Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 107:1-3

ÌWÉ KARÙN-ÚN

Saamu 107–150

107 Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun;
    nítorí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.

Jẹ́ kí àwọn ẹni ìràpadà Olúwa kí ó wí báyìí, àwọn
    ẹni tí ó rà padà kúrò lọ́wọ́ ọ̀tá,
Àwọn tí ó kójọ láti ilẹ̀ wọ̀n-ọn-nì
    láti ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn,
    láti àríwá àti Òkun wá.

Saamu 107:33-43

33 Ó sọ odò di aginjù,
    àti orísun omi di ilẹ̀ gbígbẹ.
34 Ilẹ̀ eléso di aṣálẹ̀
    nítorí ìwà búburú àwọn tí ó wà nínú rẹ̀;
35 O sọ aginjù di adágún omi àti
    ilẹ̀ gbígbẹ di orísun omi
36 Níbẹ̀ ó mú ẹni tí ebi ń pa wà,
    wọ́n sì pilẹ̀ ibi tí wọn ó máa gbé
37 Wọn fún irúgbìn, wọ́n sì gbin ọgbà àjàrà
    tí yóò máa so èso tí ó dára;
38 Ó bùkún wọn, wọ́n sì pọ̀ sí i ní iye
    kò sí jẹ́ kí ẹran ọ̀sìn wọn kí ó dínkù.

39 Nígbà náà, ọjọ́ wọn kúrú,
    ìnira, ìpọ́njú àti ìṣòro wọn sì dínkù
40 Ẹni tí ó da ẹ̀gàn lu ọmọ-aládé
    ó sì mú wọn rìn níbi tí ọ̀nà kò sí
41 Ṣùgbọ́n ó gbé aláìní sókè kúrò nínú ìnira
    ó mú ìdílé wọn pọ̀ bí agbo ẹran
42 Àwọn tí ó dúró sì rí i, inú wọn sì dùn
    ṣùgbọ́n gbogbo olùṣe búburú yóò pa ẹnu rẹ̀ mọ́.

43 Ẹni tí ó bá gbọ́n, jẹ́ kí ó kíyèsi nǹkan wọ̀nyí
    kí ó wo títóbi ìfẹ́ Olúwa.

Isaiah 55:1-9

Ìpè sí àwọn tí òrùngbẹ n gbẹ

55 (A)“Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òǹgbẹ ń gbẹ,
    ẹ wá sí ibi omi;
àti ẹ̀yin tí kò ní owó;
    ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!
Ẹ wá ra wáìnì àti wàrà
    láìsí owó àti láìdíyelé.
Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrà
    àti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?
Tẹ́tí sílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,
    bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.
(B)Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ mi
    gbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láààyè.
Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lú rẹ,
    ìfẹ́ òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dafidi.
Kíyèsi i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,
    olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.
Lóòtítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀
    àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,
Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ
    Ẹni Mímọ́ Israẹli
    nítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”

Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;
    ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.
Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀
    àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.
Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,
    àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjì.

“Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,
    tàbí ọ̀nà yín a ha máa ṣe ọ̀nà mi,”
    ni Olúwa wí.
“Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,
    bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọ
    àti èrò mi ju èrò yín lọ.

Marku 8:1-10

Jesu bọ́ ẹgbàajì ènìyàn

(A)Ní ọjọ́ kan, bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ, kò sí oúnjẹ fún wọn mọ́ láti jẹ. Jesu pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Ó wí fún wọn pé, “Àánú ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ṣe mí nítorí pé ó tó ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n ti wà níhìn-ín, kò sì sí ohun kan tí ó kù sílẹ̀ fún wọn láti jẹ. Bí mo bá sọ fún wọn láti máa lọ sí ilé wọn bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ebi, wọn yóò dákú lójú ọ̀nà, nítorí pé àwọn mìíràn nínú wọn ti ọ̀nà jíjìn wá.”

Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè pé, “Níbo ni a ó ti rí àkàrà tí ó tó láti fi bọ́ wọn nínú aṣálẹ̀ yìí?”

Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “ìṣù àkàrà mélòó lẹ ní lọ́wọ́?”

Wọ́n fèsì pé, “ìṣù àkàrà méje.”

Nítorí náà, ó pàṣẹ fún àwọn ènìyàn náà láti jókòó lórí ilẹ̀. Ó sì mú odindi àkàrà méje náà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ó sì bù wọ́n sí wẹ́wẹ́, ó pín wọn fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti gbé ka iwájú àwọn ènìyàn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Wọ́n rí àwọn ẹja wẹ́wẹ́ díẹ̀ pẹ̀lú. Jesu tún dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìpèsè náà, ó sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ láti pín wọn fún àwọn ènìyàn náà. Gbogbo ọ̀pọ̀ ènìyàn náà ló jẹ àjẹyó àti àjẹtẹ́rùn. Lẹ́yìn èyí wọ́n kó àjẹkù ti ó kù jọ, agbọ̀n méje sì kún. Àwọn tí ó jẹ ẹ́ tó ìwọ̀n ẹgbàajì (4,000) ènìyàn, ó sì rán wọn lọ. 10 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, lẹ́yìn èyí, Jesu wọ inú ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì gúnlẹ̀ sí agbègbè Dalmanuta.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.