Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Eksodu 39-40

Aṣọ àlùfáà

39 Nínú aṣọ aláró, ti elése àlùkò àti ti òdòdó ni wọ́n fi ṣe aṣọ híhun fún àwọn òṣìṣẹ́ ní ibi mímọ́. Ó sì tún dá aṣọ mímọ́ fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ẹ̀wù efodu

(A)Ó ṣe ẹ̀wù efodu wúrà, ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. Ó sì lu wúrà náà di ewé fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì tún gé e láti fi ṣe iṣẹ́ sí aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó, àti sínú ọ̀gbọ̀ dáradára, iṣẹ́ ọlọ́nà. Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù efodu náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so ó pọ̀. Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù efodu ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli. Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Ìgbàyà

(B)Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí ìgbàyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí ẹ̀wù efodu: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elése àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ìka kan ní ìnà rẹ̀, ìwọ̀n ìka kan ní ìbú rẹ̀, ó sì jẹ́ ìṣẹ́po méjì. 10 Ó sì to ipele òkúta oníyebíye mẹ́rin sí i. Ní ipele kìn-ín-ní ní rúbì wà, topasi àti bereli; 11 ní ipele kejì, turikuoṣe, safire, emeradi àti diamọndi; 12 ní ipele kẹta, jasiniti, agate àti ametisiti; 13 ní ipele kẹrin, karisoliti, óníkìsì, àti jasperi. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn. 14 Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

15 Fún ìgbàyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn. 16 Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà. 17 Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùka náà ni igun ìgbàyà náà, 18 àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà ní iwájú. 19 Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì ìgbàyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù efodu náà. 20 Wọ́n sì túnṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù efodu náà tí ó súnmọ́ ibi tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù efodu náà. 21 Wọn so àwọn òrùka ìgbàyà mọ́ àwọn òrùka ẹ̀wù efodu ọ̀já aṣọ aláró, kí a pa á pọ̀ mọ́ ìgbànú, nítorí kí ìgbàyà náà má ṣe tú kúrò lára ẹ̀wù efodu náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Àwọn aṣọ àlùfáà mìíràn

22 (C)Ó sì ṣe ọ̀já àmùrè ẹ̀wù efodu gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ aláró iṣẹ́ aláṣọ híhun 23 Pẹ̀lú ihò ní àárín ọ̀já àmùrè náà gẹ́gẹ́ bí i ojú kọ́là, àti ìgbànú yí ihò yìí ká, nítorí kí ó má ba à ya. 24 Ó sì ṣe pomegiranate ti aṣọ aláró, elése àlùkò, òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára yí ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká. 25 Ó sì ṣe agogo kìkì wúrà, ó sì so wọ́n mọ́ àyíká ìṣẹ́tí àárín pomegiranate náà. 26 Ago àti pomegiranate kọjú sí àyíká ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

27 (D)Fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ aláṣọ híhun. 28 Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára. 29 Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elése àlùkò àti òdòdó tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

30 (E)Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì:

mímọ́ sí Olúwa.

31 Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

Mose bẹ àgọ́ náà wò

32 Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 33 Wọ́n sì mú tabanaku náà tọ Mose wá:

àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

34 ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji aṣọ títa;

35 àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;

36 (F)tábìlì pẹ̀lú gbogbo ohun èlò rẹ̀ àti àkàrà ìfihàn;

37 ọ̀pá fìtílà kìkì wúrà pẹ̀lú ipele fìtílà rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, àti òróró fún títanná rẹ̀;

38 pẹpẹ wúrà àti òróró ìtasórí, tùràrí dídùn, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà.

39 Pẹpẹ idẹ pẹ̀lú idẹ ọlọ, àwọn òpó rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀;

agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀;

40 aṣọ títa ti àgbàlá pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti àgbàlá, àti aṣọ títa fún ẹnu-ọ̀nà àgbàlá;

ọ̀já àmùrè àti èèkàn àgọ́ fún àgbàlá náà;

gbogbo ohun ọ̀ṣọ́ fún àgọ́, àgọ́ àjọ náà;

41 aṣọ híhun tí wọ́n ń wọ̀ fún iṣẹ́ ibi mímọ́, aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ àlùfáà.

42 Àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose. 43 Mose bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Nítorí náà Mose sì bùkún fún wọn.

Gbígbé àgọ́ ró

40 Olúwa sì wí fún Mose pé: Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró. Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa. Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì to àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀. Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.

“Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, àgọ́ àjọ; gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀. Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà.

“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́. 10 Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ. 11 Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.

12 “Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi. 13 Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà. 14 Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n. 15 Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.” 16 Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

17 Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì. 18 Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró. 19 Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

20 Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ. 21 Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

22 Mose gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa, 23 (G)ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

24 Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òdìkejì tábìlì ní ìhà gúúsù àgọ́ náà. 25 Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

26 Mose gbé pẹpẹ wúrà sínú àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa 27 ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

28 Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà. 29 Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

30 (H)Ó gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀, 31 Mose, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn. 32 Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkúgbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

33 Mose sì gbé àgbàlá tí ó yí àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí iṣẹ́ náà.

Ògo Olúwa

34 (I)Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà. 35 Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.

36 Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli nígbàkúgbà tí a bá ti fa ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ; 37 ṣùgbọ́n tí àwọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè. 38 Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.

Matiu 23:23-39

23 (A)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè! Nítorí ẹ̀yin ń gba ìdámẹ́wàá minti, dili àti kumini, ẹ̀yin sì ti fi ohun tí ó ṣe pàtàkì jùlọ nínú òfin sílẹ̀ láìṣe, ìdájọ́, àánú àti ìgbàgbọ́: Wọ̀nyí ni ó tọ́ tí ẹ̀yin ìbá ṣe, ẹ̀yin kò bá fi wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ láìṣe. 24 Ẹ̀yin afọ́jú tó ń fi afọ́jú mọ̀nà! Ẹ tu kòkòrò-kantíkantí tó bọ́ sì yín lẹ́nu nù, ẹ gbé ìbákasẹ mì.

25 (B)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ̀yin ń fọ òde ago àti àwo ṣùgbọ́n inú rẹ̀ kún fún ìrẹ́jẹ àti ẹ̀gbin gbogbo. 26 Ìwọ afọ́jú Farisi, tètè kọ́ fọ inú ago àti àwo, gbogbo ago náà yóò sì di mímọ́.

27 (C)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin Farisi àti ẹ̀yin olùkọ́ òfin, ẹ̀yin àgàbàgebè. Ẹ dàbí ibojì funfun tí ó dára ní wíwò, ṣùgbọ́n tí ó kún fún egungun ènìyàn àti fún ẹ̀gbin àti ìbàjẹ́. 28 Ẹ̀yin gbìyànjú láti farahàn bí ènìyàn mímọ́, olódodo, lábẹ́ aṣọ mímọ́ yín ni ọkàn tí ó kún fún ìbàjẹ́ pẹ̀lú oríṣìíríṣìí àgàbàgebè àti ẹ̀ṣẹ̀ wà.

29 (D)“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisi, ẹ̀yin àgàbàgebè, nítorí ẹ̀yin kọ́ ibojì àwọn wòlíì tí í ṣe ibojì àwọn olódodo ní ọ̀ṣọ́. 30 Ẹ̀yin sì wí pé, Àwa ìbá wà ní àsìkò àwọn baba wa, àwa kì bá ní ọwọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlíì. 31 Ǹjẹ́ ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí fún ara yín pé, ẹ̀yin ni ọmọ àwọn tí ó pa àwọn wòlíì. 32 Àti pé, ẹ̀yin ń tẹ̀lé ìṣísẹ̀ àwọn baba yín. Ẹ̀yin ń kún òṣùwọ̀n ìwà búburú wọn dé òkè.

33 (E)“Ẹ̀yin ejò! Ẹ̀yin paramọ́lẹ̀! Ẹ̀yin yóò ti ṣe yọ nínú ẹ̀bi ọ̀run àpáàdì? 34 Nítorí náà èmi yóò rán àwọn wòlíì àti àwọn ọlọ́gbọ́n ọkùnrin tí ó kún fún ẹ̀mí mímọ́, àti àwọn akọ̀wé sí yín. Ẹ̀yin yóò pa àwọn kan nínú wọn nípa kíkàn wọ́n mọ́ àgbélébùú. Ẹ̀yin yóò fi pàṣán na àwọn ẹlòmíràn nínú Sinagọgu yín, tí ẹ̀yin yóò sì ṣe inúnibíni sí wọn láti ìlú dé ìlú. 35 Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run. 36 Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò wà sórí ìran yìí.

37 (F)“Jerusalẹmu, Jerusalẹmu, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adìyẹ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀. 38 Wò ó, a fi ilé yín sílẹ̀ fún yín ní ahoro. 39 Nítorí èmi sọ èyí fún yín, ẹ̀yin kì yóò rí mi mọ́, títí ẹ̀yin yóò fi sọ pé ‘Olùbùkún ni ẹni tó ń bọ̀ ní orúkọ Olúwa.’ ”

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.