Revised Common Lectionary (Complementary)
23 Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run,
ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀;
24 (A)Ó rọ manna fún àwọn ènìyàn láti jẹ,
ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run.
25 Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli;
Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó,
26 Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá
ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀.
27 Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀,
àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun
28 Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn,
yíká àgọ́ wọn.
29 Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ
nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún
Òfin Àjọ ìrékọjá
43 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé, “Ìwọ̀n yìí ni àwọn òfin fún àjọ ìrékọjá:
“Àjèjì kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀. 44 Ẹrú tí ẹ̀yin bá rà lè jẹ́ nínú rẹ̀ lẹ́yìn tí ẹ̀yin bá ti kọ ọ́ ní ilà, 45 Ṣùgbọ́n àtìpó àti alágbàṣe kò ni jẹ nínú rẹ̀.
46 (A)“Nínú ilé ni ẹ ti gbọdọ̀ jẹ ẹ́; ẹ kò gbọdọ̀ mú èyíkéyìí nínú ẹran náà jáde kúrò nínú ilé. Ẹ má ṣe ṣẹ́ ọ̀kankan nínú egungun rẹ̀. 47 Gbogbo àjọ Israẹli ni ó gbọdọ̀ ṣe àjọyọ̀ ọ rẹ̀.
48 “Àjèjì ti ó bá ń gbé ní àárín yín ti ó bá fẹ́ kópa nínú àjọ ìrékọjá Olúwa, ni o gbọdọ̀ kọ gbogbo àwọn ọmọkùnrin ilé rẹ̀ ní ilà; ní ìgbà náà ni ó lè kó ipa gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ tí a bí ní ilẹ̀ náà. Gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí a kò bá kọ ní ilà, wọ́n kò ni jẹ nínú rẹ̀. 49 (B)Òfin yìí kan náà ni ó mú àwọn ọmọ tí a bí ni ilẹ̀ náà àti àwọn àlejò tí ń gbé ní àárín yín.”
50 Gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose àti Aaroni. 51 Àti pé ní ọjọ́ náà gan an ni Olúwa mú àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti gẹ́gẹ́ bí ìpín ìpín wọn.
Ìyàsímímọ́ àwọn àkọ́bí
13 Olúwa sọ fún Mose pé, 2 (C)“Ẹ ya àwọn àkọ́bí yín ọkùnrin sọ́tọ̀ fún mi. Èyí ti ó bá jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn ọmọ Israẹli jẹ́ tèmi, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko.”
27 Nítorí náà tí ẹnikẹ́ni bá jẹ lára àkàrà yìí, tí ẹ sì ń mu nínú ago Olúwa yìí, ní ọ̀nà tí kò bójúmu, yóò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ sí ara àti ẹ̀jẹ̀ Olúwa. 28 Ìdí nìyìí tí ó fi yẹ kí ènìyàn yẹ ara rẹ̀ wò dáradára kí ó tó jẹ lára àkàrà nà án àti kí ó tó mu nínú ago náà. 29 Nítorí tí ẹ bá jẹ lára àkàrà, tí ẹ sì mu nínú ago láìyẹ, tí ẹ kò ronú ara Kristi àti nǹkan tí ó túmọ̀ sí, ẹ̀ ń jẹ, ẹ sì ń mú ẹ̀bi ìdájọ́ Ọlọ́run wá sórí ara yín. 30 Ìdí nìyìí tí ọ̀pọ̀ yín fi di ẹni tí kò lágbára mọ́, tí ọ̀pọ̀ yín sì ń ṣàìsàn, àwọn mìíràn nínú yín tilẹ̀ ti sùn. 31 Ṣùgbọ́n tí ẹ bá yẹ ara yín wò dáradára, kí ẹ tó jẹ ẹ́, a kì yóò dá yín lẹ́jọ́. 32 (A)Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá dá wa lẹ́jọ́, láti ọwọ́ Olúwa ni a ti nà wá, kí a má ba à dá wa lẹ́bi pẹ̀lú ayé.
33 Nítorí náà, ẹ̀yin arákùnrin mi ọ̀wọ́n, nígbàkúgbà ti ẹ bá péjọ láti jẹ́ oúnjẹ alẹ́ Olúwa, tàbí fún ìsìn oúnjẹ alẹ́ Olúwa, ẹ dúró de ara yín. 34 (B)Bí ebi bá ń pa ẹnikẹ́ni nínú yin, kí ó jẹun láti ilé wá, kí ó má ba á mú ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ nígbà tí ẹ bá péjọ.
Tí mo bá dé, èmi yóò máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn kókó-ọ̀rọ̀ ìyókù tí n kò ì ti fẹnu bà lẹ́sẹẹsẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.