Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Revised Common Lectionary (Complementary)

Daily Bible readings that follow the church liturgical year, with thematically matched Old and New Testament readings.
Duration: 1245 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Saamu 103:1-7

Ti Dafidi.

103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
    tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
    ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
    kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.

Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
    gbogbo àwọn tí a ni lára.

Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;

Saamu 103:8-13

(A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
    ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
Òun kì í bá ni wí ní ìgbà gbogbo
    bẹ́ẹ̀ ni kì í pa ìbínú rẹ mọ́ láéláé;
10 Òun kì í ṣe sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ wa
    bẹ́ẹ̀ ni kì í san án fún wa gẹ́gẹ́
bí àìṣedéédéé wa.
11 Nítorí bí ọ̀run ṣe ga sílẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ tóbi sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.
12 Bí ìlà-oòrùn ti jìnnà sí ìwọ̀-oòrùn
    bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe mú ìrékọjá wá jìnnà sí wa.

13 Bí baba ti ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn ọmọ rẹ̀,
    bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ń ṣe ìyọ́nú sí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀;

Gẹnẹsisi 41:53-42:17

53 Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Ejibiti, 54 (A)Ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Josẹfu ti wí gan an. Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tókù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 55 (B)Nígbà tí àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Farao. Nígbà náà ni Farao wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Josẹfu, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.”

56 Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Josẹfu ṣí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan an ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 57 Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń wá sí Ejibiti láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Josẹfu, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.

Àwọn arákùnrin Josẹfu lọ sí Ejibiti

42 Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” (C)“Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.”

Nígbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Josẹfu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ra ọkà. Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i. (D)Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú.

Nísinsin yìí, Josẹfu ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, òun sì ni ó ń bojútó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Josẹfu. Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?”

Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.”

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Josẹfu mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n. (E)Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Ayọ́lẹ̀wò (Amí) ni yín, ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”

10 Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni, 11 Ọmọ baba ni wá, olóòtítọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.”

12 Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”

13 Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kenaani. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”

14 Josẹfu wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni: Ayọ́lẹ̀wò ni yín! 15 Èyí sì ni a ó fi dán an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Farao bá wà láààyè, ẹ kì yóò kúrò níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá sí ibí. 16 Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú túbú, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Farao ti ń bẹ láààyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!” 17 Ó sì fi gbogbo wọn sínú túbú fún ọjọ́ mẹ́ta.

Ìṣe àwọn Aposteli 7:9-16

(A)(B) “Àwọn baba ńlá sí ṣe ìlara Josẹfu, wọ́n sì tà á sí Ejibiti; ṣùgbọ́n Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀, 10 (C)ó sì yọ ọ́ kúrò nínú ìpọ́njú rẹ̀ gbogbo. Ó sì fún Josẹfu ní ọgbọ́n, ó sì mú kí ó rí ojúrere Farao ọba Ejibiti; òun sì fi jẹ baálẹ̀ Ejibiti àti gbogbo ilé rẹ̀.

11 (D)“Ìyàn kan sì mú ni gbogbo ilẹ̀ Ejibiti àti ni Kenaani, àti ìpọ́njú ńlá, àwọn baba wa kò sì rí oúnjẹ. 12 (E)Ṣùgbọ́n nígbà tí Jakọbu gbọ́ pé alikama ń bẹ ni Ejibiti, ó rán àwọn baba wa lọ lẹ́ẹ̀kínní. 13 (F)Nígbà kejì Josẹfu fi ara rẹ̀ hàn fún àwọn arákùnrin rẹ̀, a sì tún fi wọ́n hàn fún Farao. 14 (G)(H)Lẹ́yìn èyí, Josẹfu ránṣẹ́ pe Jakọbu baba rẹ̀, àti àwọn ìbátan rẹ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ, gbogbo wọ́n sì tó àrùndínlọ́gọ́rin ọkàn. 15 Nígbà náà ni Jakọbu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti, ní ibi tí òun àti àwọn baba wa kú sí. 16 (I)A sì gbé òkú wọn padà wá sí Ṣekemu, a sì tẹ́ wọn sínú ibojì ti Abrahamu rà ni ọwọ́ àwọn ọmọ Amori ní Ṣekemu ní iye owó wúrà kan.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.