Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 113

113 Ẹ máa yin Olúwa.

Yìn ín ẹ̀yin ìránṣẹ́ Olúwa,
ẹ yin orúkọ Olúwa.
Fi ìbùkún fún orúkọ Olúwa láti
    ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé.
Láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀ rẹ̀
    orúkọ Olúwa ni kí a máa yìn.

Olúwa ga lórí gbogbo orílẹ̀-èdè,
    àti ògo rẹ̀ lórí àwọn ọ̀run.
Ta ló dàbí Olúwa Ọlọ́run wa,
    tí ó gbé ní ibi gíga.
Tí ó rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ láti wò
    òun tí ó ń bẹ lọ́run, àti nínú ayé!

Ó gbé òtòṣì dìde láti inú erùpẹ̀, àti pé
    ó gbé aláìní sókè láti inú ààtàn wá.
Kí ó le mú un jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé
    àní pẹ̀lú àwọn ọmọ-aládé àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ó mú àgàn obìnrin gbé inú ilé,
    àti láti jẹ́ aláyọ̀ ìyá fún àwọn ọmọ rẹ̀.

Ẹ yin Olúwa.

Isaiah 5:8-23

Ègún àti ìdájọ́

Ègbé ni fún àwọn tí ń kọ́lé mọ́lé
    tí ó sì ń ra ilẹ̀ mọ́lẹ̀
tó bẹ́ẹ̀ tí ààyè kò ṣẹ́kù
    tí ó sì nìkan gbé lórí ilẹ̀.

Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sọ ọ́ sí mi létí:

“Ó dájú pé àwọn ilé ńláńlá
    yóò di ahoro, àwọn ilé dáradára yóò wà láìní olùgbé.
10 Ọgbà àjàrà sáré oko mẹ́wàá yóò mú
    ìkòkò wáìnì kan wá,
nígbà tí òṣùwọ̀n homeri kan yóò mú
    agbọ̀n irúgbìn kan wá.”

11 Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n dìde
    ní kùtùkùtù òwúrọ̀
láti lépa ọtí líle,
    tí wọ́n sì mu ún títí alẹ́ fi lẹ́
    títí wọ́n fi gbinájẹ pẹ̀lú wáìnì.
12 Wọ́n ní dùùrù àti ohun èlò orin olókùn níbi àsè wọn,
    ṣaworo òun fèrè àti wáìnì,
ṣùgbọ́n wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí,
    wọn kò sí bọ̀wọ̀ fún iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.
13 Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò
    lọ sí ìgbèkùn
nítorí òye kò sí fún wọn,
    ebi ni yóò pa àwọn ọlọ́lá wọn kú;
ẹgbàágbèje wọn ni òǹgbẹ
    yóò sì gbẹ.
14 Nítorí náà isà òkú ti ń dátọ́mì gidigidi,
    ó sì ti ya ẹnu rẹ̀ sílẹ̀ gbagada,
nínú rẹ̀ ni àwọn gbajúmọ̀ àti mẹ̀kúnnù yóò sọ̀kalẹ̀ sí
    pẹ̀lú ọlá àti ògo wọn.
15 Báyìí, ènìyàn yóò di ìrẹ̀sílẹ̀
    àti ọmọ ènìyàn ni a sọ di onírẹ̀lẹ̀
    ojú agbéraga ni a sì rẹ̀ sílẹ̀.
16 Ṣùgbọ́n Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni a ó gbéga nípa ẹ̀tọ́ rẹ̀,
    Ọlọ́run ẹni mímọ́ yóò sì fi ara rẹ̀ hàn ní mímọ́ nípa òdodo rẹ̀.
17 Nígbà náà ni àwọn àgùntàn yóò máa jẹ́ ko ní ibùgbé e wọn,
    àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yóò máa jẹ nínú ahoro àwọn ọlọ́rọ̀.

18 Ègbé ni fún àwọn tí ń fi ohun asán fa ẹ̀ṣẹ̀,
    àti àwọn tí o dàbí ẹni pé wọ́n ń fi okùn kẹ̀kẹ́ ẹ̀sìn fa ẹsẹ̀,
19 sí àwọn tí ó sọ pé, “Jẹ́ kí Ọlọ́run ṣe kíákíá,
    jẹ́ kí ó yára ṣiṣẹ́ rẹ̀ kí a lè rí i,
    jẹ́ kí ó súnmọ́ bí
jẹ́ kí ètò ẹni mímọ́ Israẹli kí ó dé,
    kí àwa kí ó le mọ̀ ọ́n.”

20 Ègbé ni fún àwọn tí ń pe ibi ní rere, àti rere ní ibi,
    tí ń fi òkùnkùn ṣe ìmọ́lẹ̀ àti ìmọ́lẹ̀ ṣe òkùnkùn,
    tí ń fi ìkorò ṣe adùn àti adùn ṣe ìkorò.

21 Ègbé ni fún àwọn tí ó gbọ́n lójú ara wọn
    tí wọ́n jáfáfá lójú ara wọn.

22 Ègbé ni fún àwọn akọni nínú wáìnì mímu
    àti àwọn akíkanjú nínú àdàlú ọtí,
23 tí wọ́n dá ẹlẹ́bi sílẹ̀ nítorí àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
    tí wọn sì du aláre ní ẹ̀tọ́.

Marku 12:41-44

Ọ̀rẹ́ opó

41 (A)Jesu jókòó ní òdìkejì kọjú sí àpótí ìṣúra: ó ń wo ìjọ ènìyàn ti ń sọ owó sínú àpótí ìṣúra, ọ̀pọ̀ àwọn ọlọ́rọ̀ sì sọ púpọ̀ sí i. 42 Ṣùgbọ́n obìnrin opó kan wà, ó sì fi ààbọ̀ owó idẹ méjì síbẹ̀, tí ì ṣe ìdá méjì owó-babà kan sínú rẹ̀.

43 Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sọ fún wọn wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yin pé, tálákà opó yìí sọ sínú àpótí ìṣúra ju gbogbo àwọn ìyókù to sọ sínú rẹ lọ. 44 Nítorí pé, àwọn ìyókù mú nínú ọ̀pọ̀ ìní wọ́n, ṣùgbọ́n ní tirẹ̀, nínú àìní rẹ̀, ó sọ gbogbo ohun tí ó ní náà sílẹ̀ àní gbogbo ìní rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.