Old/New Testament
Ìdájọ́ n bọ̀ lórí Israẹli àti Juda
5 “Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà!
Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ Israẹli!
Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba!
Ìdájọ́ yìí kàn yín:
Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní Mispa
àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí Tabori
2 Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn
gbogbo wọn ni èmi ó bá wí,
3 Mo mọ ohun gbogbo nípa Efraimu
Israẹli kò sì pamọ́ fún mi
Efraimu, ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè
Israẹli sì ti díbàjẹ́.
4 “Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè
láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn.
Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn,
wọn kò sì mọ Olúwa.
5 Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí lé wọn;
Àwọn ọmọ Israẹli, àti Efraimu pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn.
6 Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran
àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa,
wọn kò ní rí i,
ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn.
7 Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa
wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ.
Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn,
ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn.
8 “Fọn fèrè ní Gibeah,
kí ẹ sì fun ìpè ní Rama.
Ẹ pariwo ogun ní Beti-Afeni
máa wárìrì, ìwọ Benjamini.
9 Efraimu yóò di ahoro
ní ọjọ́ ìbáwí
láàrín àwọn ẹ̀yà Israẹli
Mo sọ ohun tí ó dájú.
10 Àwọn olórí Juda dàbí àwọn tí í
máa yí òkúta ààlà kúrò.
Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé
wọn lórí bí ìkún omi.
11 A ni Efraimu lára,
A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́
nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà
12 Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí Efraimu
Mo sì dàbí ìdin ara Juda.
13 “Nígbà ti Efraimu ri àìsàn rẹ̀,
tí Juda sì rí ojú egbò rẹ̀
ni Efraimu bá tọ ará Asiria lọ,
ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́
Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn
bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná
14 Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Efraimu,
bí i kìnnìún ńlá sí ilé Juda.
Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;
Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.
15 Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi
títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi
wọn yóò sì wá ojú mi
nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”
Àìronúpìwàdà Israẹli
6 “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a padà sọ́dọ̀ Olúwa
ó ti fà wá ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ
ṣùgbọ́n yóò mú wa láradá
Ó ti pa wá lára
ṣùgbọ́n yóò dí ojú ọgbẹ́ wa.
2 Lẹ́yìn ọjọ́ méjì, yóò sọ wá jí
ní ọjọ́ kẹta yóò mú wa padà bọ̀ sípò
kí a ba à le wá gbé níwájú rẹ̀
3 Ẹ jẹ́ kí a mọ Olúwa
Ẹ jẹ́ kí a tẹ̀síwájú láti mọ̀ ọ́n.
Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,
Yóò jáde;
Yóò tọ̀ wá wá bí òjò
bí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”
4 “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Efraimu?
Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Juda?
Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùkuu òwúrọ̀
bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.
5 Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.
Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu mi
Ìdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín
6 (A)Nítorí àánú ni mo fẹ́, kì í ṣe ẹbọ;
àti ìmọ̀ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.
7 Bí i Adamu, wọ́n da májẹ̀mú
wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí mi níbẹ̀.
8 Gileadi jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburú
tí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.
9 Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùba de àwọn ènìyàn
bẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;
tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣekemu,
tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.
10 Mo ti rí ohun tó ba ni lẹ́rù
ní ilé Israẹli.
Níbẹ̀ Efraimu, fi ara rẹ̀ fún àgbèrè
Israẹli sì di aláìmọ́.
11 “Àti fún ìwọ, Juda
A ti yan ọjọ́ ìkórè rẹ.
“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,
7 nígbà tí èmi ìbá mú Israẹli láradá.
Ẹ̀ṣẹ̀ Efraimu ń farahàn
ìwà búburú Samaria sì ń hàn síta.
Wọ́n ń ṣe ẹ̀tàn,
àwọn olè ń fọ́ ilé;
àwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà;
2 Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pé
mo rántí gbogbo ìwà búburú wọn:
Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátápátá;
wọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.
3 “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,
àti inú ọmọ-aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn
4 Alágbèrè ni gbogbo wọn
wọ́n gbóná bí ààrò àkàrà
tí a dáwọ́ kíkoná dúró,
lẹ́yìn ìgbà tí o ti pò ìyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.
5 Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wa
wáìnì mú ara ọmọ-aládé gbóná
ó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.
6 Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààrò
wọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkíṣí,
ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òru
ó sì bú jáde bí ọ̀wọ́-iná ní òwúrọ̀.
7 Gbogbo wọn gbóná bí ààrò
wọ́n pa gbogbo olórí wọn run,
gbogbo ọba wọn si ṣubú
kò sì ṣí ẹnìkan nínú wọn tí ó ké pè mí.
8 “Efraimu ti darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn náà;
Efraimu jẹ́ àkàrà tí a kò yípadà
9 Àwọn àlejò ti jẹ agbára rẹ̀ run
ṣùgbọ́n kò sì mọ̀,
Ewú ti wà ní orí rẹ̀ káàkiri
bẹ́ẹ̀ ni kò kíyèsi i
10 Ìgbéraga Israẹli ń jẹ́rìí sí i
ṣùgbọ́n pẹ̀lú gbogbo èyí
kò padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa
Ọlọ́run, tàbí kí ó wá a.
11 “Efraimu dàbí àdàbà
tó rọrùn láti tànjẹ àti aláìgbọ́n
tó wá ń pé Ejibiti nísinsin yìí
tó sì tún ń padà lọ si Asiria.
12 Nígbà tí wọ́n bá lọ, èmi ó ta àwọ̀n mi sórí wọn
Èmi ó fà wọ́n lulẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ojú ọ̀run
Nígbà tí mo bá gbọ́ pé wọ́n rìn pọ̀
Èmi ó nà wọ́n fún iṣẹ́ búburú ọwọ́ wọn.
13 Ègbé ní fún wọn,
nítorí pé wọ́n ti yà kúrò lọ́dọ̀ mi!
Ìparun wà lórí wọn,
nítorí pé wọ́n ti ṣọ̀tẹ̀ sí mi!
Èmi fẹ́ láti rà wọ́n padà.
Ṣùgbọ́n wọ́n ń parọ́ mọ́ mi
14 Wọn kò kégbe pè mí láti ọkàn wọn,
Ṣùgbọ́n wọ́n ń pohùnréré ẹkún lórí ibùsùn wọn.
Wọ́n kó ara wọn jọ, nítorí ọkà àti wáìnì
ṣùgbọ́n wọ́n yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.
15 Mo kọ́ wọn, mo sì fún wọn ní agbára,
síbẹ̀ wọ́n tún ń dìtẹ̀ mọ́ mi.
16 Wọn kò padà sí ọ̀dọ̀ Ọ̀gá-ògo;
wọ́n dàbí ọfà tí ó ti bàjẹ́
Àwọn aṣíwájú wọn yóò ti ipa idà ṣubú
nítorí ìrunú ahọ́n wọn.
Torí èyí, wọn ó fi wọ́n ṣe
ẹlẹ́yà ní ilẹ̀ Ejibiti.
Israẹli yípadà kúrò ní ọnà
8 “Fi ìpè sí ẹnu rẹ!
Ẹyẹ idì wà lórí ilé Olúwa
nítorí pé àwọn ènìyàn ti dalẹ̀ májẹ̀mú,
wọ́n sì ti ṣọ̀tẹ̀ sí òfin mi.
2 Israẹli kígbe pè mí
‘Háà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́n!’
3 Ṣùgbọ́n Israẹli ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀
ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀
4 Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ mi
wọ́n yan ọmọ-aládé láì si ìmọ̀ mi níbẹ̀.
Wọ́n fi fàdákà àti wúrà
ṣe ère fún ara wọn,
si ìparun ara wọn.
5 Ju ère ẹgbọrọ màlúù rẹ, ìwọ Samaria!
Ìbínú mi ń ru sí wọn:
yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?
6 Israẹli ni wọ́n ti wá!
Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe é
Àní ère ẹgbọrọ màlúù Samaria, ni a ó fọ́ túútúú.
7 “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́
wọ́n sì ká ìjì
Igi ọkà kò lórí,
kò sì ní mú oúnjẹ wá.
Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkà
àwọn àjèjì ni yóò jẹ.
8 A ti gbé Israẹli mì,
báyìí, ó sì ti wà láàrín àwọn orílẹ̀-èdè
bí ohun èlò tí kò wúlò.
9 Nítorí pé wọ́n ti gòkè lọ sí Asiria
gẹ́gẹ́ bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó tó ń rìn kiri.
Efraimu ti ta ara rẹ̀ fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀.
10 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárín orílẹ̀-èdè
Èmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsin yìí
Wọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànù
lọ́wọ́ ìnilára ọba alágbára.
11 “Nítorí Efraimu ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀
gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un
12 Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn.
Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì
13 Wọ́n ń rú ẹbọ tí wọ́n yàn fún mi,
wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀
Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.
Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọn
yóò sì jẹ wọ́n ní yà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
Wọn yóò padà sí Ejibiti
14 (B)Nítorí Israẹli ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀
Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀
Juda ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀
ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kan
sí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”
Sí ìjọ Efesu
2 “Sí angẹli ìjọ ní Efesu kọ̀wé:
Nǹkan wọ̀nyí ní ẹni tí ó mú ìràwọ̀ méje náà ni ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ wí, ẹni tí ń rìn ní àárín ọ̀pá wúrà fìtílà méje:
2 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti làálàá rẹ, àti ìfaradà rẹ, àti bí ara rẹ kò ti gba àwọn ẹni búburú: àti bí ìwọ sì ti dán àwọn tí ń pe ara wọn ní aposteli, tí wọ́n kì í sì í ṣe bẹ́ẹ̀ wo, tí ìwọ sì rí pé èké ni wọ́n; 3 Tí ìwọ sì faradà ìyà, àti nítorí orúkọ mi tí ó sì rọ́jú, tí àárẹ̀ kò sì mú ọ.
4 Síbẹ̀ èyí ni mo rí wí sí ọ, pé, ìwọ ti fi ìfẹ́ ìṣáájú rẹ sílẹ̀. 5 Rántí ibi tí ìwọ ti gbé ṣubú! Ronúpìwàdà, kí ó sì ṣe iṣẹ́ ìṣáájú; bí kò sì ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó sì tọ̀ ọ́ wá, èmi ó sì ṣí ọ̀pá fìtílà rẹ̀ kúrò ní ipò rẹ̀, bí kò ṣe bí ìwọ bá ronúpìwàdà. 6 Ṣùgbọ́n èyí ni ìwọ ní, pé ìwọ kórìíra ìṣe àwọn Nikolatani, èyí tí èmi pẹ̀lú sì kórìíra.
7 (A)Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun ni èmi yóò fi èso igi ìyè nì fún jẹ, tí ń bẹ láàrín Paradise Ọlọ́run.
Sí Ìjọ ní Smirna
8 (B)“Àti sí angẹli ìjọ ní Smirna kọ̀wé:
Nǹkan wọ̀nyí ni ẹni tí í ṣe ẹni ìṣáájú àti ẹni ìkẹyìn wí, ẹni tí ó ti kú, tí ó sì tún yè:
9 Èmi mọ iṣẹ́ rẹ, àti ìpọ́njú, àti àìní rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́, èmi sì mọ ọ̀rọ̀-òdì tí àwọn tí ń wí pé, Júù ni àwọn tìkára wọn, tí wọn kì sì í ṣe bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n tí wọ́n jẹ́ Sinagọgu ti Satani. 10 (C)Má ṣe bẹ̀rù ohunkóhun tí ìwọ ń bọ wá jìyà rẹ̀. Kíyèsi i, èṣù yóò gbé nínú yín jù sínú túbú, kí a lè dán yin wò; ẹ̀yin ó sì ní ìpọ́njú ní ọjọ́ mẹ́wàá: ìwọ ṣa ṣe olóòtítọ́ dé ojú ikú, èmi ó sì fi adé ìyè fún ọ.
11 Ẹni tí ó bá ní etí kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ. Ẹni tí ó bá ṣẹ́gun kì yóò fi ara pa nínú ikú kejì.
Sí ìjọ ní Pargamu
12 “Àti sì angẹli ìjọ ni Pargamu kọ̀wé:
Ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni ẹni tí ó ní idà mímú olójú méjì.
13 Èmí mọ̀ ibi tí ìwọ ń gbé, àní ibi tí ìtẹ́ Satani wà. Síbẹ̀ ìwọ di orúkọ mi mú ṣinṣin. Ìwọ kò sì sẹ́ ìgbàgbọ́ nínú mi, pàápàá jùlọ ni ọjọ́ Antipa ẹlẹ́rìí mi, olóòtítọ́ ènìyàn, ẹni tí wọn pa láàrín yín, níbi tí Satani ń gbé.
14 (D)Ṣùgbọ́n mo ni nǹkan díẹ̀ wí sí ọ; nítorí tí ìwọ ní àwọn kan tí ó di ẹ̀kọ́ Balaamu mú síbẹ̀, ẹni tí ó kọ́ Balaki láti mú ohun ìkọ̀sẹ̀ wá síwájú àwọn ọmọ Israẹli, láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sí òrìṣà, àti láti máa ṣe àgbèrè. 15 Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ sì ní àwọn tí ó gbá ẹ̀kọ́ àwọn Nikolatani pẹ̀lú, ohun tí mo kórìíra. 16 Nítorí náà, ronúpìwàdà; bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó tọ̀ ọ́ wá nísinsin yìí, èmí o sì fi idà ẹnu mi bá wọn jà.
17 (E)Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ; Ẹni tí o bá ṣẹ́gun ni èmi o fi manna tí ó pamọ́ fún, èmi ó sì fún un ni òkúta funfun kan, àti sára òkúta náà ni a kọ orúkọ tuntun kan, tí ẹnìkan kò mọ̀ bí kò ṣe ẹni tí ó gbà á.
Sí ìjọ ni Tiatira
18 (F)“Àti sí angẹli ìjọ ní Tiatira kọ̀wé:
Nǹkan wọ̀nyí ni Ọmọ Ọlọ́run wí, ẹni tí ojú rẹ̀ dàbí ọ̀wọ́-iná, tí ẹsẹ̀ rẹ̀ sì dàbí idẹ dáradára:
19 Èmi mọ̀ iṣẹ́, ìfẹ́, àti ìgbàgbọ́ àti ìsìn àti sùúrù rẹ̀; àti pé iṣẹ́ rẹ̀ ìkẹyìn ju tí ìṣáájú lọ.
20 (G)Ṣùgbọ́n èyí ni mo rí wí sí ọ: nítorí tí ìwọ fi ààyè sílẹ̀ fún obìnrin Jesebeli tí ó ń pe ara rẹ̀ ní wòlíì. Nípasẹ̀ ẹ̀kọ́ rẹ̀, ó sì ń kọ́ àwọn ìránṣẹ́ mi, ó sì ń tàn wọ́n láti máa ṣe àgbèrè, àti láti máa jẹ ohun tí a pa rú ẹbọ sì òrìṣà. 21 Èmi fi àkókò fún un, láti ronúpìwàdà; ṣùgbọ́n òun kò fẹ́ ronúpìwàdà àgbèrè rẹ̀. 22 Nítorí náà, èmi ó gbé e sọ sí orí àkéte ìpọ́njú, àti àwọn tí ń bá a ṣe panṣágà ni èmi ó fi sínú ìpọ́njú ńlá, bí kò ṣe bí wọ́n bá ronúpìwàdà iṣẹ́ wọn. 23 (H)Èmi o pa àwọn ọmọ rẹ̀ run; gbogbo ìjọ ni yóò sì mọ̀ pé, èmi ni ẹni tí ń wádìí inú àti ọkàn: èmi ó sì fi fún olúkúlùkù yín gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.
24 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni mò ń sọ fún, ẹ̀yin ìyókù tí ń bẹ ní Tiatira, gbogbo ẹ̀yin tí kò ni ẹ̀kọ́ yìí, ti kò ì tí ì mọ̀ ohun tí wọn pè ni ohun ìjìnlẹ̀ Satani, èmi kò di ẹrù mìíràn rù yín: 25 Ṣùgbọ́n èyí tí ẹ̀yin ní, ẹ di mú ṣinṣin títí èmi ó fi dé.
26 (I)Ẹni tí ó bá sì ṣẹ́gun, àti tí ó sì ṣe ìfẹ́ mi títí dé òpin, èmi ó fún un láṣẹ lórí àwọn orílẹ̀-èdè: 27 ‘Òun ó sì máa fi ọ̀pá irin ṣe àkóso wọn; gẹ́gẹ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò amọ̀kòkò ni a ó fọ́ wọn túútúú,’ gẹ́gẹ́ bí èmi pẹ̀lú tí gbà àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Baba mi. 28 Èmi yóò sì fi ìràwọ̀ òwúrọ̀ fún un. 29 Ẹni tí ó bá létí, kí ó gbọ́ ohun tí Ẹ̀mí ń sọ fún àwọn ìjọ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.