Revised Common Lectionary (Complementary)
Maskili ti Etani ará Esra.
89 Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé;
pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.
2 Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé,
pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnrarẹ̀.
3 (A)Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi
mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.
4 ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé
èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”
5 Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa,
òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.
6 Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa?
Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?
7 Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi;
ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.
8 Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ
ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.
9 Ìwọ ń darí ríru omi Òkun;
nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.
10 Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ
bí ẹni tí a pa;
ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ
tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.
11 Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ:
ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀:
ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.
12 Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn;
Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.
13 Ìwọ ní apá agbára;
agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.
14 Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ:
ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.
15 Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì,
Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.
16 Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́,
wọn ń yin òdodo rẹ.
17 Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn;
nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.
18 Nítorí ti Olúwa ni asà wa,
ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.
Manase ọba Juda
33 (A)Manase jẹ́ ọmọ ọdún méjìlá nígbà tí ó di ọba. Ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún márùn-dínlọ́gọ́ta. 2 Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa. Nípa títẹ̀lé ọ̀nà iṣẹ́ ìríra ti àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa ti lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli rìn. 3 Ó tún kọ́ àwọn ibi gíga tí baba rẹ̀ Hesekiah ti fọ́ túútúú. Ó sì gbé àwọn pẹpẹ dìde fún àwọn Baali ó sì ṣe àwọn ère Aṣerah. Ó foríbalẹ̀ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run ó sì sìn wọ́n. 4 Ó kọ́ àwọn pẹpẹ sínú ilé Olúwa ní èyí tí Olúwa ti wí pé “Orúkọ mi yóò wà ní Jerusalẹmu títí láé.” 5 Nínú ààfin méjèèje ti ilé Olúwa, ó kọ́ àwọn pẹpẹ fún gbogbo àwọn ogun ọ̀run 6 Ó sì mú kí àwọn ọmọ ara rẹ̀ kí ó kọjá láàrín iná ní Àfonífojì Beni-Hinnomu, ó ń ṣe àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì ń lo àlúpàyídà, ó sì ń bá àwọn òku àti oṣó lò. Ó ṣe ọ̀pọ̀ ohun búburú ní ojú Olúwa láti mú un bínú.
7 Ó mú ère gbígbẹ́ tí ó ti gbẹ́ ó sì gbé e sínú ilé Olúwa, ní èyí tí Ọlọ́run ti sọ fún Dafidi àti sí ọmọ rẹ̀ Solomoni, “Nínú ilé Olúwa yìí àti ní Jerusalẹmu, tí mo ti yàn kúrò nínú gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli, èmi yóò fi orúkọ mi síbẹ̀ títí láé. 8 Èmi kì yóò ṣí ẹsẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli kúrò mọ́ ní ilẹ̀ náà tí èmi ti yàn fún àwọn baba ńlá yín, níwọ̀n bí wọ́n bá ṣe pẹ̀lẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí mo paláṣẹ fún wọn, gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin, àṣẹ àti àwọn ìlànà tí a fún yín láti ọwọ́ Mose wá.” 9 Ṣùgbọ́n Manase mú kí Juda àti àwọn tí ń gbé Jerusalẹmu yapa, àti láti ṣe búburú ju àwọn orílẹ̀-èdè lọ, àwọn tí Olúwa ti parun níwájú àwọn ọmọ Israẹli.
10 Ọlọ́run bá Manase sọ̀rọ̀ àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò kọbi ara sí i 11 Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa mú àwọn alákòóso ọmọ-ogun ọba Asiria láti dojúkọ wọ́n, tí ó mú Manase nígbèkùn, ó fi ìwọ̀ mú un ní imú rẹ̀, ó dè é pẹ̀lú ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ idẹ ó sì mú un lọ sí Babeli. 12 Nínú ìpọ́njú rẹ̀, ó wá ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀. Ó sì rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ gidigidi níwájú Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀. 13 Nígbà tí ó sì gbàdúrà sí i, inú Olúwa dùn sí àdúrà rẹ̀, ó sì tẹ́tí sí ẹ̀bẹ̀ rẹ̀; bẹ́ẹ̀ ni ó mú un padà wá sí Jerusalẹmu àti sí ìjọba rẹ̀. Nígbà náà Manase mọ̀ wí pé Olúwa ni Ọlọ́run.
14 Ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí, ó mọ odi kan lẹ́yìn ìlú Dafidi, ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Gihoni, ní àfonífojì, àní ní àtiwọ ẹnu ibodè ẹja, ó sì yí orí òkè Ofeli ká; ó sì mọ ọ́n ga sókè gidigidi, ó sì fi balógun sínú gbogbo ìlú olódi Juda wọ̀n-ọn-nì.
15 Ó pa gbogbo àwọn Ọlọ́run àjèjì run. Ó sì hú gbogbo àwọn ère kúrò nínú ilé Olúwa, pẹ̀lú gbogbo àwọn pẹpẹ tí ó ti kọ́ ní òkè ilé Olúwa àti ní Jerusalẹmu; ó sì kó wọn jáde kúrò nínú ìlú. 16 Nígbà náà ni ó mú àwọn pẹpẹ padà bọ̀ sípò. Ó sì rú ọrẹ ìdàpọ̀ àti ọrẹ-ọpẹ́ lórí rẹ̀. Ó sì sọ fún Juda láti sin Olúwa, Ọlọ́run Israẹli. 17 Àwọn ènìyàn, ko tẹ̀síwájú láti máa rú ẹbọ ní àwọn ibi gíga. Ṣùgbọ́n sí Olúwa Ọlọ́run wọn nìkan.
Nípa ìgbàgbọ́
11 Ǹjẹ́ ìgbàgbọ́ ní ìdánilójú ohun tí o ń retí, ìjẹ́rìí ohun tí a kò rí. 2 Nítorí nínú rẹ ni àwọn alàgbà àtijọ́ ní ẹ̀rí rere.
3 Nípa ìgbàgbọ́ ni a mọ̀ pé a ti dá ayé nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; nítorí náà kì í ṣe ohun tí o hàn ni a fi dá ohun tí a ń ri.
4 (A)Nípa ìgbàgbọ́ ní Abeli rú ẹbọ sí Ọlọ́run tí ó sàn ju ti Kaini lọ, nípa èyí tí a jẹ́rìí rẹ̀ pe olódodo ni, Ọlọ́run sí ń jẹ́rìí ẹ̀bùn rẹ̀: Àti nípa rẹ̀ náà, bí o ti jẹ́ pé o ti kú, síbẹ̀ o ń fọhùn.
5 (B)Nípa ìgbàgbọ́ ni a ṣí Enoku ní ipò padà kí o má ṣe rí ikú; a kò sì rí i mọ́, nítorí Ọlọ́run ṣí i ní ipò padà: nítorí ṣáájú ìṣípò padà rẹ̀, a jẹ́rìí yìí sí i pé o wu Ọlọ́run. 6 Ṣùgbọ́n láìsí ìgbàgbọ́ kò ṣe é ṣe láti wù ú; nítorí ẹni tí ó bá ń tọ Ọlọ́run wá kò lè ṣàì gbàgbọ́ pé ó ń bẹ, àti pé òun ní olùṣẹ̀san fún àwọn tí o fi ara balẹ̀ wá a.
7 (C)Nípa ìgbàgbọ́ ni Noa, nígbà ti Ọlọ́run, kìlọ̀ ohun tí a kóò tí ì rí fún un, o bẹ̀rù Ọlọ́run ó sì kan ọkọ̀ fún ìgbàlà ilé rẹ̀, nípa èyí tí ó da ayé lẹ́bi, ó sì di ajogún òdodo tí i ṣe nípa ìgbàgbọ́.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.