Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Lefitiku 15-16

Ìsunjáde láti inú ara ti ń sọ ni di aláìmọ́

15 Olúwa sọ fún Mose àti Aaroni pé: Ẹ bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀: kí ẹ wí fún wọn pé: Bí ìsunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara: ìsunjáde náà jẹ́ àìmọ́. Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìsunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́.

“ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìsunjáde náà bá sùn di àìmọ́. Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jókòó lórí ohunkóhun tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde bá jókòó le gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀: kí ó sì wẹ̀, kí ó sì wà láìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ọkùnrin náà tí ó ní ìsunjáde gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

“ ‘Bí ẹni tí ó ní ìsunjáde bá tu itọ́ sí ẹni tí ó mọ́ lára, ẹni tí ó mọ́ náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

“ ‘Gàárì ẹranko tí ẹni náà bá gùn yóò di àìmọ́. 10 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó wà lábẹ́ ọkùnrin náà di aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. Ẹnikẹ́ni tí ó bá mú irú nǹkan bẹ́ẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó wẹ ara rẹ̀. Yóò sì jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

11 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí ọkùnrin tí ó ní ìsunjáde ní ara rẹ̀ bá fi ara kàn láìfi omi fọ ọwọ́ rẹ̀, gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

12 “ ‘Ìkòkò amọ̀ tí ọkùnrin náà bá fọwọ́ kàn ni kí ẹ fọ́, gbogbo ohun èlò igi tí ó fọwọ́ kàn ni kí ẹ fi omi sàn.

13 “ ‘Ẹnikẹ́ni tí a bá wẹ̀nù kúrò nínú ìsunjáde rẹ̀ gbọdọ̀ ka ọjọ́ méje fún àwọn ọjọ́ ìwẹ̀nùmọ́: kí ó fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì fi omi wẹ ara rẹ̀: yóò sì di mímọ́. 14 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì, kí ó sì wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Olúwa, kí ó sì kó wọn fún àlùfáà. 15 Kí àlùfáà fi wọ́n rú ẹbọ: ọ̀kan fún ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ọrẹ ẹbọ sísun níwájú Olúwa ní ipò ọkùnrin náà nítorí ìsunjáde rẹ̀.

16 “ ‘Bí nǹkan ọkùnrin kan bá tú jáde, kí ó wẹ gbogbo ara rẹ̀: kí ó wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́. 17 Yálà àwọ̀ tàbí aṣọ tí nǹkan ọkùnrin bá dà sí lórí ni kí ẹ fọ̀: yóò sì wà ní ipò àìmọ́ di ìrọ̀lẹ́. 18 Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin lòpọ̀ tí nǹkan ọkùnrin sì tú jáde lára rẹ̀. Àwọn méjèèjì gbọdọ̀ fi omi wẹ̀: kí wọ́n sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

19 “ ‘Bí obìnrin bá ń ṣe nǹkan oṣù rẹ̀: obìnrin yìí wà ní àìmọ́ títí di ọjọ́ méje. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

20 “ ‘Gbogbo ohun tí ó bá sùn lé ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ di àìmọ́. 21 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ibùsùn rẹ̀ gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 22 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kan ohunkóhun tí ó bá jókòó lé gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀, yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́. 23 Ìbá à ṣe ibùsùn tàbí ohunkóhun tí ó jókòó lé. Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn án yóò jẹ́ aláìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

24 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá a lòpọ̀, tí nǹkan oṣù rẹ̀ sì kàn án lára, yóò jẹ́ aláìmọ́ fún ọjọ́ méje, gbogbo ibùsùn tí ọkùnrin náà bá sùn yóò jẹ́ aláìmọ́.

25 “ ‘Bí obìnrin bá ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún ọjọ́ púpọ̀ yálà sí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tàbí tí nǹkan oṣù rẹ̀ bá kọjá ìgbà tí ó yẹ. Gbogbo ìgbà tí ó bá fi ń ní ìsun ẹ̀jẹ̀ náà ni yóò fi wà ní àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. 26 Ibùsùn tí ó wù kí ó sùn sí ní gbogbo ìgbà tí ẹ̀jẹ̀ náà ń wá yóò jẹ́ àìmọ́ bí ibùsùn rẹ̀ ṣe jẹ́ ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. Gbogbo ohun tí ó bá jókòó lé yóò wà ní àìmọ́, gẹ́gẹ́ bí àkókò nǹkan oṣù rẹ̀. 27 Ẹnikẹ́ni tí ó bá fọwọ́ kàn wọ́n yóò wà ní àìmọ́. Ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ̀ kí ó sì wà ní àìmọ́ títí di ìrọ̀lẹ́.

28 “ ‘Nígbà tí ó bá di mímọ́ kúrò nínú ìsun rẹ̀, kí ó ka ọjọ́ méje lẹ́yìn náà, a ó kà á sí mímọ́. 29 Ní ọjọ́ kẹjọ kí ó mú àdàbà méjì àti ọmọ ẹyẹlé wá síwájú àlùfáà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. 30 Kí àlùfáà fi ọ̀kan rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti èkejì fún ẹbọ sísun. Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún un, níwájú Olúwa fún àìmọ́ ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

31 “ ‘Ẹ ya ará Israẹli sọ́tọ̀ kúrò nínú ohun tí ó ń sọ wọ́n di aláìmọ́, kí wọ́n má bá a kú nínú àìmọ́ wọn nípa bíba ibùgbé mímọ́ mi jẹ́: Èyí tí ó wà láàrín wọn.’ ”

32 Ìwọ̀nyí ni àwọn òfin fún ọkùnrin tí ó ni ìsunjáde fún ẹnikẹ́ni tí a sọ di àìmọ́ nípa ìsunjáde nǹkan ọkùnrin rẹ̀. 33 Fún obìnrin ní nǹkan oṣù rẹ̀, fún ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó ní ìsunjáde, àti fún ọkùnrin tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú obìnrin tí ó jẹ́ aláìmọ́.

Ọjọ́ ètùtù ìwẹ̀nùmọ́ ẹ̀ṣẹ̀

16 Olúwa sọ fún Mose lẹ́yìn ikú àwọn ọmọ Aaroni méjèèjì tí wọ́n kú nígbà tí wọ́n súnmọ́ Olúwa. (A)Olúwa sì sọ fún Mose pé “Kìlọ̀ fún Aaroni arákùnrin rẹ pé kí ó má ṣe máa wá nígbà gbogbo sí ibi mímọ́ jùlọ tí ó wà lẹ́yìn aṣọ títa ní ibi tí àpótí ẹ̀rí àti ìtẹ́ àánú wà, kí ó má ba à kú” nítorí pé Èmi ó farahàn nínú ìkùùkuu lórí ìtẹ́ àánú.

(B)Báyìí ni Aaroni yóò ṣe máa wá sí ibi mímọ́ pẹ̀lú ọ̀dọ́ akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ àti àgbò fún ẹbọ sísun. Òun yóò sì wọ aṣọ funfun mímọ́ pẹ̀lú àwọ̀tẹ́lẹ̀ funfun, yóò sì fi àmùrè funfun mímọ́ dì í: yóò sì dé fìlà funfun: àwọn aṣọ mímọ́ nìwọ̀nyí: Òun yóò sì fi omi wẹ̀, kí ó tó wọ̀ wọ́n. Òun yóò sì mú ọmọ ewúrẹ́ méjì láti ọ̀dọ̀ gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli láti fi ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wọ́n: àti àgbò kan fún ẹbọ sísun.

Aaroni yóò sì fi akọ màlúù rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ èyí tí ṣe ti ara rẹ̀ òun yóò sì ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Lẹ́yìn náà yóò sì mú ewúrẹ́ méjì náà wá sí iwájú Olúwa ní ibi ìlẹ̀kùn àgọ́ ìpàdé. Aaroni yóò sì dìbò ní ti àwọn ewúrẹ́ méjèèjì náà, ìbò àkọ́kọ́ fún ti Olúwa, àti èkejì fún ewúrẹ́ ìpààrọ̀. Aaroni yóò sì mú ewúrẹ́ tí ìbò Ọlọ́run mú, yóò sì fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. 10 Ṣùgbọ́n ewúrẹ́ tí ìbò bá mú gẹ́gẹ́ bí ewúrẹ́ ìpààrọ̀ ni a ó mú wá láààyè síwájú Olúwa láti fi ṣe ètùtù sí i àti láti jẹ́ kí ó lọ lọ́fẹ̀ẹ́, sí aginjù.

Ètùtù fún olórí àlùfáà

11 Aaroni yóò sì mú akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ wá láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti ìdílé rẹ̀. Yóò sì pa akọ màlúù náà fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tirẹ̀. 12 Yóò sì mú àwo tùràrí tí ó kún fún èédú tí a ti sun pẹ̀lú iná láti orí pẹpẹ wá síwájú Olúwa: àti ẹ̀kúnwọ́ méjì tùràrí tí a gún kúnná yóò sì mú un wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa. 13 Yóò sì fi tùràrí náà lé orí iná níwájú Olúwa: kí èéfín tùràrí náà ba à le bo ìtẹ́ àánú tí ó wà ní orí àpótí ẹ̀rí kí o má ba à kú. 14 Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ ọmọ màlúù náà yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn, ní iwájú ìtẹ́ àánú, yóò sì fi ìka rẹ̀ wọ́n ọn nígbà méje níwájú ìtẹ́ àánú.

Ètùtù fún àwọn ènìyàn

15 (C)Nígbà yìí ni yóò pa ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí ó wà fún àwọn ènìyàn yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹ̀yìn aṣọ títa, bí ó ti ṣe ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà ni yóò ṣe ti ewúrẹ́ yìí, yóò sì wọ́n ọn sórí ìtẹ́ ètùtù àti síwájú ìtẹ́ ètùtù. 16 Báyìí ni yóò ṣe ètùtù fún ibi mímọ́ jùlọ nítorí àìmọ́ àwọn ará Israẹli àti nítorí gbogbo ìrékọjá wọn àti ìṣọ̀tẹ̀ wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbogbo, bákan náà ni yóò sì ṣe fún àgọ́ ìpàdé, èyí tí ó wà láàrín wọn nínú àìmọ́ wọn. 17 Kí ó má ṣe sí ẹyọ ènìyàn kan nínú àgọ́ ìpàdé nígbà tí òun bá wọ ibi mímọ́ lọ láti ṣe ètùtù: títí di ìgbà tí yóò fi jáde lẹ́yìn tí ó ba ṣe ètùtù fúnrarẹ̀ fún ìdílé rẹ̀ àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ Israẹli.

18 Lẹ́yìn náà òun yóò lọ sí ibi pẹpẹ tí ó wà níwájú Olúwa: yóò sì ṣe ètùtù fún pẹpẹ náà. Yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù àti nínú ẹ̀jẹ̀ ewúrẹ́ náà, yóò sì fi sí orí ọ̀kọ̀ọ̀kan ìwo pẹpẹ náà yíká. 19 Lẹ́yìn náà, òun yóò wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà sórí rẹ̀ pẹ̀lú ìka rẹ̀ nígbà méje láti wẹ̀ ẹ́ mọ́ àti láti sọ ọ́ dí mímọ́ kúrò nínú àìmọ́ àwọn ọmọ Israẹli.

20 Lẹ́yìn ti Aaroni ti parí ṣíṣe ètùtù ti ibi mímọ́ jùlọ, ti àgọ́ ìpàdé àti ti pẹpẹ: òun yóò sì mú ààyè ewúrẹ́ wá. 21 Aaroni yóò sì gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé orí ààyè ewúrẹ́ náà, yóò sì jẹ́wọ́ gbogbo ìwà búburú àti ìṣọ̀tẹ̀ àwọn ara Israẹli lé e lórí: gbogbo ìrékọjá wọn àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn ni yóò sì gbé ka orí ewúrẹ́ náà. Yóò sì rán an lọ sí ijù láti ọwọ́ ẹni tí a yàn fún iṣẹ́ náà. 22 Ewúrẹ́ náà yóò sì ru gbogbo àìṣedéédéé wọn lọ sí ilẹ̀ tí ènìyàn kò gbé. Òun yóò sì jọ̀wọ́ ewúrẹ́ náà lọ́wọ́ lọ sínú ijù.

23 (D)Aaroni yóò sì padà wá sí ibi àgọ́ ìpàdé, yóò sì bọ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀, tí ó wọ̀ nígbà tí ó lọ sí ibi mímọ́ jùlọ, yóò sì fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀ 24 Yóò sì fi omi wẹ ara rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan: yóò sì wọ aṣọ rẹ̀ yóò sì wá ṣí iwájú: yóò sì rú ẹbọ sísun ti ara rẹ̀ àti ẹbọ sísun ti àwọn ènìyàn láti ṣe ètùtù fún ara rẹ̀ àti fún àwọn ènìyàn: 25 Òun yóò sì sun ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà lórí pẹpẹ.

26 Ẹni tí ó tú ewúrẹ́ ìpààrọ̀ náà sílẹ̀ yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀ nínú omi: lẹ́yìn èyí ó lè wá sí ibùdó. 27 (E)Ọ̀dọ́ akọ màlúù àti ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ tí a ti mú ẹ̀jẹ̀ wọn wá sí ibi mímọ́ jùlọ ni kí a gbe jáde kúrò ní ibùdó. Awọ wọn ni a ó fi iná sun bákan náà. 28 Ẹni tí ó sun wọ́n yóò sì fọ aṣọ rẹ̀: yóò sì wẹ ara rẹ̀: lẹ́yìn èyí ni ó tó le wọ ibùdó.

29 (F)Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà títí láé fún un yín: pé ní ọjọ́ kẹwàá oṣù keje ni ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín: kí ẹ má ṣe ṣe iṣẹ́ kankan, yálà onílé tàbí àlejò tí ó ń gbé pẹ̀lú yín. 30 Torí pé ní ọjọ́ yìí ni àlùfáà yóò ṣe ètùtù fún yín láti sọ yín di mímọ́: kí ẹ̀yin bá à le mọ́ níwájú Olúwa yín kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ yín gbogbo. 31 Ọjọ́ yìí yóò jẹ́ ọjọ́ ìsinmi pátápátá fún un yín: ẹ̀yin yóò sì ṣẹ́ ara yín: Èyí yóò sì jẹ́ ìlànà títí láé. 32 Àlùfáà náà tí a ti fi òróró yàn tí a sì ti sọ di mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ ní ilé ìsìn ní ipò baba rẹ̀: òun ni kí ó ṣe ètùtù: yóò sì wọ aṣọ funfun gbòò àní aṣọ mímọ́ náà: òun yóò sì ṣe ètùtù. 33 Yóò sì ṣe ètùtù fún àgọ́ ìpàdé àti fún pẹpẹ: yóò sì ṣe ètùtù fún àlùfáà àti fún gbogbo àgbájọpọ̀ àwọn ènìyàn náà.

34 “Èyí ni yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún yín: láti máa ṣe ètùtù fún àwọn ará Israẹli fún gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ẹ̀kan lọ́dún.”

Ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Matiu 27:1-26

Judasi lọ pokùnso

27 (A)Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù tún padà láti gbìmọ̀ bí wọn yóò ti ṣe pa Jesu. Lẹ́yìn èyí, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, wọ́n sì jọ̀wọ́ rẹ̀ fún Pilatu tí i ṣe gómìnà.

(B)(C) Nígbà tí Judasi, ẹni tí ó fi í hàn, rí i wí pé a ti dá a lẹ́bi ikú, ó yí ọkàn rẹ̀ padà, ó sì káàánú nípa ohun tí ó ṣe. Ó sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí ó gba náà wá fún àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù. Ó wí pé, “Mo ti ṣẹ̀ nítorí tí mo ti ta ẹ̀jẹ̀ aláìlẹ́ṣẹ̀ sílẹ̀.”

Wọ́n dá a lóhùn pẹ̀lú ìbínú pé, “Èyí kò kàn wá! Wàhálà tìrẹ ni!”

Nígbà náà ni Judasi da owó náà sílẹ̀ nínú tẹmpili. Ó jáde, ó sì lọ pokùnso.

(D)Àwọn olórí àlùfáà sì mú owó náà. Wọ́n wí pé, “Àwa kò lè fi owó yìí sínú owó ìkójọpọ̀. Ní ìwọ̀n ìgbà tí ó lòdì sí òfin wa nítorí pé owó ẹ̀jẹ̀ ni.” Wọ́n sì gbìmọ̀, wọ́n sì fi ra ilẹ̀ amọ̀kòkò, láti máa sin òkú àwọn àjèjì nínú rẹ̀. Ìdí nìyìí tí à ń pe ibi ìsìnkú náà ní “Ilẹ̀ Ẹ̀jẹ̀” títí di òní. (E)Èyí sì jẹ́ ìmúṣẹ èyí tí a ti sọtẹ́lẹ̀ láti ẹnu wòlíì Jeremiah wí pé, “Wọ́n sì mú ọgbọ̀n owó fàdákà tí àwọn ènìyàn Israẹli díye lé e. 10 Wọ́n sì fi ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ àwọn amọ̀kòkò gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ.”

Jesu níwájú Pilatu

11 (F)Nígbà náà ni Jesu dúró níwájú baálẹ̀ láti gba ìdájọ́. Baálẹ̀ sì béèrè pé, “Ṣe ìwọ ni ọba àwọn Júù?”

Jesu dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, nítorí tí ìwọ wí i.”

12 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù fi gbogbo ẹ̀sùn wọn kàn án, Jesu kò dáhùn kan. 13 Nígbà náà ni Pilatu, béèrè lọ́wọ́ Jesu pé, “Àbí ìwọ kò gbọ́ ẹ̀rí tí wọn ń wí nípa rẹ ni?” 14 (G)Jesu kò sì tún dáhùn kan. Èyí sì ya baálẹ̀ lẹ́nu.

15 Ó jẹ́ àṣà gómìnà láti dá ọ̀kan nínú àwọn ẹlẹ́wọ̀n Júù sílẹ̀ lọ́dọọdún, ní àsìkò àjọ̀dún ìrékọjá. Ẹnikẹ́ni tí àwọn ènìyàn bá ti fẹ́ ni. 16 Ní àsìkò náà ọ̀daràn paraku kan wà nínú ẹ̀wọ̀n tí à ń pè Jesu Baraba. 17 Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti péjọ síwájú ilé Pilatu lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Baraba tàbí Jesu, ẹni tí ń jẹ́ Kristi?” 18 Òun ti mọ̀ pé nítorí ìlara ni wọn fi fà á lé òun lọ́wọ́.

19 (H)Bí Pilatu sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.”

20 Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbàgbà Júù rọ àwọn ènìyàn, láti béèrè kí a dá Baraba sílẹ̀, kí a sì béèrè ikú fún Jesu.

21 (I)Nígbà tí Pilatu sì tún béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Èwo nínú àwọn méjèèjì yìí ni ẹ̀ ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín?”

Àwọn ènìyàn sì kígbe padà pé, “Baraba!”

22 Pilatu béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe sí Jesu ẹni ti a ń pè ní Kristi?”

Gbogbo wọn sì tún kígbe pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

23 Pilatu sì béèrè pé, “Nítorí kí ni? Kí ló ṣe tí ó burú?”

Wọ́n kígbe sókè pé, “Kàn án mọ́ àgbélébùú! Kàn án mọ́ àgbélébùú!”

24 (J)Nígbà tí Pilatu sì rí i pé òun kò tún rí nǹkan kan ṣe mọ́, àti wí pé rògbòdìyàn ti ń bẹ̀rẹ̀, ó béèrè omi, ó sì wẹ ọwọ́ rẹ̀ níwájú ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó wí pé, “Ọrùn mí mọ́ nípa ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí. Ẹ̀yin fúnrayín, ẹ bojútó o!”

25 (K)Gbogbo àgbájọ náà sì ké pé, “Kí ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí wa, àti ní orí àwọn ọmọ wa!”

26 Nígbà náà ni Pilatu dá Baraba sílẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn tí òun ti na Jesu tán, ó fi í lé wọn lọ́wọ́ láti mú un lọ kàn mọ́ àgbélébùú.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.