Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 73

ÌWÉ KẸTA

Saamu 73–89

Saamu ti Asafu.

73 Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
    fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
    ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
    nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.

Wọn kò ṣe wàhálà;
    ara wọn mókun wọn sì lágbára.
Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
    a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;
    ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;
    ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n
Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti
    ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run
    ahọ́n wọn gba ipò ayé.
10 Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn
    wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?
    Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

12 Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí
    ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.

13 Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;
    nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14 Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;
    a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.

15 Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”
    Èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,
    Ó jẹ́ ìnilára fún mi.
17 Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;
    Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

18 Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́
    ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí
    bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!
Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,
    bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,
    ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́
    àti ọkàn mi ṣì korò,
22 Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;
    mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;
    ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi
    ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo
25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?
    Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà
    ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi
    àti ìpín mi títí láé.

27 Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé
    ìwọ ti pa gbogbo wọn run;
tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ
28 Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run
    Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi;
    Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

Amosi 7:1-6

Eṣú, iná àti ìwọ̀n okùn

Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Ó pèsè ọwọ́ eṣú lẹ́yìn ìgbà tí a kórè ìpín ọba, ní ìgbà ti èso ẹ̀ẹ̀kejì ń jáde bọ̀. Nígbà tí wọ́n jẹ koríko ilẹ̀ náà mọ́ féfé nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè, mo bẹ̀ ọ́, dáríjì! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.

“Èyí kò ni ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa wí.

Èyí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè fihàn mí: Olúwa Olódùmarè ń pè fún ìdájọ́ pẹ̀lú iná; ó jó ọ̀gbun ńlá rún, ó sì jẹ ilẹ̀ run. Nígbà náà ni mo gbé ohùn mi sókè pé, “Olúwa Olódùmarè jọ̀wọ́ má ṣe ṣe é! Báwo ni Jakọbu yóò ha ṣe lè dìde? Òun kéré jọjọ!”

Olúwa ronúpìwàdà nípa èyí.

“Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Olúwa Olódùmarè wí.

1 Timotiu 1:18-20

18 Àṣẹ yìí ni mo pa fún ọ, Timotiu ọmọ mi, gẹ́gẹ́ bí ìsọtẹ́lẹ̀ wọ̀nyí tó ó ti ṣáájú nípa rẹ̀, pé nípasẹ̀ wọ́n kí ìwọ lè máa ja ìjà rere; 19 Máa ní ìgbàgbọ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere. Èyí ti àwọn mìíràn ti mú kúrò lọ́dọ̀ wọn tí wọ́n sì rí ọkàn ìgbàgbọ́ wọn; 20 Nínú àwọn ẹni tí Himeneu àti Aleksanderu wà; àwọn tí mo ti fi lé Satani lọ́wọ́, kí a lè kọ́ wọn kí wọ́n má sọ̀rọ̀-òdì mọ́.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.