Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Jeremiah 46-47

Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí Ejibiti

46 (A)Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ Jeremiah wòlíì wá nípa àwọn orílẹ̀-èdè:

Ní ti Ejibiti:

Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun Farao Neko ọba Ejibiti ẹni tí a borí rẹ̀ ní Karkemiṣi, ní odò Eufurate láti ọwọ́ Nebukadnessari ọba Babeli ní ọdún kẹrin Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda:

“Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré,
    kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà!
Ẹ di ẹṣin ní gàárì,
    kí ẹ sì gùn ún.
Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ
    pẹ̀lú àṣíborí yín!
Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín,
    kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin.
(B)Kí ni nǹkan tí mo tún rí?
    Wọ́n bẹ̀rù,
wọ́n sì ń padà sẹ́yìn,
    wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun.
Wọ́n sá,
    wọn kò sì bojú wẹ̀yìn,
ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,”
    ni Olúwa wí.
“Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ,
    tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà.
Ní àríwá ní ibi odò Eufurate
    wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú.

“Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti,
    tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?
Ejibiti dìde bí odò náà,
    bí omi odò tí ń ru.
Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’
    Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run.
Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin,
    ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́.
Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú,
    àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará Puti tí ń di asà mú;
    àti àwọn ará Lidia tí ń fa ọrun.
10 Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun,
    ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀.
Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn,
    títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀.
Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ
    ní ilẹ̀ gúúsù ní odò Eufurate.

11 “Gòkè lọ sí Gileadi, kí o sì mú ìkunra,
    ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin Ejibiti.
Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn,
    kì yóò sí ìwòsàn fún ọ.
12 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ,
    igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé.
Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ,
    àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.”

13 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá Jeremiah wòlíì nì sọ nípa wíwá Nebukadnessari ọba Babeli láti lọ dojú ìjà kọ Ejibiti:

14 “Kéde èyí ní Ejibiti, sì sọ ọ́ ní Migdoli,
    sọ ọ́ ní Memfisi àti Tafanesi:
‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀,
    nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’
15 Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú?
    Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú.
16 Wọn yóò máa ṣubú léraléra
    wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn.
Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà
    sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa,
    kúrò níbi idà àwọn aninilára.’
17 Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé,
    ‘Ariwo lásán ni Farao ọba Ejibiti pa,
    ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’

18 “Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba,
    ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé,
“nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí Tabori láàrín àwọn òkè àti
    gẹ́gẹ́ bi Karmeli lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé.
19 Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé Ejibiti
    pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ
nítorí Memfisi yóò di ahoro
    a ó sì fi jóná, láìní olùgbé.

20 “Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní Ejibiti
    ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé,
    ó dé láti àríwá.
21 Àwọn jagunjagun rẹ̀
    dàbí àbọ́pa akọ màlúù.
Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà,
    wọn ó sì jùmọ̀ sá,
wọn kò ní le dúró,
    Nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn
    àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà.
22 Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá
    bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára.
Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké,
    gẹ́gẹ́ bí i ti agégi.
23 Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,”
    ni Olúwa wí,
“nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀,
    nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye.
24 A ó dójútì ọmọbìnrin Ejibiti,
    a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.”

25 Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí Amoni òrìṣà Tebesi, sórí Farao, sórí Ejibiti àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé Farao. 26 Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé Nebukadnessari ọba Babeli, ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí.

27 “Má bẹ̀rù, ìwọ Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
    má fòyà, ìwọ Israẹli.
Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn,
    àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn.
Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò,
    kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á.
28 Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi,
    nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí.
“Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run,
    láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí.
Èmi kò ní run yín tán.
    Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo,
    èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”

Àṣọtẹ́lẹ̀ ní tí àwọn ará Filistini

47 (C)Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tó tọ wòlíì Jeremiah wá nípa àwọn Filistini, kí ó tó di pé Farao dojúkọ Gasa:

Báyìí ni Olúwa wí:

“Wo bí omi ti ń ru sókè ní àríwá,
    wọn ó di odò tí ń bo bèbè mọ́lẹ̀.
Wọn kò ní borí ilẹ̀ àti ohun gbogbo tó wà lórí rẹ̀,
    ìlú àti àwọn tó ń gbé nínú wọn.
Àwọn ènìyàn yóò kígbe;
    gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà yóò hu
Nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ìró títẹ̀lé pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin alágbára
    nígbà tí wọ́n bá gbọ́ ariwo kẹ̀kẹ́ ogun ọ̀tá ńlá
àti iye kẹ̀kẹ́ wọn.
    Àwọn baba kò ní lè ran àwọn ọmọ lọ́wọ́;
    ọwọ́ wọn yóò kákò.
Nítorí tí ọjọ́ náà ti pé
    láti pa àwọn Filistini run,
kí a sì mú àwọn tí ó là
    tí ó lè ran Tire àti Sidoni lọ́wọ́ kúrò.
Olúwa ti ṣetán láti pa Filistini run,
    àwọn tí ó kù ní agbègbè Kafitori.
Gasa yóò fá irun orí rẹ̀ nínú ọ̀fọ̀.
    A ó pa Aṣkeloni lẹ́nu mọ́;
ìyókù ní pẹ̀tẹ́lẹ̀,
    ìwọ yóò ti sá ara rẹ lọ́gbẹ́ pẹ́ tó?

“Ẹ̀yin kígbe, ‘Yé è, idà Olúwa,
    yóò ti pẹ́ tó tí ìwọ yóò sinmi?
Padà sínú àkọ̀ rẹ;
    sinmi kí o sì dákẹ́ jẹ́ẹ́.’
Ṣùgbọ́n báwo ni yóò ṣe sinmi,
    nígbà tí Olúwa ti pàṣẹ fún un,
nígbà tí ó ti pa á láṣẹ
    láti dojúkọ Aṣkeloni àti agbègbè rẹ̀.”

Heberu 6

Nítorí náà, ó yẹ kí á fi àwọn ẹ̀kọ́ ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ gba Kristi sílẹ̀, kí á tẹ̀síwájú nínú àwọn ẹ̀kọ́ tí yóò mú wa dàgbàsókè ní pípé. Láìtún ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ máa tẹnumọ́ ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ bí i ìrònúpìwàdà kúrò nínú òkú iṣẹ́ àti ìgbàgbọ́ nípa ti Ọlọ́run, ti ẹ̀kọ́ àwọn bamitiisi, àti ti ìgbọ́wọ́-léni, ti àjíǹde òkú, àti tí ìdájọ́ àìnípẹ̀kun. Èyí ní àwa yóò sì ṣe bí Ọlọ́run bá fẹ́.

Nítorí pé, kò ṣe é ṣe fún àwọn tí a ti là lójú lẹ́ẹ̀kan, tí wọ́n sì ti tọ́ ẹ̀bùn ọ̀run wò, tí wọn sì ti di alábápín Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọn sì tọ́ ọ̀rọ̀ rere Ọlọ́run wò, àti agbára ayé tí ń bọ̀, láti tún sọ wọ́n di ọ̀tun sí ìrònúpìwàdà bí wọn bá ṣubú kúrò; nítorí tí wọ́n tún kan ọmọ Ọlọ́run mọ́ àgbélébùú sí ara wọn lọ́tun, wọ́n sì dójútì í ní gbangba. Nítorí ilẹ̀ tí ó ń fa omi òjò tí ń rọ̀ sórí rẹ̀ nígbà gbogbo mu, tí ó sì ń hu ewébẹ̀ tí ó dára fún àwọn tí à ń tìtorí wọn ro ó pẹ̀lú, ń gba ìbùkún lọ́wọ́ Ọlọ́run. (A)Ṣùgbọ́n bí ó ba ń hu ẹ̀gún àti òṣùṣú yóò di kíkọ̀sílẹ̀, kò si jìnnà sí fífi gégùn ún, òpin èyí tí yóò wà fún ìjóná.

Ṣùgbọ́n olùfẹ́, àwa ní ohun tí ó dára jù bẹ́ẹ̀ lọ, ní tiyín, àti ohun tí ó fi ara mọ́ ìgbàlà, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń ṣe báyìí sọ̀rọ̀. 10 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yin àti ìfẹ́ tí ẹ̀yin fihàn sí orúkọ rẹ̀, nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ tí ẹ ti ṣe fún àwọn ènìyàn mímọ́, tí ẹ sì tún ń ṣe. 11 Àwa sì fẹ́ kí olúkúlùkù yín máa fi irú àìsimi kan náà hàn, fún ẹ̀kún ìdánilójú ìrètí títí dé òpin: 12 Kí ẹ má ṣe di onílọ̀ra, ṣùgbọ́n aláfarawé àwọn tí wọn ti ipa ìgbàgbọ́ àti sùúrù jogún àwọn ìlérí.

Ìdánilójú ìlérí Ọlọ́run

13 (B)Nítorí nígbà tí Ọlọ́run ṣe ìlérí fún Abrahamu, bí kò ti rí ẹni tí ó pọ̀jù òun láti fi búra, ó fi ara rẹ̀ búra, wí pé, 14 “Nítòótọ́ ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i.” 15 Bẹ́ẹ̀ náà sì ni, lẹ́yìn ìgbà tí Abrahamu fi sùúrù dúró, ó ri ìlérí náà gbà.

16 Nítorí ènìyàn a máa fi ẹni tí ó pọ̀jù wọ́n lọ búra: ìbúra náà a sì fi òpin sí gbogbo ìjiyàn wọn fún ìfẹ̀sẹ̀ múlẹ̀ ọ̀rọ̀. 17 Nínú èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí ń fẹ́ gidigidi láti fi àìlèyípadà ète rẹ̀ hàn fún àwọn ajogún ìlérí náà, ó fi ìbúra sáàrín wọn. 18 Pé, nípa ohun àìlèyípadà méjì, nínú èyí tí kò le ṣe é ṣe fún Ọlọ́run láti ṣèké, kí a lè mú àwa tí ó ti sá sábẹ́ ààbò rẹ̀ ní ọkàn lè láti di ìrètí tí a gbé kalẹ̀ níwájú wa mú ṣinṣin: 19 (C)Èyí tí àwa níbi ìdákọ̀ró ọkàn fún ọkàn wa, ìrètí tí ó dájú tí ó sì dúró ṣinṣin, tí ó sì wọ inú ilé lọ lẹ́yìn aṣọ ìkélé; 20 (D)níbi tí Jesu, aṣáájú wa ti wọ̀ lọ fún wa, òun sì ni a fi jẹ alábojútó àlùfáà títí láé ní ipasẹ̀ Melkisedeki.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.