Revised Common Lectionary (Complementary)
Ti Dafidi.
103 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi; àti gbogbo ohun tí ó wà nínú mi, yín orúkọ rẹ̀ mímọ́.
2 Yin Olúwa, ìwọ ọkàn mi, kí o má ṣe gbàgbé gbogbo oore rẹ̀
3 Ẹni tí ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ jì ọ́
tí ó sì wo gbogbo ààrùn rẹ̀ sàn,
4 Ẹni tí ó ra ẹ̀mí rẹ padà kúrò nínú kòtò ikú
ẹni tí ó fi ìṣeun ìfẹ́ àti ìyọ́nú dé ọ ní adé,
5 Ẹni tí ó fi ohun dídára tẹ́ ọ lọ́rùn
kí ìgbà èwe rẹ̀ lè di ọ̀tún bí ti ẹyẹ idì.
6 Olúwa ń ṣe òdodo àti ìdájọ́ fún
gbogbo àwọn tí a ni lára.
7 Ó fi ọ̀nà rẹ̀ hàn fún Mose, iṣẹ́ rẹ̀ fun àwọn ọmọ Israẹli;
8 (A)Olúwa ni aláàánú àti olóore,
ó lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ ní ìfẹ́.
Ìjìyà fún rírú òfin ọjọ́ ìsinmi
32 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli wà nínú aginjù, wọ́n rí ọkùnrin kan tí ń ṣá igi ní ọjọ́ Ìsinmi. 33 Àwọn tó sì rí i níbi tó ti ń ṣá igi wọ́n sì mú un wá sí ọ̀dọ̀ Mose àti Aaroni àti síwájú gbogbo ìjọ ènìyàn; 34 Wọ́n fi sí ìpamọ́ nítorí pé ohun tí wọn ó ṣe fún un kò tí ì yé wọn. 35 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mose pé, “Kíkú ni ọkùnrin náà yóò kú kí gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli sọ ọ́ lókùúta pa ní ẹ̀yìn ibùdó.” 36 Wọ́n mú un jáde sí ẹ̀yìn ibùdó, gbogbo ìjọ ènìyàn sì sọ ọ́ lókùúta pa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.
Wajawaja lára aṣọ
37 Olúwa sọ fún Mose pé, 38 (A)“Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, kí o sọ fún wọn pé: ‘Títí dé àwọn ìran tó ń bọ̀ ni kí wọn máa ṣe wajawaja sí etí aṣọ wọn, kí wọn sì fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ búlúù sí wajawaja kọ̀ọ̀kan. 39 Wajawaja yìí ni ẹ sì máa wọ̀ láti lè mú yín rántí gbogbo òfin Olúwa, kí ẹ bá à lè ṣe wọ́n, kí ẹ sì má bá à ṣe àgbèrè nípa títẹ̀lé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn àti ojú yín. 40 Nígbà náà ni ẹ ó gbọ́rọ̀ láti pa gbogbo òfin mi mọ́, ẹ ó sì jẹ́ mímọ́ sí Ọlọ́run yín. 41 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti Ejibiti láti jẹ́ Ọlọ́run yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.’ ”
3 Máa ro ti ẹni tí ó faradà irú ìṣọ̀rọ̀-òdì yìí láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ si ara rẹ̀, kí ẹ má ba á rẹ̀wẹ̀sì ni ọkàn yín, kí àárẹ̀ si mu yín.
4 Ẹ̀yin kò sá à tí ì kọ ojú ìjà si ẹ̀ṣẹ̀ títí dé títa ẹ̀jẹ̀ yín sílẹ̀ nínú ìjàkadì yín. 5 (A)Ẹ̀yin sì ti gbàgbé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ó n ba yin sọ̀rọ̀ bí ọmọ pé,
“Ọmọ mi, ma ṣe aláìnání ìbáwí Olúwa,
kí o má sì ṣe rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí a bá ń ti ọwọ́ rẹ̀ ba ọ wí:
6 Nítorí pé ẹni ti Olúwa fẹ́, òun ni i bá wí,
a sì máa na olúkúlùkù ọmọ tí òun tẹ́wọ́gbà.”
7 Ẹ máa ní sùúrù lábẹ́ ìbáwí: Ọlọ́run bá wa lò bí ọmọ ni; nítorí pé ọmọ wo ni ń bẹ ti baba kì í bá wí? 8 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin ba wà láìsí ìbáwí, nínú èyí tí gbogbo ènìyàn ti jẹ alábápín, ǹjẹ́ ọmọ àlè ni yín, ẹ kì í sì ṣe ọmọ. 9 Pẹ̀lúpẹ̀lú àwa ni baba wa nípa ti ara tí o ń tọ́ wa, àwa sì ń bu ọlá fún wọn: kò ha yẹ kí a kúkú tẹríba fún Baba àwọn ẹ̀mí, kí a sì yè? 10 Nítorí wọ́n tọ́ wa fún ọjọ́ díẹ̀ bí o bá ti dára lójú wọn; ṣùgbọ́n òun (tọ́ wa) fún èrè wa, kí àwa lè ṣe alábápín ìwà mímọ́ rẹ̀. 11 Gbogbo ìbáwí kò dàbí ohun ayọ̀ nísinsin yìí bí kò ṣe ìbànújẹ́; ṣùgbọ́n níkẹyìn yóò so èso àlàáfíà fún àwọn tí a tọ́ nípa rẹ̀, àní èso òdodo.
12 (B)Nítorí náà, ẹ na ọwọ́ tí ó rọ, àti eékún àìlera; 13 (C)“Kí ẹ sì ṣe ipa ọ̀nà tí ó tọ́ fún ẹsẹ̀ yin,” kí èyí tí ó rọ má bá a kúrò lórí ike ṣùgbọ́n kí a kúkú wò ó sàn.
Ìkìlọ̀ lòdì sí kíkọ Ọlọ́run
14 Ẹ máa lépa àlàáfíà pẹ̀lú ènìyàn gbogbo, àti ìwà mímọ́, láìsí èyí yìí kò sí ẹni tí yóò rí Olúwa: 15 (D)Ẹ máa kíyèsára kí ẹnikẹ́ni má ṣe kùnà oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run; kí “gbòǹgbò ìkorò” kan máa ba hù sókè kí ó sì yọ yín lẹ́nu, ọ̀pọ̀lọpọ̀ a sì ti ipa rẹ̀ di àìmọ́. 16 (E)Kí o má bá à si àgbèrè kan tàbí aláìwà-bí-Ọlọ́run bi Esau, ẹni tí o tìtorí òkèlè oúnjẹ kan ta ogún ìbí rẹ̀. 17 (F)Nítorí ẹ̀yin mọ pé lẹ́yìn náà, nígbà tí ó fẹ́ láti jogún ìbùkún náà, a kọ̀ ọ́, nítorí kò ri ààyè ìrònúpìwàdà, bí o tilẹ̀ jẹ́ pé ó fi omijé wa a gidigidi.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.