Old/New Testament
Àwọn onírúurú òfin
19 Olúwa sọ fún Mose pé, 2 (A)“Bá gbogbo àpéjọpọ̀ àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀, sì wí fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ́ mímọ́ nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run yín jẹ́ mímọ́.
3 (B)“ ‘Ẹnìkọ̀ọ̀kan yín gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún ìyá àti baba rẹ̀, kí ẹ sì ya ọjọ́ ìsinmi mi sí mímọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
4 (C)“ ‘Ẹ má ṣe yípadà tọ ère òrìṣà lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ rọ ère òrìṣà idẹ fún ara yín. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
5 “ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá sì rú ẹbọ àlàáfíà sí Olúwa, kí ẹ̀yin kí ó ṣe é ní ọ̀nà tí yóò fi jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà dípò yín. 6 Ní ọjọ́ tí ẹ bá rú u náà ni ẹ gbọdọ̀ jẹ ẹ́ tàbí ní ọjọ́ kejì; èyí tí ó bá ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta ni kí ẹ fi iná sun. 7 Bí ẹ bá jẹ nínú èyí tí ó ṣẹ́kù di ọjọ́ kẹta, àìmọ́ ni èyí jẹ́, kò ní jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà. 8 Nítorí náà ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a ó di ẹ̀bi rẹ̀ rù, nítorí pé ó ti ba ohun mímọ́ Olúwa jẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
9 (D)“ ‘Nígbà tí ẹ̀yin bá kórè nǹkan oko yín, kí ẹ̀yin kí ó fi díẹ̀ sílẹ̀ láìkórè ní àwọn igun oko yín, ẹ̀yin kò sì gbọdọ̀ ṣa ẹ̀ṣẹ́ (nǹkan oko tí ẹ ti gbàgbé tàbí tí ó bọ́ sílẹ̀). 10 Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ kórè oko yín tan pátápátá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣa èso tí ó rẹ̀ bọ́ sílẹ̀ nínú ọgbà àjàrà yín. Ẹ fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn aláìní àti fún àwọn àlejò. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
11 (E)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ parọ́.
“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ tan ara yín jẹ.
12 (F)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ fi orúkọ mi búra èké: kí o sì tipa bẹ́ẹ̀ ba orúkọ Ọlọ́run rẹ jẹ́. Èmi ni Olúwa.
13 (G)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ rẹ́ aládùúgbò rẹ jẹ bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ jà á lólè.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dá owó iṣẹ́ alágbàṣe dúró di ọjọ́ kejì.
14 (H)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣépè lé adití: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ fi ohun ìdìgbòlù sí iwájú afọ́jú, ṣùgbọ́n bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run rẹ: Èmi ni Olúwa.
15 (I)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ yí ìdájọ́ po, má ṣe ojúsàájú sí ẹjọ́ tálákà: bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ gbé ti ọlọ́lá lẹ́yìn: ṣùgbọ́n fi òdodo ṣe ìdájọ́, àwọn aládùúgbò rẹ.
16 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olóòfófó láàrín àwọn ènìyàn rẹ.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mí aládùúgbò rẹ wéwu: Èmi ni Olúwa.
17 “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kórìíra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládùúgbò rẹ wí, kí o má ba à jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.
18 (J)“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyìí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, kí ìwọ kí ó fẹ́ ẹnìkejì rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa.
19 (K)“ ‘Máa pa àṣẹ mi mọ́.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan.
“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.
20 “ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá obìnrin tí ó jẹ́ ẹrú lòpọ̀, ẹni tí a ti mọ̀ pọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin mìíràn tí a kò sì tí ì rà á padà tàbí sọ ọ́ di òmìnira. Ẹ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí kí ẹ sì jẹ wọ́n ní ìyà tó tọ́ ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ pa wọ́n, torí pé kò ì tí ì di òmìnira. 21 Kí ọkùnrin náà mú àgbò kan wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé bí i ẹbọ ẹ̀bi sí Olúwa. 22 Àlùfáà yóò sì ṣe ètùtù fún un, pẹ̀lú àgbò ẹbọ ẹ̀bi náà níwájú Olúwa fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀. A ó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ náà jì í.
23 “ ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ náà tí ẹ sì gbin igi eléso, kí ẹ ká èso wọn sí ohun èèwọ̀. Fún ọdún mẹ́ta ni kí ẹ kà á sí èèwọ̀, ẹ kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́ 24 Ṣùgbọ́n ní ọdún kẹrin, gbogbo èso wọ̀nyí yóò jẹ́ mímọ́, ọrẹ fún ìyìn Olúwa. 25 Ní ọdún karùn-ún ni ẹ̀yin tó lè jẹ nínú èso igi náà, kí èso wọn ba à le máa pọ̀ sí i. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
26 (L)“ ‘Ẹ má ṣe jẹ ẹrankẹ́ran pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
“ ‘Ẹ kò gbọdọ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ yẹ̀míwò tàbí oṣó.
27 (M)“ ‘Ẹ má ṣe dá òṣù sí àárín orí yín (fífá irun ẹ̀gbẹ́ orí, tí a ó sì dá irun àárín orí sí) tàbí kí ẹ ré orí irùngbọ̀n yín bí àwọn aláìkọlà ti ń ṣe.
28 “ ‘Ẹ má ṣe tìtorí òkú, gé ibi kankan nínú ẹ̀yà ara yín, Ẹ kò sì gbọdọ̀ sín gbẹ́rẹ́ kankan. Èmi ni Olúwa.
29 (N)“ ‘Ẹ má ṣe ba ọmọbìnrin yín jẹ́ láti sọ ọ́ di panṣágà, kí ilẹ̀ yín má ba à di ti àgbèrè, kí ó sì kún fún ìwà búburú.
30 (O)“ ‘Ẹ gbọdọ̀ máa pa ìsinmi mi mọ́ kí ẹ sì fi ọ̀wọ̀ fún ibi mímọ́ mi, Èmi ni Olúwa.
31 (P)“ ‘Ẹ má ṣe tọ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí àwọn àjẹ́ lọ, ẹ kò gbọdọ̀ tọ̀ wọ́n lẹ́yìn láti jẹ́ kí wọ́n sọ yín di aláìmọ́. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
32 “ ‘Fi ọ̀wọ̀ fún ọjọ́ orí arúgbó kí ẹ sì bu ọlá fún àwọn àgbàlagbà. Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run yín: Èmi ni Olúwa.
33 (Q)“ ‘Nígbà tí àjèjì kan bá ń gbé pẹ̀lú yín ní ilẹ̀ yín, ẹ má ṣe ṣe é ní ibi 34 kí àjèjì tí ń gbé pẹ̀lú yín dàbí onílé láàrín yín kí ẹ sì fẹ́ràn rẹ̀ bí i ara yín, torí pé ẹ̀yin ti jẹ́ àjèjì ní ilẹ̀ Ejibiti rí. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.
35 (R)“ ‘Ẹ má ṣe lo òṣùwọ̀n èké, nígbà tí ẹ bá ń díwọ̀n yálà nípa òṣùwọ̀n ọ̀pá, òṣùwọ̀n ìwúwo tàbí òṣùwọ̀n onínú. 36 Ẹ jẹ́ olódodo pẹ̀lú àwọn òṣùwọ̀n yín òṣùwọ̀n ìtẹ̀wọ̀n, òṣùwọ̀n wíwúwo, òṣùwọ̀n ìyẹ̀fun àti òṣùwọ̀n nǹkan olómi yín ní láti jẹ́ èyí tí kò ní èrú nínú. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti.
37 “ ‘Ẹ ó sì máa pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, ẹ ó sì máa ṣe wọ́n. Èmi ni Olúwa.’ ”
Ìjìyà fún ẹ̀ṣẹ̀
20 Olúwa sọ fún Mose pé, 2 (S)“Sọ fún àwọn ará Israẹli pé: ‘Ẹnikẹ́ni nínú àwọn ará Israẹli tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrín Israẹli, tí ó bá fi èyíkéyìí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún Moleki, kí wọ́n pa á, kí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà sọ ọ́ ní òkúta pa. 3 Èmi tìkára mi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀, ń ó sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀ fún òrìṣà Moleki ó ti ba ibi mímọ́ mi jẹ́ pẹ̀lú. 4 Bí àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà bá mójú kúrò lára irú ẹni bẹ́ẹ̀ tí ó fi ọ̀kan nínú àwọn ọmọ rẹ̀ fún òrìṣà Moleki tí wọn kò sì pa irú ẹni bẹ́ẹ̀. 5 Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀ àti gbogbo ìdílé rẹ̀, èmi yóò sì ké wọn kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn: òun àti gbogbo àwọn tí ó jọ ṣe àgbèrè tọ òrìṣà Moleki lẹ́yìn.
6 (T)“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá tọ àwọn abókùúsọ̀rọ̀ àti àwọn ẹlẹ́mìí òkùnkùn lọ, tí ó sì ṣe àgbèrè tọ̀ wọ́n lẹ́yìn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni bẹ́ẹ̀; Èmi yóò sì gé e kúrò láàrín àwọn ènìyàn rẹ̀.
7 (U)“ ‘Torí náà ẹ ya ara yín sí mímọ́ kí ẹ sì jẹ́ mímọ́, torí pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín. 8 Ẹ máa kíyèsi àṣẹ mi, kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́: Èmi ni Olúwa tí ó sọ yín di mímọ́.
9 (V)“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣépè lé baba tàbí ìyá rẹ̀ ni kí ẹ pa, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wà lórí ara rẹ̀ torí pé ó ti ṣépè lé baba àti ìyá rẹ̀.
10 (W)“ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá bá aya aládùúgbò rẹ̀ lòpọ̀: ọkùnrin àti obìnrin náà ni kí ẹ sọ ní òkúta pa.
11 (X)“ ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá bá aya baba rẹ̀ lòpọ̀ ti tàbùkù baba rẹ̀. Àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa. Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.
12 (Y)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá arábìnrin ìyàwó rẹ̀ lòpọ̀, àwọn méjèèjì ni kí ẹ pa, wọ́n ti ṣe ohun tí ó lòdì, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.
13 (Z)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ọkùnrin mìíràn lòpọ̀ bí wọ́n ti í bá obìnrin lòpọ̀: àwọn méjèèjì ti ṣe ohun ìríra: pípa ni kí ẹ pa wọ́n, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.
14 (AA)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ tìyátọmọ papọ̀: ìwà búburú ni èyí: iná ni kí ẹ fi sun wọ́n, òun àti àwọn méjèèjì, kí ìwà búburú má ba à gbilẹ̀ láàrín yín.
15 (AB)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá ẹranko lòpọ̀, ẹ gbọdọ̀ pa ọkùnrin náà àti ẹranko náà.
16 “ ‘Bí obìnrin kan bá súnmọ́ ẹranko tí ó sì bá a lòpọ̀ obìnrin náà àti ẹranko náà ni kí ẹ pa: ẹ̀jẹ̀ wọn yóò sì wà lórí ara wọn.
17 (AC)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá fẹ́ arábìnrin rẹ̀ yálà ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀, ohun ìtìjú ni èyí: Ẹ ó gé wọn kúrò lójú àwọn ènìyàn wọn: ó ti tàbùkù arábìnrin rẹ̀. Ẹ̀bi rẹ̀ yóò wá sórí rẹ̀.
18 (AD)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá súnmọ́ obìnrin, ní àkókò nǹkan oṣù rẹ̀ tí ó sì bá a lòpọ̀. Ó ti tú orísun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Òun náà sì gbà á láààyè. Àwọn méjèèjì ni a ó gé kúrò láàrín àwọn ènìyàn wọn.
19 (AE)“ ‘Má ṣe bá arábìnrin baba tàbí ti ìyá rẹ lòpọ̀, nítorí o ti tú ìhòhò ìbátan rẹ: Ẹ̀yin méjèèjì ni yóò ru ẹ̀bi yín.
20 (AF)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá bá aya arákùnrin baba rẹ̀ lòpọ̀ ó ti tàbùkù arákùnrin baba rẹ̀. A ó jẹ wọ́n ní ìyà; wọn yóò sì kú láìlọ́mọ.
21 (AG)“ ‘Bí ọkùnrin kan bá gba aya arákùnrin rẹ̀, ohun àìmọ́ ni èyí, ó ti tàbùkù arákùnrin rẹ̀, wọn ó wà láìlọ́mọ.
22 “ ‘Kí ẹ pa gbogbo àṣẹ àti òfin mi mọ́, kí ẹ sì máa ṣe wọ́n. Kí ilẹ̀ náà tí èmi ó fi fún yín láti máa gbé má ba à pọ̀ yín jáde. 23 Ẹ má ṣe tẹ̀lé àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí mo lé jáde níwájú yín torí pé gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni wọ́n ń ṣe, tí mo kórìíra wọn. 24 Ṣùgbọ́n mo ti sọ fún yín pé, “Ẹ̀yin ni yóò jogún ilẹ̀ wọn; Èmi yóò sì fi fún yín láti jogún ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.” Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó ti yà yín sọ́tọ̀ kúrò láàrín àwọn ènìyàn yòókù.
25 “ ‘Ẹ gbọdọ̀ pààlà sáàrín ẹran tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Láàrín ẹyẹ tí ó mọ́ àti àwọn tí kò mọ́. Ẹ má ṣe sọ ara yín di àìmọ́ nípasẹ̀ àwọn ẹranko tàbí ẹyẹ tàbí ohunkóhun tí ń rìn lórí ilẹ̀: èyí tí mo yà sọ́tọ̀ fún yín gẹ́gẹ́ bí ohun àìmọ́. 26 (AH)Ẹ gbọdọ̀ jẹ́ mímọ́ fún mi torí pé èmi Olúwa fẹ́ mímọ́. Mó sì ti yà yín kúrò nínú àwọn orílẹ̀-èdè yòókù kí ẹ le jẹ́ tèmi.
27 (AI)“ ‘Ọkùnrin tàbí obìnrin tí ó jẹ́ abókùúsọ̀rọ̀ tàbí oṣó láàrín yín ni kí ẹ pa. Ẹ sọ wọ́n ní òkúta, ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wà lórí wọn.’ ”
51 (A)Lójúkan náà aṣọ ìkélé tẹmpili fàya, láti òkè dé ìsàlẹ̀. Ilẹ̀ sì mì tìtì. Àwọn àpáta sì sán. 52 Àwọn isà òkú sì ṣí sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ òkú àwọn ẹni mímọ́ tí ó ti sùn sì tún jíǹde. 53 Wọ́n jáde wá láti isà òkú lẹ́yìn àjíǹde Jesu, wọ́n sì lọ sí ìlú mímọ́. Níbẹ̀ ni wọ́n ti fi ara han ọ̀pọ̀ ènìyàn.
54 (B)Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń sọ Jesu rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í ṣe!”
55 Ọ̀pọ̀ obìnrin tí ó wá láti Galili pẹ̀lú Jesu láti tọ́jú rẹ̀ wọn ń wò ó láti òkèèrè. 56 (C)Nínú àwọn obìnrin ti ó wà níbẹ̀ ni Maria Magdalene, àti Maria ìyá Jakọbu àti Josẹfu, àti ìyá àwọn ọmọ Sebede méjèèjì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.
A tẹ́ Jesu sínú ibojì
57 (D)Nígbà tí alẹ́ sì lẹ́, ọkùnrin ọlọ́rọ̀ kan láti Arimatea, tí à ń pè ní Josẹfu, ọ̀kan nínú àwọn tí ó jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, 58 lọ sọ́dọ̀ Pilatu, ó sì tọrọ òkú Jesu. Pilatu sì pàṣẹ kí a gbé é fún un. 59 Josẹfu sì gbé òkú náà. Ó fi aṣọ funfun mímọ́ dì í. 60 Ó sì tẹ́ ẹ sínú ibojì òkúta tí ó gbẹ́ nínú àpáta fúnrarẹ̀. Ó sì yí òkúta ńlá dí ẹnu-ọ̀nà ibojì náà, ó sì lọ. 61 Maria Magdalene àti Maria kejì wà níbẹ̀, wọn jókòó òdìkejì ibojì náà.
Àwọn olùṣọ́ ní ibojì
62 Lọ́jọ́ kejì tí ó tẹ̀lé ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi lọ sọ́dọ̀ Pilatu. 63 (E)Wọ́n sọ fún un pé, “Alàgbà àwa rántí pé ẹlẹ́tàn nnì wí nígbà tí ó wà láyé pé, ‘Lẹ́yìn ọjọ́ kẹta èmi yóò tún jí dìde.’ 64 Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọningbọnin títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ má ṣe wá jí gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
65 Pilatu sì pàṣẹ pé, “Ẹ lo àwọn olùṣọ́ yín kí wọn dáàbò bo ibojì náà bí ẹ bá ti fẹ́.” 66 (F)Nítorí náà wọ́n lọ. Wọ́n sì ṣé òkúta ibojì náà dáradára. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sí ibẹ̀ láti dáàbò bò ó.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.