Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 25:11-20

11 Nítorí orúkọ rẹ, Olúwa,
    dárí ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí, nítorí tí ó tóbi.

12 Àwọn wo ni ó bẹ̀rù Olúwa?
    Yóò kọ́ wọn ní ọ̀nà èyí tí wọn yóò yàn.
13 Wọn yóò lo ọjọ́ wọn nínú àlàáfíà,
    àwọn ọmọ wọn yóò sì gba ilẹ̀ náà.
14 Olúwa fi ọkàn tán, àwọn tí o bẹ̀rù u rẹ̀;
    ó sọ májẹ̀mú rẹ̀ di mí mọ̀ fún wọn.
15 Ojú mi gbé sókè sọ́dọ̀ Olúwa,
    nítorí pé yóò yọ ẹsẹ̀ mi kúrò nínú àwọ̀n náà.

16 Yípadà sí mi, kí o sì ṣe oore fún mi;
    nítorí pé mo nìkan wà, mo sì di olùpọ́njú.
17 Tì mí lẹ́yìn kúrò nínú ìpọ́njú àyà mi;
    kí o sì fà mí yọ kúrò nínú ìpọ́njú mi.
18 Kíyèsi ìjìyà àti wàhálà mi,
    kí o sì dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ mi jì.
19 Kíyèsi ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀tá mi,
    tí wọn kórìíra mi pẹ̀lú ìwà ìkà wọn.

20 Pa ọkàn mi mọ́, kí o sì gbà mí sílẹ̀;
    Má ṣe jẹ́ kí a fi mí sínú ìtìjú,
    nítorí pé ìwọ ni ibi ìsádi mi.

Jobu 24:1-8

Ìbéèrè Jobu

24 “Ṣe bí ìgbà kò pamọ́ lọ́dọ̀ Olódùmarè fún ìdájọ́?
    Èéṣe tí ojúlùmọ̀ rẹ̀ kò fi rí ọjọ́ rẹ̀?
Wọ́n a sún ààmì ààlà ilẹ̀,
    wọ́n á fi agbára kó agbo ẹran lọ, wọ́n a sì bọ́ wọn.
Wọ́n á sì da kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ aláìní baba
    lọ, wọ́n a sì gba ọ̀dá màlúù opó ní ohun ògo.
Wọ́n á bi aláìní kúrò lójú ọ̀nà,
    àwọn tálákà ayé a fi agbára sápamọ́.
Kíyèsi i, bí i kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó nínú ijù ni àwọn tálákà jáde lọ sí iṣẹ́ wọn,
    wọ́n a tètè dìde láti wá ohun ọdẹ;
    ijù pèsè oúnjẹ fún wọn àti fún àwọn ọmọ wọn.
Olúkúlùkù a sì sá ọkà oúnjẹ ẹran rẹ̀ nínú oko,
    wọn a sì ká ọgbà àjàrà ènìyàn búburú.
Ní ìhòhò ni wọn máa sùn láìní aṣọ,
    tí wọn kò ní ìbora nínú òtútù.
Ọ̀wààrà òjò òkè ńlá sì pa wọ́n,
    wọ́n sì lẹ̀ mọ́ àpáta nítorí tí kò sí ààbò.

Jakọbu 2:1-7

Ojúsàájú jẹ́ èèwọ̀

Ẹ̀yin ará mi, gẹ́gẹ́ bí onígbàgbọ́ nínú ògo Olúwa wá Jesu Kristi, ẹ máa ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni. Nítorí bí ọkùnrin kan bá wá sí ìpéjọpọ̀ yín, pẹ̀lú òrùka wúrà àti aṣọ dáradára, tí tálákà kan sì wá pẹ̀lú nínú aṣọ èérí; tí ẹ̀yin sì bu ọlá fún ẹni tí ó wọ aṣọ dáradára tí ẹ sì wí pé, “Ìwọ jókòó níhìn-ín yìí ní ibi dáradára” tí ẹ sì wí fún tálákà náà pé, “Ìwọ dúró níbẹ̀” tàbí “jókòó níhìn-ín lábẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ mi,” ẹyin kò ha ń dá ara yín sí méjì nínú ara yín, ẹ̀yin kò sì di onídàájọ́ tí ó ní èrò búburú bí?

Ẹ fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́: Ọlọ́run kò ha ti yan àwọn tálákà ayé yìí láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́, àti ajogún ìjọba náà, tí ó ti ṣe ìlérí fún àwọn tí ó fẹ́ ẹ? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti bu tálákà kù. Àwọn ọlọ́rọ̀ kò ha ń pọ́n yin lójú bí; wọn kò ha sì ń wọ́ yín lọ sílé ẹjọ́? Wọn kò ha ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rere nì tí a fi ń pè yín bí?

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.