Revised Common Lectionary (Complementary)
16 Ṣùgbọ́n èmi pe Ọlọ́run;
Olúwa yóò sì gbà mí.
17 Ní alẹ́, ní òwúrọ̀ àti ní ọ̀sán
èmi sọkún jáde nínú ìpọ́njú,
o sì gbọ́ ohùn mi.
18 Ó rà mí padà láìléwu
kúrò nínú ogun tí ó dìde sí mi,
nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó dìde sí mi.
19 Ọlọ́run yóò gbọ́, yóò sì pọ́n wọn lójú
àní, ẹni tí ó ti jókòó láti ìgbàanì—Sela.
Nítorí tí wọn kò ní àyípadà,
tí wọn kò sì bẹ̀rù Ọlọ́run.
20 Ọ̀rẹ́ mi yìí ti dalẹ̀ èmi ọ̀rẹ́ rẹ̀;
ó ti ba májẹ̀mú rẹ̀ jẹ́.
21 Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ kúnná ju òrí-àmọ́,
ṣùgbọ́n ogun wà ni àyà rẹ̀;
ọ̀rọ̀ rẹ̀ fẹ́lẹ́ ju òróró lọ,
ṣùgbọ́n idà fífàyọ ní wọn.
22 (A)Gbé ẹrù rẹ lọ sí ọ̀dọ̀ Olúwa
yóò sì mú ọ dúró;
òun kò ní jẹ́ kí olódodo ṣubú.
23 Ṣùgbọ́n ìwọ, Ọlọ́run, ni yóò mu àwọn ọ̀tá mi
wá sí ihò ìparun;
Àwọn ẹni tí òǹgbẹ ẹ̀jẹ̀ ń gbẹ àti ẹni ẹ̀tàn,
kì yóò gbé ààbọ̀ ọjọ́ wọn.
Ṣùgbọ́n fún èmi, èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ.
7 Ọba sì dìde pẹ̀lú ìbínú, ó fi wáìnì sílẹ̀ ó sì jáde lọ sí àgbàlá ààfin. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hamani, ti rí i dájú pé ọba ti pinnu láti pa òun, ó dúró lẹ́yìn láti bẹ Esteri ayaba nítorí ẹ̀mí rẹ̀.
8 Bí ọba ṣe padà dé láti àgbàlá ààfin wá sí gbọ̀ngàn àsè náà, Hamani ṣubú sórí àga tí Esteri ayaba fẹ̀yìn tì.
Ọba sì pariwo pé, “Yóò ha tún tẹ́ ayaba níbí yìí, nínú ilé, ní ojú mi bí?”
Ní kété tí ọba sọ ọ̀rọ̀ yìí jáde, wọ́n da aṣọ bo Hamani lójú. 9 Nígbà náà Harbona ọ̀kan nínú àwọn ìwẹ̀fà tó ń dúró níwájú ọba, sọ wí pé, “igi tí ó ga tó ìwọ̀n ẹsẹ̀ bàtà marunlélaadọrin ni Hamani ti rì sí ẹ̀gbẹ́ ilé e rẹ̀. Ó ṣe é fún Mordekai, ẹni tí ó sọ̀rọ̀ jáde láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọba.”
Ọba wí pé, ẹ so ó rọ̀ sórí i rẹ́! 10 Wọ́n sì so Hamani sórí igi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún Mordekai, ìbínú ọba sì rọ̀.
Àṣẹ ọba nítorí àwọn Júù
8 Ní ọjọ́ kan náà ni ọba Ahaswerusi fún Esteri ayaba ní ilé e Hamani, ọ̀tá àwọn Júù. Mordekai sì wá síwájú ọba, nítorí Esteri ti sọ bí ó ṣe jẹ́ sí ọba. 2 Ọba sì bọ́ òrùka dídán an rẹ̀, èyí tí ó ti gbà lọ́wọ́ Hamani ó sì fi fún Mordekai, Esteri sì yàn án gẹ́gẹ́ bí olórí ilé e Hamani.
3 Esteri sì tún bẹ ọba lórí ìkúnlẹ̀, pẹ̀lú omijé lójú. Ó bẹ̀ ẹ́ kí ó fi òpin sí ètò búburú Hamani ará Agagi, èyí tí ó ti pète fún àwọn Júù. 4 Nígbà náà ni ọba na ọ̀pá aládé wúrà sí Esteri ó sì dìde, ó dúró níwájú rẹ̀.
5 Ó wí pé, “Bí ó bá wu ọba, tí ó bá sì bọ̀wọ̀ fún mi pẹ̀lú ojúrere tí ó sì rò pé ohun tí ó dára ni láti ṣe, tí ó bá sì ní inú dídùn pẹ̀lú mi, jẹ́ kí a kọ ìwé àṣẹ láti yí ète tí Hamani ọmọ Hammedata, ará Agagi, tí ó kọ́ pàṣẹ pé kí a pa àwọn Júù tí wọ́n wà ní gbogbo àgbáyé ìjọba ọba run. 6 Nítorí báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á tí èmi yóò sì rí kí ibi máa ṣubú lu àwọn ènìyàn mi? Báwo ni èmi yóò ṣe fi ara dà á, tí èmi yóò sì máa wo ìparun àwọn ìdílé mi?”
7 Ọba Ahaswerusi dá Esteri ayaba àti Mordekai ará a Júù náà lóhùn pé, “Nítorí Hamani kọlu àwọn ará a Júù, èmi ti fi ilé e rẹ̀ fún Esteri, wọ́n sì ti ṣo ó kọ́ sórí igi. 8 Nísinsin yìí, kọ ìwé àṣẹ mìíràn ní orúkọ ọba bí àwọn Júù ṣe jẹ́ pàtàkì sí ọ, kí o sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì dì í, nítorí kò sí àkọsílẹ̀ tí a bá ti kọ ní orúkọ ọba tí a sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì tí a lè yìí padà.”
9 Lẹ́sẹ̀kan náà àwọn akọ̀wé ọba péjọ ní ọjọ́ kẹtàlélógún oṣù kẹta, oṣù Sifani. Wọ́n kọ gbogbo àṣẹ Mordekai sí àwọn Júù, àti sí àwọn alákòóso baálẹ̀ àti àwọn ọlọ́lá ìgbèríko mẹ́tà-dínláàádóje tí ó lọ láti India títí ó fi dé Kuṣi. Kí a kọ àṣẹ náà ní ìlànà bí ìgbèríko kọ̀ọ̀kan ṣe ń kọ̀wé àti bí èdè olúkúlùkù àti pẹ̀lú sí àwọn Júù ní ìlànà bí wọ́n ṣe ń kọ̀wé àti èdè e wọn. 10 Mordekai sì fi àṣẹ ọba Ahaswerusi kọ̀wé, ó sì fi òrùka ọba ṣe èdìdì i rẹ̀, ó rán an lọ ní kíákíá, ó sì rán àwọn ìránṣẹ́ ayaba, tiwọn yára bí àṣà àwọn tí wọ́n ń gun ẹṣin tí ó yára, ní pàtàkì èyí tí a ń bọ́ fún ọba.
11 Àṣẹ ọba sì dé ọ̀dọ̀ àwọn Júù ní gbogbo ìlú láti kó ara wọn jọ kí wọn sì dáàbò bo ara wọn; láti pa, láti run àti láti kọlu ogunkógun orílẹ̀-èdè kórílẹ̀ èdè kankan tàbí ìgbèríko tí ó bá fẹ́ kọlù wọ́n, àwọn obìnrin àti àwọn ọmọ wọn; kí ẹ sì kó gbogbo ohun ìní àwọn ọ̀tá wọn. 12 Ọjọ́ tí a yàn fún àwọn Júù ní gbogbo agbègbè ọba Ahaswerusi láti ṣe nǹkan yìí ni ọjọ́ kẹtàlá èyí tí í ṣe oṣù kejìlá, oṣù Addari. 13 Ọkàn ìwé àṣẹ náà ni kí a gbé jáde gẹ́gẹ́ bí òfin ní gbogbo ìgbèríko kí ẹ sì jẹ́ kí ó di mí mọ̀ fún gbogbo ènìyàn ìlú nítorí àwọn Júù yóò le è múra ní ọjọ́ náà láti gbẹ̀san fún ara wọn lára àwọn ọ̀tá wọn.
14 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìránṣẹ́ ayaba tiwọn yára bí àṣà tí wọ́n ń gun ẹṣin ọba, sáré jáde, wọ́n sáré lọ nípa àṣẹ ọba. A sì tún gbé àṣẹ náà jáde ní ilé ìṣọ́ ti Susa.
15 Mordekai sì kúrò níwájú ọba, ó wọ aṣọ aláró àti funfun, ó dé adé e wúrà ńlá pẹ̀lú ìgbànú elése àlùkò dáradára, ìlú Susa sì ṣe àjọyọ̀ ńlá. 16 Àsìkò ìdùnnú àti ayọ̀, inú dídùn àti ọlá ni ó jẹ́ fún àwọn Júù. 17 Ní gbogbo ìgbèríko àti ní gbogbo ìlú, ní gbogbo ibi tí àṣẹ ọba dé, ni ayọ̀ àti inú dídùn ti wà láàrín àwọn Júù, wọ́n sì ń ṣe àsè àti àjọyọ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú tókù sọ ara wọn di Júù nítorí ẹ̀rù àwọn Júù bà wọ́n.
Fẹ́ràn ọ̀tá rẹ
43 (A)“Ẹ̀yin ti gbọ́ bí òfin ti wí pé, ‘Ìwọ fẹ́ ọmọnìkejì rẹ, kí ìwọ sì kórìíra ọ̀tá rẹ̀.’ 44 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín. 45 Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín ti ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo. 46 Bí ẹ̀yin bá fẹ́ràn àwọn tí ó fẹ́ràn yín nìkan, èrè kí ni ẹ̀yin ní? Àwọn agbowó òde kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́? 47 Àti bí ó bá sì jẹ́ pé kìkì àwọn arákùnrin yín nìkan ni ẹ̀yin ń kí, kín ni ẹ̀yin ń ṣe ju àwọn mìíràn lọ? Àwọn kèfèrí kò ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? 48 Nítorí náà, ẹ jẹ́ pípé, gẹ́gẹ́ bí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ṣe jẹ́ pípé.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.