Revised Common Lectionary (Complementary)
Fún adarí orin. Saamu ti Dafidi.
13 Yóò ti pẹ́ tó, Olúwa? Ìwọ o ha gbàgbé mi títí láé?
Yóò tí pẹ́ tó tí ìwọ yóò máa fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?
2 Yóò ti pẹ́ tó tí èmi ó máa bá èrò mi jà,
àti ní ojoojúmọ́ ni èmi ń ní ìbànújẹ́ ní ọkàn mi?
Yóò ti pẹ́ tó tí àwọn ọ̀tá mi yóò máa borí mi?
3 Wò mí kí o sì dá mi lóhùn, Olúwa Ọlọ́run mi.
Fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú mi, kí èmi ó má sún oorun ikú;
4 Ọ̀tá mi wí pé, “Èmi ti ṣẹ́gun rẹ̀,”
àwọn ọ̀tá mi yóò yọ̀ tí mo bá ṣubú.
5 Ṣùgbọ́n mo gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà;
ọkàn mi ń yọ̀ nínú ìgbàlà rẹ.
6 Èmi ó máa kọrin sí Olúwa,
nítorí ó dára sí mi.
A o pa àwọn ọ̀tá Jerusalẹmu run
12 Ọ̀rọ̀-ìmọ̀: Ọ̀rọ̀ Olúwa fún Israẹli ni.
Olúwa wí, ẹni tí ó na àwọn ọ̀run, tí ó sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀, tí ó sì da ẹ̀mí ènìyàn tí ń bẹ ni inú rẹ̀: 2 “Kíyèsi í, èmi yóò sọ Jerusalẹmu dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Juda àti Jerusalẹmu. 3 Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jerusalẹmu di òkúta ti ko ṣe yí kúrò fún gbogbo ènìyàn: gbogbo àwọn tí ó bá sì fẹ́ yí i ni a ó gé sí wẹ́wẹ́, 4 ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fi ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì ṣí ojú mi sí ilé Juda, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè. 5 Àti àwọn baálẹ̀ Juda yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jerusalẹmu ni agbára mi nípa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run wọn.’
6 “Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò ṣe àwọn baálẹ̀ Juda bí ààrò iná kan láàrín igi, àti bi ẹ̀fúùfù iná láàrín ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì: a ó sì tún máa gbé inú Jerusalẹmu ní ipò rẹ̀.
7 “Olúwa pẹ̀lú yóò kọ́ tètè gba àgọ́ Juda là ná, kí ògo ilé Dafidi àti ògo àwọn ara Jerusalẹmu má ba gbé ara wọn ga sí Juda. 8 Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò dáàbò bò àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu; ẹni tí ó bá sì ṣe àìlera nínú wọn ní ọjọ́ náà, yóò dàbí Dafidi; ilé Dafidi yóò sì dàbí Ọlọ́run, bí angẹli Olúwa níwájú wọn. 9 Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, èmi yóò wá láti pa gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè run tí ó wá kọjú ìjà sí Jerusalẹmu.”
Ìṣọ̀fọ̀ fún ọba wọn tí wọn gún lọ́kọ̀
10 (A)“Èmi ó sì tu ẹ̀mí oore-ọ̀fẹ́ àti ẹ̀bẹ̀ sórí ilé Dafidi àti sórí Jerusalẹmu: wọn ó sì máa wo ẹni tí wọn tí gún ni ọ̀kọ̀, wọn ó sì máa ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, bí ẹnìkan ti ń ṣọ̀fọ̀ fún ọmọ rẹ̀ kan ṣoṣo àti gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí wọn yóò sì wà ni ìbànújẹ́, bí ẹni tí ń banújẹ́ fún àkọ́bí rẹ̀. 11 Ní ọjọ́ náà ni ẹkún, ńláńlá yóò wà ni Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí ọ̀fọ̀ Hadadi Rimoni ni Àfonífojì Megido. 12 Ilẹ̀ náà yóò ṣọ̀fọ̀, ìdílé, kọ̀ọ̀kan fun ara rẹ, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀; ìdílé Dafidi lọ́tọ̀; àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Natani lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ́. 13 Ìdílé Lefi lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀; ìdílé Ṣimei lọ́tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀. 14 Gbogbo àwọn ìdílé tí o kù, ìdílé, ìdílé, lọ́tọ̀ọ̀tọ̀, àti àwọn aya wọn lọ́tọ̀ọ̀tọ̀.
Ìwẹ̀nùmọ́ kúrò nínú ẹsẹ̀
13 “Ní ọjọ́ náà ìsun kan yóò ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi àti fún àwọn ará Jerusalẹmu, láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìmọ́ wọn.
9 (A)“Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn nǹkan wọ̀nyí bá bẹ̀rẹ̀ sí i ṣẹlẹ̀, ẹ kíyèsára! Nítorí ẹ̀yin yóò wà nínú ewu. Wọn yóò fà yín lọ ilé ẹjọ́ gbogbo. Wọn yóò fi ìyà jẹ yín nínú Sinagọgu wọn. Àwọn ènìyàn yóò fẹ̀sùn kàn yín níwájú àwọn baálẹ̀ àti níwájú àwọn ọba nítorí orúkọ mi, fún ẹ̀rí fún wọn. 10 Nítorí pé ẹ gbọdọ̀ kọ́kọ́ wàásù ìhìnrere náà fún gbogbo orílẹ̀-èdè kí òpin tó dé. 11 (B)Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n bá ń fà yín lọ, tí wọ́n bá sì ń fi yín lé wọn lọ́wọ́, ẹ má ṣe ṣàníyàn ṣáájú ohun tí ẹ ó sọ. Ṣùgbọ́n ohun tí bá fi fún yín ní wákàtí náà, òun ni kí ẹ̀yin kí ó wí. Nítorí kì í ṣe ẹ̀yin ni ó ń wí, bí kò ṣe Ẹ̀mí Mímọ́.
12 “Arákùnrin yóò máa fi ẹ̀sùn kan arákùnrin rẹ̀, tí yóò sì yọrí sí ikú. Baba yóò máa ṣe ikú pa ọmọ rẹ̀. Àwọn ọmọ yóò máa dìtẹ̀ sí òbí wọn. Àní, àwọn ọmọ pẹ̀lú yóò máa ṣe ikú pa òbí wọn. 13 (C)Àwọn ènìyàn yóò kórìíra yín nítorí tí ẹ jẹ́ tèmi. Ṣùgbọ́n ẹni tó bá fi ara da ìyà títí dé òpin tí kò sì kọ̀ mí sílẹ̀ òun ni yóò rí ìgbàlà.
14 (D)“Ṣùgbọ́n nígba tí ẹ̀yin bá rí ìríra ìsọdahoro, tí ó dúró níbí tí kò yẹ, tí a tí ẹnu wòlíì Daniẹli sọ, (ẹnikẹ́ni tí ó bá kà á ki í ó yé e) nígbà náà ni kí àwọn tí ń bẹ ni Judea sálọ sí orí òkè. 15 Kí ẹni ti ń bẹ lórí ilé má ṣe sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ilé, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe wọ inú rẹ̀, láti mú ohunkóhun jáde nínú ilé rẹ̀. 16 Kí ẹni tí ó wà lóko má ṣe padà sẹ́yìn láti wá mú aṣọ rẹ̀. 17 (E)Ègbé ní fún àwọn tí ó lóyún, àti fún obìnrin tí ń fún ọ́mọ lọ́mú ní ọjọ́ wọ̀nyí. 18 Kí ẹ sì máa gbàdúrà pé èyí ṣẹlẹ̀ ní àkókò òtútù. 19 Nítorí ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì yóò jẹ́ àkókò ìpọ́njú, irú èyí tí kò ì ṣẹlẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ ẹ̀dá Ọlọ́run. Irú rẹ̀ kò sì ni ṣẹlẹ̀ mọ́.
20 “Àfi tí Olúwa bá gé àkókò ìjìyà náà kúrú, ẹyọ ẹ̀mí kan ní ayé kì yóò là. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn tí Ọlọ́run yàn, ni yóò ṣe dín àwọn ọjọ́ náà kù. 21 Nígbà náà, bí ẹnikẹ́ni bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, Kristi wa níbi yìí!’ tàbí, sọ fún un yín pé, ‘Ẹ wò ó, ó wà lọ́hùn ún nì!’ Ẹ má ṣe gbà wọ́n gbọ́. 22 (F)Nítorí àwọn èké Kristi àti àwọn wòlíì èké ni yóò wá, wọn yóò sì fi iṣẹ́ ìyanu tí yóò tan ènìyàn jẹ hàn. Bí ó bá ṣe é ṣe, wọn yóò tan àwọn àyànfẹ́ pàápàá jẹ. 23 Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra. Mo ti kìlọ̀ fún un yín ṣáájú tó!
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.