Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 93

93 Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ;
    ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ
    àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára.
Ó fi ìdí ayé múlẹ̀;
    kò sì le è yí.
Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́;
    ìwọ wà títí ayérayé.

A ti gbé Òkun sókè, Olúwa,
    Òkun ti gbé ohùn wọn sókè;
    Òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.
Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ,
    ó ni ògo ju Òkun rírú lọ
    Olúwa ga ní ògo.

Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin;
    ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́
    fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.

Esekiẹli 28:1-10

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí ọba Tire

28 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: (A)“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi,
    ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;
Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà,
    ní àárín gbùngbùn Òkun.”
Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,
    bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?
    Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,
    ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,
àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,
    nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,
    ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
    ọkàn rẹ gbé sókè,
    nítorí ọrọ̀ rẹ.

“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,
    pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,
    ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;
wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,
    ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,
    wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò,
    ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná,
    àwọn tí a pa ní àárín Òkun.
Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”
    ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?
Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,
    ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.
10 Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà,
    ní ọwọ́ àwọn àjèjì.

Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

Ìṣe àwọn Aposteli 7:54-8:1

A sọ Stefanu ní òkúta pa

54 Nígbà tí wọn sì gbọ́ nǹkan wọ̀nyí ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọn sì payínkeke sí i. 55 Ṣùgbọ́n Stefanu, ẹni tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó tẹjúmọ́ ọ̀run, ó sì rí ògo Ọlọ́run, àti Jesu dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. 56 Ó sì wí pé, “Wò ó, mo rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, Ọmọ Ènìyàn sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.”

57 Nígbà náà ni wọn kígbe ní ohùn rara, wọn sí di etí wọ́n, gbogbo wọn sì sáré sí i, wọ́n sì rọ́ lù ú, 58 wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sísọ ọ́ ní òkúta; àwọn ẹlẹ́rìí sì fi aṣọ wọn lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ ọmọkùnrin kan tí a ń pè ní Saulu.

59 Bí wọ́n ti ń sọ Stefanu ní òkúta, ó sì ké pe Olúwa wí pé, “Jesu Olúwa, gba ẹ̀mí mi.” 60 Nígbà náà ni ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó kígbe sókè pé, “Olúwa, má ṣe ka ẹ̀ṣẹ̀ yìí sí wọn ní ọrùn.” Nígbà ti ó sì wí èyí tán, ó sùn lọ.

(A)Saulu sì wà níbẹ̀, ó sì fi àṣẹ sí ikú rẹ̀.

Wọ́n ṣe inúnibíni sí ìjọ, wọ́n sì túká

Ní àkókò náà, inúnibíni ńlá kan dìde sí ìjọ tí ó wà ni Jerusalẹmu, gbogbo wọn sì túká káàkiri agbègbè Judea àti Samaria, àyàfi àwọn aposteli.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.