Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Pẹ̀lú ohun èlò orin olókùn. Saamu ti Asafu. Orin.
76 Ní Juda ni a mọ Ọlọ́run;
orúkọ rẹ̀ sì lágbára ní Israẹli
2 Àgọ́ rẹ̀ wà ní Salẹmu,
ibùgbé rẹ̀ ni Sioni.
3 Níbẹ̀ ni ó ṣẹ́ ọfà,
asà àti àwọn idà, ohun ìjà ogun. Sela.
4 Ìwọ ni ògo àti ọlá
Ju òkè ńlá ìkógun wọ̀nyí lọ.
5 A kó àwọn alágídí ọkàn ní ìkógun
wọ́n sun oorun ìgbẹ̀yìn wọn;
kò sí ọ̀kan nínú àwọn akọni
tó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.
6 Ní ìfibú rẹ, Ọlọ́run Jakọbu,
àwọn ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀.
7 Ìwọ nìkan ni ó yẹ kí a bẹ̀rù.
Ta ló lé dúró níwájú rẹ, nígbà tí ìwọ bá ń bínú?
8 Ìwọ ń ṣe ìdájọ́ láti ọ̀run,
ilé ayé bẹ̀rù, ó sì dúró jẹ́ẹ́:
9 Nígbà tí, ìwọ Ọlọ́run,
bá dìde láti ṣe ìdájọ́,
láti gba àwọn ẹni ìnilára ilẹ̀ náà. Sela.
10 Lóòótọ́, ìbínú rẹ sí àwọn ènìyàn ń mú ìyìn wá fún ọ,
ẹni tí ó yọ nínú ìbínú rẹ ní a dá nígbà tí ìwọ bá fi ìbínú ìyókù di ara rẹ ni àmùrè.
11 Jẹ́ ẹ̀jẹ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì mú un ṣẹ;
kí gbogbo àwọn tí ó yí i ká
mú ẹ̀bùn wá fún ẹni tí ó tọ́ láti bẹ̀rù.
12 Ó ké ẹ̀mí àwọn aládé kúrò;
àwọn ọba ayé sì ń bẹ̀rù rẹ̀.
Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ejibiti
29 (A)Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2 “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. 3 Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:
“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ
èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
4 Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
5 Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.
6 Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.
“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. 7 Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.
8 “ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: kéyèsi Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. 9 Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.
“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; Èmi ni mo ṣe é,” 10 Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11 Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12 Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.
Ìpè méje
15 (A)Angẹli keje sì fọn ìpè; a sì gbọ́ ohùn ńlá láti ọ̀run, wí pé,
“Ìjọba ayé di ti Olúwa wá, àti tí Kristi rẹ̀;
òun yóò sì jẹ ọba láé àti láéláé!”
16 Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún náà tí wọn jókòó níwájú Ọlọ́run lórí ìtẹ́ wọn, dojúbolẹ̀, wọn sì sin Ọlọ́run, 17 wí pé:
“Àwa fi ọpẹ́ fún ọ, Olúwa Ọlọ́run, Olódùmarè,
tí ń bẹ, tí ó sì ti wà,
nítorí pé ìwọ ti gba agbára ńlá rẹ̀,
ìwọ sì ti jẹ ọba.
18 (B)Inú bí àwọn orílẹ̀-èdè, bẹ́ẹ̀ ni ìbínú rẹ̀ ti dé,
àti àkókò láti dá àwọn òkú lẹ́jọ́,
àti láti fi èrè fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì,
àti àwọn ènìyàn mímọ́, àti àwọn tí o bẹ̀rù orúkọ rẹ̀,
àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá;
àti láti run àwọn tí ń pa ayé run.”
19 (C)A sì ṣí tẹmpili Ọlọ́run sílẹ̀ ní ọ̀run, a sì ri àpótí májẹ̀mú nínú tẹmpili rẹ̀. Mọ̀nàmọ́ná sì kọ, a sì gbọ́ ohùn, àrá sì sán, ilẹ̀ sì mi, yìnyín ńlá sì bọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.