Revised Common Lectionary (Complementary)
Ti Dafidi.
25 Olúwa,
ìwọ ni mo gbé ọkàn mi sókè sí.
2 Ọlọ́run, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ;
Má ṣe jẹ́ kí ojú ó tì mí
Má ṣe jẹ́ kí àwọn ọ̀tá mi ó yọ̀ mí.
3 Ẹni tí ó dúró tì ọ́
ojú kì yóò tì í,
àwọn tí ń ṣẹ̀ láìnídìí
ni kí ojú kí ó tì.
4 Fi ọ̀nà rẹ hàn mí, Olúwa,
kọ mi ní ipa tìrẹ;
5 ṣe amọ̀nà mi nínú òtítọ́ ọ̀ rẹ, kí o sì kọ́ mi,
Nítorí ìwọ ni Ọlọ́run ìgbàlà mi;
ìwọ ni mo dúró tì ní gbogbo ọjọ́.
6 Rántí, Olúwa àánú àti ìfẹ́ ẹ̀ rẹ̀ ńlá,
torí pé wọ́n ti wà ní ìgbà àtijọ́
7 Má ṣe rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ìgbà èwe mi
tàbí ìrékọjá mi;
gẹ́gẹ́ bí i ìfẹ́ ẹ rẹ̀ rántí mi
nítorí tí ìwọ dára, Ìwọ! Olúwa.
8 Rere àti ẹni ìdúró ṣinṣin ní Olúwa:
nítorí náà, ó kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ọ̀nà náà.
9 Ó ṣe amọ̀nà àwọn onírẹ̀lẹ̀ ni ohun tí ó dára,
ó sì kọ́ àwọn onírẹ̀lẹ̀ ní ọ̀nà rẹ̀.
17 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, jẹ oúnjẹ rẹ pẹ̀lú ìwárìrì, sì mu omi rẹ pẹ̀lú ìwárìrì àti àìbalẹ̀ àyà. 19 Sọ fún àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn olùgbé Jerusalẹmu àti ilẹ̀ Israẹli pé: Pẹ̀lú àìbalẹ̀ àyà ni wọn yóò máa jẹun wọn, wọn yóò sì mu omi pẹ̀lú àìnírètí, kí ilẹ̀ wọn lè di ahoro torí ìwà ipá àwọn tó ń gbé ibẹ̀. 20 Ìlú tó jẹ́ ibùgbé ènìyàn tẹ́lẹ̀ yóò di òfo, ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa.’ ”
21 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 22 “Ọmọ ènìyàn, irú òwe wo ni ẹ pa nílẹ̀ Israẹli pé: ‘A fa ọjọ́ gùn, gbogbo ìran di asán’? 23 Nítorí náà wí fún wọn pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi yóò fi òpin sí òwe yìí, wọn kò ní ipa mọ́ ní Israẹli.’ Sọ fún wọn, ‘Ọjọ́ náà súnmọ́ tòsí nígbà tí gbogbo ìran àti ìsọtẹ́lẹ̀ yóò sì wá sí ìmúṣẹ. 24 Nítorí kò ní sí ìran asán tàbí àfọ̀ṣẹ tí ó ń pọ́n ni mọ́ ní àárín ilé Israẹli. 25 Ṣùgbọ́n Èmi Olúwa yóò sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ tí mo sọ yóò sì ṣẹ láì falẹ̀. Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, ní àsìkò yín, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀ ilé ni Èmi yóò mú ọ̀rọ̀ yówù tí mo bá sọ ṣẹ.’ ”
26 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá pé: 27 “Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ń wí pé, ‘Ìran ọjọ́ pípẹ́ ni ìwọ rí, ìwọ sì sọtẹ́lẹ̀ nípa àsìkò tó jìnnà réré.’
28 “Nítorí náà sọ fún wọn, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kò sí ọ̀kan nínú ọ̀rọ̀ mi tí yóò sún síwájú mọ́; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí mo bá sọ yóò ṣẹ.’ ”
11 Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́. 12 Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?
Má ṣe ìlérí nípa ọjọ́ ọ̀la
13 Ẹ wá nísinsin yìí, ẹ̀yin tí ó ń wí pé, “Lónìí tàbí lọ́la àwa ó lọ sí ìlú báyìí, a ó sì ṣe ọdún kan níbẹ̀, a ó sì ṣòwò, a ó sì jèrè.” 14 Nígbà tí ẹ̀yin kò mọ ohun tí yóò hù lọ́la. Kí ni ẹ̀mí yín? Ìkùùkuu sá à ni yín, tí ó hàn nígbà díẹ̀, lẹ́yìn náà a sì túká lọ. 15 Èyí tí ẹ̀ bá fi wí pé, “Bí Olúwa bá fẹ́, àwa yóò wà láààyè, àwa ó sì ṣe èyí tàbí èyí i nì.” 16 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ẹ̀yin ń gbéraga nínú ìfọ́nnu yín, gbogbo irú ìfọ́nnu bẹ́ẹ̀, ibi ni.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.