Revised Common Lectionary (Complementary)
112 Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.
Ìbùkún ni fún ọkùnrin náà tí ó bẹ̀rù Ọlọ́run,
tí ó ní inú dídùn ńlá sí àwọn òfin rẹ̀.
2 Irú-ọmọ rẹ̀ yóò jẹ́ alágbára ní ayé:
ìran àwọn olóòtítọ́ ni a ó bùkún fún.
3 Ọlá àti ọrọ̀ yóò wà nínú ilé rẹ̀;
òdodo rẹ̀ sì dúró láé.
4 Fún olóòótọ́ ni ìmọ́lẹ̀ yóò tàn fún ní òkùnkùn:
olóore-ọ̀fẹ́ àti aláàánú àti òdodo.
5 Ènìyàn rere fi ojúrere hàn,
a sì wínni;
ìmòye ni yóò máa fi la ọ̀nà iṣẹ́ rẹ̀.
6 Dájúdájú a kì yóò le yí ní ipò padà láéláé:
olódodo ni a ó máa ṣe ìrántí rẹ láéláé.
7 Òun kì yóò béèrè ìyìn búburú:
ọkàn rẹ̀ ti dúró, ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa.
8 Ó ti mú ọkàn rẹ̀ gbilẹ̀, ẹ̀rù kí yóò bà á,
títí yóò fi rí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá rẹ̀.
9 (A)Ó ti pín ká, ó ti fi fún àwọn olùpọ́njú;
Nítorí òdodo rẹ̀ dúró láé;
ìwo rẹ̀ ní a ó gbé sókè pẹ̀lú ọlá.
10 Ènìyàn búburú yóò ri, inú wọn yóò sì bàjẹ́,
yóò sì pa eyín keke, yó sì yọ dànù:
èròǹgbà ọkàn ènìyàn búburú ni yóò ṣègbé.
Ìrúfin ìgbéyàwó
13 Bí ọkùnrin kan bá mú ìyàwó àti, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti dùbúlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kórìíra rẹ̀, 14 tí ó ṣì sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sì i, tí o sì fún un ní orúkọ búburú, wí pé, “Mo fẹ́ obìnrin yìí, ṣùgbọ́n nígbà tí mo súnmọ́ ọn. Èmi kò rí ààmì ìbálé rẹ̀.” 15 Nígbà náà ni baba ọmọbìnrin náà àti ìyá rẹ̀ yóò mú ẹ̀rí pé, ó ti wà ní ìbálé tẹ́lẹ̀ wá sí ọ̀dọ̀ àwọn àgbàgbà ìlú ní ẹnu-bodè. 16 Baba obìnrin náà yóò wí fún àwọn àgbàgbà, pé “Mo fi ọmọbìnrin mi fún ọkùnrin yìí láti fẹ́ níyàwó, ṣùgbọ́n ó kórìíra rẹ̀. 17 Ní ìsinsin yìí ó ti sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí i ó sì wí pé, ‘Èmi kò rí ọmọbìnrin rẹ kí ó wà ní wúńdíá.’ Ṣùgbọ́n níhìn-ín yìí ni ẹ̀rí ìbálé ọmọbìnrin mi.” Nígbà náà ni àwọn òbí rẹ̀ yóò fi aṣọ hàn níwájú àwọn àgbàgbà ìlú, 18 àwọn àgbàgbà yóò sì mú ọkùnrin náà, wọn yóò sì jẹ ní yà. 19 Wọn yóò sì gba ìtánràn ọgọ́rùn-ún ṣékélì owó fàdákà fún baba ọmọbìnrin náà, nítorí ọkùnrin yìí ti fi orúkọ búburú fún wúńdíá Israẹli. Yóò sì máa ṣe ìyàwó rẹ̀; kò gbọdọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀ ní gbogbo ayé e rẹ̀.
20 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀sùn náà bá jẹ́ òtítọ́ tí a kò sí rí ẹ̀rí ìbálé obìnrin náà, 21 (A)wọn yóò mú wá sí ẹnu-ọ̀nà ilé baba rẹ̀ níbẹ̀ sì ni àwọn ọkùnrin ìlú rẹ̀ yóò ti sọ ọ́ ní òkúta pa. Ó ti ṣe ohun ìtìjú ní Israẹli nípa ṣíṣe àgbèrè nígbà tí ó wà nílé baba rẹ̀. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín yín.
22 Bí o bá rí ọkùnrin kan tí ó bá ìyàwó ọkùnrin mìíràn lòpọ̀, àwọn méjèèjì ní láti kú. Ẹ ní láti pa ohun búburú kúrò láàrín Israẹli.
23 Bí ó bá ṣẹlẹ̀ wí pé ọkùnrin kan pàdé wúńdíá tí a ti fi fún ni láti fẹ́ láàrín ìlú tí ó sì lòpọ̀ pẹ̀lú u rẹ̀, 24 (B)ìwọ yóò mú àwọn méjèèjì lọ sí ẹnu ibodè ìlú náà kí o sì sọ wọ́n ní òkúta pa nítorí ọmọbìnrin náà wà ní ìlú kò sì kígbe fún ìrànlọ́wọ́, àti ọkùnrin náà nítorí ó ba ìyàwó ọkùnrin mìíràn jẹ́. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ.
25 Ṣùgbọ́n bí ó bá ṣe ìgbẹ́ ní ó ti ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin kan ti pàdé ọmọbìnrin tí a ti fẹ́ ṣọ́nà tí o sì fi tagbára tagbára bá a ṣe, ọkùnrin náà nìkan tí ó ṣe èyí ni yóò kú. 26 Má ṣe fi ohunkóhun ṣe ọmọbìnrin náà; kò ṣẹ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó tọ́ sí ikú. Ẹjọ́ yìí rí bí i ti ẹnìkan tí a gbámú tí ó pa aládùúgbò rẹ̀. 27 Nítorí ọkùnrin náà rí ọmọbìnrin náà ní ìta ibodè, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọbìnrin àfẹ́sọ́nà kígbe, kò sí ẹnìkankan níbẹ̀ láti gbà á kalẹ̀.
28 (C)Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ọkùnrin pàdé wúńdíá tí kò ì tí ì ní àfẹ́sọ́nà tí ó sì fi tipátipá bá a ṣe tí a gbá wọn mú. 29 Ó ní láti san àádọ́ta fàdákà fún baba obìnrin náà, nítorí tí ó ti bà á jẹ́. Kò lè kọ̀ ọ́ sílẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó sì wà láààyè.
30 (D)Ọkùnrin kò gbọdọ̀ fẹ́ ìyàwó baba rẹ̀; kò gbọdọ̀ sọ ìtẹ́ baba rẹ̀ di àìlọ́wọ̀.
Ìgbéyàwó
7 Ní báyìí, nítorí àwọn ohun tí ẹ ṣe kọ̀wé: Ó dára fún ọkùnrin kí ó máa ṣe ni ìdàpọ̀ pẹ̀lú obìnrin. 2 Ṣùgbọ́n nítorí àgbèrè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan gbéyàwó tirẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni kí obìnrin kọ̀ọ̀kan ní ọkọ tirẹ̀. 3 Kí ọkùnrin kí ó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ìyàwó rẹ̀ fún ún, kí ìyàwó fi gbogbo ẹ̀tọ́ ọkọ fún ọkọ rẹ̀. 4 Aya kò láṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ọkọ rẹ̀. Bákan náà ni ọkùnrin tí ó gbéyàwó kò ní àṣẹ lórí ara rẹ̀ mọ́, ara rẹ̀ ti di ti ìyàwó rẹ̀. 5 (A)Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ẹ̀tọ́ tọkọtaya wọ̀nyí dun ara yín, bí kò ṣe nípa ìfìmọ̀ṣọ̀kan, kí ẹ̀yin lè fi ara yín fún àwẹ̀ àti àdúrà, kí ẹ̀yin sì tún jùmọ̀ pàdé, lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ ara wọn kí Satani má ba à dán wọn wò nítorí àìlèmáradúró wọn. 6 Mo sọ èyí fún un yín bí ìmọ̀ràn ní kì í ṣe bí àṣẹ. 7 (B)Ó wù mí kí olúkúlùkù dàbí èmi, ṣùgbọ́n gbogbo ènìyàn kò le jẹ́ bákan náà, Ọlọ́run fún olúkúlùkù ènìyàn ní ẹ̀bùn tirẹ̀, ọ̀kan bí irú èyí àti èkejì bí irú òmíràn.
8 Nítorí náà, mo wí fún àwọn àpọ́n àti opó pé, ó sàn kí wọ́n kúkú wà gẹ́gẹ́ bí èmi tí wà. 9 (C)Ṣùgbọ́n bí wọ́n kò bá lè mú ara dúró, kí wọ́n gbéyàwó tàbí kí wọ́n fẹ́ ọkọ, nítorí pé ó sàn láti gbéyàwó jù láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.