Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 45-46

Ilẹ̀ pínpín

45 “ ‘Nígbà ti ẹ̀yin bá pín ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ogún, ẹ gbọdọ̀ gbé ìpín ilẹ̀ kan kalẹ̀ fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ibi mímọ́, ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ogún ẹgbẹ̀rún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú; gbogbo agbègbè rẹ̀ yíká ni yóò jẹ́ mímọ́. Lára inú èyí, ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta yóò jẹ́ ti ibi mímọ́ ní gígùn, pẹ̀lú ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ní ìbú, ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yíká, àti àádọ́ta ìgbọ̀nwọ́ fún gbangba rẹ̀ yíká. Ní agbègbè ibi mímọ́, wọn ya ibi kan sọ́tọ̀ kí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ìbú. Ní inú rẹ ni ilẹ̀ ti a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa yóò wà, ìyẹn ibi mímọ́ jùlọ. Yóò jẹ́ ibi mímọ́ lára ilẹ̀ náà fún àwọn àlùfáà, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ibi mímọ́ àti àwọn tí ó súnmọ́ àlùfáà ní iwájú Olúwa. Ibẹ̀ yóò jẹ ibi tí yóò wà fún ilé gbígbé wọn, bákan náà ni yóò jẹ́ ibi mímọ́ fún ilé Olúwa. Agbègbè kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá ní ìbú yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ Lefi, tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili, gẹ́gẹ́ bi ìní wọn fún ìlú wọn láti máa gbé ibẹ̀.

“ ‘Ìwọ yóò fi ìlú náà ti agbègbè rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, papọ̀ mọ́ ibi mímọ́ fún àwọn ilé Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìní: yóò jẹ́ ti gbogbo ilé Israẹli.

“ ‘Àwọn ọmọ-aládé ni yóò bá ibi mímọ́ pààlà ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan agbègbè tí ó jẹ ibi mímọ́ àti ohun tí ó jẹ́ ti ìlú. Yóò fẹ̀ sẹ́yìn sí ìhà ìwọ̀-oòrùn láti apá ìwọ̀-oòrùn àti si ìlà-oòrùn, láti apá ìlà-oòrùn, gígùn rẹ̀ yóò jẹ́ láti ìwọ̀-oòrùn sí ààlà ìlà-oòrùn, ti ìṣe déédé rẹ̀ yóò jẹ́ ti ọ̀kan lára àwọn ìpín ẹ̀yà. Ilẹ̀ yìí ni yóò jẹ́ ìpín rẹ̀ ní Israẹli. Àwọn ọmọ-aládé mìíràn kò ní rẹ́ àwọn ènìyàn mi jẹ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yóò jẹ́ kí àwọn ilé Israẹli gba ilẹ̀ wọn gẹ́gẹ́ bi ẹ̀yà wọn.

“ ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ẹ̀yin ti rìn jìnnà tó, Ẹ̀yin ọmọ-aládé tí Israẹli! Ẹ fi ìwà ipá àti ìrẹ́jẹ yín sílẹ̀ kí ẹ̀yin sì ṣe èyí tí ó tọ́ àti èyí tí ó yẹ. Ẹ dáwọ́ gbígbà ní ọwọ́ àwọn ènìyàn mi dúró, ni Olúwa Ọlọ́run wí. 10 Kí ẹ̀yin kì ó lo òṣùwọ̀n tó tọ́ àti efa títọ́ àti bati títọ́. 11 Efa àti bati gbọdọ̀ jẹ́ bákan náà, kí bati tí ó gba ìdámẹ́wàá homeri, àti efa ìdámẹ́wàá homeri: Homeri ni kí ó jẹ́ òṣùwọ̀n tí ẹ̀yin yóò lò fún méjèèjì. 12 Ṣékélì ní kí o gba ogún gera. Ogún ṣékélì pẹ̀lú ṣékélì márùn-dínlọ́gbọ̀n pẹ̀lú ṣékélì mẹ́ẹ̀ẹ́dógún yóò jẹ́ minas kan.

Ọrẹ àti àwọn ọjọ́ mímọ́

13 “ ‘Èyí yìí ni ẹ̀bùn pàtàkì tí ẹ gbọdọ̀ ṣe: efa kẹfà láti inú homeri ọkà kọ̀ọ̀kan àti efa kẹfà láti inú homeri barle kọ̀ọ̀kan. 14 Ìpín òróró tí a júwe, tí a fi bati wọ́n, ni ìdámẹ́wàá bati láti inú kórì (èyí tí ó gba ìdámẹ́wàá bati tàbí homeri kan, fún ìdámẹ́wàá bati jẹ́ bákan náà sì homeri kan.) 15 Bákan náà ni ọ̀dọ́-àgùntàn kan láti inú agbo ẹran, láti inú igba, láti inú pápá oko tútù Israẹli, fún ọrẹ ẹbọ jíjẹ, àti fún ọrẹ ẹbọ sísun, àti fún ọrẹ ẹbọ ìdúpẹ́ láti ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún àwọn ènìyàn, ní Olúwa Olódùmarè wí. 16 Gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà ni yóò kópa nínú ẹ̀bùn pàtàkì fún ìlò àwọn ọmọ-aládé ni Israẹli. 17 Yóò jẹ́ ojúṣe ọmọ-aládé láti pèsè ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti ọrẹ ẹbọ mímu níbi àsè gbogbo, ti oṣù tuntun àti ní àwọn ọjọ́ ìsinmi ni gbogbo àjọ̀dún tí a yàn ní ilé Israẹli. Òun yóò pèsè ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ jíjẹ, ọrẹ ẹbọ sísun àti ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀, láti ṣe ètùtù fún ilé Israẹli.

18 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ìwọ yóò mú akọ màlúù aláìlábàwọ́n kì o sì sọ ilé Ọlọ́run di mímọ́. 19 Àlùfáà ni yóò mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, kí o sì fi si ẹnu ìlẹ̀kùn ilé Ọlọ́run, àti sí ara àwọn ìlẹ̀kùn tí ó wà ní àgbàlá ti inú. 20 Ìwọ yóò ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ọjọ́ keje oṣù fún àwọn tí ó dá ẹ̀ṣẹ̀ àìmọ̀ọ́mọ̀dá tàbí nínú àìmọ̀kan; nítorí náà, ìwọ yóò ṣe ìwẹ̀nùmọ́ fún ilé Ọlọ́run.

21 “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní ní ìwọ yóò ṣe àjọ ìrékọjá, àsè ọjọ́ méje, àsìkò yìí ní ẹ̀yin yóò jẹ àkàrà tí kò ni ìwúkàrà. 22 Ní ọjọ́ náà ní ọmọ-aládé yóò pèsè akọ màlúù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ara rẹ̀ àti fún gbogbo ènìyàn ni ilẹ̀ náà. 23 Ní ojoojúmọ́ ni àárín ọjọ́ méje àsè ni òun yóò pèsè akọ màlúù méje àti àgbò méje tí kò ní àbùkù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa, àti akọ ewúrẹ́ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 24 Òun yóò sì pèsè efa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ jíjẹ. Efa kan fún akọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti efa kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, pẹ̀lú hínì òróró kan fún efa kan.

25 “ ‘Láàrín ọjọ́ méje àsè náà, tí ó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù keje, òun yóò tún pèsè ohun kan náà fún ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ, àti fún òróró.

46 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ẹnu-ọ̀nà àgbàlá ti inú tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí a tì pa fún ọjọ́ mẹ́fà tí a fi ń ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ ìsinmi àti ní ọjọ́ oṣù tuntun ni kí a ṣí i. Ọmọ-aládé ni kí ó wọlé láti ìta tí ó kángun sí àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà, kí ó sì dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Àwọn àlùfáà ni yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ àti ọrẹ ìdàpọ̀. Òun ni yóò jọ́sìn ní ìloro ilé ní ẹnu-ọ̀nà, lẹ́yìn náà ni wọn yóò jáde, ṣùgbọ́n wọn kò ni ti ìlẹ̀kùn títí ìrọ̀lẹ́. Ní àwọn ọjọ́ ìsinmi àti àwọn oṣù tuntun ni kí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà jọ́sìn ní iwájú Olúwa ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. Ọrẹ ẹbọ sísun tí ọmọ-aládé mú wá fún Olúwa ni ọjọ́ ìsinmi ní láti jẹ́ ọ̀dọ́ àgbò mẹ́fà àti àgbò kan, gbogbo rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ aláìlábùkù. Ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú papọ̀ mọ́ àgbò gbọdọ̀ jẹ́ efa kan, ọrẹ ẹbọ jíjẹ tí a mú pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn ni kí ó pò gẹ́gẹ́ bí ó bá ṣe fẹ́, papọ̀ mọ hínì òróró kan pẹ̀lú efa kọ̀ọ̀kan. Àti ni ọjọ́ oṣù tuntun, ẹgbọrọ màlúù kan àìlábàwọ́n, àti ọ̀dọ́-àgùntàn mẹ́fà, àti àgbò kan: wọn o wà láìlábàwọ́n. Yóò si pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ efa fun ẹgbọrọ akọ màlúù, àti efa kan fun àgbò kan, àti fun àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bi èyí ti ipá rẹ̀ ká, àti hínì òróró kan fún efa kan. Nígbà tí ọmọ-aládé bá wọlé, ó gbọdọ̀ gbá àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà wọ inú, kí ó sì gba ibẹ̀ jáde.

“ ‘Nígbà tí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá wá síwájú Olúwa ni àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá wọlé láti jọ́sìn gbọdọ̀ gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù jáde; ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ti ẹnu-ọ̀nà ìhà gúúsù wọlé yóò gba tí ẹnu-ọ̀nà ìhà àríwá jáde. Kò sí ẹni tí ó gbọdọ̀ gba ibi tí ó bá wọlé jáde, ṣùgbọ́n kí olúkúlùkù gba òdìkejì ẹnu-ọ̀nà tí ó gbà wọlé jáde. 10 Ọmọ-aládé gbọdọ̀ wà ní àárín wọn, kí ó wọlé nígbà tí wọn bá wọlé, kí ó sì jáde nígbà tí wọn bá jáde.

11 “ ‘Níbi àwọn àjọ̀dún àti àwọn àjọ̀dún tí a yàn, ọrẹ ẹbọ jíjẹ gbọdọ̀ jẹ́ efa kan fún ẹgbọrọ akọ màlúù kan, efa kan fún àgbò kan, àti fún àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn gẹ́gẹ́ bí ó bá ti wu onílúlùkù, pẹ̀lú òróró hínì kan fún efa kan. 12 Nígbà tí ọmọ-aládé bá pèsè ọrẹ àtinúwá fún Olúwa yálà ọrẹ ẹbọ sísun tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ ojú ọ̀nà tí ó dojúkọ ìhà ìlà-oòrùn ni kí ó wà ni ṣíṣí sílẹ̀ fún un Òun yóò rú ọrẹ ẹbọ sísun rẹ̀ tàbí ọrẹ ẹbọ ìdàpọ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ní ọjọ́ ìsinmi. Lẹ́yìn náà, òun yóò jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá jáde tán wọn yóò ti ẹnu-ọ̀nà.

13 “ ‘Ní ojoojúmọ́ ni ìwọ yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù fún ọrẹ ẹbọ sísun sí Olúwa; àràárọ̀ ni ìwọ yóò máa pèsè rẹ̀. 14 Ìwọ yóò sì máa pèsè ọrẹ ẹbọ jíjẹ pẹ̀lú rẹ̀ ní àràárọ̀, èyí yóò ni ìdámẹ́fà nínú efa àti ìdámẹ́fà nínú òróró hínì láti fi po ìyẹ̀fun. Gbígbé ọrẹ ẹbọ jíjẹ fún Olúwa jẹ́ ìlànà tí ó wà títí. 15 Nítorí náà ọ̀dọ́-àgùntàn àti ọrẹ ẹbọ jíjẹ àti òróró ni wọn yóò pèsè ní àràárọ̀ fún ọrẹ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo.

16 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Tí ọmọ-aládé bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọkùnrin rẹ̀, yóò jẹ́ ìní tiwọn nípa ogún jíjẹ. 17 Tí ó bá mú ọrẹ láti inú ogún ìní rẹ̀ fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọ̀dọ̀, ọmọ le pamọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀; Lẹ́yìn náà yóò padà sí ọ̀dọ̀ ọmọ-aládé. Ogún ìní rẹ̀ jẹ́ ti àwọn ọmọ rẹ̀ nìkan; ó jẹ́ tiwọn. 18 Ọmọ-aládé kò gbọdọ̀ mú nǹkan kan lára ogún ìní àwọn ènìyàn, tàbí mú wọn kúrò níbi ohun ìní wọn. Ó ní láti fi ogún ìní rẹ̀ láti inú ìní rẹ̀ fún àwọn ọmọ rẹ̀, kí a ma ba à ya nǹkan kan kúrò lára ìní rẹ̀.’ ”

19 Lẹ́yìn náà ọkùnrin náà mú mi kọjá ní àbáwọlé tí ó wà lẹ́bàá ẹnu-ọ̀nà, sí àwọn yàrá mímọ́ tí ó kọjú sí ìhà àríwá, èyí tí ó jẹ́ tí àwọn àlùfáà, ó sì fi ibi kan hàn mí ní apá ìwọ̀-oòrùn. 20 O sọ fún mi pé, “Èyí yìí ni ibi tí àwọn àlùfáà yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ ìdálẹ́bi àti ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àti tí wọn yóò ti ṣe ọrẹ ẹbọ jíjẹ, láti má ṣe jẹ́ kí wọn mú wọn wá sí ìta àgbàlá, kí wọn sì ya àwọn ènìyàn sí mímọ́.”

21 Ó sì mú mi lọ sí ìta àgbàlá, ó sì mú mi yí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ká, mo sì ri àgbàlá mìíràn ní igun kọ̀ọ̀kan. 22 Ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ìta àgbàlá tí ó pẹnu pọ̀, ogójì ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn àti ọgbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú; àgbàlá kọ̀ọ̀kan ni igun kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìwọ̀n kan náà. 23 Ní agbègbè inú ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àgbàlá náà ni ọwọ́ ilẹ̀ kan wà yíká wọn, a sì ṣe ibi ìdáná si abẹ́ ọwọ́ náà yípo. 24 Ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ̀nyí ni àwọn ilé ìdáná níbi tí ó ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ nínú tẹmpili yóò ti ṣe ẹbọ fún àwọn ènìyàn.”

1 Johanu 2

(A)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, mo kọ ìwé nǹkan wọ̀nyí sí yín, kí ẹ̀yin má bà á dẹ́ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá sì dẹ́ṣẹ̀, àwa ni alágbàwí lọ́dọ̀ Baba: Jesu Kristi, olódodo nìkan. (B)Òun sì ní ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kì í tilẹ̀ ṣe fún tiwa nìkan ṣùgbọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ gbogbo aráyé.

Àwa mọ̀ pé àwa ti wá mọ̀ ọ́n, bí àwa bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́. (C)Ẹni tí ó bá wí pé, “Èmi mọ̀ ọ́n,” tí kò sì pa òfin rẹ̀ mọ́, èké ni, òtítọ́ kò sì ṣí nínú rẹ̀. (D)Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́, lára rẹ̀ ni a gbé mú ìfẹ́ Ọlọ́run pé nítòótọ́. Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa ń wà nínú rẹ̀. (E)Ẹnikẹ́ni tí ó bá wí pé òun ń gbé inú rẹ̀, òun náà pẹ̀lú sì yẹ láti máa rìn gẹ́gẹ́ bí Jesu ti rìn.

(F)Ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, kì í ṣe òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín ṣùgbọ́n òfin àtijọ́, èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe. Òfin àtijọ́ ni ọ̀rọ̀ náà tí ẹ̀yin tí gbọ́. (G)Pẹ̀lúpẹ̀lú, òfin tuntun ni mo ń kọ̀wé rẹ̀ sí yín; èyí tí í ṣe òtítọ́ nínú rẹ̀ àti nínú yin, nítorí òkùnkùn ń kọjá lọ, ìmọ́lẹ̀ òtítọ́ sì tí ń tàn.

Ẹni tí ó bá sì wí pé òun ń wà nínú ìmọ́lẹ̀, tí ó sì kórìíra arákùnrin rẹ̀ sì ń bẹ nínú òkùnkùn. 10 (H)Ẹni tí ó ba fẹ́ràn arákùnrin rẹ̀, ó ń gbé inú ìmọ́lẹ̀, kò sì ṣí ohun ìkọ̀sẹ̀ kan nínú rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ẹni tí o bá kórìíra arákùnrin rẹ̀ ń gbé nínú òkùnkùn, ó sì ń rìn nínú òkùnkùn; kò sì mọ ibi tí òun ń lọ, nítorí tí òkùnkùn tí fọ́ ọ lójú.

12 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n,
    nítorí tí a darí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín nítorí orúkọ rẹ̀.
13 (I)Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,
    nítorí tí ẹ̀yin tí mọ ẹni tí ó wà ní àtètèkọ́ṣe,
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,
    nítorí tí ẹ̀yin ti ṣẹ́gun ẹni ibi náà.

14 Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọmọdé mi ọ̀wọ́n,
    nítorí ẹ̀yin ti mọ Baba.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin baba,
    nítorí ti ẹ̀yin tí mọ ẹni tí o wà ni àtètèkọ́ṣe.
Èmi ń kọ̀wé sí yín, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọkùnrin,
    nítorí tí ẹ̀yin ni agbára,
    tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ń gbé nínú yín,
    tí ẹ sì ṣẹ́gun ẹni ibi náà.

Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé

15 Ẹ má ṣe fẹ́ràn ayé tàbí ohunkóhun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ràn ayé, ìfẹ́ tí Baba kò sí nínú rẹ̀. 16 Nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé: ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ojú, àti ìgbéraga ti ohun ti ó ní àti ohun tí ó ṣe: kò wá láti ọ̀dọ̀ Baba bí kò ṣe láti ọwọ́ ayé. 17 Ayé sì ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò wà títí láéláé.

Ìkìlọ̀ nípa àwọn aṣòdì sí Kristi

18 (J)Ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ìgbà ìkẹyìn ni èyí; bí ẹ̀yin sì tí gbọ́ pé aṣòdì sí Kristi ń bọ̀ wá, àní nísinsin yìí, púpọ̀ aṣòdì sí Kristi ló ń bẹ. Nípa èyí ni àwa fi mọ́ pé ìgbà ìkẹyìn ni èyí. 19 Wọ́n ti ọ̀dọ̀ wá jáde, ṣùgbọ́n wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí wọ́n bá jẹ́ ara wa, wọn ìbá bá wa dúró: ṣùgbọ́n jíjáde lọ wọn fihàn pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa.

20 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ní ìfòróróyàn láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ wá, gbogbo yín sì mọ òtítọ́. 21 Èmi kò kọ̀wé sí yín nítorí pé ẹ̀yin kò mọ òtítọ́, ṣùgbọ́n nítorí tí ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, àti pé kò sí èké nínú òtítọ́. 22 (K)Ta ni èké? Ẹni tí ó sẹ́ pé Jesu kì í ṣe Kristi. Eléyìí ni Aṣòdì sí Kristi: ẹni tí ó sẹ́ Baba àti Ọmọ. 23 (L)Ẹnikẹ́ni tí o ba sẹ́ Ọmọ, kò gba Baba; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba jẹ́wọ́ Ọmọ, ó gba Baba pẹ̀lú.

24 Ẹ jẹ́ kí èyí tí ẹ tí gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe máa gbé inú yín. Bí èyí tí ẹ̀yin tí gbọ́ ní àtètèkọ́ṣe bá ń gbé inú yín, ẹ̀yin ó sì dúró nínú Ọmọ àti nínú Baba. 25 Èyí sì ni ìlérí náà tí ó tí ṣe fún wa, àní ìyè àìnípẹ̀kun.

26 Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé sí yín ní ti àwọn tí wọ́n fẹ́ ẹ mún un yín ṣìnà. 27 (M)Ṣùgbọ́n ní ti ìfóróróyàn tí ẹ̀yín gba lọ́wọ́ rẹ̀ ṣì ń gbé inú yín, ẹ̀yin kò tún nílò pé kí ẹnìkan kọ yín. Ṣùgbọ́n bí ìfòróróyàn náà ti ń kọ́ yín ní ohun gbogbo tí ó jẹ́ òtítọ́, tí kì í sì í ṣe èké, àní gẹ́gẹ́ bí ó sì ti kọ́ yín, ẹ máa gbé inú rẹ̀.

Àwọn ọmọ Ọlọ́run

28 (N)Àti nísinsin yìí, ẹ̀yin ọmọ mi ọ̀wọ́n, ẹ máa gbé inú rẹ̀, pé nígbà tí òun ó bá farahàn, kí a lè ni ìgboyà níwájú rẹ̀, kí ojú má sì tì wá níwájú rẹ̀ ni ìgbà wíwá rẹ̀.

29 (O)Bí ẹ̀yin ba mọ̀ pé olódodo ni òun, ẹ mọ̀ pé a bí olúkúlùkù ẹni tí ń ṣe òdodo nípa rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.