Old/New Testament
Àsọtẹ́lẹ̀ si Edomu
35 Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 2 “Ọmọ ènìyàn kọjú sí òkè Seiri; sọtẹ́lẹ̀ sí i 3 Kí o sì sọ wí pé: ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmí lòdì sí ọ, òkè Seiri, Èmi yóò sì na ọwọ́ mi síta ní ìlòdì sí ọ, èmi yóò sì mú kí ó di ahoro. 4 Èmi yóò pa àwọn ìlú rẹ run, ìwọ yóò sì di ahoro. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
5 “ ‘Nítorí ìwọ dá ààbò bo ọ̀tẹ̀ àtayébáyé, tí ìwọ sì fi Israẹli lé idà lọ́wọ́, ní àsìkò ìdààmú wọn, ní àsìkò tí ìjìyà wọn dé góńgó, 6 nítorí náà bi mo ti wà láààyè, ni Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò fi ọ kalẹ̀ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. Níwọ́n ìgbà tí ìwọ kò ti kórìíra ìtàjẹ̀ sílẹ̀, ìtàjẹ̀ sílẹ̀ yóò sì lépa rẹ. 7 Èmi yóò mú kí òkè Seiri di ahoro; ọ̀fọ̀ gbogbo àwọn tí ó ń lọ tí ó ń bọ̀ ní èmi yóò gé kúrò lára rẹ. 8 Èmi yóò fi àwọn tí a pa kún orí òkè rẹ: àwọn tí a fi idà pa yóò ṣubú ní orí òkè rẹ, àti ní àárín àwọn òkè rẹ. 9 Èmi yóò mú kí ó di ahoro títí láé; Kò ní sí olùgbé ní ìlú rẹ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.
10 “ ‘Nítorí tí ìwọ sọ pé, “Àwọn orílẹ̀-èdè àti ilẹ̀ méjì wọ̀nyí yóò jẹ́ tiwa, àwa yóò sì gbà wọ́n ní ìní,” bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi Olúwa wà níbẹ̀, 11 nítorí náà níwọ̀n ìgbà tí mo ti wà láààyè, ní Olúwa Olódùmarè wí, èmi yóò hùwà sí ọ ní ìbámu pẹ̀lú ìbínú àti owú tí o fihàn nínú ìkórìíra rẹ sí wọn, èmi yóò fi ara mi hàn ní àárín wọn, nígbà tí mo bá ṣe ìdájọ́ rẹ. 12 Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti gbọ́ gbogbo ohun ẹ̀gàn tí ìwọ ti sọ lòdì sí àwọn òkè Israẹli náà. Ìwọ wí pé, “A sọ wọ́n di ahoro, a sì fi wọ́n fún wa láti run.” 13 Ìwọ lérí sí mi, ó sì sọ̀rọ̀ lòdì sí mí láìsí ìdádúró, èmi sì gbọ́ ọ. 14 Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí gbogbo ayé bá ń yọ̀, èmi yóò mú kí ó di ahoro 15 Nítorí pé ìwọ ń yọ̀ nígbà tí ìní ilé Israẹli di ahoro, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni èmi yóò ṣe hùwà sí ọ. Ìwọ yóò di ahoro, ìwọ òkè Seiri, ìwọ àti gbogbo ará Edomu. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa.’ ”
Àsọtẹ́lẹ̀ kan sí àwọn òkè Israẹli
36 “Ọmọ ènìyàn, sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn òkè gíga Israẹli kí o sì wí pé, ‘Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa. 2 Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Àwọn ọ̀tá sọ nípa yín pé, “Háà! Àwọn ibi gíga ìgbàanì ti di ohun ìní wa.” ’ 3 Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé wọn sọ ọ di ahoro, tí wọn sì ń dọdẹ rẹ ní gbogbo ọ̀nà kí ìwọ kí ó lè di ìní fún àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù, àti ohun ti àwọn ènìyàn ń sọ ọ̀rọ̀ ìríra àti ìdíbàjẹ́ sí, 4 nítorí náà, Ẹ̀yin òkè gíga Israẹli gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè: Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí fún àwọn òkè gíga àti àwọn òkè kéékèèkéé, fún Àfonífojì ńlá àti Àfonífojì kéékèèkéé, fún àwọn ibi ìsọdahoro ìparun àti fún àwọn ìlú tí a ti kọ̀sílẹ̀ tí a ti kó tí àwọn orílẹ̀-èdè tí ó kù ní àyíká sì fi ṣe ẹlẹ́yà, 5 èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ní ìgbóná ọkàn ní mo sọ̀rọ̀ sí àwọn kèfèrí yòókù, àti sí Edomu, nítorí pẹ̀lú ìbínú àti ìjowú ní ọkàn wọn ni wọ́n sọ ilé mi di ohun ìní wọn, kí wọn kí o lè kó pápá oko tútù rẹ̀.’ 6 Nítorí náà, sọtẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Israẹli náà kí o sì sọ sí àwọn òkè gíga náà àti àwọn òkè kéékèèkéé, sí àwọn Àfonífojì ńlá àti sí àwọn Àfonífojì kéékèèkéé: ‘Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi sọ̀rọ̀ nínú ìrunú owú mi nítorí pé ìwọ ti jìyà ìfiṣẹ̀sín àwọn orílẹ̀-èdè. 7 Nítorí náà, Èyí yìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Èmi ṣe ìbúra nípa nína ọwọ́ mi sókè pé; àwọn orílẹ̀-èdè àyíká rẹ náà yóò jìyà ìfiṣẹ̀sín.
8 “ ‘Ṣùgbọ́n ìwọ, òkè gíga Israẹli, yóò mú ẹ̀ka àti èso fún àwọn ènìyàn mi Israẹli, nítorí wọn yóò wá sílé ní àìpẹ́ yìí. 9 Èmi ń ṣe àníyàn fún ọ, èmi yóò sì fi rere wọ̀ ọ́; àwa yóò tu ọ́, àwa yóò sì gbìn ọ́, 10 èmi yóò sì sọ iye àwọn ènìyàn di púpọ̀ nínú rẹ àti gbogbo ilé Israẹli. Àwọn ìlú yóò di ibùgbé, a yóò sì tún àwọn ibi ìparun kọ́. 11 Èmi yóò sọ iye ènìyàn àti ẹran dì púpọ̀ nínú yín, wọn yóò sì so èso, wọn yóò sì di púpọ̀ yanturu. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn máa gbé nínú rẹ bí ti àtẹ̀yìnwá, èmi yóò sì mú kí o ṣe rere ju ìgbà àtijọ́ lọ. Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ pé èmi ni Olúwa. 12 Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn, àní àwọn ènìyàn Israẹli, rìn lórí rẹ̀. Wọn yóò gbà ọ́, ìwọ yóò sì di ogún ìní wọn; ìwọ kì yóò sì gba àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ wọn mọ́.
13 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Nítorí pé àwọn ènìyàn sọ fún ọ pé, “Ìwọ pa àwọn ènìyàn run, ìwọ sì gba àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ wọn,” 14 nítorí náà ìwọ kì yóò pa àwọn ènìyàn run tàbí mú kì orílẹ̀-èdè di aláìlọ́mọ mọ́, ni Olúwa Olódùmarè wí. 15 Èmi kì yóò mú ki ó gbọ́ ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn láti ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́, ìwọ kì yóò jìyà ọ̀rọ̀ ìfiṣẹ̀sín láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tàbí mú kí orílẹ̀-èdè rẹ ṣubú, ni Olúwa Olódùmarè wí.’ ”
16 Síwájú sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 17 “Ọmọ ènìyàn, nígbà tí àwọn ènìyàn Israẹli: ń gbé ní ilẹ̀ wọn, wọ́n bà á jẹ́ nípa ìwà àti ìṣe wọn. Ìwà wọn dàbí nǹkan àkókò àwọn obìnrin ni ojú mi. 18 Nítorí náà mo tú ìbínú mi jáde sórí wọn nítorí wọn ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ àti nítorí pé wọ́n ti fi ère wọn ba a jẹ́. 19 Mo tú wọn ká sí àárín àwọn orílẹ̀-èdè, a sì fọ́n wọn ká sí àwọn ìlú; mo ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìwà àti ìṣe wọn. 20 Gbogbo ibi tí wọ́n lọ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè ni wọn ti sọ orúkọ mímọ́ mi di aláìmọ́, nítorí tí a sọ nípa wọn pé, ‘Ìwọ̀nyí ni àwọn ènìyàn Olúwa, síbẹ̀ wọn ní láti fi ilẹ̀ náà sílẹ̀.’ 21 Orúkọ mímọ́ mi jẹ́ mi lógún, èyí tí ilé Israẹli sọ di aláìmọ́ ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti lọ.
22 “Nítorí náà, sọ fún ilé Israẹli, ‘Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kì í ṣe nítorí rẹ, ìwọ ilé Israẹli, ni èmi yóò ṣe ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣùgbọ́n nítorí orúkọ mímọ́ mi, èyí ti ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti lọ. 23 Èmi yóò fi jíjẹ́ mímọ́ orúkọ ńlá mi, èyí tí a ti sọ di aláìmọ́ hàn ni àárín àwọn orílẹ̀-èdè, orúkọ tí ìwọ ti sọ di aláìmọ́ ni àárín wọn. Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa, ni Olúwa Olódùmarè wí, nígbà tí mo bá fi ara mi hàn ni mímọ́ nípasẹ̀ yín ni iwájú wọn.
24 “ ‘Nítorí èmi yóò mú yín jáde kúrò ni àwọn orílẹ̀-èdè náà; Èmi yóò ṣà yín jọ kúrò ní gbogbo àwọn ìlú náà; Èmi yóò sì mú yín padà sí ilẹ̀ ẹ̀yin tìkára yín. 25 Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára ẹ̀yin yóò sì mọ́; Èmi yóò sì fọ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìwà èérí yin gbogbo àti kúrò nínú gbogbo òrìṣà yin. 26 Èmi yóò fún yín ni ọkàn tuntun, èmi yóò sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín; Èmi yóò sì mú ọkàn òkúta kúrò nínú yín, èmi yóò sì fi ọkàn ẹran fún yín. 27 Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, èmi yóò sì mú ki ẹ tẹ̀lé àṣẹ mi, kí ẹ sì fiyèsí àti pa òfin mi mọ́. 28 Ẹ̀yin yóò sì máa gbé ilẹ̀ náà tí mo ti fi fún àwọn baba ńlá yín; ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ènìyàn mi èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín. 29 Èmi yóò sì gbà yín kúrò nínú gbogbo ìwà àìmọ́ yín. Èmi yóò pèsè ọkà, èmi yóò sì mú kí ó pọ̀ yanturu, èmi kì yóò sì mú ìyàn wá sí orí yín. 30 Èmi yóò sọ èso àwọn igi yín àti ohun ọ̀gbìn oko yín di púpọ̀, nítorí kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jìyà ìdójútì mọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè náà nítorí ìyàn. 31 (A)Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò rántí àwọn ọ̀nà búburú àti àwọn ìwà ìkà yín, ẹ̀yin yóò sì kórìíra ara yín fún ẹ̀ṣẹ̀ yín, ìwà tí kò bójúmu. 32 Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé ń kò ṣe nǹkan wọ̀nyí nítorí yín, ni Olúwa Olódùmarè wí. Jẹ kí ojú kí ó tì yín, kí ẹ sì gba ẹ̀tẹ́ nítorí ìwà yín ẹ̀yin ilé Israẹli!
33 “ ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ní ọjọ́ tí mo wẹ̀ yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo, èmi yóò ṣe àtúnṣe àwọn ìlú yín, wọn yóò sì ṣe àtúnkọ́ ìwólulẹ̀. 34 Ilẹ̀ ahoro náà ní àwa yóò tún kọ́ ti kì yóò wà ní ahoro lójú àwọn tí ó ń gba ibẹ̀ kọjá mọ́. 35 Wọn yóò sọ wí pé, “Ilẹ̀ yìí tí ó ti wà ní ahoro tẹ́lẹ̀ ti dàbí ọgbà Edeni; àwọn ìlú tí ó wà ní wíwó lulẹ̀, ahoro tí a ti parun, ni àwa yóò mọdi sí tí yóò sì wà fún gbígbé ni ìsinsin yìí.” 36 Nígbà náà àwọn orílẹ̀-èdè tí ó wà ní àyíká yín tí ó kù yóò mọ̀ pé èmi Olúwa ti tún àwọn ohun tí ó bàjẹ́ kọ́, mo sì ti tún ohun tí ó di ìṣòfo gbìn. Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, èmi yóò sì ṣe e?’
37 “Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè sọ: Lẹ́ẹ̀kan sí i èmi yóò yí sí ilé Israẹli, èmi yóò sì ṣe èyí fún wọn. Èmi yóò mú kí àwọn ènìyàn yín pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí àgùntàn, 38 Kí ó pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ bí ọ̀wọ́ ẹran fún ìrúbọ ní Jerusalẹmu ní àsìkò àjọ̀dún tí a yàn. Ìlú ti a parun yóò wá kún fún agbo àwọn ènìyàn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”
1 Simoni Peteru, ìránṣẹ́ àti aposteli Jesu Kristi,
Sí àwọn tí ó gba irú iyebíye ìgbàgbọ́ kan náà pẹ̀lú wá nínú òdodo Ọlọ́run wa àti ti Jesu Kristi Olùgbàlà.
2 Kí oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà máa bí sí i fún yín nínú ìmọ̀ Ọlọ́run àti ti Jesu Olúwa wa.
Mímú kí ìpè àti yíyàn ẹni dájú
3 Bí agbára rẹ̀ bí Ọlọ́run ti fún wa ní ohun gbogbo tí a nílò fún ṣe ti ìyè àti ti ìwà-bí-Ọlọ́run, nípa ìmọ̀ ẹni tí ó pè wá nípa Ògo àti ìṣeun rẹ̀. 4 Nípa èyí tí ó fi àwọn ìlérí rẹ̀ tí ó tóbi púpọ̀ tí ó ṣe iyebíye fún wa: pé nípa ìwọ̀nyí ni kí ẹ̀yin lè di alábápín nínú àbùdá ti Ọlọ́run, nígbà tí ẹ̀yin bá ti yọ kúrò nínú ìbàjẹ́ tí ó ń bẹ nínú ayé nípa ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.
5 Àti nítorí ìdí èyí, ẹ máa ṣe àìsimi gbogbo, ẹ fi ìwà rere kún ìgbàgbọ́, àti ìmọ̀ kún ìwà rere; 6 àti àìrékọjá kún ìmọ̀; àti sùúrù kún àìrékọjá; àti ìwà-bí-Ọlọ́run kún sùúrù. 7 Àti ìfẹ́ ọmọnìkejì kún ìwà-bí-Ọlọ́run; àti ìfẹ́ni kún ìfẹ́ ọmọnìkejì. 8 Nítorí bí ẹ̀yin bá ní nǹkan wọ̀nyí tí wọ́n bá sì pọ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ ṣe ọ̀lẹ tàbí aláìléso nínú ìmọ̀ Olúwa wa Jesu Kristi. 9 Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ṣe aláìní nǹkan wọ̀nyí, kò lè ríran ní òkèèrè, ó fọjú, ó sì ti gbàgbé pé a ti wẹ òun nù kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.
10 Nítorí náà, ará ẹ túbọ̀ máa ṣe àìsimi láti sọ ìpè àti yíyàn yín di dájúdájú: nítorí bí ẹ̀yin bá ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, ẹ̀yin kì yóò ṣubú. 11 Nítorí báyìí ni a ó pèsè fún yín lọ́pọ̀lọpọ̀ láti wọ ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.
Àsọtẹ́lẹ̀ ti ọrọ̀ Ọlọ́run
12 Nítorí náà, èmi ó máa rán yin létí àwọn nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀yin ti mọ̀ wọ́n, tí ẹsẹ̀ yín sì múlẹ̀ nínú òtítọ́ tí ẹ ní báyìí. 13 Èmi sì rò pé ó tọ́ láti máa mú wọn wá sí ìrántí yín, níwọ̀n ìgbà tí èmí ba ń bẹ nínú àgọ́ ara yìí. 14 Bí èmi ti mọ̀ pé, bíbọ́ àgọ́ ara mi yìí sílẹ̀ kù sí dẹ̀dẹ̀, àní, bí Olúwa wa Jesu Kristi ti fihàn mí. 15 Èmi ó sì máa ṣaápọn pẹ̀lú, kí ẹ̀yin lè máa rántí nǹkan wọ̀nyí nígbà gbogbo lẹ́yìn ikú mi.
16 Nítorí kì í ṣe bí ẹni tí ó ń tọ ìtàn asán lẹ́yìn tí a fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n là sílẹ̀, nígbà tí àwa sọ fún yín ní ti agbára àti wíwá Jesu Kristi Olúwa, ṣùgbọ́n ẹlẹ́rìí ọláńlá rẹ̀ ni àwa jẹ́. 17 (A)Nítorí tí Ó gba ọlá àti ògo láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, nígbà tí irú ohùn yìí fọ̀ sí i láti inú ògo ńlá náà wá pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.” 18 Àwa pẹ̀lú sì gbọ́ ohun yìí tí ó ti ọ̀run wá nígbà tí àwa wà pẹ̀lú rẹ̀ ní orí òkè mímọ́ náà.
19 Àwa sì ní ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì dunjúdunjú sí i, èyí tí ó yẹ kí ẹ kíyèsi gẹ́gẹ́ bí fìtílà tó ń mọ́lẹ̀ níbi tí òkùnkùn gbé wà, títí ilẹ̀ yóò fi mọ́, tí ìràwọ̀ òwúrọ̀ yóò sì yọ lọ́kàn yín. 20 Ju gbogbo rẹ̀ lọ, kí ẹ ní òye yìí pé kò sí àsọtẹ́lẹ̀ ìwé mímọ́ kankan tí ó wáyé nípa ìtumọ̀ wòlíì fún rara rẹ̀. 21 Nítorí àsọtẹ́lẹ̀ kan kò ti ipá ìfẹ́ ènìyàn wá rí; ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ń sọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run bí a ti ń darí wọn láti ọwọ́ Ẹ̀mí Mímọ́ wá.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.