Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Sekariah 5-8

Ìwé kíkà ti n fò

Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò.

Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?”

Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”

Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé: nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀. ‘Èmi yóò mú un jáde,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké: yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”

Obìnrin nínú agbọ̀n

Angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ sì jáde lọ, ó sì wí fún mi pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wo nǹkan tí yóò jáde lọ.”

Mo sì wí pé, “Kí ni nǹkan náà?”

Ó sì wí pé, “Èyí ni òṣùwọ̀n tí ó jáde lọ.” Ó sì wí pé, “Èyí ni àwòrán ní gbogbo ilẹ̀ ayé.”

Sì kíyèsi i, a gbé tálẹ́ǹtì òjé sókè: obìnrin kan sì nìyìí tí ó jókòó sí àárín àpẹẹrẹ òṣùwọ̀n. Ó sì wí pé, “Èyí ni ìwà búburú.” Ó sì ti sí àárín òṣùwọ̀n: ó sì ju ìdérí òjé sí ẹnu rẹ̀.

Mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, obìnrin méjì jáde wá, ẹ̀fúùfù sì wá nínú ìyẹ́ wọn; nítorí wọ́n ní ìyẹ́ bí ìyẹ́ àkọ̀: Wọ́n sì gbé àpẹẹrẹ òṣùwọ̀n náà dé àárín méjì ayé àti ọ̀run.

10 Mo sì sọ fún angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Níbo ni àwọn wọ̀nyí ń gbé òṣùwọ̀n náà lọ.”

11 Ó si wí fún mi pé, “Sí orílẹ̀-èdè Babeli láti kọ ilé fún un. Tí ó bá ṣetán, a ó sì fi ìdí rẹ̀ mulẹ̀, a o sì fi ka orí ìpìlẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.”

Kẹ̀kẹ́ ogun mẹ́rin tí ìdájọ́ Ọlọ́run

(A)Mo sì yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, kẹ̀kẹ́ mẹ́rin jáde wá láti àárín òkè ńlá méjì, àwọn òkè-ńlá náà sì jẹ́ òkè-ńlá idẹ. Àwọn ẹṣin pupa wà ní kẹ̀kẹ́ èkínní; àti àwọn ẹṣin dúdú ní kẹ̀kẹ́ èkejì. Àti àwọn ẹṣin funfun ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹta; àti àwọn adíkálà àti alágbára ẹṣin ní kẹ̀kẹ́ ẹ̀kẹrin. Mo sì dáhùn, mo sì béèrè lọ́wọ́ angẹli tí ń bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kí ni ìwọ̀nyí, olúwa mi.”

(B)Angẹli náà si dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ẹ̀mí mẹ́rin ti ọ̀run, tí wọn ń lọ kúrò lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ara wọn hàn níwájú Olúwa gbogbo ayé. Àwọn ẹṣin dúdú tí ó wà nínú rẹ̀ jáde lọ sí ilẹ̀ àríwá; àwọn funfun sì jáde lọ si ìwọ̀-oòrùn; àwọn adíkálà sì jáde lọ sí ìhà ilẹ̀ gúúsù.”

Àwọn alágbára ẹṣin sì jáde lọ, wọ́n sì ń wá ọ̀nà àti lọ kí wọn bá a lè rìn síhìn-ín sọ́hùn-ún ni ayé; ó sì wí pé, “Ẹ lọ, ẹ lọ rìn síhìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé!” Wọ́n sì rín síhìn-ín sọ́hùn-ún ní ayé.

Nígbà náà ni ohùn kan sì ké sí mi, ó sì bá mi sọ̀rọ̀ wí pé, “Wò ó, àwọn wọ̀nyí tí ó lọ síhà ilẹ̀ àríwá ti mú ẹ̀mí mi parọ́rọ́ ni ilẹ̀ àríwá.”

Adé fún Joṣua

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 10 “Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Heldai, tí Tobiah, àti ti Jedaiah, tí ó ti Babeli dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Josiah ọmọ Sefaniah lọ. 11 Kí o sì mú fàdákà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. 12 (C)Sì sọ fún un pé: ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹmpili Olúwa wa. 13 Òun ni yóò sì kọ́ tẹmpili Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jẹ ọba lórí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrín àwọn méjèèjì.’ 14 Adé wọ̀nyí yóò sì wà fún Helemu àti fún Tobiah, àti fún Jedaiah, àti fún Heni ọmọ Sefaniah fún ìrántí ni tẹmpili Olúwa. 15 Àwọn tí ó jìnnà réré yóò wá láti kọ́ tẹmpili Olúwa, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti rán mi sí yín. Yóò sì rí bẹ́ẹ̀ bí ẹ̀yin yóò bá gbà ohùn Olúwa, Ọlọ́run yín gbọ́ nítòótọ́.”

Òdodo àti àánú, kì í ṣe àwẹ̀

Ó sì ṣe ní ọdún kẹrin Dariusi ọba, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ́ Sekariah wá ni ọjọ́ kẹrin oṣù Kisleu tí ń ṣe oṣù kẹsànán. Nígbà tí wọ́n ènìyàn Beteli rán Ṣareseri àti Regemmeleki, àti àwọn ènìyàn wọn sí ilé Ọlọ́run láti wá ojúrere Olúwa. Àti láti bá àwọn àlùfáà tí ó wà ní ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun, àti àwọn wòlíì sọ̀rọ̀ wí pé, “Ṣé kí èmi ó sọkún ní oṣù karùn-ún kí èmi ya ara mi sọ́tọ̀, bí mo ti ń ṣe láti ọdún mélòó wọ̀nyí wá bí?”

Nígbà náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tọ̀ mí wá pé, “Sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, àti fún àwọn àlùfáà pé, ‘Nígbà tí ẹ̀yin gbààwẹ̀, tí ẹ sì ṣọ̀fọ̀ ní oṣù karùn-ún àti keje, àní fun àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, ǹjẹ́ èmi ni ẹ̀yin ha ń gbààwẹ̀ yín fún? Nígbà tí ẹ sì jẹ, àti nígbà tí ẹ mu, fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin jẹ, àti fún ara yín kọ́ ni ẹ̀yin mú bí? Wọ̀nyí kọ́ ni ọ̀rọ̀ ti Olúwa ti kígbe láti ọ̀dọ̀ àwọn wòlíì ìṣáájú wá, nígbà tí a ń gbé Jerusalẹmu, tí ó sì wà ní àlàáfíà, pẹ̀lú àwọn ìlú rẹ̀ tí ó yí i káàkiri, nígbà tí a ń gbé gúúsù àti pẹ̀tẹ́lẹ̀.’ ”

Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Sekariah wá, wí pé: “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀. 10 Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’

11 “Ṣùgbọ́n wọ́n kọ̀ láti gbọ́, wọ́n sì gún èjìká, wọ́n sì pa ẹ̀yìn dà, wọ́n di etí wọn, kí wọn má ba à gbọ́. 12 Wọ́n sé ọkàn wọn bí òkúta líle, kí wọn má ba à gbọ́ òfin, àti ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fi ẹ̀mí rẹ̀ rán nípa ọwọ́ àwọn wòlíì ìṣáájú wá. Ìbínú ńlá sì dé láti ọ̀dọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.

13 “ ‘Ó sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ó ti kígbe, tí wọn kò sì fẹ́ gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n kígbe, tí èmi kò sì fẹ́ gbọ́,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 14 ‘Mo sì fi ìjì tú wọn ká sí gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọn kò mọ̀. Ilẹ̀ náà sì dahoro lẹ́yìn wọn, tí ẹnikẹ́ni kò là á kọjá tàbí kí ó padà bọ̀: wọ́n sì sọ ilẹ̀ ààyò náà dahoro.’ ”

Ọlọ́run ṣe ìpinnu láti bùkún Jerusalẹmu

Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun si tún tọ́ mí wá.

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Owú ńláńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńláńlá ni mo fi jowú fún un.”

Báyìí ni Olúwa wí: “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu: Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Arúgbó ọkùnrin, àti arúgbó obìnrin, yóò gbé ìgboro Jerusalẹmu, àti olúkúlùkù pẹ̀lú ọ̀pá ni ọwọ́ rẹ̀ fún ogbó. Ìgboro ìlú yóò sì kún fún ọmọdékùnrin, àti ọmọdébìnrin, tí ń ṣiré ní ìta wọn.”

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Bí ó bá ṣe ìyanu ní ojú ìyókù àwọn ènìyàn yìí ni ọjọ́ wọ̀nyí, ǹjẹ́ ó ha lè jẹ́ ìyanu ni ojú mi bí?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

Báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Kíyèsi i, èmi ó gba àwọn ènìyàn mi kúrò ni ilẹ̀ ìlà-oòrùn, àti kúrò ni ilẹ̀ ìwọ̀-oòrùn. Èmi ó sì mú wọn padà wá, wọn ó sì máa gbé àárín Jerusalẹmu. Wọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi, èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, ní òtítọ́, àti ní òdodo.”

Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Jẹ́ kí ọwọ́ yín le ẹ̀yin ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ọjọ́ wọ̀nyí ni ẹnu àwọn wòlíì tí ó wà ni ọjọ́ tí a fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun lélẹ̀, jẹ́ ki ọwọ́ rẹ̀ le kí a bá lè kọ́ tẹmpili. 10 Nítorí pé, ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí, owó ọ̀yà ènìyàn kò tó nǹkan, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀yà ẹran pẹ̀lú, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àlàáfíà fún ẹni ń jáde lọ, tàbí ẹni ti ń wọlé bọ, nítorí ìpọ́njú náà: nítorí mo dojú gbogbo ènìyàn, olúkúlùkù kọ aládùúgbò rẹ̀. 11 Ṣùgbọ́n ní ìsinsin yìí èmi kì yóò ṣè sí ìyókù àwọn ènìyàn yìí gẹ́gẹ́ bí tí ìgbà àtijọ́,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

12 “Nítorí irúgbìn yóò gbilẹ̀: àjàrà yóò ṣo èso rẹ̀, ilẹ̀ yóò sì hu ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan rẹ̀ jáde, àwọn ọ̀run yóò sì mu ìrì wọn wá; èmi ó sì mu kí èyí jẹ ogún ìní àwọn ìyókù ènìyàn yìí ni gbogbo nǹkan wọ̀nyí. 13 Yóò sì ṣe, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin tí jẹ́ ègún láàrín àwọn kèfèrí, ẹ̀yin ilé Juda, àti ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni èmi ó gbà yín sílẹ̀; ẹ̀yin o sì jẹ́ ìbùkún: ẹ má bẹ̀rù, ṣùgbọ́n jẹ́ ki ọwọ́ yín le.”

14 Nítorí báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: “Gẹ́gẹ́ bí mo ti rò láti ṣe yín níbi nígbà tí àwọn baba yín mú mi bínú,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, tí èmi kò sì ronúpìwàdà. 15 “Bẹ́ẹ̀ ni èmi sì ti ro ọjọ́ wọ̀nyí láti ṣe rere fún Jerusalẹmu, àti fún ilé Juda: ẹ má bẹ̀rù. 16 (D)Wọ̀nyí ni nǹkan tí ẹ̀yin ó ṣe: ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́; ṣe ìdájọ́ tòótọ́ àti àlàáfíà ní àwọn ibodè yín. 17 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan ro ibi ni ọkàn rẹ̀ sí ẹnìkejì rẹ̀; ẹ má fẹ́ ìbúra èké; nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni mo kórìíra,” ni Olúwa wí.

18 Ọ̀rọ̀ Olúwa àwọn ọmọ-ogun sì tọ mi wá wí pé.

19 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwẹ̀ oṣù kẹrin, karùn-ún, keje, àti tí ẹ̀kẹwàá, yóò jẹ́ ayọ̀ àti dídùn inú, àti àpéjọ àríyá fún ilé Juda; nítorí náà, ẹ fẹ́ òtítọ́ àti àlàáfíà.”

20 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Àwọn ènìyàn yóò sá à tún wa, àti ẹni tí yóò gbe ìlú ńlá púpọ̀. 21 Àwọn ẹni tí ń gbé ìlú ńlá kan yóò lọ sí òmíràn, wí pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a yára lọ gbàdúrà kí a sì wá ojúrere Olúwa, àti láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Èmi pẹ̀lú yóò sì lọ.’ 22 Nítòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn alágbára orílẹ̀-èdè yóò wá láti wá Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní Jerusalẹmu; àti láti gbàdúrà, àti láti wá ojúrere Olúwa.”

23 Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé: “Ní àwọn ọjọ́ wọ̀nyí ni ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àti orílẹ̀-èdè yóò dìímú, àní yóò di etí aṣọ ẹni tí i ṣe Júù mú, wí pé, ‘Àwa yóò ba ọ lọ, nítorí àwa tí gbọ́ pé, Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ.’ ”

Ìfihàn 19

Haleluya

19 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí mo gbọ́ ohùn ńlá ní ọ̀run bí ẹni pé tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, ń wí pé:

“Haleluya!
Ti Olúwa Ọlọ́run wa ni ìgbàlà, àti ọlá àti agbára,
    (A)nítorí òtítọ́ àti òdodo ni ìdájọ́ rẹ̀.
Nítorí o ti ṣe ìdájọ́ àgbèrè ńlá a nì,
    tí o fi àgbèrè rẹ̀ ba ilẹ̀ ayé jẹ́, ó sì ti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ náà.”

(B)Àti lẹ́ẹ̀kejì wọ́n wí pé:

“Haleluya!
Èéfín rẹ̀ sì gòkè lọ láé àti láéláé.”

Àwọn àgbà mẹ́rìnlélógún nì, àti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin nì sì wólẹ̀, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run tí ó jókòó lórí ìtẹ́, wí pé:

“Àmín, Haleluya!”

(C)Ohùn kan sì ti ibi ìtẹ́ náà jáde wá, wí pé:

“Ẹ máa yin Ọlọ́run wa,
    ẹ̀yin ìránṣẹ́ rẹ̀ gbogbo,
ẹ̀yin tí ó bẹ̀rù rẹ̀,
    àti èwe àti àgbà!”

Mo sì gbọ́ bí ẹni pé ohùn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àti bí ìró omi púpọ̀, àti bí ìró àrá ńláńlá, ń wí pé:

“Haleluya!
Nítorí Olúwa Ọlọ́run wa, Olódùmarè ń jẹ ọba.
(D)Ẹ jẹ́ kí a yọ̀, kí inú wa kí ó sì dùn gidigidi,
    kí a sì fi ògo fún un.
Nítorí pé ìgbéyàwó Ọ̀dọ́-Àgùntàn dé,
    aya rẹ̀ sì ti múra tán.
Òun ni a sì fi fún pé kí ó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀
    wíwẹ́ tí ó funfun gbòò.”

(Nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ nì dúró fún iṣẹ́ òdodo àwọn ènìyàn mímọ́.)

Ó sì wí fún mi pé, “Kọ̀wé rẹ̀, ‘Ìbùkún ni fún àwọn tí a pè sí àsè alẹ́ ìgbéyàwó ọ̀dọ́-àgùntàn.’ ” Ó sì wí fún mi pé: “Ìwọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ òtítọ́ Ọlọ́run.”

10 Mo sì wólẹ̀ ní ẹsẹ̀ rẹ̀ láti foríbalẹ̀ fún un. Ó sì wí fún mi pé, “Wò ó, má ṣe bẹ́ẹ̀: ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ni èmi, àti ti àwọn arákùnrin rẹ̀ tí wọ́n di ẹ̀rí Jesu mú. Foríbalẹ̀ fún Ọlọ́run: nítorí pé ẹ̀rí Jesu ni ìsọtẹ́lẹ̀.”

Ẹni tó gun ẹṣin funfun

11 (E)Mo sì rí ọ̀run ṣí sílẹ̀, sì wò ó, ẹṣin funfun kan; ẹni tí ó jókòó lórí rẹ̀ ni à ń pè ní Olódodo àti Olóòtítọ́, nínú òdodo ni ó sì ń ṣe ìdájọ́, tí ó ń jagun. 12 (F)Ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, àti ní orí rẹ̀ ni adé púpọ̀ wà; ó sì ní orúkọ kan tí a kọ, tí ẹnikẹ́ni kò mọ́, bí kò ṣe òun tìkára rẹ̀. 13 A sì wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí a tẹ̀ bọ inú ẹ̀jẹ̀: a sì ń pe orúkọ rẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. 14 Àwọn ogun tí ń bẹ ní ọ̀run tí a wọ̀ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ wíwẹ́, funfun àti mímọ́, sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn lórí ẹṣin funfun. 15 (G)Àti láti ẹnu rẹ̀ ni idà mímú ti ń jáde lọ, kí ó lè máa fi sá àwọn orílẹ̀-èdè: “Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn.” Ó sì ń tẹ ìfúntí àti ìbínú Ọlọ́run Olódùmarè. 16 (H)Ó sì ní lára aṣọ rẹ̀ àti ni ìtàn rẹ̀ orúkọ kan tí a kọ:

ọba àwọn ọba àti olúwa àwọn olúwa.

17 (I)Mo sì rí angẹli kan dúró nínú oòrùn; ó sì fi ohùn rara kígbe, ó ń wí fún gbogbo àwọn ẹyẹ tí ń fò ní agbede-méjì ọ̀run pé: “Ẹ wá ẹ sì kó ara yín jọ pọ̀ sí àsè ńlá Ọlọ́run; 18 kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ ẹran-ara àwọn ọba, àti ẹran-ara àwọn olórí ogun àti ẹran-ara àwọn ènìyàn alágbára, àti ẹran àwọn ẹṣin, àti ti àwọn tí ó jókòó lórí wọn, àti ẹran-ara ènìyàn gbogbo, àti ti òmìnira, àti ti ẹrú, àti ti èwe àti ti àgbà.”

19 Mo sì rí ẹranko náà àti àwọn ọba ayé, àti àwọn ogun wọn tí a gbá jọ láti bá ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà àti ogun rẹ̀ jagun. 20 A sì mú ẹranko náà, àti wòlíì èké nì pẹ̀lú rẹ̀, tí ó ti ń ṣe iṣẹ́ ìyanu níwájú rẹ̀, èyí tí ó fi ń tan àwọn tí ó gba ààmì ẹranko náà àti àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún àwòrán rẹ̀ jẹ. Àwọn méjèèjì yìí ni a sọ láààyè sínú adágún iná tí ń fi sulfuru jó. 21 Àwọn ìyókù ni a sì fi idà ẹni tí ó jókòó lórí ẹṣin náà pa, àní idà tí ó ti ẹnu rẹ̀ jáde: Gbogbo àwọn ẹyẹ sì ti ipa ẹran-ara wọn yó.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.