Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

Old/New Testament

Each day includes a passage from both the Old Testament and New Testament.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Ọbadiah

Ìran ti Ọbadiah.

(A)Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí nípa Edomu.

Àwa ti gbọ́ ohùn kan láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá:
    A sì ti rán ikọ̀ kan sí gbogbo kèfèrí láti sọ pé,
“Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a dìde ogun sí i.”

“Kíyèsi i, Èmi yóò sọ ọ́ di kékeré láàrín àwọn kèfèrí;
    ìwọ yóò sì di gígàn lọ́pọ̀lọpọ̀,
Ìgbéraga àyà rẹ ti tàn ọ́ jẹ,
    ìwọ tí ń gbé inú pálapàla àpáta,
    tí o sì kọ́ ibùgbé rẹ sí ibi gíga,
ìwọ wí nínú ọkàn rẹ pé,
    ‘ta ni yóò mú mi sọ̀kalẹ̀?’
Bí ìwọ tilẹ̀ gbé ara rẹ ga bí ẹyẹ idì,
    bí ìwọ tilẹ̀ tẹ́ ìtẹ́ rẹ sí àárín àwọn ìràwọ̀,
    láti ibẹ̀ ni èmi yóò ti sọ̀ ọ kalẹ̀,”
    ni Olúwa wí.
“Bí àwọn olè tọ̀ ọ́ wá,
    bí àwọn ọlọ́ṣà ní òru,
Háà! Irú ìparun wo ló dúró dè ọ́:
    wọn kò ha jalè tó bí wọ́n ti fẹ́?
Bí àwọn tí ń ká èso àjàrà tọ̀ ọ́ wá,
    wọn kò ha ni fi èso àjàrà díẹ̀ sílẹ̀?
Báwo ni a ṣe ṣe àwárí nǹkan Esau,
    tí a sì wá ohun ìní ìkọ̀kọ̀ rẹ̀ jáde.
Gbogbo àwọn ẹni ìmùlẹ̀ rẹ
    ti mú ọ dé ìpẹ̀kun ilẹ̀ rẹ:
Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ti tàn ọ́ jẹ, wọ́n sì ti borí rẹ;
    àwọn tó jẹ oúnjẹ rẹ dẹ pàkúté dè ọ́,
    ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ní òye rẹ̀.”

Olúwa wí pé, “Ní ọjọ́ náà,
    Èmi kì yóò ha pa àwọn ọlọ́gbọ́n Edomu run,
    àti àwọn amòye run kúrò ní òkè Esau?
A ó ṣe ẹ̀rù ba àwọn jagunjagun rẹ, Ìwọ Temani,
    gbogbo àwọn tó wà ní orí òkè Esau
    ní a ó gé kúrò nínú ìpànìyàn náà.
10 Nítorí ìwà ipá sí Jakọbu arákùnrin rẹ,
    ìtìjú yóò bò ọ,
    a ó sì pa ọ run títí láé.
11 Ní ọjọ́ tí ìwọ dúró ní apá kan,
    ní ọjọ́ tí àlejò kó ogún rẹ lọ,
tí àwọn àjèjì sì wọ ibodè rẹ
    tí wọ́n sì sẹ́ kèké lórí Jerusalẹmu,
    ìwọ náà wà bí ọ̀kan nínú wọn.
12 Ìwọ kì bá tí fi ojú kéré arákùnrin rẹ,
    ní àkókò ìbànújẹ́ rẹ̀
ìwọ kì bá tí yọ̀ lórí àwọn ọmọ Juda,
    ní ọjọ́ ìparun wọn
ìwọ kì bá tí gbéraga púpọ̀
    ní ọjọ́ wàhálà wọn.
13 Ìwọ kì bá tí wọ inú ibodè àwọn ènìyàn mi lọ,
    ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí fojú kó wọn mọ́lẹ̀
    nínú ìdààmú wọn, ní ọjọ́ àjálù wọn.
Ìwọ kì bá tí jí ẹrù wọn kó,
    ní ọjọ́ ìpọ́njú wọn.
14 Ìwọ kì bá tí dúró ní ìkóríta ọ̀nà
    láti ké àwọn tirẹ̀ tó ti sálà kúrò.
Ìwọ kì bá tí fa àwọn tó ṣẹ́kù nínú
    wọn lélẹ̀ ní ọjọ́ wàhálà wọn.

15 “Nítorí ọjọ́ Olúwa súnmọ́ etílé
    lórí gbogbo àwọn kèfèrí.
Bí ìwọ ti ṣe, bẹ́ẹ̀ ni a ó ṣe sí ìwọ náà;
    ẹ̀san rẹ yóò sì yípadà sí orí ara rẹ.
16 Gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀ ṣe mu lórí òkè mímọ́ mi
    bẹ́ẹ̀ ni gbogbo kèfèrí yóò máa mu títí
Wọn yóò mu wọn yóò sì mu àmutẹ́rùn
    wọn yóò sì wà bí ẹni pé wọn kò wà rí
17 Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni
    Wọn yóò sì jẹ́ mímọ́
àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn
18 Ilé Jakọbu yóò sì jẹ́ iná
    àti ilé Josẹfu ọwọ́ iná
ilé Esau yóò jẹ àgékù koríko
    wọn yóò fi iná sí i,
wọn yóò jo run.
    Kì yóò sí ẹni tí yóò kù ní ilé Esau.”
Nítorí Olúwa ti sọ̀rọ̀.

19 Àwọn ará gúúsù yóò ni òkè Esau,
    àwọn ará ẹsẹ̀ òkè yóò ni
ilẹ̀ àwọn ará Filistini ní ìní.
    Wọn yóò sì ni oko Efraimu àti Samaria;
    Benjamini yóò ní Gileadi ní ìní.
20 Àwọn ìgbèkùn Israẹli tí ó wà ní Kenaani
    yóò ni ilẹ̀ títí dé Sarefati;
àwọn ìgbèkùn láti Jerusalẹmu tí ó wà ní Sefaredi
    yóò ni àwọn ìlú gúúsù ní ìní
21 Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá
    láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau.
    Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.

Ìfihàn 9

Angẹli karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀ mo sì rí ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá: a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un. (A)Ó sì ṣí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn àti ojú sánmọ̀ sì ṣókùnkùn nítorí èéfín ihò náà. (B)Àwọn eṣú sì jáde ti inú èéfín náà wá sórí ilẹ̀: a sì fi agbára fún wọn gẹ́gẹ́ bí agbára àkéekèe ilẹ̀. (C)A sì fún wọn pé ki wọn má ṣe pa koríko ilẹ̀ lára tàbí ohun tútù kan, tàbí igikígi kan; bí kò ṣe àwọn ènìyàn tí kò ni èdìdì Ọlọ́run ní iwájú wọn. A sì pàṣẹ fún wọn pé, kí wọn má ṣe pa wọ́n, ṣùgbọ́n kí a dá wọn ni oró ni oṣù márùn-ún: oró wọn sì dàbí oró àkéekèe, nígbà tí o bá ta ènìyàn. (D)Ní ọjọ́ wọ̀nyí ni àwọn ènìyàn yóò sì máa wá ikú, wọn kì yóò sì rí i; wọn yóò sì fẹ́ láti kú, ikú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.

(E)Ìrísí àwọn eṣú náà sì dàbí àwọn ẹṣin tí a múra sílẹ̀ fún ogun; àti ní orí wọn ni ohun tí o dàbí àwọn adé wúrà wà, ojú wọn sì dàbí ojú ènìyàn; (F)wọ́n sì ní irun bí obìnrin, eyín wọn sì dàbí ti kìnnìún. (G)Wọ́n sì ní ìgbàyà tí ó dàbí ìgbàyà irin; ìró ìyẹ́ wọn sì dàbí ìró kẹ̀kẹ́-ẹṣin púpọ̀ tí ń súré lọ sí ogun. 10 Wọ́n sì ni ìrù àti oró bí tí àkéekèe, àti ní ìrù wọn ni agbára wọn wà láti pa ènìyàn lára fún oṣù márùn-ún. 11 Wọ́n ní angẹli ọ̀gbun náà bí ọba lórí wọn, orúkọ rẹ̀ ní èdè Heberu ní Abaddoni, àti ni èdè Giriki orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Apollioni.

12 Ègbé kan tí kọjá, kíyèsi i, ègbé méjì ń bọ̀ síbẹ̀ lẹ́yìn èyí.

13 (H)Angẹli kẹfà si fọn ìpè rẹ̀, mo sì gbọ́ ohùn kan láti ibi ìwo mẹ́rin pẹpẹ wúrà wá, tí ń bẹ níwájú Ọlọ́run. 14 Òun wí fún angẹli kẹfà náà tí o ni ìpè náà pé, “Tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀ tí a dè lẹ́bàá odò ńlá Eufurate!” 15 A sì tú àwọn angẹli mẹ́rin náà sílẹ̀, tí a ti pèsè tẹ́lẹ̀ fún wákàtí náà, àti ọjọ́ náà, àti oṣù náà, àti ọdún náà, láti pa ìdámẹ́ta ènìyàn. 16 Iye ogún àwọn ẹlẹ́ṣin sì jẹ́ àádọ́ta ọ̀kẹ́ lọ́nà igba: mo sì gbọ́ iye wọn.

17 Báyìí ni mo sì rí àwọn ẹṣin náà ní ojúran, àti àwọn tí o gùn wọ́n, wọ́n ni ìgbàyà aláwọ̀ iná, àti ti jakinti, àti tí sulfuru: orí àwọn ẹṣin náà sì dàbí orí àwọn kìnnìún; àti láti ẹnu wọn ni iná, àti èéfín, àti sulfuru tí ń jáde. 18 Nípa ìyọnu mẹ́ta wọ̀nyí ni a tí pa ìdámẹ́ta ènìyàn, nípa iná, àti nípa èéfín, àti nípa sulfuru tí o ń tí ẹnu wọn jáde. 19 Nítorí pé agbára àwọn ẹṣin náà ń bẹ ní ẹnu wọn àti ní ìrù wọn: nítorí pé ìrù wọn dàbí ejò, wọn sì ní orí, àwọn wọ̀nyí ni wọn sì fi ń pa ni lára.

20 (I)Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn ìyókù tí a kò sì ti ipa ìyọnu wọ̀nyí pa, kò sì ronúpìwàdà iṣẹ́ ọwọ́ wọn, kí wọn má ṣe sin àwọn ẹ̀mí èṣù àti ère wúrà, àti ti fàdákà, àti ti idẹ, àti òkúta, àti ti igi mọ́: àwọn tí kò lè ríran, tàbí kí wọn gbọ́rọ̀, tàbí kí wọn rìn: 21 Bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ronúpìwàdà ìwà ìpànìyàn wọn, tàbí oṣó wọn tàbí àgbèrè wọn, tàbí olè wọn.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.