Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 73

ÌWÉ KẸTA

Saamu 73–89

Saamu ti Asafu.

73 Nítòótọ́ Ọlọ́run dára fún Israẹli,
    fún àwọn ọlọ́kàn funfun.

Ṣùgbọ́n bí ó ṣe ti èmi, ẹsẹ̀ mi ti yẹ̀ tán;
    ìrìn mi fẹ́rẹ̀ yọ̀ tán.
Nítorí èmi ń ṣe ìlara àwọn tó ń ṣe féfé
    nígbà tí mo bá rí àlàáfíà àwọn ènìyàn búburú.

Wọn kò ṣe wàhálà;
    ara wọn mókun wọn sì lágbára.
Wọn kò ní ìpín nínú àjàgà tó ń ṣẹlẹ̀ sí ènìyàn;
    a kò pọ́n wọn lójú nípa ẹlòmíràn.
Ìgbéraga ni ọ̀ṣọ́ ọrùn wọn;
    ìwà ipá bò wọ́n mọ́lẹ̀ bí aṣọ.
Láti inú ọkàn àrékérekè ni àìṣòdodo ti wá;
    ẹ̀rí ọkàn búburú wọn kò ní òdínwọ̀n
Wọn ń ṣẹ̀sín, wọn sì ń sọ̀rọ̀-òdì ní ti
    ìnilára, wọ́n ń sọ̀rọ̀ láti ibi gíga.
Wọ́n ń gbé ẹ̀mí wọn lé ọ̀run
    ahọ́n wọn gba ipò ayé.
10 Nítorí náà àwọn ènìyàn wọn yípadà sí wọn
    wọ́n sì mu omi ní ọ̀pọ̀lọpọ̀.
11 Wọ́n wí pé, “Báwo ni Ọlọ́run yóò ṣe mọ̀?
    Ọ̀gá-ògo ha ní ìmọ̀ bí?”

12 Bí àwọn ènìyàn búburú ṣe rí nìyí
    ènìyàn asán, wọ́n ń pọ̀ ní ọrọ̀.

13 Nítòótọ́ nínú asán ni mo pa ọkàn mi mọ́;
    nínú asán ni mo wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀.
14 Ní gbogbo ọjọ́ ni a ń yọ mí lẹ́nu;
    a sì ń jẹ mí ní yà ní gbogbo òwúrọ̀.

15 Bí mo bá wí pé, “Èmi ó wí báyìí,”
    Èmi ó ṣẹ̀ sí ìran àwọn ọmọ rẹ̀.
16 Nígbà tí mo gbìyànjú láti mọ èyí,
    Ó jẹ́ ìnilára fún mi.
17 Títí mo fi wọ ibi mímọ́ Ọlọ́run;
    Nígbà náà ni òye ìgbẹ̀yìn wọn yé mi.

18 Lóòtítọ́ ìwọ gbé wọn lórí ilẹ̀ yíyọ́
    ìwọ jù wọ́n sílẹ̀ sínú ìparun.
19 Báwo ní a ti mú wọn lọ sínú ìdahoro yìí
    bí ẹni pé ní ìṣẹ́jú kan!
Ìbẹ̀rù ni a fi ń run wọ́n pátápátá!
20 Bí àlá nígbà tí ènìyàn bá jí,
    bẹ́ẹ̀ ni nígbà tí ìwọ bá dìde, Olúwa,
    ìwọ yóò ṣe àbùkù àwòrán wọn.

21 Nígbà tí inú mi bàjẹ́
    àti ọkàn mi ṣì korò,
22 Mo jẹ́ aṣiwèrè àti aláìlóye;
    mo jẹ́ ẹranko ní iwájú rẹ.

23 Síbẹ̀ mo wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo;
    ìwọ di ọwọ́ ọ̀tún mi mú.
24 Ìwọ fi ìmọ̀ràn rẹ tọ́ mi
    ní ìkẹyìn ìwọ ó mú mi lọ sí inú ògo
25 Ta ni mo ní ní ọ̀run, bí kò ṣe ìwọ?
    Àti ní ayé kò sí ohun tí mo fẹ́ lẹ́yìn rẹ.
26 Ara mi àti ọkàn mi le è kùnà
    ṣùgbọ́n Ọlọ́run ni agbára ẹ̀mí mi
    àti ìpín mi títí láé.

27 Àwọn tí ó jìnnà sí ọ yóò ṣègbé
    ìwọ ti pa gbogbo wọn run;
tí ń ṣe àgbèrè kiri kúrò lọ́dọ̀ rẹ
28 Ṣùgbọ́n ní ti èmi, ó dára láti súnmọ́ Ọlọ́run
    Èmi ti fi Olúwa Olódùmarè ṣe ààbò mi;
    Kí èmi ó lè máa sọ̀rọ̀ iṣẹ́ rẹ.

Jobu 40:6-14

Nígbà náà ní Olúwa dá Jobu lóhùn láti inú ìjì àyíká wá, ó sì wí pé:

“Di àmùrè gírí ní ẹgbẹ́ rẹ bí ọkùnrin,
    èmi ó bi ọ léèrè,
    kí ìwọ kí ó sì dá mi lóhùn.

“Ìwọ ha fẹ́ mú ìdájọ́ mi di asán?
    Ìwọ ó sì dá mi lẹ́bi, kí ìwọ lè ṣe olódodo
Ìwọ ni apá bí Ọlọ́run
    tàbí ìwọ lè fi ohùn sán àrá bí òun?
10 Fi ọláńlá àti ọlá ìtayọ rẹ̀ ṣe ara rẹ ní ọ̀ṣọ́,
    tí ó sì fi ògo àti títóbi ọ̀ṣọ́ bo ara ní aṣọ.
11 Mú ìrunú ìbínú rẹ jáde;
    kíyèsí gbogbo ìwà ìgbéraga rẹ kí o sì rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀.
12 Wo gbogbo ìwà ìgbéraga, ènìyàn kí o sì rẹ ẹ sílẹ̀
    kí o sì tẹ ènìyàn búburú mọ́lẹ̀ ní ipò wọn.
13 Sin gbogbo wọn papọ̀ nínú erùpẹ̀,
    kí o sì di ojú ìkọ̀kọ̀ wọn ní isà òkú
14 Nígbà náà ní èmi ó yìn ọ́ pé,
    ọwọ́ ọ̀tún ara rẹ lè gbà ọ́ là.

Jobu 42:1-6

Ìrònúpìwàdà Jobu

42 Nígbà náà ní Jobu dá Olúwa lóhùn, ó sì wí pé:

“Èmi mọ̀ pé, ìwọ lè e ṣe ohun gbogbo,
    àti pé, kò si ìrò inú tí a lè fa sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ.
Ìwọ béèrè, ta ni ẹni tí ń fi ìgbìmọ̀ pamọ́ láìní ìmọ̀?
    Nítorí náà ní èmi ṣe ń sọ èyí tí èmi kò mọ̀,
    ohun tí ó ṣe ìyanu jọjọ níwájú mi, ti èmi kò mòye.

“Ìwọ wí pé, ‘gbọ́ tèmi báyìí,
    èmi ó sì sọ; èmi ó béèrè lọ́wọ́ rẹ,
    ìwọ yóò sì dá mi lóhùn.’
Etí mi sì ti gbọ́ nípa rẹ,
    ṣùgbọ́n nísinsin yìí ojú mi ti rí ọ.
Ǹjẹ́ nítorí náà èmi kórìíra ara mi,
    mo sì ronúpìwàdà nínú ekuru àti eérú.”

Luku 22:31-33

31 (A)Olúwa sì wí pé, “Simoni, Simoni, wò ó, Satani fẹ́ láti gbà ọ́, kí ó lè kù ọ́ bí alikama: 32 (B)Ṣùgbọ́n mo ti gbàdúrà fún ọ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má ṣe yẹ̀; àti ìwọ nígbà tí ìwọ bá sì padà bọ̀ sípò, mú àwọn arákùnrin rẹ lọ́kàn le.”

33 (C)Ó sì wí fún un pé, “Olúwa, mo múra tán láti bá ọ lọ sínú túbú, àti sí ikú.”

Luku 22:54-62

Peteru sẹ́ Jesu

54 (A)Wọ́n sì gbá a mú, wọ́n sì fà á lọ, wọ́n sì mú un wá sí ilé olórí àlùfáà. Ṣùgbọ́n Peteru tọ̀ ọ́ lẹ́yìn ní òkèrè. 55 Nígbà tí wọ́n sì ti dáná láàrín àgbàlá, tí wọ́n sì jókòó pọ̀, Peteru jókòó láàrín wọn. 56 (B)Ọmọbìnrin kan sì rí i bí ó ti jókòó níbi ìmọ́lẹ̀ iná náà, ó sì tẹjúmọ́ ọn, ó ní, “Eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀.”

57 Ṣùgbọ́n, ó wí pé, “Obìnrin yìí, èmi kò mọ̀ ọ́n.”

58 Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ẹlòmíràn sì rí i, ó ní, “Ìwọ pẹ̀lú wà nínú wọn.”

Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kọ́.”

59 Ó sì tó bí i wákàtí kan síbẹ̀ ẹlòmíràn tẹnumọ́ ọn, wí pé, “Nítòótọ́ eléyìí náà wà pẹ̀lú rẹ̀: nítorí ará Galili ní í ṣe.”

60 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Ọkùnrin yìí, èmi kò mọ ohun tí ìwọ ń wí!” Lójúkan náà, bí ó tí ń wí lẹ́nu, àkùkọ kọ! 61 (C)Olúwa sì yípadà, ó wo Peteru. Peteru sì rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí fún un pé, “Kí àkùkọ tó kọ, ìwọ ó sẹ́ mi lẹ́ẹ̀mẹ́ta.” 62 Peteru sì bọ́ sí òde, ó sọkún kíkorò.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.