Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Mika 6-7

Ọlọ́run pe Israẹli níjà

Ẹ fi etí sí ohun tí Olúwa wí:

“Dìde dúró, bẹ ẹ̀bẹ̀ fún ẹjọ́ rẹ níwájú òkè ńlá;
    sì jẹ́ kí àwọn òkè kéékèèkéé gbọ́ ohun tí ó fẹ́ wí.

“Gbọ́, ìwọ òkè ńlá, ẹ̀sùn Olúwa;
    gbọ́, ìwọ ìpìlẹ̀ ilé ayérayé.
Nítorí Olúwa ń bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wíjọ́;
    òun yóò sì bá Israẹli rojọ́.

“Ẹ̀yin ènìyàn mi, kí ni mo ṣe fún yín?
    Àti nínú kí ni mo ti dá yin lágara? Dá mi lóhùn.
Nítorí èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá,
    mo sì rà yín padà láti ilẹ̀ ẹrú wá.
Mo rán Mose láti darí yín,
    bákan náà mo rán Aaroni àti Miriamu síwájú rẹ̀.
Ìwọ ènìyàn mi,
    rántí ohun tí Balaki ọba Moabu gbèrò
    àti ohun tí Balaamu ọmọ Beori dáhùn.
Rántí ìrìnàjò rẹ̀ láti Ṣittimu dé Gilgali,
    kí ìwọ ba le mọ òdodo Olúwa.”

Kí ni èmi yóò ha mú wá síwájú Olúwa
    tí èmi ó fi tẹ ara mi ba níwájú Ọlọ́run gíga?
Kí èmi ha wá sí iwájú rẹ̀ pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun,
    pẹ̀lú ọmọ màlúù ọlọ́dún kan?
Ǹjẹ́ Olúwa yóò ní inú dídùn sí ẹgbẹgbàarùn-ún àgbò,
    tàbí sí ẹgbẹgbàarùn-ún ìṣàn òróró?
Èmi yóò ha fi àkọ́bí mi sílẹ̀ fún ìré-òfin-kọjá mi,
    èso inú ara mi fún ẹ̀ṣẹ̀ ọkàn mi?
Ó ti fihàn ọ́, ìwọ ènìyàn, ohun tí ó dára,
    àti ohun tí Olúwa ń béèrè lọ́wọ́ rẹ?
Bí kò ṣe láti ṣe òtítọ́, kí o sì fẹ́ràn àánú,
    àti kí o rìn ní ìrẹ̀lẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run rẹ̀.

Ẹ̀ṣẹ̀ Israẹli àti ìjìyà wọn

Gbọ́! Ohùn Olúwa kígbe sí ìlú ńlá náà,
    láti jẹ ọlọ́gbọ́n ni láti bẹ̀rù orúkọ rẹ.
    “Ẹ kíyèsi ọ̀pá rẹ̀ gbọ́ ọ̀pá àti Ẹni náà tí ó yàn án
10 Ǹjẹ́ ìṣúra ìwà búburú ha wà
    ní ilé ènìyàn búburú síbẹ̀,
    àti òṣùwọ̀n àìkún tí ó jẹ́ ohun ìbínú?
11 Ǹjẹ́ èmi ha lè kà wọ́n sí mímọ́
    pẹ̀lú òṣùwọ̀n búburú,
    pẹ̀lú àpò òṣùwọ̀n ẹ̀tàn?
12 Àwọn ọlọ́rọ̀ inú rẹ̀ kún fún ìwà ipá;
    àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ ti ọ̀rọ̀ èké
    àti ahọ́n wọn ń sọ ẹ̀tàn?
13 Nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ ṣàìsàn ní lílù ọ́,
    láti sọ ọ́ dahoro nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ.
14 Ìwọ yóò jẹun ṣùgbọ́n kì yóò yó;
    ìyàn yóò wà láàrín rẹ;
Ìwọ yóò kó pamọ́, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò lò láìléwu,
    nítorí ohun tí ìwọ kò pamọ́ ni èmi yóò fi fún idà.
15 Ìwọ yóò gbìn ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò kórè
    ìwọ yóò tẹ olifi,
ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò fi òróró rẹ̀ kún ara rẹ;
    ìwọ yóò tẹ èso àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò mu wáìnì.
16 Nítorí tí ìwọ ti pa òfin Omri mọ́,
    àti gbogbo iṣẹ́ ilé Ahabu,
    tí ó sì ti tẹ̀lé ìmọ̀ràn wọn,
nítorí náà ni èmi yóò ṣe mú ọ fún ìparun
    àti àwọn ènìyàn rẹ fún ìfiṣe ẹlẹ́yà;
    ìwọ yóò sì ru ẹ̀gàn àwọn ènìyàn mi.”

Ìrora Israẹli

Ègbé ni fún mi!
Nítorí èmi sì dàbí ẹni tí ń kó èso ẹ̀ẹ̀rùn jọ,
    ìpèsè ọgbà àjàrà;
kò sì ṣí odidi àjàrà kankan láti jẹ,
    kò sì ṣí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ nítorí tí ebi ń pa mí.
Àwọn olódodo sì ti kúrò ní ilẹ̀ náà,
    kò sì ṣí ẹnìkan tí ó ṣẹ́kù tí ó jọ olóòtítọ́;
gbogbo wọn sì ń purọ́ ní dídúró nítorí ìtàjẹ̀ sílẹ̀,
    olúkúlùkù wọ́n sì ń fi àwọ̀n de arákùnrin rẹ̀.
Ọwọ́ wọn méjèèjì ti múra tán láti ṣe búburú;
    àwọn alákòóso ń béèrè fún ẹ̀bùn,
àwọn onídàájọ́ sì ń gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀
    alágbára sì ń pàṣẹ ohun tí wọ́n fẹ́,
    gbogbo wọn sì jùmọ̀ ń dìtẹ̀.
Ẹni tí ó sàn jùlọ nínú wọn sì dàbí ẹ̀gún,
    ẹni tí ó jẹ́ olódodo jùlọ burú ju ẹ̀gún ọgbà lọ.
Ọjọ́ àwọn olùṣọ́ rẹ̀ ti dé,
    àti ọjọ́ tí Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ wò.
    Nísinsin yìí ní àkókò ìdààmú wọn.
Ẹ má ṣe gba ọ̀rẹ́ kan gbọ́;
    ẹ má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé amọ̀nà kankan.
Pa ìlẹ̀kùn ẹnu rẹ fún ẹni
    tí ó sùn ní oókan àyà rẹ.
(A)Nítorí tí ọmọkùnrin kò bọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀,
    ọmọbìnrin sì dìde sí ìyá rẹ̀,
aya ọmọ sí ìyá ọkọ rẹ̀,
    ọ̀tá olúkúlùkù ni àwọn ará ilé rẹ̀.

Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi ní ìwòye ní ìrètí sí Olúwa,
    Èmi dúró de Ọlọ́run olùgbàlà mi;
    Ọlọ́run mi yóò sì tẹ́tí sí mi.

Israẹli yóò dìde

Má ṣe yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi;
    Bí mó bá ṣubú, èmi yóò dìde.
Nígbà tí mo bá jókòó sínú òkùnkùn
    Olúwa yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún mi.
Nítorí èmi ti dẹ́ṣẹ̀ sí i,
    Èmi yóò faradà ìbínú Olúwa,
títí òun yóò ṣe gba ẹjọ́ mi rò,
    tí yóò sì ṣe ìdájọ́ mi.
Òun yóò sì mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀;
    èmi yóò sì rí òdodo rẹ̀.
10 Nígbà náà ni ọ̀tá mi yóò rí i
    ìtìjú yóò sì bo ẹni tí ó wí fún mi pé,
“Níbo ni Olúwa Ọlọ́run rẹ wà?”
    Ojú mi yóò rí ìṣubú rẹ̀;
nísinsin yìí ni yóò di ìtẹ̀mọ́lẹ̀
    bí ẹrẹ̀ òpópó.

11 Ọjọ́ tí a ó mọ odi rẹ yóò dé,
    ọjọ́ náà ni àṣẹ yóò jìnnà réré.
12 Ní ọjọ́ náà àwọn ènìyàn yóò wá sọ́dọ̀ rẹ
    láti Asiria àti ìlú ńlá Ejibiti
àní láti Ejibiti dé Eufurate
    láti Òkun dé Òkun
    àti láti òkè ńlá dé òkè ńlá.
13 Ilẹ̀ náà yóò di ahoro fún àwọn olùgbé inú rẹ̀,
    nítorí èso ìwà wọn.

Àdúrà àti ìyìn

14 Fi ọ̀pá rẹ bọ́ àwọn ènìyàn, agbo ẹran ìní rẹ,
    èyí tí ó ń dágbé nínú igbó
ní àárín Karmeli;
    Jẹ́ kí wọn jẹun ní Baṣani àti Gileadi
    bí ọjọ́ ìgbàanì.

15 “Bí i ọjọ́ tí ó jáde kúrò ní Ejibiti wá,
    ni èmi yóò fi ohun ìyanu hàn án.”

16 Orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú yóò sì tì wọ́n,
    nínú gbogbo agbára wọn.
Wọn yóò fi ọwọ́ lé ẹnu wọn,
    etí wọn yóò sì di.
17 Wọn yóò lá erùpẹ̀ bí ejò,
    wọn yóò sì jáde kúrò nínú ihò wọn bí ekòló.
Wọn yóò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run wa,
    wọn yóò sì bẹ̀rù nítorí rẹ̀.
18 Ta ni Ọlọ́run bí rẹ̀,
    ẹni tí ó dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì,
    tí ó sì fojú fo ìrékọjá èyí tókù ìní rẹ̀?
Kì í dúró nínú ìbínú rẹ̀ láéláé
    nítorí òun ní inú dídùn sí àánú.
19 Òun yóò tún padà yọ́nú sí wa;
    òun yóò tẹ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa mọ́lẹ̀,
    yóò sì fa gbogbo àìṣedéédéé wa sínú ibú Òkun.
20 (B)Ìwọ yóò fi òtítọ́ hàn sí Jakọbu
    ìwọ yóò sì fi àánú hàn sí Abrahamu,
bí ìwọ ṣe búra fún àwọn baba wa
    láti ọjọ́ ìgbàanì.

Ìfihàn 13

Ẹranko kan tí n ti inú okun jáde wá

13 (A)Mo sì rí ẹranko kan ń ti inú Òkun jáde wá, ó ní ìwo mẹ́wàá àti orí méje, lórí àwọn ìwo náà ni adé méje wà, ni orí kọ̀ọ̀kan ni orúkọ ọ̀rọ̀-òdì wà. Ẹranko tí mo rí náà sì dàbí ẹkùn, ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí tí beari ẹnu rẹ̀ sì dàbí tí kìnnìún: dragoni náà sì fún un ni agbára rẹ̀, àti ìtẹ́ rẹ̀, àti àṣẹ ńlá. Mo sì rí ọ̀kan nínú àwọn orí rẹ̀ bí ẹni pé a sá a pa, a sì tí wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ náà sàn, gbogbo ayé sì fi ìyanu tẹ̀lé ẹranko náà. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún dragoni náà, nítorí tí o fún ẹranko náà ní àṣẹ, wọn sì foríbalẹ̀ fún ẹranko náà, wí pé, “Ta ni o dàbí ẹranko yìí? Ta ni ó sì lè bá a jagun?”

(B)A sì fún un ni ẹnu láti má sọ ohun ńlá àti ọ̀rọ̀-òdì, a sì fi agbára fún un láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni oṣù méjìlélógójì. Ó sì ya ẹnu rẹ̀ ni ọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ rẹ̀, àti sí àgọ́ rẹ̀, àti sí àwọn tí ń gbé ọ̀run. (C)A sì fún un láti máa bá àwọn ènìyàn mímọ́ jagun, àti láti ṣẹ́gun wọn: a sì fi agbára fún un lórí gbogbo ẹ̀yà, àti ènìyàn, àti èdè, àti orílẹ̀. Gbogbo àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé yóò sì máa sìn ín, olúkúlùkù ẹni tí a kò kọ orúkọ rẹ̀, sínú ìwé ìyè Ọ̀dọ́-Àgùntàn tí a tí pa láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

(D)Bí ẹnikẹ́ni bá létí kí o gbọ́.

10 (E)Ẹni tí a ti pinnu rẹ̀ fún ìgbèkùn,
    ìgbèkùn ni yóò lọ;
ẹni tí a sì ti pinnu rẹ̀ fún idà,
    ni a ó sì fi idà pa.

Níhìn-ín ni sùúrù àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn mímọ́ wà.

Ẹranko jáde nínú ilẹ̀

11 Mo sì rí ẹranko mìíràn gòkè láti inú ilẹ̀ wá; ó sì ní ìwo méjì bí ọ̀dọ́-àgùntàn, ó sì ń sọ̀rọ̀ bí dragoni. 12 Ó sì ń lo gbogbo agbára ẹranko èkínní níwájú rẹ̀, ó sì mú ilẹ̀ ayé àti àwọn tí ń gbé inú rẹ̀ foríbalẹ̀ fún ẹranko èkínní tí a ti wo ọgbẹ́ àṣápa rẹ̀ sàn. 13 Ó sì ń ṣe ohun ìyanu ńlá, àní tí ó fi ń mú iná sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá sì ilẹ̀ ayé níwájú àwọn ènìyàn. 14 (F)Ó sì ń tán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé jẹ nípa àwọn ohun ìyanu tí a fi fún un láti ṣe níwájú ẹranko náà; ó wí fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé láti ya àwòrán fún ẹranko náà tí o tí gbá ọgbẹ́ idà, tí ó sì yè. 15 (G)A sì fi fún un, láti fi ẹ̀mí fún àwòrán ẹranko náà kí ó máa sọ̀rọ̀ kí ó sì mu kí a pa gbogbo àwọn tí kò foríbalẹ̀ fún àwòrán ẹranko náà. 16 Ó sì mu gbogbo wọn, àti kékeré àti ńlá, ọlọ́rọ̀ àti tálákà, olómìnira àti ẹrú, láti gba ààmì kan sí ọwọ́ ọ̀tún wọn, tàbí ní iwájú orí wọn; 17 àti kí ẹnikẹ́ni má lè rà tàbí tà, bí kò ṣe ẹni tí o bá ní ààmì náà, èyí ni orúkọ ẹranko náà, tàbí ààmì orúkọ rẹ̀.

18 Níhìn-ín ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹni tí o bá ní òye, kí o ka òǹkà tí ń bẹ̀ lára ẹranko náà: nítorí pé òǹkà ènìyàn ni, òǹkà rẹ̀ náà sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta-ọgọ́ta-ẹẹ́fà. (666).

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.