Old/New Testament
Ère wúrà àti iná ìléru
3 Nebukadnessari ọba gbẹ́ ère wúrà kan, èyí tí gíga rẹ̀ tó àádọ́rùn-ún ìgbọ̀nwọ́, tí fífẹ̀ rẹ̀ tó ẹsẹ̀ mẹ́fà, ó sì gbé e kalẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dura ní agbègbè ìjọba Babeli. 2 Nígbà náà ni ọba ránṣẹ́ pe àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn ìgbìmọ̀, àwọn baálẹ̀, àwọn balógun, àwọn onídàájọ́, àwọn olùtọ́jú ìṣúra àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba láti wá sí ibi ìyàsímímọ́ ère tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. 3 Nígbà náà ni àwọn ọmọ-aládé, àwọn olóyè, àwọn onímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn onídàájọ́ àti gbogbo àwọn olórí agbègbè ìjọba, wọn péjọ láti ya ère tí Nebukadnessari ọba gbé kalẹ̀ sí mímọ́, gbogbo wọn sì dúró síwájú u rẹ̀.
4 Nígbà náà ni a kéde kígbe sókè wí pé, “Ohun tí a paláṣẹ fún un yín láti ṣe nìyìí, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo: 5 (A)Bí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò, kí ẹ wólẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀. 6 Ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ̀ tí kò bá wólẹ̀, kí ó fi orí balẹ̀, kí a ju ẹni náà sínú iná ìléru.”
7 Nítorí náà, bí wọ́n ṣe gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, gbogbo ènìyàn, orílẹ̀-èdè, àti èdè gbogbo wólẹ̀, wọ́n sì fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ọba Nebukadnessari gbé kalẹ̀.
8 Ní àsìkò yìí ni àwọn awòràwọ̀ bọ́ síwájú, wọ́n sì fi ẹ̀sùn kan àwọn ará Juda. 9 Wọ́n sọ fún ọba Nebukadnessari pé, “Kí ọba kí ó pẹ́. 10 Ìwọ ọba ti pàṣẹ pé, ẹnikẹ́ni tí ó bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin gbọdọ̀ wólẹ̀ kí ó fi orí balẹ̀ fún ère wúrà 11 àti ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kí ó foríbalẹ̀, a ó sọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sínú iná ìléru. 12 Ṣùgbọ́n àwọn ará Juda kan wà, àwọn tí a yàn láti ṣe olórí agbègbè ìjọba Babeli: Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, wọ́n ò ka ìwọ ọba sí. Wọn kò sin òrìṣà rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
13 Nígbà náà ni Nebukadnessari pàṣẹ ní ìrunú àti ìbínú pé kí a mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wá, wọ́n sì mú wọn wá síwájú ọba. 14 Nebukadnessari wí fún wọn wí pé, “Ṣé òtítọ́ ni, Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego wí pé ẹ̀yin kò sin òrìṣà mi àti pé ẹ̀yin kò fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí èmi gbé kalẹ̀. 15 Ní ìsinsin yìí, tí ẹ̀yin bá ti gbọ́ ohùn ìwo, fèrè, dùùrù, ohun èlò orin olókùn, ìpè àti onírúurú orin, bí ẹ̀yin bá ṣetán láti wólẹ̀ kí ẹ̀yin fi orí balẹ̀ fún ère tí mo gbé kalẹ̀ ó dára. Ṣùgbọ́n tí ẹ̀yìn bá kọ̀ láti sìn ín, lójúkan náà ni a ó gbé e yín jù sínú iná ìléru. Ǹjẹ́, ta ni Ọlọ́run náà tí yóò gbà yín kúrò lọ́wọ́ mi?”
16 Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego dá ọba lóhùn wí pé, “Nebukadnessari, kì í ṣe fún wa láti gba ara wa sílẹ̀ níwájú u rẹ nítorí ọ̀rọ̀ yìí. 17 Bí ẹ̀yin bá jù wá sínú iná ìléru, Ọlọ́run tí àwa ń sìn lágbára láti gbà wá kúrò nínú rẹ̀, yóò sì gbà wá lọ́wọ́ ọ̀ rẹ, ìwọ ọba. 18 Ṣùgbọ́n tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ dájú wí pé àwa kò ní sin òrìṣà rẹ bẹ́ẹ̀ ni a kò ní fi orí balẹ̀ fún ère wúrà tí ìwọ gbé kalẹ̀.”
19 Nígbà náà ni Nebukadnessari bínú gidigidi sí Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ojú u rẹ̀ sì yípadà, ó sì pàṣẹ pé, kí wọn dá iná ìléru náà kí ó gbóná ní ìlọ́po méje ju èyí tí wọn ń dá tẹ́lẹ̀, 20 ó sì pàṣẹ fún àwọn alágbára nínú ogun rẹ̀ pé, kí wọ́n de Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, kí wọn sì jù wọ́n sínú iná ìléru. 21 Nígbà náà ni a dè wọ́n pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn, ṣòkòtò, ìbòrí àti àwọn aṣọ mìíràn, a sì jù wọ́n sínú iná ìléru. 22 Nítorí bí àṣẹ ọba ṣe le tó, tí iná ìléru náà sì gbóná, ọwọ́ iná pa àwọn ọmọ-ogun tí wọ́n mú Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego lọ. 23 Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ṣubú lulẹ̀ sínú iná ìléru náà pẹ̀lú bí a ṣe dè wọ́n.
24 Nígbà náà ni ó ya Nebukadnessari ọba lẹ́nu, ó sì yára dìde dúró, ó béèrè lọ́wọ́ àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ pé, “Ṣe bí àwọn mẹ́ta ni a gbé jù sínú iná?”
Wọ́n wí pé, “Òtítọ́ ni ọba.”
25 Ó sì wí pé, “Wò ó! Mo rí àwọn mẹ́rin tí a kò dè tí wọ́n ń rìn ká nínú iná, ẹni kẹrin dàbí ọmọ Ọlọ́run.”
26 Nígbà náà, ni Nebukadnessari dé ẹnu-ọ̀nà iná ìléru, ó sì kígbe pé, “Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, ẹ jáde, ẹ wá níbi!”
Nígbà náà ni Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego jáde láti inú iná. 27 Àwọn ọmọ-aládé, ìjòyè, baálẹ̀, àwọn ìgbìmọ̀ ọba péjọ sí ọ̀dọ̀ ọ wọn. Wọ́n rí i wí pé iná kò ní agbára lára wọn, bẹ́ẹ̀ ni kò jó wọn lára, bẹ́ẹ̀ ni irun orí wọn kò jóná, àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọn kò jóná, òórùn iná kò rùn ní ara wọn rárá.
28 Nígbà náà, ni Nebukadnessari sọ wí pé, “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego, ẹni tí ó rán angẹli rẹ̀ láti gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tí ó gbẹ́kẹ̀lé e, wọn kọ àṣẹ ọba, dípò èyí, wọ́n fi ara wọn lélẹ̀ ju kí wọn sìn tàbí foríbalẹ̀ fún ọlọ́run mìíràn yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn. 29 Nítorí náà, mo pa àṣẹ pé, ẹnikẹ́ni, orílẹ̀-èdè tàbí èdè kan tí ó bá sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego kí a gé wọn sí wẹ́wẹ́ kí a sì sọ ilé e wọn di ààtàn; nítorí kò sí ọlọ́run mìíràn tí ó lè gba ènìyàn bí irú èyí.”
30 Nígbà náà ni ọba gbé Ṣadraki, Meṣaki àti Abednego ga ní gbogbo agbègbè ìjọba Babeli.
Nebukadnessari lá àlá nípa igi
4 Nebukadnessari ọba,
Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé:
Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín.
Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀!
2 Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ ààmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn.
3 Báwo ni ààmì rẹ̀ ti tóbi tó,
Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó!
Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni;
ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.
4 Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà. 5 Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí. 6 Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Babeli wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. 7 Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. 8 Ní ìkẹyìn Daniẹli wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ̀.)
9 Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi. 10 Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrín ayé, igi náà ga gidigidi. 11 Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé. 12 (B)Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ.
13 “Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run 14 ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. 15 Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí koríko igbó.
“ ‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrín ilẹ̀ ayé. 16 Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.
17 “ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’
18 “Èyí ni àlá tí èmi Nebukadnessari ọba lá. Ní ìsinsin yìí ìwọ Belṣassari, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú rẹ.”
Daniẹli túmọ̀ àlá náà
19 Nígbà náà ni Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari) páyà gidigidi fún ìgbà díẹ̀, èrò inú rẹ̀ sì bà á lẹ́rù. Nígbà náà ni ọba wí pé, “Belṣassari, má ṣe jẹ́ kí àlá náà tàbí ìtumọ̀ rẹ̀ kí ó dẹ́rùbà ọ́.”
Belṣassari sì dáhùn wí pé, “olúwa mi, kí àlá yìí jẹ́ ti àwọn ọ̀tá a rẹ, kí ìtumọ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ti àwọn aṣòdì sí ọ: 20 Igi tí ìwọ rí, tí ó dàgbà, tí ó sì lágbára, tí orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run, tí ó lẹ́wà àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso, tí ó ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn, tí ó ṣe ààbò lórí ẹranko igbó àti èyí tí ẹ̀ka rẹ̀ pèsè ààyè fún ẹyẹ ojú ọ̀run. 21 Èyí tí ewé e rẹ̀ lẹ́wà, tí èso rẹ̀ si pọ̀, nínú èyí tí oúnjẹ sì wà fún gbogbo ẹ̀dá, lábẹ́ èyí tí àwọn ẹranko igbó ń gbé, lórí ẹ̀ka èyí ti àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run ní ibùgbé wọn. 22 Ìwọ ọba ni igi náà, ìwọ ti dàgbà, o sì lágbára, títóbi i rẹ ga ó sì kan ọ̀run, ìjọba rẹ sì gbilẹ̀ títí dé òpin ayé.
23 “Ìwọ ọba, rí ìránṣẹ́ ẹni mímọ́ kan, tí ó ń bọ̀ láti ọ̀run ó sì sọ pé, ‘Gé igi náà kí o sì run ún, ṣùgbọ́n fi kùkùté rẹ tí a dè pẹ̀lú irin àti idẹ sílẹ̀ nínú koríko igbó, nígbà tí gbòǹgbò rẹ̀ sì wà nínú ilẹ̀ kí o sì jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sórí i rẹ̀, jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà láàrín ẹranko búburú títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀.’
24 “Èyí ni ìtumọ̀ àlá rẹ ọba àti àṣẹ tí Ọ̀gá-ògo mú wá sórí ọba olúwa mi: 25 A ó lé ọ jáde kúrò láàrín ènìyàn, ìwọ yóò sì máa gbé láàrín ẹranko búburú: ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run yóò sì sẹ̀ sára rẹ. Ìgbà méje yóò sì kọjá lórí rẹ, títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú. 26 Bí wọ́n ṣe pàṣẹ pé kí wọn fi kùkùté àti gbòǹgbò igi náà sílẹ̀, èyí túmọ̀ sí wí pé a ó dá ìjọba rẹ padà fún ọ lẹ́yìn ìgbà tí o bá ti mọ̀ wí pé, Ọ̀run jẹ ọba. 27 Nítorí náà ọba, jẹ́ kí ìmọ̀ràn mi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún ọ, kọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ sílẹ̀ kí o sì ṣe rere, àti ìwà búburú rẹ nípa ṣíṣe àánú fún àwọn tálákà. Ó lè jẹ́ pé nígbà náà ni ìwọ yóò ṣe rere.”
Àlá náà ṣẹ
28 Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí Nebukadnessari ọba. 29 Lẹ́yìn oṣù kejìlá, bí ọba ṣe ń rìn káàkiri lórí òrùlé ààfin ìjọba Babeli, 30 Ó sọ pé, “Èyí ha kọ́ ni Babeli ńlá tí mo kọ́ gẹ́gẹ́ bí ilé ọba, nípa agbára à mi àti fún ògo ọláńlá à mi?”
31 Bí ọba ṣe ń sọ ọ̀rọ̀ náà lọ́wọ́ ohùn kan wá láti ọ̀run “Ìwọ Nebukadnessari ọba, ìwọ ni a ti pàṣẹ nípa rẹ̀, a ti gba ìjọba à rẹ kúrò ní ọwọ́ ọ̀ rẹ. 32 A ó lé ọ kúrò láàrín àwọn ènìyàn, ìwọ yóò sì lọ máa gbé àárín àwọn ẹranko igbó; ìwọ yóò jẹ koríko bí i màlúù, ìgbà méje yóò kọjá lórí i rẹ títí ìwọ yóò fi mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo jẹ ọba lórí ìjọba ènìyàn àti pé ó ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú.”
33 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni ohun tí a sọ nípa Nebukadnessari ṣẹlẹ̀ sí i. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, ó sì ń jẹ koríko bí i màlúù, ìrì ọ̀run sì ń sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí irun orí rẹ̀ fi gùn bí i ti ìyẹ́ ẹyẹ idì, tí èékánná rẹ̀ sì dàbí i ti ẹyẹ.
34 Ní òpin ìgbà náà, Èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé.
Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni
ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran
35 Gbogbo àwọn ènìyàn ayé
ni a kà sí asán.
Ó ń ṣe bí ó ti wù ú,
pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run,
àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé
tí kò sì ṣí ẹnìkankan tí ó lè dí i lọ́wọ́
tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?”
36 Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ. 37 Báyìí, èmi, Nebukadnessari fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́. Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀.
Ìgbàgbọ́ nínú ọmọ Ọlọ́run
5 (A)Olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbàgbọ́ pé Jesu ni Kristi, a bí i nípa ti Ọlọ́run: àti olúkúlùkù ẹni tí ó fẹ́ràn. Ẹni tí ó bi nì, ó fẹ́ràn ẹni tí a bí nípasẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú. 2 Nípa èyí ni àwa mọ̀ pé àwa fẹ́ràn àwọn ọmọ Ọlọ́run, nígbà tí a bá fẹ́ràn Ọlọ́run, tí a sì ń pa òfin rẹ̀ mọ́. 3 (B)Nítorí èyí ni ìfẹ́ Ọlọ́run, pé kí àwa pa òfin rẹ̀ mọ́: òfin rẹ̀ kò sì nira, 4 (C)nítorí olúkúlùkù ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run, ó ṣẹ́gun ayé. Èyí sì ni ìṣẹ́gun tí ó ṣẹ́gun ayé, àní ìgbàgbọ́ wa. 5 Ta ni ẹni tí ó ṣẹ́gun ayé, bí kò ṣe ẹni tí ó gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jesu jẹ́?
6 (D)Èyí ni ẹni tí ó wá nípa omi àti ẹ̀jẹ̀, Jesu Kristi, kì í ṣe nípa omi nìkan, bí kò ṣe nípa omi àti ẹ̀jẹ̀. Àti pé Ẹ̀mí ni ó sì ń jẹ́rìí, nítorí pé òtítọ́ ni Ẹ̀mí. 7 Nítorí pé àwọn mẹ́ta ni ó ń jẹ́rìí. 8 Ẹ̀mí, omi, àti ẹ̀jẹ̀: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta sì wà ni ìṣọ̀kan. 9 (E)Bí àwa ba ń gba ẹ̀rí ènìyàn, ẹ̀rí Ọlọ́run tóbi jù: nítorí ẹ̀rí Ọlọ́run ni èyí pé, Ó tí jẹ́rìí ní ti Ọmọ rẹ̀. 10 (F)Ẹni tí ó bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́, ó ni ẹ̀rí nínú ara rẹ̀; ẹni tí kò bá gba Ọlọ́run gbọ́, ó ti mú un ni èké; nítorí kò gba ẹ̀rí náà gbọ́ tí Ọlọ́run jẹ́ ní ti Ọmọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rí náà sì ni èyí pé Ọlọ́run fún wa ní ìyè àìnípẹ̀kun, ìyè yìí sì ń bẹ nínú Ọmọ rẹ̀. 12 (G)Ẹni tí ó bá ni Ọmọ, ó ni ìyè; ẹni tí kò bá sì ni Ọmọ Ọlọ́run, kò ní ìyè.
Àwọn àfiyèsí ìparí
13 (H)Nǹkan wọ̀nyí ni mo kọ̀wé rẹ̀ sí yín, àní sí ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́; kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé ẹ̀yin ní ìyè àìnípẹ̀kun, àní fún ẹ̀yin tí ó gba orúkọ Ọmọ Ọlọ́run gbọ́. 14 (I)Èyí sì ni ìgboyà tí àwa ní níwájú rẹ̀, pé bí àwa bá béèrè ohunkóhun gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tí wa; 15 Bí àwa bá sì mọ̀ pé ó ń gbọ́ tí wa, ohunkóhun tí àwa bá béèrè, àwa mọ̀ pé àwa rí ìbéèrè tí àwa ti béèrè lọ́dọ̀ rẹ̀ gbà.
16 Bí ẹnikẹ́ni bá rí arákùnrin rẹ̀ tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú, òun yóò béèrè, Ọlọ́run yóò sì fún un ni ìyè, àní, fún àwọn tí ń dẹ́ṣẹ̀ tí kì í ṣe sí ikú. Ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ sì ikú: èmi kò wí pé ki òun gbàdúrà fún èyí. 17 Gbogbo àìṣòdodo ni ẹ̀ṣẹ̀: ẹ̀ṣẹ̀ kan ń bẹ tí kì í ṣe sí ikú.
18 (J)Àwa mọ̀ pé ẹnikẹ́ni tí a bí nípa ti Ọlọ́run kì í dẹ́ṣẹ̀: ṣùgbọ́n ẹni tí a bí nípa tí Ọlọ́run a pa ara rẹ̀ mọ́, ẹni búburú kò ní lè fọwọ́ kàn án. 19 Àwa mọ̀ pé tí Ọlọ́run ni wá, àti gbogbo ayé ni ó wà lábẹ́ agbára ẹni búburú náà. 20 (K)Àwa sì mọ̀ pé Ọmọ Ọlọ́run dé, ó sì tí fi òye fún wa, kí àwa lè mọ ẹni tí í ṣe òtítọ́, àwa sì ń bẹ nínú ẹni tí í ṣe òtítọ́, àní, nínú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Èyí ni Ọlọ́run òtítọ́, àti ìyè àìnípẹ̀kun.
21 Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ pa ara yín mọ́ kúrò nínú òrìṣà.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.