Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 119:97-104

Òfin Olúwa ni ìfẹ́ pípé

97 Báwo ni èmi ti fẹ́ òfin rẹ tó!
    Èmi ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀
ní gbogbo ọjọ́ pípẹ́ wá.
98 Àṣẹ rẹ mú mi gbọ́n ju àwọn ọ̀tá mi lọ,
    nítorí wọ́n wà pẹ̀lú mi láé.
99 Èmi ní iyè inú ju gbogbo olùkọ́ mi lọ,
    nítorí èmi ń ṣe àṣàrò nínú òfin rẹ.
100 Èmi ni òye ju àwọn àgbà lọ,
    nítorí mo gba ẹ̀kọ́ rẹ.
101 Èmi ti pa ẹsẹ̀ mi mọ́ nínú gbogbo ọ̀nà ibi
    nítorí kí èmi lè gba ọ̀rọ̀ rẹ.
102 Èmi kò yà kúrò nínú òfin rẹ,
    nítorí ìwọ fúnrarẹ̀ ni ó kọ́ mi.
103 Báwo ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣe dùn mọ́ mi lẹ́nu tó,
    ó dùn ju oyin lọ ní ẹnu mi!
104 Èmi rí òye gbà nínú ẹ̀kọ́ rẹ;
    nítorí náà èmi kórìíra gbogbo ọ̀nà tí kò tọ́.

Isaiah 33:10-16

10 “Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.
    “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga,
    ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
11 Ìwọ lóyún ìyàngbò,
    o sì bí koríko;
    èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.
12 A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;
    bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13 Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun
    tí mo ti ṣe;
    Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!
14 Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni;
    ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:
“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?
    Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”
15 Ẹni tí ó ń rìn lódodo
    tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,
tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,
    tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn
    tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi
16 Òun náà yóò gbé ní ibi gíga,
    ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.
A ó mú oúnjẹ fún un,
    omi rẹ̀ yóò sì dájú.

Johanu 15:16-25

16 (A)Kì í ṣe ẹ̀yin ni ó yàn mí, ṣùgbọ́n èmi ni ó yàn yín, mo sì fi yín sípò, kí ẹ̀yin kí ó lè lọ, kí ẹ sì so èso, àti kí èso yín lè dúró; kí ohunkóhun tí ẹ bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, kí ó lè fi í fún yín. 17 Nǹkan wọ̀nyí ni mo pàṣẹ fún yín pé, kí ẹ̀yin kí ó fẹ́ràn ara yín.

Ayé kórìíra àwọn ọmọ-ẹ̀yìn

18 (B)“Bí ayé bá kórìíra yín, ẹ mọ̀ pé, ó ti kórìíra mi ṣáájú yín. 19 Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ń ṣe ti ayé, ayé ìbá fẹ́ yin bi àwọn tirẹ̀; gẹ́gẹ́ bi o ṣe ri tí ẹ̀yin kì ń ṣe ti ayé, ṣùgbọ́n èmi ti yàn yín kúrò nínú ayé, nítorí èyí ni ayé ṣe kórìíra yín. 20 (C)Ẹ rántí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fún yín pé, ‘Ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju olúwa rẹ̀ lọ.’ Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọ́n ó ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú: bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọ́n ó sì pa tiyín mọ́ pẹ̀lú. 21 Ṣùgbọ́n gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n yóò ṣe sí yín, nítorí orúkọ mi, nítorí tí wọn kò mọ ẹni tí ó rán mi. 22 (D)Ìbá ṣe pé èmi kò ti wá kí n sì ti bá wọn sọ̀rọ̀, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n di aláìríwí fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 23 Ẹni tí ó bá kórìíra mi, ó kórìíra Baba mi pẹ̀lú. 24 Ìbá ṣe pé èmi kò ti ṣe iṣẹ́ wọ̀n-ọn-nì láàrín wọn tí ẹlòmíràn kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀: ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n sì rí, wọ́n sì kórìíra èmi àti Baba mi. 25 (E)Ṣùgbọ́n èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí a kọ nínú òfin wọn kí ó lè ṣẹ pé, ‘Wọ́n kórìíra mi ní àìnídìí.’

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.