Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 126

Orin fún ìgòkè.

126 Nígbà tí Olúwa mú ìkólọ Sioni padà,
    àwa dàbí ẹni tí ó ń lá àlá.
Nígbà náà ni ẹnu wa kún fún ẹ̀rín,
    àti ahọ́n wa kọ orin;
nígbà náà ni wọ́n wí nínú àwọn kèfèrí pé,
    Olúwa ṣe ohun ńlá fún wọn.
Olúwa ṣe ohun ńlá fún wa;
    nítorí náà àwa ń yọ̀.

Olúwa mú ìkólọ wa padà,
    bí ìṣàn omi ní gúúsù.
Àwọn tí ń fi omijé fún irúgbìn
    yóò fi ayọ̀ ka.
Ẹni tí ń fi ẹkún rìn lọ,
    tí ó sì gbé irúgbìn lọ́wọ́,
lóòtítọ́, yóò fi ayọ̀ padà wá,
    yóò sì ru ìtí rẹ̀.

Jeremiah 23:9-15

Àwọn wòlíì èké

Nípa ti àwọn wòlíì èké:

Ọkàn mi ti bàjẹ́ nínú mi,
    gbogbo egungun mi ni ó wárìrì.
Èmi dàbí ọ̀mùtí ènìyàn,
    bí ọkùnrin tí ọtí wáìnì ń pa;
    nítorí Olúwa àti àwọn ọ̀rọ̀ mímọ́ rẹ̀.
10 Ilẹ̀ náà kún fún panṣágà ènìyàn
    nítorí ègún, ilẹ̀ náà gbẹ,
àwọn koríko orí aṣálẹ̀ ilẹ̀ náà rọ.
    Àwọn wòlíì tẹ̀lé ọ̀nà búburú,
    wọ́n sì ń lo agbára wọn lọ́nà àìtọ́.

11 “Wòlíì àti àlùfáà kò gbé ìgbé ayé ìwà-bí-Ọlọ́run;
    kódà nínú tẹmpili mi ni mo rí ìwà búburú wọn,”
    ni Olúwa wí.
12 “Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́,
    a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn;
níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú.
    Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn,
ní ọdún tí a jẹ wọ́n ní ìyà,”
    ni Olúwa wí.

13 “Láàrín àwọn wòlíì Samaria,
    Èmi rí ohun tí ń lé ni sá:
Wọ́n sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ Baali
    wọ́n sì mú Israẹli ènìyàn mi ṣìnà.
14 Àti láàrín àwọn wòlíì Jerusalẹmu,
    èmi ti rí ohun búburú:
Wọ́n ṣe panṣágà, wọ́n sì ń ṣèké.
    Wọ́n fún àwọn olùṣe búburú ní agbára,
tó bẹ́ẹ̀ tí kò sí ẹnìkan tí ó yípadà kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀.
    Gbogbo wọn dàbí Sodomu níwájú mi,
    àti àwọn ènìyàn olùgbé rẹ̀ bí Gomorra.”

15 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Ọlọ́run Alágbára wí ní ti àwọn wòlíì:

“Èmi yóò mú wọn jẹ oúnjẹ kíkorò,
    wọn yóò mu omi májèlé
nítorí láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì Jerusalẹmu
    ni àìwà-bí-Ọlọ́run ti tàn ká gbogbo ilẹ̀.”

Heberu 7:1-10

Melkisedeki jẹ́ àlùfáà

(A)Nítorí Melkisedeki yìí, ọba Salẹmu, àlùfáà Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹni tí ó pàdé Abrahamu bí ó ti ń padà bọ̀ láti ibi pípa àwọn ọba, tí ó sì súre fún un, ẹni tí Abrahamu sì pín ìdámẹ́wàá ohun gbogbo fún. Ní ọ̀nà èkínní orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí “ọba òdodo,” àti lẹ́yìn náà pẹ̀lú, “ọba Salẹmu,” tí í ṣe “ọba àlàáfíà.” Láìní baba, láìní ìyá, láìní ìtàn ìran, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọjọ́ ayé; ṣùgbọ́n a ṣe é bí ọmọ Ọlọ́run; ó wà ní àlùfáà títí.

Ǹjẹ́ ẹ gbà á rò bí ọkùnrin yìí ti pọ̀ tó, ẹni tí Abrahamu baba ńlá fi ìdámẹ́wàá nínú àwọn àṣàyàn ìkógun fún. Àti nítòótọ́ àwọn tí ó jẹ́ ọmọ Lefi, tí o gba oyè àlùfáà, wọ́n ní àṣẹ láti máa gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí òfin, èyí yìí, lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí ó tilẹ̀ ti jẹ́ pé, wọn ti inú Abrahamu jáde. Ṣùgbọ́n òun ẹni tí a kò tilẹ̀ pìtàn ìran rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ wọn wá, gba ìdámẹ́wàá lọ́wọ́ Abrahamu, ó sì súre fún ẹni tí ó gba ìlérí, láìsí ìjiyàn rárá ẹni kò tó ẹni tí à ń súre fún láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ju ni. Ni apá kan, àwọn ẹni kíkú gba ìdámẹ́wàá; ṣùgbọ́n níbẹ̀, ẹni tí a jẹ́rìí rẹ̀ pé o ń bẹ láààyè nì. Àti bí a ti lè wí, Lefi pàápàá tí ń gba ìdámẹ́wàá, ti san ìdámẹ́wàá nípasẹ̀ Abrahamu. 10 Nítorí o sá à sì ń bẹ ní inú baba rẹ̀, nígbà ti Melkisedeki pàdé rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.