Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 49:1-12

Fún adarí orin. Ti àwọn ọmọ Kora. Saamu.

49 Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn!
    Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé.
Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré
    tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú!
Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
    èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá
Èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe,
    èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù.

Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé?
    Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká,
Àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn,
    tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn.
Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀
    padà tàbí san owó ìràpadà fún
Ọlọ́run.
Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye
    kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀,
Ní ti kí ó máa wà títí ayé
    láìrí isà òkú.
10 Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú,
    bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé
wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.
11 Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé,
    ibùgbé wọn láti ìrandíran,
wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn.

12 Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́
    ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Òwe 23:1-11

Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ohun àdídùn

23 Nígbà tí ìwọ bá jókòó láti bá ìjòyè jẹun,
    kíyèsi ohun tí ó wà níwájú rẹ gidigidi.
Ìwọ a sì fi ọ̀bẹ lé ara rẹ ní ọ̀fun,
    bí ìwọ bá jẹ́ òkúndùn ènìyàn.
Má ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀:
    nítorí pé oúnjẹ ẹ̀tàn ni.

Má ṣe ṣe làálàá láti lọ́rọ̀:
    ṣíwọ́ kúrò nínú ọgbọ́n ara rẹ.
Ìwọ ó ha fi ojú rẹ lépa ohun tí kò sí?
    Nítorí tí ọ̀rọ̀ hu ìyẹ́ apá fún ara rẹ̀,
    ó sì ń fò bí idì ní ojú ọ̀run.

Má ṣe jẹ oúnjẹ ẹni tí ó háwọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni kí o má sì ṣe fẹ́ oúnjẹ dídùn rẹ̀.
Nítorí pé bí ẹni tí ń ṣírò ní ọkàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó rí:
    “Máa jẹ, kí o sì máa mu,” ni ó ń wí fún ọ;
    ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ kò pẹ̀lú rẹ.
Òkèlè tí ìwọ jẹ ni ìwọ ó pọ̀ jáde,
    ìwọ a sì sọ ọ̀rọ̀ dídùn rẹ̀ nù.

Má ṣe sọ̀rọ̀ ní etí aṣiwèrè;
    nítorí tí yóò gan ọgbọ́n ọ̀rọ̀ rẹ.

10 Má ṣe ṣí ààlà àtijọ́ kúrò;
    má sì ṣe bọ́ sínú oko aláìní baba.
11 Nítorí pé Olùràpadà wọn lágbára;
    yóò gba ìjà wọn jà sí ọ.

Romu 11:33-36

Ìyìn fún Ọlọ́run

33 (A)A! Ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run!
    Àwámárídìí ìdájọ́ rẹ̀ ti rí,
    ọ̀nà rẹ̀ sì jù àwárí lọ!
34 (B)“Nítorí ta ni ó mọ ọkàn Olúwa?
    Tàbí ta ni í ṣe ìgbìmọ̀ rẹ̀?”
35 (C)“Tàbí ta ni ó kọ́ fi fún un,
    tí a kò sì san padà fún un?”
36 (D)Nítorí láti ọ̀dọ̀ rẹ̀, àti nípa rẹ̀, àti fún un ni ohun gbogbo;
    ẹni tí ògo wà fún láéláé! Àmín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.