Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 11-13

Ẹ̀ka láti ọ̀dọ̀ Jese

11 (A)Èèkàn kan yóò sọ láti ibi
    kùkùté Jese,
láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan
    yóò ti so èso.
(B)Ẹ̀mí Olúwa yóò sì bà lé e
    ẹ̀mí ọgbọ́n àti ti òye
ẹ̀mí ìmọ̀ràn àti ti agbára
    ẹ̀mí ìmọ̀ àti ti ìbẹ̀rù Olúwa
Òun yóò sì ní inú dídùn nínú ìbẹ̀rù Olúwa.

    Òun kì yóò ṣe ìdájọ́ pẹ̀lú ohun tí ó fi ojú u rẹ̀ rí,
    tàbí pẹ̀lú ohun tí ó fi etí i rẹ̀ gbọ́,
Ṣùgbọ́n pẹ̀lú òdodo ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn aláìní,
    pẹ̀lú òtítọ́ ni yóò ṣe ìpinnu
fún àwọn aláìní ayé.
    Òun yóò lu ayé pẹ̀lú ọ̀pá tí ó wà ní ẹnu rẹ̀,
    pẹ̀lú èémí ẹnu rẹ̀ ni yóò pa àwọn ìkà.
(C)Òdodo ni yóò jẹ́ ìgbànú rẹ̀
    àti òtítọ́ ni yóò ṣe ọ̀já yí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ká.

(D)Ìkookò yóò sì máa bá ọmọ àgùntàn gbé,
    ẹkùn yóò sì sùn ti ewúrẹ́
ọmọ màlúù òun ọmọ kìnnìún
    àti ọmọ ẹran ó wà papọ̀
    ọ̀dọ́mọdé yóò sì máa dà wọ́n.
Màlúù àti beari yóò máa jẹun pọ̀,
    àwọn ọmọ wọn yóò dùbúlẹ̀ pọ̀,
kìnnìún yóò sì máa jẹ koríko
    gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù.
Ọ̀dọ́mọdé yóò ṣeré lẹ́bàá ihò ọká,
    ọmọdé yóò ki ọwọ́ rẹ̀ bọ ìtẹ́ paramọ́lẹ̀.
Wọn kò ní ṣe ni léṣe tàbí pa ni run
    ní gbogbo òkè mímọ́ mi,
nítorí gbogbo ayé yóò kún fún ìmọ̀ Olúwa
    gẹ́gẹ́ bí omi ti bo Òkun.

10 (E)Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo. 11 Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò na ọwọ́ rẹ̀ jáde nígbà kejì láti tún gba àwọn tí ó ṣẹ́kù àní àwọn tí a ṣẹ́kù nínú àwọn ènìyàn an rẹ̀ láti Asiria wá, láti ìsàlẹ̀ Ejibiti àti Òkè Ejibiti, láti Kuṣi, láti Elamu láti Babiloni, láti Hamati àti láti àwọn erékùṣù inú Òkun.

12 Òun yóò gbé àsíá sókè fún àwọn orílẹ̀-èdè,
    yóò sì kó àwọn ìgbèkùn Israẹli jọ,
yóò kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda tí a ti fọ́n káàkiri jọ,
    láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé.
13 Owú jíjẹ Efraimu yóò pòórá,
    àwọn ọ̀tá Juda ni a ó ké kúrò,
Efraimu kò ní jowú Juda,
    tàbí Juda kó dojúkọ Efraimu.
14 Wọn yóò fò mọ́ èjìká Filistini
    sí apá ìwọ̀-oòrùn,
wọn yóò pawọ́pọ̀ kọlu àwọn
    ènìyàn apá ìlà-oòrùn.
Wọn yóò gbé ọwọ́ wọn lé Edomu àti Moabu,
    àwọn ará Ammoni yóò sì di ìwẹ̀fà wọn.
15 Olúwa yóò sọ di gbígbé
    àyasí Òkun Ejibiti,
pẹ̀lú atẹ́gùn gbígbóná ni yóò na ọwọ́ rẹ̀,
    kọjá lórí odò Eufurate.
Òun yóò sì sọ ọ́ di ọmọdò méje
    tó fi jẹ́ pé àwọn ènìyàn
    yóò máa là á kọjá pẹ̀lú bàtà.
16 Ọ̀nà gidi yóò wà fún àwọn ènìyàn an rẹ̀ tí ó ṣẹ́kù
    tí ó kù sílẹ̀ ní Asiria,
gẹ́gẹ́ bí ó ti wà fún Israẹli
    nígbà tí wọ́n gòkè láti Ejibiti wá.

Orin ìyìn

12 Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé:

“Èmi ó yìn ọ́, Olúwa.
    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi
ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀
ìwọ sì ti tù mí nínú.
Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi,
    èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù.
Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi,
    òun ti di ìgbàlà mi.”
Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi
    láti inú kànga ìgbàlà.

Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé:

“Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀,
    Jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè,
ohun tí ó ti ṣe
    kí o sì kéde pé a ti gbé
    orúkọ rẹ̀ ga.
Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo,
    jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé.
Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn Sioni,
    nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo
    ti Israẹli láàrín yín.”

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Babeli

13 (F)Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Babeli

    èyí tí Isaiah ọmọ Amosi rí:
Gbé àsíá sókè ní orí òkè gbẹrẹfu,
    kígbe sí wọn, pè wọ́n
    láti wọlé sí ẹnu-ọ̀nà àwọn ọlọ́lá.
Mo ti pàṣẹ fún àwọn ẹni mímọ́ mi,
    mo ti pe àwọn jagunjagun mi
láti gbé ìbínú mi jáde
    àwọn tí ń yọ̀ nínú ìṣẹ́gun mi.

Gbọ́ ohùn kan ní àwọn orí òkè,
    gẹ́gẹ́ bí i ti ogunlọ́gọ̀ ènìyàn
Gbọ́ ìdàrúdàpọ̀ láàrín àwọn ìjọba,
    gẹ́gẹ́ bí i ti ìkórajọ àwọn orílẹ̀-èdè!
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti kó ogun rẹ̀ jọ
    àwọn jagunjagun fún ogun.
Wọ́n wá láti ọ̀nà jíjìn réré,
    láti ìpẹ̀kun ọ̀run wá
Olúwa pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ìbínú rẹ̀,
    láti pa gbogbo orílẹ̀-èdè náà run.

Ẹ hu, nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ tòsí,
    yóò sì wá gẹ́gẹ́ bí ìparun láti ọ̀dọ̀ Alágbára jùlọ.
Nítorí èyí, gbogbo ọwọ́ ni yóò rọ,
    ọkàn ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò rẹ̀wẹ̀sì.
Ẹ̀rù yóò gbá wọn mú,
    ìrora àti ìpayínkeke yóò dìwọ́n mú,
wọn yóò kérora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó ń rọbí.
    Ẹnìkínní yóò wo ẹnìkejì rẹ̀ pẹ̀lú ìpayà
    ojú wọn á sì gbinájẹ.

Kíyèsi i, ọjọ́ Olúwa ń bọ̀
    ọjọ́ búburú, pẹ̀lú ìbínú
àti ìrunú gbígbóná—
    láti sọ ilẹ̀ náà dahoro,
    àti láti pa àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ inú rẹ̀ run.
10 (G)Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn
    kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn.
Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn
    àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.
11 Èmi yóò jẹ ayé ní ìyà nítorí ibi rẹ̀,
    àwọn ìkà nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Èmi yóò fi òpin sí gààrù àwọn agbéraga
    èmi ó sì rẹ ìgbéraga àwọn aláìláàánú sílẹ̀.
12 Èmi yóò jẹ́ kí ọkùnrin kí ó wọn
    ju ojúlówóo wúrà lọ,
    yóò sì ṣọ̀wọ́n ju wúrà Ofiri lọ.
13 Nítorí náà èmi yóò jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó wárìrì;
    ayé yóò sì mì tìtì ní ibùjókòó rẹ̀
láti ọwọ́ ìbínú Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná rẹ.

14 Gẹ́gẹ́ bí egbin tí à ń dọdẹ rẹ̀,
    gẹ́gẹ́ bí àgùntàn tí kò ní olùṣọ́,
ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò padà tọ àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ,
    ọ̀kọ̀ọ̀kan yóò sá padà sí ilẹ̀ abínibí i rẹ̀.
15 Ẹnikẹ́ni tí a bá gbámú ni a ó wọ́ nílẹ̀ tuurutu,
    gbogbo àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ ni yóò ti ipa idà kú.
16 Àwọn ọ̀dọ́mọdé wọn ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́ níṣojú wọn,
    gbogbo ilẹ̀ wọn ni a ó kó
    àwọn aya wọn ni a ó sì bá dàpọ̀.

17 Kíyèsi i, èmi yóò ru àwọn Media sókè sí wọn,
    àwọn tí kò bìkítà fún fàdákà
    tí kò sì ní inú dídùn sí wúrà.
18 Ọrùn wọn yóò ré àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin lulẹ̀;
    wọn kò ní ṣàánú àwọn ọ̀dọ́mọdé
    tàbí kí wọn ṣíjú àánú wo àwọn ọmọdé.
19 Babeli, ohun ọ̀ṣọ́ àwọn ìjọba
    ògo ìgbéraga àwọn ará Babeli
ni Ọlọ́run yóò da ojú rẹ̀ bolẹ̀
    gẹ́gẹ́ bí Sodomu àti Gomorra.
20 A kì yóò tẹ̀ ibẹ̀ dó mọ́
    tàbí kí á gbé inú rẹ̀ láti ìrandíran;
    Ará Arabia kì yóò pa àgọ́ níbẹ̀ mọ́,
    olùṣọ́-àgùntàn kan kì yóò kó ẹran rẹ̀ sinmi níbẹ̀.
21 (H)Ṣùgbọ́n àwọn ẹranko igbó ni yóò dùbúlẹ̀ níbẹ̀,
    àwọn ajáko yóò kún inú ilé wọn,
níbẹ̀ ni àwọn òwìwí yóò máa gbé
    níbẹ̀ ni àwọn ewúrẹ́ igbó yóò ti máa bẹ́ kiri.
22 Ìkookò yóò máa gbó ní ibùba wọn,
    àwọn ajáko nínú arẹwà ààfin wọn.

Efesu 4

Ìṣọ̀kan nínú ara Jesu

Nítorí náà, èmi òǹdè nínú Olúwa ń bẹ̀ yín pé kí ẹ̀yin máa gbé ìgbé ayé tí ó yẹ sí ìpè tí a pè yín sí. (A)Pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ gbogbo àti inú tútù, pẹ̀lú ìpamọ́ra, ẹ máa fi ìfẹ́ faradà fún ẹnìkejì yín. Kí ẹ sì máa làkàkà láti pa ìṣọ̀kan Ẹ̀mí mọ́ ni ìdàpọ̀ àlàáfíà. Ara kan ni ń bẹ, àti Ẹ̀mí kan, àní bí a ti pè yín sínú ìrètí kan nígbà tí a pè yín. Olúwa kan, ìgbàgbọ́ kan àti ìtẹ̀bọmi kan. Ọlọ́run kan àti Baba gbogbo aráyé, ẹni tí ó ṣe olórí ohun gbogbo àti nípá gbogbo àti nínú ohun gbogbo.

Ṣùgbọ́n olúkúlùkù wa ni a fi oore-ọ̀fẹ́ fun gẹ́gẹ́ bi òṣùwọ̀n ẹ̀bùn Kristi. (B)Nítorí náà a wí pé:

“Nígbà tí ó gòkè lọ sí ibi gíga,
    ó di ìgbèkùn ni ìgbèkùn,
    ó sì fi ẹ̀bùn fun ènìyàn.”

(Ǹjẹ́ ní ti pé, “Ó gòkè lọ!” Kín ni ó túmọ̀ sí, bí kò ṣe pé ó kọ́ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú lọ sí ìsàlẹ̀ ilẹ̀? 10 Ẹni tí ó ti sọ̀kalẹ̀, Òun kan náà ni ó sì ti gòkè rékọjá gbogbo àwọn ọ̀run, kí ó lè kún ohun gbogbo.) 11 Nítorí náà ó sì ti fi àwọn kan fún ni bí aposteli; àti àwọn mìíràn bí i wòlíì; àti àwọn mìíràn bí efangelisti, àti àwọn mìíràn bí olùṣọ́-àgùntàn àti olùkọ́ni. 12 Fún àṣepé àwọn ènìyàn mímọ́ fun iṣẹ́ ìránṣẹ́, fún ìmúdàgbà ara Kristi. 13 Títí gbogbo wa yóò fi dé ìṣọ̀kan ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀ Ọmọ Ọlọ́run, títí a ó fi di ọkùnrin, títí a ó fi dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìwọ̀n Kristi.

14 Kí àwa má ṣe jẹ́ èwe mọ́, tí a ń fi gbogbo afẹ́fẹ́ ẹ̀kọ́ tì síwá tì sẹ́yìn, tí a sì fi ń gbá kiri, nípa ìtànjẹ ènìyàn, nípa àrékérekè fun ọgbọ́nkọ́gbọ́n àti mú ni ṣìnà; 15 (C)Ṣùgbọ́n ká a máa sọ òtítọ́ ní ìfẹ́, kí a lè máa dàgbàsókè nínú rẹ̀ ní ohun gbogbo ẹni tí i ṣe orí, àní Kristi. 16 (D)Láti ọ̀dọ̀ ẹni ti ara náà tí a ń so ṣọ̀kan pọ̀, tí ó sì ń fi ara mọ́ra, nípasẹ̀ oríkèé kọ̀ọ̀kan tí a ti pèsè, nígbà tí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan bá ń ṣiṣẹ́ dáradára, yóò mú ara dàgbà, yóò sì gbé ara òun tìkára rẹ̀ dìde nínú ìfẹ́.

Gbígbé ìgbé ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìmọ́lẹ̀

17 Ǹjẹ́ èyí ni mo ń wí, tí mo sì ń jẹ́rìí nínú Olúwa pé, láti ìsinsin yìí lọ, kí ẹ̀yin má ṣe rìn mọ́, àní gẹ́gẹ́ bí àwọn aláìkọlà ti ń rìn nínú ìrònú asán wọn. 18 Òye àwọn ẹni tí ó ṣókùnkùn, a sì yà wọ́n nínú ìyè Ọlọ́run nítorí àìmọ̀ tí ń bẹ nínú wọn, nítorí líle ọkàn wọn. 19 Àwọn ẹni tí ọkàn wọn le rékọjá, tí wọ́n sì ti fi ara wọn fún wọ̀bìà, láti máa fi ìwọra ṣiṣẹ́ ìwà èérí gbogbo.

20 Ṣùgbọ́n a kò fi Kristi kọ́ yín bẹ́ẹ̀. 21 Bí ó bá ṣe pé nítòótọ́ ni ẹ ti gbóhùn rẹ̀ ti a sì ti kọ́ yín nínú rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ti ń bẹ nínú Jesu. 22 Pé, ní tì ìwà yín àtijọ́, kí ẹ̀yin bọ́ ògbólógbòó ọkùnrin nì sílẹ̀, èyí tí ó díbàjẹ́ gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹ̀tàn; 23 Kí ẹ sì di tuntun ni ẹ̀mí inú yín; 24 kí ẹ sì gbé ọkùnrin tuntun ni wọ̀, èyí tí a dá ni àwòrán Ọlọ́run nínú òdodo àti ìwà mímọ́ ti òtítọ́.

25 (E)Nítorí náà ẹ fi èké ṣíṣe sílẹ̀, ki olúkúlùkù yín kí ó máa ba ọmọnìkejì rẹ̀ sọ òtítọ́, nítorí ẹ̀yà ara ọmọnìkejì wa ni àwa jẹ́. 26 Nínú ìbínú yín, ẹ máa ṣe ṣẹ̀, ẹ má ṣe jẹ́ kí oòrùn wọ̀ bá ìbínú yín: 27 Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe fi ààyè ẹ̀gbẹ́ kan fún Èṣù. 28 Kí ẹni tí ń jalè má ṣe jalè mọ́: ṣùgbọ́n kí ó kúkú máa ṣe làálàá, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣiṣẹ́ ohun tí ó dára, kí òun lè ní láti pín fún ẹni tí ó ṣe aláìní.

29 Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọ̀rọ̀ ìdíbàjẹ́ kan ti ẹnu yín jáde, ṣùgbọ́n irú èyí tí ó lè ràn ìdàgbàsókè wọn lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí wọ́n nílò, kí ó lè máa fi oore-ọ̀fẹ́ fún àwọn tí ń gbọ́. 30 Ẹ má sì ṣe mú Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run bínú, ẹni tí a fi ṣe èdìdì yín dé ọjọ́ ìdáǹdè. 31 Gbogbo ìwà kíkorò àti ìbínú, àti ìrunú, àti ariwo, àti ọ̀rọ̀ búburú ni kí a mú kúrò lọ́dọ̀ yín, pẹ̀lú gbogbo àrankàn: 32 Ẹ máa ṣoore fún ọmọnìkejì yín, ẹ ní ìyọ́nú, ẹ máa dáríjì ara yín, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run nínú Kristi ti dáríjì yín.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.