Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 90:12-17

12 Kọ́ wa bí a ti ń kaye ọjọ́ wa dáradára,
    kí àwa ba à lè fi ọkàn wa sípa ọgbọ́n.

13 Yípadà, Olúwa! Yóò ti pẹ́ tó?
    Ṣàánú fún àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ.
14 Tẹ́ wa lọ́rùn ní òwúrọ̀ nínú ìṣeun ìfẹ́ rẹ,
    kí àwa kí ó lè kọrin fún ayọ̀
    kí inú wa sì dùn ní gbogbo ọjọ́.
15 Mú inú wa dùn bí ọjọ́ tí ìwọ ti pọ́n wa lójú,
    fún ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rí wàhálà.
16 Jẹ́ kí a fi iṣẹ́ rẹ̀ han àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀,
    ògo rẹ̀ sí àwọn ọmọ wọn.

17 Jẹ́ kí ẹwà Olúwa Ọlọ́run wa wà lára wa;
    fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀ lára wa
    bẹ́ẹ̀ ni, kí ó sì fi ìdí iṣẹ́ ọwọ́ wa múlẹ̀.

Amosi 3:13-4:5

13 “Gbọ́ èyí kí o sì jẹ́rìí nípa ilé Jakọbu,” ni Olúwa wí, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun.

14 “Ní ọjọ́ tí mo fìyà jẹ Israẹli lórí ẹ̀ṣẹ̀ wọn,
    Èmi yóò pa pẹpẹ Beteli run;
ìwo pẹpẹ ni a ó ké kúrò
    yóò sì wó lulẹ̀.
15 Èmi yóò wó ilé òtútù
    lulẹ̀ pẹ̀lú ilé ooru;
ilé tí a fi eyín erin ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ yóò ṣègbé
    a ó sì pa ilé ńlá náà run,”
    ni Olúwa wí.

Israẹli kò yípadà sí Ọlọ́run

Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Baṣani lórí òkè Samaria,
    ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni tálákà lára,
    tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”
Olúwa Olódùmarè ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra:
    “Àkókò náà yóò dé nítòótọ́
nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ,
    ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja.
Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọ
    gba àárín odi yíya
    a ó sì lé e yín sí Harmoni,”
    ni Olúwa wí.
“Ẹ lọ sí Beteli láti dẹ́ṣẹ̀;
    ẹ lọ sí Gilgali kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i.
Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá,
    ìdámẹ́wàá yín ní ọdọọdún mẹ́ta.
Kí ẹ mú ọ̀rẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun ìwúkàrà ti a sun
    kí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwá
lọ fi wọ́n yangàn, ẹ̀yin ènìyàn Israẹli,
    nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,”
    ni Olúwa Olódùmarè wí.

Matiu 15:1-9

Ohun mímọ́ àti ohun àìmọ́

15 (A)Nígbà náà ní àwọn Farisi àti àwọn olùkọ́ òfin tọ Jesu wá láti Jerusalẹmu, wọn béèrè pé, “Èéṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ fi ń rú òfin àtayébáyé àwọn alàgbà? Nítorí tí wọn kò wẹ ọwọ́ wọn kí wọ́n tó jẹun!”

Jesu sì dá wọn lóhùn pé, “Èéha ṣe tí ẹ̀yin fi rú òfin Ọlọ́run, nítorí àṣà yín? Nítorí Ọlọ́run wí pé, ‘Bọ̀wọ̀ fún Baba òun ìyá rẹ,’ àti pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí baba tàbí ìyá rẹ̀, ní láti kú.’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá wí fún baba tàbí ìyá rẹ̀ pé, ‘Ẹ̀bùn fún Ọlọ́run ni ohunkóhun tí ìwọ ìbá fi jèrè lára mi;’ Tí Òun kò sì bọ̀wọ̀ fún baba tàbí ìyá rẹ̀, ó bọ́; bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin sọ òfin Ọlọ́run di asán nípa àṣà yín. Ẹ̀yin àgàbàgebè, ní òtítọ́ ni Wòlíì Isaiah sọtẹ́lẹ̀ nípa yín wí pé:

(B)“ ‘Àwọn ènìyàn wọ̀nyí ń fi ẹnu lásán bu ọlá fún mi,
    ṣùgbọ́n ọkàn wọn jìnnà réré sí mi.
Lásán ni ìsìn wọn;
    nítorí pé wọ́n ń fi òfin ènìyàn kọ́ ni ní ẹ̀kọ́.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.