Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 37:23-40

23 Ìlànà ìgbésẹ̀ ènìyàn rere wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá,
    o sì ṣe inú dídùn sí ọ̀nà rẹ̀;
24 Bí ó tilẹ̀ ṣubú a kì yóò ta á nù pátápátá,
    nítorí tí Olúwa di ọwọ́ rẹ̀ mú.

25 Èmi ti wà ni èwe, báyìí èmi sì dàgbà;
    síbẹ̀ èmi kò ì tí ì ri kí a kọ olódodo sílẹ̀,
    tàbí kí irú-ọmọ rẹ̀ máa ṣagbe oúnjẹ.
26 Aláàánú ni òun nígbà gbogbo a máa yá ni;
    a sì máa bùsi i fún ni.

27 Lọ kúrò nínú ibi, kí o sì máa ṣe rere;
    nígbà náà ni ìwọ yóò gbé ní ilẹ̀ náà títí láéláé.
28 Nítorí pé Olúwa fẹ́ràn ìdájọ́ òtítọ́,
    kò sì kọ àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀.

Àwọn olódodo ni a ó pamọ́ títí ayérayé,
    ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ènìyàn búburú ni a ó ké kúrò.
29 Olódodo ni yóò jogún ilẹ̀ náà,
    yóò sì máa gbé ibẹ̀ títí ayérayé.

30 Ẹnu olódodo sọ̀rọ̀ ọgbọ́n,
    ahọ́n rẹ̀ a sì máa sọ̀rọ̀ ìdájọ́.
31 Òfin Ọlọ́run rẹ̀ ń bẹ ní àyà wọn;
    àwọn ìgbésẹ̀ rẹ̀ kì yóò yẹ̀.

32 Ènìyàn búburú ń ṣọ́ olódodo,
    Ó sì ń wá ọ̀nà láti pa á.
33 Olúwa kì yóò fi lé e lọ́wọ́ kì yóò sì dá a lẹ́bi,
    nígbà tí a bá ń ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

34 Dúró de Olúwa,
    kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́.
Yóò sì gbé ọ lékè láti jogún ilẹ̀ náà;
    nígbà tí a bá gé àwọn ènìyàn búburú kúrò ìwọ yóò ri.

35 Èmi ti rí ènìyàn búburú tí ń hu ìwà ìkà,
    ó sì fi ara rẹ̀ gbilẹ̀ bí igi tútù ńlá,
36 ṣùgbọ́n ní ìṣẹ́jú kan sí i ó kọjá lọ, sì kíyèsi, kò sì sí mọ́;
    bi ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé mo wá a kiri, ṣùgbọ́n a kò le è ri.

37 Máa kíyèsi ẹni pípé, kí o sì wo ẹni tó dúró ṣinṣin;
    nítorí àlàáfíà ni òpin ọkùnrin náà.
38 Ṣùgbọ́n àwọn olùrékọjá ni a ó parun papọ̀;
    ìran àwọn ènìyàn búburú ni a ó gé kúrò.

39 Ìgbàlà àwọn onídùúró ṣinṣin wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa;
    òun ni ààbò wọn ní ìgbà ìpọ́njú
40 Olúwa yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ yóò sì gbà wọ́n;
    yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ènìyàn búburú, yóò sì gbà wọ́n là,
    nítorí tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé e.

1 Samuẹli 8:1-18

Israẹli béèrè fún ọba

Nígbà tí Samuẹli di arúgbó, ó yan àwọn ọmọ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí adájọ́ fún Israẹli. Orúkọ àkọ́bí rẹ̀ a máa jẹ́ Joeli àti orúkọ èkejì a máa jẹ́ Abijah, wọ́n ṣe ìdájọ́ ní Beerṣeba. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ rẹ̀, kò rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Wọ́n yípadà sí èrè àìṣòótọ́, wọ́n gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀, wọ́n sì ń yí ìdájọ́ po.

Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn àgbàgbà ti Israẹli péjọpọ̀, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ Samuẹli ní Rama. Wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ ti di arúgbó, àwọn ọmọ rẹ kò sì rìn ní ọ̀nà rẹ: Nísinsin yìí, yan ọba fún wa kí ó lè máa darí wa gẹ́gẹ́ bí i tí gbogbo orílẹ̀-èdè.”

Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n wí pé, “Fún wa ní ọba tí yóò darí wa” Èyí kò tẹ́ Samuẹli lọ́rùn, ó sì gbàdúrà sí Olúwa. Olúwa sì sọ fún Samuẹli pé: “Gbọ́ ohùn àwọn ènìyàn náà, ní gbogbo èyí tí wọ́n sọ fún ọ; nítorí kì í ṣe ìwọ ni wọ́n kọ̀, ṣùgbọ́n Èmi ni wọ́n kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba lórí wọn. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní ọjọ́ tí mo mú wọn jáde wá láti Ejibiti títí di ọjọ́ òní, wọ́n kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ń sin ọlọ́run mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń ṣe sí ọ. Nísinsin yìí, gbọ́ tiwọn; ṣùgbọ́n kìlọ̀ fún wọn dáradára, kí o sì jẹ́ kí wọ́n mọ irú ohun tí ọba tí yóò jẹ́ lórí wọn yóò ṣe.”

10 Samuẹli sọ gbogbo ọ̀rọ̀ Olúwa sí àwọn ọmọ ènìyàn tí ó ń béèrè fún ọba lọ́wọ́ rẹ̀. 11 Ó wí pé, “Èyí ni ohun tí ọba tí yóò jẹ lórí yín yóò ṣe. Yóò kó àwọn ọmọkùnrin yín, yóò sì mú wọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ àti fún ẹlẹ́ṣin rẹ, wọn yóò sì máa sáré níwájú kẹ̀kẹ́ rẹ̀. 12 Yóò yan díẹ̀ láti jẹ́ olórí ẹgbẹ̀rún àti olórí àádọ́ta àti àwọn mìíràn. Yóò yan wọ́n láti máa tulẹ̀ oko rẹ̀ àti láti máa kórè rẹ̀ àti àwọn mìíràn láti máa ṣe ohun èlò ogun àti ohun èlò kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀. 13 Yóò mú àwọn ọmọbìnrin yín láti máa ṣe olùṣe ìkunra olóòórùn dídùn àti láti máa ṣe àsè àti láti máa ṣe àkàrà. 14 Yóò mú èyí tí ó dára jù nínú oko yín, àti nínú ọgbà àjàrà yín àti nínú igi olifi yín, yóò sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 15 Yóò mú ìdásímẹ́wàá hóró ọkà yín àti àká èso àjàrà yín, yóò sì fi fún àwọn oníṣẹ́ àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀. 16 Àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin yín àti èyí tí ó dára jù nínú ẹran ọ̀sìn àti àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ yín ni yóò mú fún ìlò ti ara rẹ̀. 17 Yóò sì mú ìdámẹ́wàá nínú àwọn agbo ẹran yín, yóò sì máa ṣe ẹrú u rẹ̀. 18 Tí ọjọ́ náà bá dé, ẹ̀yin yóò kígbe fún ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ ọba tí ẹ̀yin ti yàn. Olúwa kò sì ní dá a yín lóhùn ní ọjọ́ náà.”

Heberu 6:1-12

Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run, ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. Èyí ní àwa yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́.

Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba. Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run. (A)Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná.

Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. 10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. 11 Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin: 12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.