Add parallel Print Page Options

12 (A)Mo sì wí fún wọn pé, “Bí ó bá dára ní ojú yin, ẹ fún mi ni owó ọ̀yà mi; bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ mú un lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n wọn ọgbọ̀n owó fàdákà fún iye owó ọ̀yà mi.

13 Olúwa sì wí fún mi pé, “Sọ ọ sí amọ̀kòkò.” Iye dáradára náà, tí wọn yọ owó mi sí. Mo sì mu ọgbọ̀n owó fàdákà náà, mo sì sọ wọ́n sí àpótí ìṣúra ní ilé Olúwa.

Read full chapter

Jeremiah wí pé, “Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: Hanameli ọmọkùnrin Ṣallumu ẹ̀gbọ́n rẹ̀ yóò tọ̀ ọ́ wá pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti; nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹni tó súnmọ́ wọn, ẹ̀tọ́ àti ìṣe rẹ ní láti rà á.’

“Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ, Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi tọ̀ mí wá ní àgbàlá túbú wí pé, ‘Ra pápá mi tí ó wà ní Anatoti tí ó wà ní ilẹ̀ Benjamini, èyí tí ó jẹ́ pé ẹ̀tọ́ rẹ ni láti gbà á àti láti ni, rà á fún ara rẹ.’

“Nígbà náà ni èmi mọ̀ wí pé ọ̀rọ̀ Olúwa ni èyí. Bẹ́ẹ̀ ni; èmi ra pápá náà ní Anatoti láti ọwọ́ Hanameli ọmọ ẹ̀gbọ́n mi. Mo sì wọn ìwọ̀n ṣékélì àti fàdákà mẹ́tà-dínlógún fún un. 10 Mo fọwọ́ sínú ìwé, mo sì dì í pa. Mo pe ẹlẹ́rìí sí i, mo sì wọn fàdákà náà lórí òṣùwọ̀n. 11 Mo mú ìwé tí mo fi rà á, èyí tí a di pa nípa àṣẹ àti òfin wa, àti èyí tí a kò lẹ̀. 12 Èmi sì fi èyí fún Baruku, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, ní ojú Hanameli, ọmọ ẹ̀gbọ́n mi àti níwájú àwọn ẹlẹ́rìí tí ó ti fi ọwọ́ sí ìwé àti ní ojú àwọn Júù gbogbo tí wọ́n jókòó ní àgbàlá ilé túbú.

13 “Ní ojú wọn ni èmi ti pàṣẹ fún Baruku pé: 14 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; mú àwọn ìwé tí a fi rà á wọ̀nyí, àti èyí tí a lẹ̀ àti èyí tí a kò lẹ̀, kí o wá gbé wọn sínú ìkòkò amọ̀, kí wọn ó lè wà ní ọjọ́ púpọ̀. 15 Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí; àwọn ilẹ̀, pápá àti ọgbà àjàrà ni à ó tún rà padà nílẹ̀ yìí.

Read full chapter

“Sọ̀kalẹ̀ lọ sí ilé amọ̀kòkò, níbẹ̀ ni èmi yóò ti bá ọ sọ̀rọ̀.” Nígbà náà ni mo lọ sí ilé amọ̀kòkò mo sì rí i tí ó ń ṣiṣẹ́ kan lórí kẹ̀kẹ́.

Read full chapter