wà lọ́dọ̀ àwọn Júù, mo dàbí ọ̀kan nínú wọn, kí wọn ba à lè tẹ́tí sí ìwàásù ìhìnrere mi àti ki n le jèrè wọn fún Kristi. Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tó wà lábẹ́ òfin èmi kì í bá wọn jiyàn rárá (bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí lábẹ́ òfin), kí èmi lè jèrè àwọn ti ń bẹ lábẹ́ òfin. 21 (B)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin, èmi náà yóò dàbí ẹni tí kò sí lábẹ́ òfin (èmi kì í ṣe aláìlófin sí Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmí ń bẹ lábẹ́ òfin Kristi), kí èmi le jèrè àwọn tí kò sí lábẹ́ òfin. 22 (C)Nígbà tí mo bá wà láàrín àwọn aláìlera, èmi náà yóò di aláìlera, kí èmi lé jèrè àwọn aláìlera. Mo di ohun gbogbo fún gbogbo ènìyàn, kí èmi ba à lè gba díẹ̀ là lábẹ́ bí ó ti wù kí ó rí. 23 Èmi sì ń ṣe ohun gbogbo nítorí ti ìhìnrere, kí èmi kí ó lè jẹ́ alábápín nínú rẹ̀ pẹ̀lú yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.