Revised Common Lectionary (Complementary)
Òfin Olúwa ni ìfẹ́ pípé
97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.
Ìpè ti ọgbọ́n àti àìgbọ́n
9 Ọgbọ́n ti kọ́ ilé rẹ̀,
ó ti gbẹ́ òpó o rẹ̀ méjèèjì,
2 ó ti fi ilé pọn tí, ó ti fọ̀nà rokà.
Ó sì ti ṣètò o tábìlì oúnjẹ rẹ̀
3 ó ti rán àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ jáde, ó sì ń pè,
láti ibi tí ó ga jù láàrín ìlú.
4 “Jẹ́ kí gbogbo àwọn aláìgbọ́n wọ ibí wá!”
Ó ń wí fún àwọn tí kò lọ́gbọ́n pé
5 “Wá, ẹ wá fẹ́ oúnjẹ mi
sì mu wáìnì tí mo ti pò.
6 Fi ìwà àìmọ̀kan rẹ sílẹ̀ ìwọ yóò sì yè;
rìn ní ọ̀nà òye.
7 “Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹlẹ́gàn wí, kọ lẹ́tà sí àbùkù
ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ẹni búburú wí kọ lẹ́tà sí èébú.
8 Má ṣe bá ẹlẹ́gàn wí, àìṣe bẹ́ẹ̀ yóò kórìíra rẹ.
Bá ọlọ́gbọ́n wí yóò sì fẹ́ràn rẹ;
9 kọ́ ọlọ́gbọ́n ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì gbọ́n sí i
kọ́ olódodo ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́, yóò sì fi kún ìmọ̀ rẹ̀.
10 “Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n,
ìmọ̀ nípa Ẹni mímọ́ ni òye.
11 Nítorí nípasẹ̀ mi ọjọ́ rẹ yóò gùn
ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yóò sì kún ọjọ́ ayé rẹ.
12 Bí ìwọ bá gbọ́n, ọgbọ́n rẹ yóò fún ọ ní èrè:
bí ìwọ bá jẹ́ ẹlẹ́gàn, ìwọ nìkan ni yóò jìyà.”
13 Òmùgọ̀ obìnrin jẹ́ aláriwo;
ó jẹ́ aláìlẹ́kọ̀ọ́ àti aláìní ìmọ̀.
14 Ó jókòó ní ẹnu-ọ̀nà ilé rẹ̀
lórí ìjókòó níbi tí ó ga jù láàrín ìlú,
15 ó ń pe àwọn tí ó ń kọjá lọ,
tí wọn ń lọ tààrà ní ọ̀nà wọn.
16 “Jẹ́ kí gbogbo ẹni tí ó jẹ́ aláìlóye súnmọ́ bí!”
Ni ó wí fún ẹni tí òye kù díẹ̀ ká à tó fún.
17 “Omi tí a jí mu dùn
oúnjẹ tí a jẹ ní ìkọ̀kọ̀ a máa ládùn!”
18 Ṣùgbọ́n wọn ò funra pé àwọn òkú wà níbẹ̀,
pé àwọn àlejò rẹ̀ wà ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀ isà òkú.
2 (A)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jesu Kristi, olódodo nìkan. 2 (B)Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.
3 Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. 4 (C)Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. 5 (D)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. 6 (E)Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.