Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Esekiẹli 27-29

Ìpohùnréré ẹkún fún Tire

27 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún fún Tire. Sọ fún Tire, tí a tẹ̀dó sí ẹnu-bodè Òkun, oníṣòwò àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù. ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ìwọ Tire wí pé
    “Ẹwà mi pé.”
Ààlà rẹ wà ní àárín Òkun;
    àwọn ọ̀mọ̀lé rẹ ti mú ẹwà rẹ pé.
Wọn ṣe gbogbo pákó rẹ
    ní igi junifa láti Seniri;
wọ́n ti mú igi kedari láti Lebanoni wá
    láti fi ṣe òpó ọkọ̀ fún ọ.
Nínú igi óákù ti Baṣani
    ní wọn ti fi gbẹ́ ìtukọ̀ ọ̀pá rẹ̀;
ìjókòó rẹ ni wọn fi eyín erin ṣe pẹ̀lú
    igi bokisi láti erékùṣù Kittimu wá
Ọ̀gbọ̀ dáradára aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́ láti Ejibiti wá
    ni èyí tí ìwọ ta láti fi ṣe àsíá ọkọ̀ rẹ;
    aṣọ aláró àti elése àlùkò
láti erékùṣù ti Eliṣa
    ni èyí tí a fi bò ó
Àwọn ará ìlú Sidoni àti Arfadi ni àwọn atukọ̀ rẹ̀
    àwọn ọlọ́gbọ́n ẹ̀rọ rẹ, ìwọ Tire,
    ni àwọn atukọ̀ rẹ.
Àwọn àgbàgbà Gebali,
    àti àwọn ọlọ́gbọ́n ibẹ̀,
wà nínú ọkọ̀ bí òṣìṣẹ́ atukọ̀ rẹ,
    gbogbo ọkọ̀ ojú Òkun
àti àwọn atukọ̀ Òkun
    wá pẹ̀lú rẹ láti dòwò pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀.

10 “ ‘Àwọn ènìyàn Persia, Ludi àti Puti
    wà nínú jagunjagun rẹ
àwọn ẹgbẹ́ ọmọ-ogun rẹ.
    Wọ́n gbé asà àti àṣíborí wọn ró
sára ògiri rẹ,
    wọn fi ẹwà rẹ hàn.
11 Àwọn ènìyàn Arfadi àti Heleki
    wà lórí odi rẹ yíká;
àti àwọn akọni Gamadi,
    wà nínú ilé ìṣọ́ rẹ.
Wọ́n fi àwọn asà wọn kọ ara odi rẹ;
    wọn ti mú ẹwà rẹ pé.

12 “ ‘Tarṣiṣi ṣòwò pẹ̀lú rẹ torí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ tí ó ní; wọn ṣe ìpààrọ̀ fàdákà, irin idẹ àti òjé fún ọjà títà rẹ̀.

13 “ ‘Àwọn ará Giriki, Tubali, Jafani àti Meṣeki, ṣòwò pẹ̀lú rẹ: wọ́n fi ẹrù àti ohun èlò idẹ ṣe pàṣípàrọ̀ fún ọrọ̀ rẹ.

14 “ ‘Àwọn ti ilé Beti-Togarma ṣe ìpààrọ̀ ẹṣin-ìṣiṣẹ́, ẹṣin ogun àti ìbáaka ṣòwò ní ọjà rẹ.

15 “ ‘Àwọn ènìyàn Dedani ni àwọn oníṣòwò rẹ, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù ni wọ́n jẹ́ oníbàárà rẹ̀; wọ́n mú eyín erin àti igi eboni san owó rẹ.

16 “ ‘Aramu ṣòwò pẹ̀lú nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ òwò rẹ̀; wọn ṣe ìpààrọ̀ (turikuoṣe) òkúta iyebíye, òwú elése àlùkò, aṣọ iṣẹ́ ọnà abẹ́rẹ́, aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ìlẹ̀kẹ̀ iyùn pupa fún ọjà títà rẹ.

17 “ ‘Juda àti Israẹli, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọn ṣe ìpààrọ̀ ọkà, Minniti, àkàrà àdídùn; pannagi, oyin, epo àti ìkunra olóòórùn dídùn ni wọ́n fi ná ọjà rẹ.

18 “ ‘Damasku, ni oníṣòwò rẹ, nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun ọjà tí ó ṣe àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀; ní ti ọtí wáìnì tí Helboni, àti irun àgùntàn funfun láti Sahari, 19 àti ìdẹ̀ ọtí wáìnì láti Isali, ohun wíwọ̀: irin dídán, kasia àti kálàmù ni àwọn ohun pàṣípàrọ̀ fún ọjà rẹ.

20 “ ‘Dedani ni oníṣòwò rẹ ní aṣọ ìjókòó-lẹ́sin fún ẹṣin-gígùn.

21 “ ‘Àwọn ará Arabia àti gbogbo àwọn ọmọ-aládé Kedari àwọn ni àwọn oníbàárà rẹ: ní ti ọ̀dọ́-àgùntàn, àgbò àti ewúrẹ́, nínú ìwọ̀nyí ni wọ́n ti jẹ́ oníbàárà rẹ.

22 “ ‘Àwọn oníṣòwò ti Ṣeba àti Raama, àwọn ni oníṣòwò rẹ; wọ́n ta onírúurú tùràrí olóòórùn dídùn dáradára ní ọjà rẹ, àti àwọn òkúta iyebíye àti wúrà.

23 “ ‘Harani àti Kanneh àti Edeni, àwọn oníṣòwò Ṣeba, Asiria àti Kilmadi, ni àwọn oníṣòwò rẹ. 24 Wọ̀nyí ní oníbàárà rẹ ní onírúurú nǹkan: aṣọ aláró, àti oníṣẹ́-ọnà àti àpótí aṣọ olówó iyebíye, tí a fi okùn dì, tí a sì fi igi Kedari ṣe, nínú àwọn ilé-ìtajà rẹ.

25 “ ‘Àwọn ọkọ̀ Tarṣiṣi ní èrò
    ní ọjà rẹ
a ti mú ọ gbilẹ̀
    a sì ti ṣe ọ́ lógo
    ní àárín gbùngbùn Òkun
26 Àwọn atukọ̀ rẹ ti mú ọ
    wá sínú omi ńlá.
Ṣùgbọ́n afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn yóò fọ́ ọ sí wẹ́wẹ́
    ní àárín gbùngbùn Òkun.
27 Ọrọ̀ rẹ, ọjà rẹ àti àwọn ohun títà rẹ,
    àwọn ìṣúra rẹ, òṣìṣẹ́ ìtukọ̀ rẹ.
Àwọn oníbàárà rẹ àti gbogbo àwọn
    jagunjagun rẹ, tí ó wà nínú rẹ
àti nínú gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
    tí ó wà ní àárín rẹ
yóò rì sínú àárín gbùngbùn Òkun
    ní ọjọ́ ìparun rẹ.
28 Ilẹ̀ etí Òkun yóò mì
    nítorí ìró igbe àwọn atukọ̀ rẹ.
29 Gbogbo àwọn alájẹ̀,
    àwọn atukọ̀ Òkun
àti àwọn atọ́kọ̀ ojú Òkun;
    yóò sọ̀ kálẹ̀ kúrò nínú ọkọ̀ wọn,
    wọn yóò dúró lórí ilẹ̀.
30 Wọn yóò jẹ́ kí a gbọ́ ohùn wọn lòdì sí ọ
    wọn yóò sì sọkún kíkorò lé ọ lórí
wọn yóò ku eruku lé orí ara wọn
    wọn yóò sì yí ara wọn nínú eérú.
31 Wọn yóò fá irun orí wọn nítorí rẹ
    wọn yóò wọ aṣọ yíya
wọn yóò pohùnréré ẹkún pẹ̀lú
    ìkorò ọkàn nítorí rẹ
    pẹ̀lú ohùn réré ẹkún kíkorò.
32 Àti nínú arò wọn ni wọn yóò sì pohùnréré ẹkún fún ọ
    wọn yóò sì pohùnréré ẹkún sórí rẹ, wí pé:
“Ta ni ó dàbí Tire
    èyí tí ó parun ní àárín Òkun?”
33 Nígbà tí ọjà títà rẹ ti Òkun jáde wá
    ìwọ tẹ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè lọ́rùn
ìwọ fi ọrọ̀ tí ó pọ̀ àti àwọn ọjà títà rẹ
    sọ àwọn ọba ayé di ọlọ́rọ̀.
34 Ní ìsinsin yìí tí Òkun fọ ọ túútúú
    nínú ibú omi;
nítorí náà òwò rẹ àti gbogbo ẹgbẹ́ rẹ
    ní àárín rẹ,
    ni yóò ṣubú.
35 Ẹnu yóò ya gbogbo àwọn ti ń gbé
    ní erékùṣù náà sí ọ
jìnnìjìnnì yóò bo àwọn ọba wọn,
    ìyọnu yóò sì han ní ojú wọn.
36 Àwọn oníṣòwò láàrín àwọn orílẹ̀-èdè dún bí ejò sí ọ
    ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù
    ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí ọba Tire

28 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: (A)“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi,
    ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;
Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà,
    ní àárín gbùngbùn Òkun.”
Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,
    bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?
    Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?
Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,
    ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,
àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,
    nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.
Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,
    ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,
    ọkàn rẹ gbé sókè,
    nítorí ọrọ̀ rẹ.

“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,
    pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.
Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,
    ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;
wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,
    ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,
    wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.
Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò,
    ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná,
    àwọn tí a pa ní àárín Òkun.
Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”
    ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?
Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,
    ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.
10 Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà,
    ní ọwọ́ àwọn àjèjì.

Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

11 Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 12 “Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà,
    o kún fún ọgbọ́n,
    o sì pé ní ẹwà.
13 Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;
    onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;
sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,
    àti jasperi, safire, emeradi,
turikuoṣe, àti karbunkili, àti wúrà,
    ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,
láti ara wúrà,
    ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.
14 A fi ààmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,
    torí èyí ni mo fi yàn ọ́.
Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;
    ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná,
15 Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,
    láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,
    títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.
16 Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,
    ìwọ kún fún ìwà ipá;
ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.
    Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,
    bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.
Èmi sì pa ọ run,
    ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.
17 Ọkàn rẹ gbéraga,
    nítorí ẹwà rẹ.
Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,
    nítorí dídára rẹ.
Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;
    mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.
18 Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,
    ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.
Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,
    láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,
èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,
    lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.
19 Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,
    ní ẹnu ń yà sí ọ;
ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,
    ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Sidoni

20 (B)Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21 “Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i 22 Kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,
    a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.
Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,
    Nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,
    tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ,
23 Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,
    èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,
ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,
    pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,
    nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.

24 “ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.

25 “ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà; Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu. 26 Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígba tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn; Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Ejibiti

29 (C)Ní ọjọ́ kejìlá, oṣù kẹwàá, ọdún kẹwàá, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: “Ọmọ ènìyàn, kọjú sí Farao ọba Ejibiti kí ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ sí i àti sí gbogbo Ejibiti. Sọ̀rọ̀, kí ó sì wí pé: ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, Farao ọba Ejibiti
    ìwọ ẹ̀mí búburú ńlá inú Òkun tí ó dùbúlẹ̀ sí
àárín àwọn odò ṣíṣàn rẹ
    èyí tí ó sọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili;
    èmi ni ó sì ṣe é fún ara mi.”
Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìwọ̀ mú ẹnu rẹ
    èmi yóò sì mú ẹja inú odò rẹ
gbogbo lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
    Èmi yóò fà ọ́ síta kúrò láàrín àwọn odò rẹ,
    àti gbogbo ẹja odò rẹ yóò lẹ̀ mọ́ ìpẹ́ ara rẹ.
Èmi yóò sọ ọ́ nù sí aginjù
    ìwọ àti gbogbo ẹja inú odò rẹ:
ìwọ yóò ṣubú sí gbangba oko
    a kì yóò sì ṣà ọ́ jọ tàbí gbé ọ sókè.
Èmi ti fi ọ ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹranko igbó
    àti fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run láti jẹ.

Nígbà náà gbogbo àwọn olùgbé ni Ejibiti yóò mọ pé Èmi ni Olúwa.

“ ‘Ìwọ ti jẹ́ ọ̀pá ìyè fún ilé Israẹli. Nígbà tí wọn fi ọwọ́ agbára wọn dì ọ́ mú. Ìwọ fọ́, ìwọ sì ya gbogbo èjìká wọn; nígbà tí wọn fi ara tì ọ́, ìwọ sẹ́, ìwọ sì mú gbogbo ẹ̀gbẹ́ wọn gbọ̀n.

“ ‘Nítorí náà, èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: kéyèsi Èmi yóò mú idà kan wá sórí rẹ tí yóò sì gé ènìyàn àti ẹran kúrò nínú rẹ. Ilẹ̀ Ejibiti yóò di aginjù àti ahoro, nígbà náà ní wọn yóò sì mọ̀ wí pé èmi ní Olúwa.

“ ‘Nítorí tí ìwọ wí pé, “Tèmi ni odò Naili; Èmi ni mo ṣe é,” 10 Nítorí náà, mo lòdì sí ọ àti sí àwọn odò rẹ, èmi yóò sì mú kí ilẹ̀ Ejibiti di píparun àti ahoro, pátápátá, láti Migdoli lọ dé Siene, dé ààlà ilẹ̀ Kuṣi. 11 Kò sí ẹsẹ̀ ènìyàn tàbí tí ẹranko tí yóò gba ibẹ̀ kọjá; ẹni kankan kò ní gbé ibẹ̀ fún ogójì ọdún. 12 Èmi yóò sọ ilẹ̀ Ejibiti di ọ̀kan ní àárín àwọn ìlú tí ó di ahoro, fún ogójì ọdún, Èmi yóò sì fọ́n àwọn ara Ejibiti ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò sì tú wọn ká sáàárín gbogbo ilẹ̀.

13 “ ‘Ṣùgbọ́n báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Ní òpin ogójì ọdún, èmi yóò ṣa àwọn ará Ejibiti jọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn níbi tí a fọ́n wọn ká sí. 14 Èmi yóò sì tún mú ìgbèkùn Ejibiti padà bọ̀, èmi yóò sì dá wọn padà sí ilẹ̀ Paturosi, ilẹ̀ àwọn baba ńlá wọn. Wọn yóò wà níbẹ̀ bí ìjọba tí a rẹ̀ sílẹ̀. 15 Ibẹ̀ yóò jẹ́ ìjọba tí ó rẹlẹ̀ jùlọ nínú àwọn ìjọba, kì yóò sì gbé ara rẹ̀ ga mọ́ sórí àwọn orílẹ̀-èdè: nítorí èmi ni ó dín wọn kù, tiwọn kì yóò fi ṣe olórí àwọn orílẹ̀-èdè yòókù mọ́. 16 Ejibiti kí yóò sì jẹ orísun ìgbẹ́kẹ̀lé fún ilé Israẹli mọ́ ṣùgbọ́n, yóò jẹ́ ìrántí fún àìṣedéédéé wọn, nígbà tí yóò bá wò wọ́n fún ìrànlọ́wọ́. Nígbà náà, wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.’ ”

Èrè Nebukadnessari

17 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní, ọdún kẹtà-dínlọ́gbọ̀n, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 18 “Ọmọ ènìyàn, Nebukadnessari ọba Babeli mú kí ogun rẹ sin ìrú ńlá fún Tire. Gbogbo orí pá, àti gbogbo èjìká bó, síbẹ̀, òun àti àwọn ogun rẹ̀, kò rí owó ọ̀yà gbà láti Tire fún wa, fún ìrú ti a ti sìn. 19 Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Kíyèsi i, Èmi yóò fi Ejibiti fún Nebukadnessari ọba Babeli, òun yóò sì kó ọrọ̀ rẹ̀ lọ. Òun yóò bo ilé, yóò sì ṣe ìkógun ilẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ tí a san fún ológun rẹ̀. 20 Èmi ti fi Ejibiti fún un gẹ́gẹ́ bí èrè wàhálà rẹ̀ nítorí òun àti àwọn ológun rẹ ṣe é fún mi, ni Olúwa Olódùmarè wí.

21 “Ní ọjọ́ náà, èmi yóò mú kí ìwo Israẹli ru jáde, èmi yóò sì fún ọ ní ẹnu ọ̀rọ̀ ní àárín wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.”

1 Peteru 3

Àwọn aya àti àwọn ọkọ

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ẹ̀yin aya, ẹ máa tẹríba fún àwọn ọkọ yín; pé, bí ẹnikẹ́ni ba tilẹ̀ ń ṣe àìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láì sọ̀rọ̀ nípa ìwà àwọn aya wọn. Nígbà tí wọ́n bá ń wo ìwà rere pẹ̀lú ẹ̀rù yín: Kí ọ̀ṣọ́ yín má ṣe jẹ́ ọ̀ṣọ́ òde, tí irun dídì, àti wúrà lílò, tàbí ti aṣọ wíwọ̀; Ṣùgbọ́n kí ó jẹ́ ẹni tí ó fi ara sin ní ọkàn, nínú ọ̀ṣọ́ àìdíbàjẹ́ ti ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ẹ̀mí tútù, èyí tí i ṣe iyebíye níwájú Ọlọ́run. Nítorí báyìí ni àwọn obìnrin mímọ́ ìgbàanì pẹ̀lú, tí wọ́n gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, fi ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, wọn a máa tẹríba fún àwọn ọkọ wọn. (A)Gẹ́gẹ́ bí Sara ti gbọ́ ti Abrahamu, tí ó ń pè é ní olúwa rẹ̀. Ọmọbìnrin ẹni tí ẹ̀yin jẹ́, bí ẹ̀yin bá ń ṣe rere, tí ohunkóhun kò sí dẹ́rùbà yín.

Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.

Jíjìyà fún ṣíṣe iṣẹ́ rere

Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún. 10 (B)Nítorí,

“Ẹni tí yóò bá fẹ́ ìyè,
    ti yóò sì rí ọjọ́ rere,
kí o pa ahọ́n rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ibi,
    àti ètè rẹ̀ mọ́ kúrò nínú sísọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn:
11 Kí ó yà kúrò nínú ibi, kí ó sì máa ṣe rere;
    kí ó máa wá àlàáfíà, kí ó sì máa lépa rẹ̀.
12 Nítorí ojú Olúwa ń bẹ lára àwọn olódodo,
    etí rẹ̀ sì ṣí sí ẹ̀bẹ̀ wọn:
ṣùgbọ́n ojú Olúwa korò sí àwọn tí ń ṣe búburú.”

13 Tá nì yóò sì ṣe yín ní ibi, bí ẹ̀yin bá jẹ́ onítara sí ohun rere? 14 (C)Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá jìyà nítorí òdodo, a ti bùkún yín. “Ẹ má ṣe bẹ̀rù ìhàlẹ̀ wọn, kí ẹ má sì ṣe kọminú.” 15 Ṣùgbọ́n ẹ bọ̀wọ̀ fún Kristi bí Olúwa ní ọkàn yín: kí ẹ sì múra tan nígbà gbogbo láti dá olúkúlùkù lóhùn tí ń béèrè ìrètí tí o ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn tútù àti ìbẹ̀rù. 16 Kí ẹ máa ni ẹ̀rí ọkàn rere bí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ yín ní ibi, kí ojú lè ti àwọn tí ń kẹ́gàn ìwà rere yín nínú Kristi. 17 Nítorí ó sàn, bí ó bá jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run, kí ẹ jìyà fún ṣíṣe rere ju fún ṣíṣe búburú lọ. 18 Nítorí tí Kristi pẹ̀lú jìyà lẹ́ẹ̀kan nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, olóòótọ́ fún àwọn aláìṣòótọ́, kí a lè mú wa dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí a pa nínú ara, ṣùgbọ́n tí a sọ di ààyè nínú ẹ̀mí: 19 Nínú èyí tí ó lọ pẹ̀lú tí ó sì wàásù fún àwọn ẹ̀mí nínú túbú: 20 (D)àwọn tí ó ṣe aláìgbọ́ràn nígbà kan, nígbà tí sùúrù Ọlọ́run dúró pẹ́ ní sá à kan ní ọjọ́ Noa, nígbà tí wọ́n fi kan ọkọ̀ nínú èyí tí a gba ọkàn díẹ̀ là nípa omi, èyí ni ẹni mẹ́jọ. 21 Àpẹẹrẹ èyí ti ń gbà yín là nísinsin yìí pẹ̀lú, àní ìtẹ̀bọmi, kì í ṣe wíwẹ́ èérí ti ara nù, bí kò ṣe ìdáhùn ẹ̀rí ọkàn rere si Ọlọ́run, nípa àjíǹde Jesu Kristi. 22 Ẹni tí ó lọ sí ọ̀run, tí ó sì ń bẹ lọ́wọ́ ọ̀tún Ọlọ́run: pẹ̀lú àwọn angẹli, àwọn aláṣẹ, àti àwọn alágbára sì tẹríba lábẹ́ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.