Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 15:15-21

15 Ó yé ọ, ìwọ Olúwa rántí mi kí o
    sì ṣe ìtọ́jú mi; gbẹ̀san mi lára
àwọn tó dìtẹ̀ mi. Ìwọ ti jìyà fún
    ìgbà pípẹ́, má ṣe mú mi lọ, nínú bí
    mo ṣe jìyà nítorí tìrẹ.
16 Nígbà tí ọ̀rọ̀ rẹ dé, mo jẹ wọ́n
    Àwọn ni ìdùnnú àti ayọ̀ ọkàn mi
Nítorí pé orúkọ rẹ ni a fi ń pè mí
    Ìwọ Olúwa Ọlọ́run Alágbára.
17 Èmi kò fìgbà kan jókòó láàrín àwọn ẹlẹ́gàn.
    N ko bá wọn yọ ayọ̀ pọ̀;
mo dá jókòó torí pé ọwọ́ rẹ wà
    lára mi, ìwọ sì ti fi ìbínú rẹ kún inú mi.
18 Èéṣe tí ìrora mi kò lópin,
    tí ọgbẹ́ mi kò sì ṣe é wòsàn?
Ní òtítọ́ ìwọ yóò dàbí kànga ẹ̀tàn sí mi,
    gẹ́gẹ́ bí ìsun tó kọ̀ tí kò sun?

19 Nítorí náà báyìí ni Olúwa wí:

“Tí o bá ronúpìwàdà, Èmi ó dá ọ padà
    wá kí o lè máa sìn mí. Tí ó bá
sọ ọ̀rọ̀ tó dára ìwọ yóò di agbẹnusọ
    mi. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí kọjú sí ọ;
    ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ kọjú sí wọn
20 Èmi fi ọ́ ṣe odi idẹ tí ó lágbára
    sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí. Wọn ó bá ọ jà
ṣùgbọ́n, wọn kò ní lè borí rẹ
    nítorí pé, mo wà pẹ̀lú rẹ láti gbà ọ́ là,
kí n sì dáàbò bò ọ́,”
    ni Olúwa wí.
21 “Èmi yóò gbà ọ́ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn
    ìkà ènìyàn, Èmi yóò sì rà ọ́
    padà kúrò lọ́wọ́ àwọn ẹni búburú.”

Saamu 26:1-8

Ti Dafidi.

26 Ṣe ìdájọ́ mi, Olúwa,
    nítorí tí mo ti ń rìn nínú ìwà òtítọ́ ọ̀ mi,
mo sì ti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa
    Ǹjẹ́ ẹsẹ̀ mi kì yóò yẹ̀.
Wádìí mi wò, Ìwọ Olúwa, kí o sì dán mi wò,
    dán àyà àti ọkàn mi wò;
Nítorí ìfẹ́ ẹ̀ rẹ tí ó dúró ṣinṣin ń bẹ níwájú mi,
    èmí sì ti rìn nínú òtítọ́ rẹ.

Èmi kò jókòó pẹ̀lú aláìṣòótọ́,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá àwọn àgàbàgebè wọlé;
Èmi ti kórìíra àwùjọ àwọn ènìyàn búburú
    èmi kì yóò sì bá àwọn ènìyàn ìkà jókòó.
Èmí ó wẹ ọwọ́ mi ní àìlẹ́ṣẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì yí pẹpẹ rẹ ká Olúwa.
Èmi yóò kọrin sókè àní orin ọpẹ́,
    èmi yóò sì máa sọ iṣẹ́ ìyanu rẹ̀.

Háà Olúwa, èmí ń fẹ́ ilé rẹ níbi tí ìwọ ń gbé,
    àní níbi tí ògo rẹ̀ wà.

Romu 12:9-21

Ẹ̀kọ́ nípa ìfẹ́

Kí ìfẹ́ kí ó wà ní àìṣẹ̀tàn. Ẹ máa takété sí ohun tí í ṣe búburú; ẹ fi ara mọ́ ohun tí í ṣe rere. 10 Ní ti ìfẹ́ ará, ẹ máa fi ìyọ́nú fẹ́ràn ara yín; ní ti ọlá, ẹ máa fi ẹnìkejì yín ṣáájú. 11 Ní ti iṣẹ́ ṣíṣe, ẹ má ṣe ọ̀lẹ; ẹ máa ní ìgbóná ọkàn; ẹ máa sìn Olúwa. 12 (A)Ẹ máa yọ̀ ni ìrètí; ẹ máa mú sùúrù nínú ìpọ́njú; ẹ máa dúró gbọingbọin nínú àdúrà. 13 Ẹ máa pèsè fún àìní àwọn ènìyàn mímọ́; ẹ fi ara yín fún àlejò ṣíṣe.

14 (B)Ẹ máa súre fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; ẹ máa súre, ẹ má sì ṣépè. 15 Àwọn tí ń yọ̀, ẹ máa bá wọn yọ̀, àwọn tí ń sọkún, ẹ máa bá wọn sọkún. 16 (C)Ẹ máa wà ní inú kan náà sí ara yín. Ẹ má ṣe gbéraga, ṣùgbọ́n ẹ má tẹ̀lé àwọn onírẹ̀lẹ̀. Ẹ má ṣe jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín.

17 (D)Ẹ má ṣe fi búburú san búburú fún ẹnikẹ́ni. Ẹ má pèsè ohun tí ó tọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. 18 (E)Bí ó bá sé é ṣe, bí ó ti wà ní ipa tiyín, ẹ má wà ní àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn. 19 (F)Olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ṣùgbọ́n ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún ìbínú Ọlọ́run; nítorí a ti kọ ọ́ pé, Olúwa wí pé, “Tèmi ni ẹ̀san, èmi ó gbẹ̀san.” 20 (G)Ní òdìkejì ẹ̀wẹ̀,

“Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ;
    bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mu.
Ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó kó ẹ̀yín iná lé e ní orí.”

21 Má ṣe jẹ́ kí búburú ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n fi rere ṣẹ́gun búburú.

Matiu 16:21-28

Jesu sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú ara rẹ̀

21 (A)(B) Láti ìgbà yìí lọ, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí ṣàlàyé fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ kedere nípa lílọ sí Jerusalẹmu láti jẹ ọ̀pọ̀ ìyà lọ́wọ́ àwọn àgbàgbà, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé, kí a sì pa òun, àti ní ọjọ́ kẹta, kí ó sì jíǹde.

22 Peteru mú Jesu sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí pé, “Kí a má rí i Olúwa! Èyí kì yóò ṣẹlẹ̀ sí Ọ!”

23 (C)Jesu pa ojú dà, ó sì wí fún Peteru pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani! Ohun ìkọ̀sẹ̀ ni ìwọ jẹ́ fún mi; ìwọ kò ro ohun tí i ṣe ti Ọlọ́run, bí kò ṣe èyí ti ṣe ti ènìyàn.”

24 (D)Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn. 25 Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀ là, yóò sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù nítorí mi, yóò rí i. 26 Èrè kí ni ó jẹ́ fún ènìyàn bí ó bá jèrè gbogbo ayé yìí, tí ó sì sọ ẹ̀mí rẹ̀ nù? Tàbí kí ni ènìyàn yóò fi dípò ẹ̀mí rẹ̀? 27 Nítorí Ọmọ ènìyàn yóò wá nínú ògo baba rẹ pẹ̀lú àwọn angẹli rẹ̀, nígbà náà ni yóò sì san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

28 “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín. Ẹlòmíràn wà nínú àwọn tí ó wà níhìn-ín yìí, tí kì yóò ri ikú títí wọn ó fi rí Ọmọ ènìyàn tí yóò máa bọ̀ ní ìjọba rẹ̀.”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.