Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 34:9-14

Ẹ bẹ̀rù Olúwa, ẹ̀yin ènìyàn rẹ̀ mímọ́,
    nítorí pé kò sí àìní fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
10 Àwọn ọmọ kìnnìún a máa ṣe aláìní ebi a sì máa pa wọ́n;
    ṣùgbọ́n àwọn tí ó wá Olúwa kì yóò ṣe aláìní ohun tí ó dára.
11 Wá, ẹ̀yin ọmọ mi, fi etí sí mi;
    èmi yóò kọ́ ọ yín ní ẹ̀rù Olúwa.
12 (A)Ta ni nínú yín tí ń fẹ́ ìyè, tí ó sì ń fẹ́ ọjọ́ púpọ̀;
    kí ó lè gbádùn ọjọ́ rere?
13 Pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi
    àti ètè rẹ̀ kúrò ní ẹ̀tàn sísọ.
14 Yà kúrò nínú ibi kí o sì ṣe rere;
    wá àlàáfíà, kí o sì lépa rẹ̀.

Jobu 13:1-19

Jobu gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run

13 “Wò ó, ojú mi ti rí gbogbo èyí rí,
    etí mí sì gbọ́, ó sì ti yé mi.
Ohun tí ẹ̀yin mọ̀, èmi mọ̀ pẹ̀lú,
    èmi kò kéré sí i yin.
Nítòótọ́ èmi ó bá Olódùmarè
    sọ̀rọ̀, èmi sì ń fẹ́ bá Ọlọ́run sọ àsọyé.
Ẹ̀yin fi irọ́ bá mi sọ̀rọ̀,
    oníṣègùn lásán ni gbogbo yín.
Háà! ẹ̀yin kì bá kúkú dákẹ́!
    Èyí ni kì bá sì ṣe ọgbọ́n yín.
Ẹ gbọ́ àwíyé mi nísinsin yìí;
    ẹ sì fetísílẹ̀ sí àròyé ẹnu mi.
Ẹ̀yin fẹ́ sọ ìsọkúsọ fún Ọlọ́run?
    Ki ẹ sì fi ẹ̀tàn sọ̀rọ̀ gbè é?
Ẹ̀yin fẹ́ ṣe ojúsàájú rẹ̀?
    Ẹ̀yin fẹ́ gbèjà fún Ọlọ́run?
Ó ha dára to tí yóò hú àṣírí yín síta,
    Tàbí kí ẹ̀yin tàn án bí ẹnìkan ti í tan ẹnìkejì?
10 Yóò máa bá yín wí nítòótọ́,
    bí ẹ̀yin bá ṣe ojúsàájú ènìyàn níkọ̀kọ̀.
11 Ìwà ọlá rẹ̀ kì yóò bà yín lẹ́rù bí?
    Ìpayà rẹ̀ kì yóò pá yín láyà?
12 Àwọn òwe yín dàbí eérú;
    Bẹ́ẹ̀ ni àwọn odi ìlú yin dàbí amọ̀.

13 “Ẹ pa ẹnu yín mọ́ kúrò lára mi, kí èmi kí ó lè sọ̀rọ̀,
    ki ohun tí ń bọ̀ wá í bá mi, le è máa bọ̀.
14 Ǹjẹ́ nítorí kí ni èmi ṣe ń fi eyín mi bu ẹran-ara mi jẹ,
    Tí mo sì gbé ẹ̀mí mi lé ara mi lọ́wọ́?
15 Bí ó tilẹ̀ pa mí, síbẹ̀ èmi ó máa gbẹ́kẹ̀lé e;
    Ṣùgbọ́n èmi ó máa tẹnumọ́ ọ̀nà mi níwájú rẹ̀.
16 Èyí ni yóò sì ṣe ìgbàlà mi,
    Àgàbàgebè kì yóò wá síwájú rẹ̀.
17 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹnu mi ní ìfarabalẹ̀,
    jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mí dún ni etí yín.
18 Wò ó nísinsin yìí, èmi ti mura ọ̀ràn mi sílẹ̀;
    èmi mọ̀ pé a ó dá mi láre.
19 Ta ni òun ti yóò bá mi ṣàròyé?
    Ǹjẹ́ nísinsin yìí, èmi fẹ́ pa ẹnu mi mọ́,
    èmi ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí mi lọ́wọ́.

Johanu 4:7-26

Obìnrin kan, ará Samaria sì wá láti fà omi: Jesu wí fún un pé ṣe ìwọ yóò fún mi ni omi mu. Nítorí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti lọ sí ìlú láti lọ ra oúnjẹ.

(A)Obìnrin ará Samaria náà sọ fún un pé, “Júù ni ìwọ, obìnrin ará Samaria ni èmi. Èétirí tí ìwọ ń béèrè ohun mímu lọ́wọ́ mi?” (Nítorí tí àwọn Júù kì í bá àwọn ará Samaria ṣe pọ̀.)

10 (B)Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

11 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, ìwọ kò ní igbá-ìfami tí ìwọ ó fi fà omi, bẹ́ẹ̀ ni kànga náà jì: Níbo ni ìwọ ó ti rí omi ìyè náà? 12 Ìwọ pọ̀ ju Jakọbu baba wa lọ bí, ẹni tí ó fún wa ní kànga náà, tí òun tìkára rẹ̀ si mu nínú rẹ̀, àti àwọn ọmọ rẹ̀, àti àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀?”

13 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi yìí, òǹgbẹ yóò sì tún gbẹ ẹ́: 14 (C)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

15 (D)Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

16 Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ, kí ó sì padà wá sí ìhín yìí.”

17 Obìnrin náà dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Èmi kò ní ọkọ.”

Jesu wí fún un pé, “Ìwọ́ dáhùn dáradára pé, èmi kò ní ọkọ: 18 (E)Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

19 Obìnrin náà wí fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé, wòlíì ni ìwọ ń ṣe. 20 (F)Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

21 (G)Jesu wí fún un pé, “Gbà mí gbọ́ obìnrin yìí, àkókò náà ń bọ̀, nígbà tí kì yóò ṣe lórí òkè yìí tàbí ní Jerusalẹmu ni ẹ̀yin ó máa sin Baba. 22 (H)Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá. 23 Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́: nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24 (I)Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

25 Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi: Nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

26 (J)Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.