Revised Common Lectionary (Complementary)
Miktamu ti Dafidi.
16 Pa mí mọ́, Ọlọ́run,
nítorí nínú rẹ ni ààbò mi wà.
2 Mo sọ fún Olúwa, “ìwọ ni Olúwa mi,
lẹ́yìn rẹ èmi kò ní ìre kan.”
3 Sí àwọn ènìyàn tí ó wà ní ayé,
àwọn ni ológo nínú èyí tí ayọ̀ mí wà.
4 Ìṣòro àwọn wọ̀n-ọn-nì yóò pọ̀ sí i, àní àwọn tí ń tọ ọlọ́run mìíràn lẹ́yìn.
Ẹbọ ohun mímu ẹ̀jẹ̀ wọn ni èmi kì yóò ta sílẹ̀,
bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò dá orúkọ wọn lẹ́nu mi.
5 Olúwa, ni ìpín ìní mi tí mo yàn àti ago mi,
ó ti pa ohun tí í ṣe tèmi mọ́.
6 Okùn ààlà ilẹ̀ ti bọ́ sí ọ̀dọ̀ mi ní ibi dídára;
nítòótọ́ mo ti ní ogún rere.
7 Èmi yóò yin Olúwa, ẹni tí ó gbà mí ní ìyànjú;
ní òru, ọkàn mí ń bá mi sọ̀rọ̀.
8 (A)Mo ti gbé Ọlọ́run síwájú mi ní ìgbà gbogbo.
Nítorí tí ó wà ní ọwọ́ ọ̀tún mi, a kì yóò mì mí.
9 Nítorí èyí, ọkàn mi yọ̀, ahọ́n mi pẹ̀lú ń fò fáyọ̀;
ara mi pẹ̀lú yóò sinmi ní ààbò,
10 (B)nítorí ìwọ kò ní fi ọ̀kan sílẹ̀ nínú isà òkú,
tàbí kí ìwọ jẹ́ kí ẹni mímọ́ rẹ kí ó rí ìdíbàjẹ́.
11 Ìwọ ti fi ipa ọ̀nà ìyè hàn mí;
Ìwọ yóò kún mi pẹ̀lú ayọ̀ ní iwájú rẹ,
pẹ̀lú ìdùnnú ayérayé ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
Daniẹli túmọ̀ àlá náà
19 Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.”
Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ: 20 Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè ààyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run. 21 Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èso rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko igbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn. 22 Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.
23 “Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrín ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’
24 “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ ọba àti àṣẹ tí Ọ̀gá-ògo mú wá sórí ọba olúwa mi: 25 A ó lé ọ jáde kúrò láàrín ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrín ẹranko búburú: ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú. 26 Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jẹ ọba. 27 Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”
Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ nínú ẹ̀mí nínú Kristi
6 Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀. 7 Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́.
8 Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.
9 Nítorí nínú Kristi ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwàláàyè Ọlọ́run gbé ní ara, 10 (A)ẹ̀yin sì ní ohun gbogbo ní kíkún nínú Kristi, ẹni tí i ṣe orí fún gbogbo agbára àti àṣẹ. 11 Nínú ẹni tí a kò fi ìkọlà tí a fi ọwọ́ kọ kọ yín ní ilà, ni bíbọ ara ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, nínú ìkọlà Kristi. 12 Bí a ti sin yín pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìtẹ̀bọmi, tí a sì ti jí yín dìde pẹ̀lú rẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú agbára Ọlọ́run, ẹni tí ó jí dìde kúrò nínú òkú.
13 Àti ẹ̀yin, ẹni tí ó ti kú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ yín àti àìkọlà ará yín, mo ní, ẹ̀yin ni ó sì ti sọ di ààyè pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, ó sì ti dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín; 14 Ó sì ti pa ìwé májẹ̀mú nì rẹ́, tí ó lòdì sí wa, tí a kọ nínú òfin, èyí tí o lòdì sí wa: òun ni ó sì ti mú kúrò lójú ọ̀nà, ó sì kàn án mọ àgbélébùú. 15 (B)Ó sì ti gba agbára kúrò lọ́wọ́ àwọn ìjọba ẹ̀mí búburú àti àwọn alágbára gbogbo, ó sì ti dójútì wọn ní gbangba, bí ó ti ń yọ̀ fún ìṣẹ́gun lórí wọn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.