Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Isaiah 32-33

Ìjọba òdodo náà

32 Wò ó, ọba kan yóò jẹ nínú òdodo
    àwọn olórí yóò máa fi ìdájọ́ ṣe àkóso.
Ẹnìkọ̀ọ̀kan yóò jẹ́ bí ibi ìṣápamọ́ kúrò lọ́wọ́ afẹ́fẹ́
    àti ààbò kúrò lọ́wọ́ ìjì,
gẹ́gẹ́ bí odò omi ní ilẹ̀ aṣálẹ̀,
    àti bí òjìji àpáta ńlá ní ilẹ̀ gbígbẹ.

Nígbà náà ni ojú àwọn tí ó rí kò ní padé mọ́,
    àti etí àwọn tí ó gbọ́ yóò tẹ́tí sílẹ̀.
Ọkàn àwọn oníwàdùwàdù ni yóò là tí yóò sì yè,
    àti ahọ́n tí ń kólòlò ni yóò là geerege.
A kò ní pe òmùgọ̀ ní ọlọ́lá mọ́
    tàbí kí a fi ọ̀wọ̀ tí ó ga jù fún aláìlóòótọ́ ènìyàn.
Nítorí òmùgọ̀ sọ̀rọ̀ òmùgọ̀,
    ọkàn rẹ̀ kún fún ìwà ibi:
òun hùwà àìwà-bí-Ọlọ́run
    ó sì ń tan àṣìṣe tí ó kan Olúwa kalẹ̀;
ẹni ebi ń pa ló fi sílẹ̀ lófo
    àti fún àwọn tí òǹgbẹ ń gbẹ
    ni ó mú omi kúrò.
Ibi ni gbogbo ọgbọ́n àwọn ìkà ènìyàn jẹ́,
    ó ń gba èrò búburú
láti fi ọ̀rọ̀ èké pa tálákà run,
    bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀bẹ̀ aláìní sì tọ̀nà.
Ṣùgbọ́n ọlọ́lá ènìyàn a máa pète ohun ńlá
    àti nípa èrò rere ni yóò dúró.

Àwọn obìnrin Jerusalẹmu

Ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ti gba ìtẹ́lọ́rùn gidi
    ẹ dìde kí ẹ tẹ́tí sí mi,
ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ọkàn yín ti balẹ̀,
    ẹ gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ!
10 Ní ó lé díẹ̀ ní ọdún kan
    ẹ̀yin tí ọkàn an yín balẹ̀ yóò wárìrì;
ìkórè àjàrà kò ní múnádóko,
    bẹ́ẹ̀ ni ìkórè èso kò ní sí.
11 Wárìrì, ẹ̀yin obìnrin onítẹ̀lọ́rùn
    bẹ̀rù, ẹ̀yin ọ̀dọ́mọbìnrin tí ẹ rò pé ọkàn yín balẹ̀!
Ẹ bọ́ aṣọ yín kúrò,
    ẹ ró aṣọ ọ̀fọ̀ mọ́ ẹ̀gbẹ́ yín.
12 Ẹ lu ọmú yín fún pápá ìgbádùn náà,
    fún àwọn àjàrà eléso
13 àti fún ilẹ̀ àwọn ènìyàn mi
    ilẹ̀ tí ó ti kún fún ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n—
bẹ́ẹ̀ ni, kẹ́dùn fún gbogbo ilé ìtura
    àti fún ìlú àríyá yìí.
14 Ilé olódi ni a ó kọ̀sílẹ̀,
    ìlù aláriwo ni a ó kọ̀ tì;
ilé olódi àti ilé ìṣọ́ ni yóò di ihò títí láéláé,
    ìdùnnú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti pápá
oko fún àwọn ẹran ọ̀sìn,
15 títí a ó fi tú Ẹ̀mí sí wa lórí láti òkè wá,
    àti ti aṣálẹ̀ tí yóò dí pápá oko ọlọ́ràá
    àti tí pápá ọlọ́ràá yóò dàbí ẹgàn.
16 Ẹ̀tọ́ yóò máa gbé ní inú aṣálẹ̀
    àti òdodo yóò sì máa gbé ní pápá oko ọlọ́ràá.
17 Èso òdodo náà yóò sì jẹ́ àlàáfíà;
    àbájáde òdodo yóò sì jẹ́ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé títí láé.
18 Àwọn ènìyàn mi yóò máa gbé ní ibùgbé àlàáfíà,
    ní ibùgbé ìdánilójú,
    ní àwọn ibi ìsinmi tí ó parọ́rọ́.
19 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yìnyín ti tẹ́jú igbó pẹrẹsẹ
    àti tí ojú ìlú ti tẹ́ pẹrẹsẹ pátápátá,
20 báwo ni ẹ ó ti jẹ́ alábùkún tó,
    nípa gbígbin irúgbìn sí ipa odò gbogbo,
àti nípa jíjẹ́ kí àwọn màlúù yín àti
    àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ jẹ láìsí ìdíwọ́.

Ìpọ́njú àti ìrànlọ́wọ́

33 Ègbé ni fún ọ, ìwọ apanirun,
    ìwọ tí a kò tí ì parun!
Ègbé ni fún ọ, ìwọ ọ̀dàlẹ̀,
    ìwọ tí a kò tí ì dà ọ́!
Nígbà tí o bá dẹ́kun à ń pa ni run;
    a ó pa ìwọ náà run,
nígbà tí o bá dẹ́kun à ń dani,
    a ó da ìwọ náà.

Olúwa ṣàánú fún wa
    àwa ń ṣàfẹ́rí i rẹ.
Máa jẹ́ agbára wa ní òròòwúrọ̀
    ìgbàlà wa ní àsìkò ìpọ́njú.
Ní ìkérara ohùn rẹ, àwọn ènìyàn sá,
    nígbà tí o dìde sókè, àwọn orílẹ̀-èdè fọ́nká.
Ìkógun rẹ, ìwọ orílẹ̀-èdè ni a kórè
    gẹ́gẹ́ bí i ti ọ̀dọ́ eṣú;
    gẹ́gẹ́ bí àkójọpọ̀ eṣú, àwọn ènìyàn wọ ibẹ̀.

A gbé Olúwa ga, nítorí pé ó ń gbé ibi gíga;
    Òun yóò kún Sioni pẹ̀lú ẹ̀tọ́ àti òdodo.
Òun yóò jẹ́ ìpìlẹ̀ tí ó dájú fún àkókò rẹ
    ibùjókòó ìgbàlà kíkún àti ọgbọ́n òun ìmọ̀;
    ìbẹ̀rù Olúwa ni kọ́kọ́rọ́ sí ìṣúra yìí.

Wò ó, àwọn onígboyà ọkùnrin wọn pohùnréré
    ẹkún ní òpópónà;
    àwọn ikọ̀ àlàáfíà sọkún kíkorò.
Àwọn ojú ọ̀nà ńlá ni a ṣá tì,
    kò sí arìnrìn-àjò kankan ní ojú ọ̀nà
A ti ba àdéhùn jẹ́,
    a kẹ́gàn àwọn ẹlẹ́rìí,
    a kò bu ọlá fún ẹnikẹ́ni.
Ilẹ̀ ṣọ̀fọ̀ ó sì ṣòfò dànù,
    ojú ti Lebanoni ó sì sá
Ṣaroni sì dàbí aginjù,
    àti Baṣani òun Karmeli rẹ àwọn èwe wọn.

10 “Ní ìsinsin yìí ni èmi yóò dìde,” ni Olúwa wí.
    “Ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi ga,
    ní ìsinsin yìí ni a ó gbé mi sókè.
11 Ìwọ lóyún ìyàngbò,
    o sì bí koríko;
    èémí yín bí iná tí yóò jẹ yín run.
12 A ó jó àwọn ènìyàn run bí eérú;
    bí igbó ẹ̀gún tí a gé la ó dáná sí wọn.”

13 Ìwọ tí ó wà lọ́nà jíjìn, gbọ́ ohun
    tí mo ti ṣe;
    Ìwọ tí ò ń bẹ nítòsí, jẹ́rìí agbára mi!
14 Ẹ̀rù ba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní Sioni;
    ìwárìrì bá àwọn tí kò gba Ọlọ́run gbọ́:
“Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná ajónirun?
    Ta ni nínú wa lólè gbé pẹ̀lú iná àìnípẹ̀kun?”
15 Ẹni tí ó ń rìn lódodo
    tí ó ń sọ ohun tí ó tọ́,
tí ó kọ èrè tí ó ti ibi ìlọ́nilọ́wọ́gbà wá,
    tí ó sì pa ọwọ́ rẹ̀ mọ́ kúrò nínú gbígba àbẹ̀tẹ́lẹ̀,
tí ó di etí rẹ̀ sí ọ̀tẹ̀ láti pànìyàn
    tí ó sì di ojú rẹ̀ sí à ti pète ibi
16 Òun náà yóò gbé ní ibi gíga,
    ibi ààbò rẹ̀ yóò jẹ́ òkè ńlá olódi.
A ó mú oúnjẹ fún un,
    omi rẹ̀ yóò sì dájú.

17 Ojú rẹ yóò rí ọba nínú ẹwà rẹ̀
    yóò sì rí ilẹ̀ kan tí ó tẹ́ lọ rẹrẹẹrẹ.
18 Nínú èrò rẹ ìwọ yóò rántí ẹ̀rù rẹ àtẹ̀yìnwá:
    “Níbo ni ọ̀gá àgbà náà wà?
Níbo ni ẹni tí ń gba owó òde wà?
    Níbo ni òṣìṣẹ́ ti ó ń mójútó ilé ìṣọ́ wà?”
19 Ìwọ kì yóò rí àwọn agbéraga ènìyàn mọ́,
    àwọn ènìyàn tí èdè wọn fi ara sin,
    pẹ̀lú ahọ́n tí ó ṣàjèjì tí kò sì yé ni.

20 Gbójú sókè sí Sioni, ìlú àjọ̀dún wa,
    ojú rẹ yóò rí Jerusalẹmu,
ibùgbé àlàáfíà n nì, àgọ́ tí a kò ní yí padà;
    àwọn òpó rẹ̀ ni a kì yóò fàtu
    tàbí èyíkéyìí nínú okùn rẹ̀ kí já.
21 Níbẹ̀ ni Olúwa yóò ti jẹ́ Alágbára kan fún wa.
    Yóò sì dàbí ibi àwọn odò ńláńlá àti odò kéékèèkéé.
Kì yóò sí ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú tí yóò kọjá lórí i wọn,
    ọkọ̀ ojú omi ńlá ni a kì yóò tù lórí wọn.
22 Nítorí Olúwa ni onídàájọ́ wa,
    Olúwa ni onídàájọ́ wa,
Olúwa òun ni ọba wa;
    òun ni ẹni tí yóò gbà wá là.

23 Gbogbo okùn rẹ ni ó ti dẹ̀:
    Ìgbókùnró kò fìdímúlẹ̀,
wọn kò taṣọ agbọ́kọ̀rìn,
    lẹ́yìn náà, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìkógun ni a ó pín
    àní arọ pẹ̀lú yóò ru ìkógun lọ.
24 Kò sí ẹnikẹ́ni tí ó ń gbé Sioni tí yóò wí pé, “Ara mi kò yá,”
    a ó dárí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ènìyàn tí ń gbé ibẹ̀ jì wọ́n.

Kolose 1

Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa.

(A)Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose.

Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa.

Àwọn ọpẹ́ àti àdúrà

(B)Nígbàkúgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi. Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìhìnrere náà, èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìhìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀. (C)Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa. Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí.

(D)Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. 10 Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run, 11 pé kí a lè fi ipa gbogbo sọ yín di alágbára gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ àti ògo rẹ̀, kí ó lè ṣe é ṣe fún un yín láti máa tẹ̀síwájú nínú sùúrù àti ìpamọ́ra pẹ̀lú ayọ̀. 12 Kí a máa dúpẹ́ nígbà gbogbo lọ́wọ́ Baba, ẹni tí ó kà yín láti jẹ́ alábápín nínú ogún àwọn ẹni mímọ́ nínú ìjọba ìmọ́lẹ̀. 13 (E)Nítorí tí ó ti já wa gbà kúrò nínú agbára òkùnkùn ó sì mú wa wá sí ìjọba Ọmọ tí ó fẹ́ràn. 14 Nínú ẹni tí a ní ìràpadà, àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.

Títóbi Kristi

15 (F)Kristi ni àwòrán Ọlọ́run tí a kò le rí, àkọ́bí gbogbo ẹ̀dá. 16 Nítorí nípa rẹ̀ ní a dá ohun gbogbo: àwọn ohun tí ń bẹ ní ọ̀run àti ní ayé, ohun tí a rí àti èyí tí a kò rí, wọn ìbá ṣe ìtẹ́, tàbí agbára, tàbí àṣẹ, nípasẹ̀ rẹ̀ ni a dá ohun gbogbo àti fún un. 17 (G)Ó ti wà ṣáájú kí ohunkóhun tó wà, nínú rẹ̀ ni a sì so ohun gbogbo papọ̀ ṣọ̀kan. 18 (H)Òun ni orí fún ara, èyí tí í ṣe ìjọ; òun ni ìbẹ̀rẹ̀ àti àkọ́bí nínú àwọn òkú, pé nínú ohun gbogbo kí òun lè ní ipò tí ó ga jùlọ nínú ohunkóhun. 19 Nítorí ìfẹ́ Ọlọ́run ni pé kí gbogbo ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òun tìkára rẹ̀ lè máa gbé nínú rẹ̀. 20 Àti nípasẹ̀ rẹ̀ láti bá ohun gbogbo làjà àwọn nǹkan tí ń bẹ láyé àti èyí tí ń bẹ ní ọ̀run, nípa mímú àlàáfíà wá nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, tí a ta sílẹ̀ lórí igi àgbélébùú.

21 Ẹ̀yin ya ara yín nípá kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà kan rí, ẹ jẹ́ ọ̀tá nínú ọkàn yín nítorí ìwà búburú yín. 22 Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ó ti bá yín làjà nípa ara Kristi nípa ikú láti mú un yín lọ sí iwájú rẹ̀ ní mímọ́, aláìlábàwọ́n àti kúrò nínú ìdálẹ́bi, 23 bí ẹ̀yin bá dúró nínú ìgbàgbọ́ yín, tí ẹ fi ẹsẹ̀ múlẹ̀, tí ẹ sì dúró ṣinṣin, láláìyẹsẹ̀ kúrò nínú ìrètí ti ìhìnrere ti ẹ̀yin ti gbọ́, èyí tí a ti wàásù rẹ̀ fún gbogbo ẹ̀dá lábẹ́ ọ̀run, àti èyí ti èmi Paulu ṣe ìránṣẹ́ fún.

Iṣẹ́ Paulu ṣíṣe fún àwọn ìjọ

24 Nísinsin yìí èmi ń yọ̀ nínú ìjìyà fún un yín. Inú mi sì dùn, nítorí mo ń ṣe ìrànlọ́wọ́ láti jẹ ìyà tó ṣẹ́kù nínú ìyà Kristi fún ara rẹ̀, èyí tí ì ṣe ìjọ. 25 (I)Nínú èyí tí a fi ṣe ìránṣẹ́ fún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìríjú Ọlọ́run tí a fi fún mi fún yín láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣẹ. 26 (J)Ó ti pa àṣírí ìjìnlẹ̀ yìí mọ́ fún ayérayé àti láti ìrandíran. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀, ó ti fihàn fún àwọn ẹni mímọ́. 27 Àwọn ẹni tí Ọlọ́run yàn láti fihàn láàrín àwọn aláìkọlà nípa ọ̀rọ̀ ògo ohun ìjìnlẹ̀ yìí, èyí tí í ṣe Kristi ìrètí ògo nínú yín.

28 Àwa ń wàásù rẹ̀, a ń gbani níyànjú a sì ń kọ olúkúlùkù ènìyàn ní ọgbọ́n gbogbo, kí a lè mú olúkúlùkù dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní pípé nínú Kristi. 29 Sí èyí sì ni èmi ń ṣe làálàá, ti mo sì ń làkàkà pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀, èyí tó ń ṣiṣẹ́ nínú mi.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.