Print Page Options
Previous Prev Day Next DayNext

New Testament in a Year

Read the New Testament from start to finish, from Matthew to Revelation.
Duration: 365 days
Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)
Version
Luku 19:28-48

Ó wọ ilé pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́

28 (A)Nígbà tí ó sì ti wí nǹkan wọ̀nyí tan, ó lọ síwájú, ó ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. 29 (B)Ó sì ṣe, nígbà tí ó súnmọ́ Betfage àti Betani ní òkè tí a ń pè ní òkè olifi, ó rán àwọn méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 30 Wí pé, “Ẹ lọ sí ìletò tí ó kọjú sí yín; nígbà tí ẹ̀yin bá wọ̀ ọ́ lọ, ẹ̀yin ó rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tí a so, tí ẹnikẹ́ni kò gùn rí: ẹ tú u, kí ẹ sì fà á wá. 31 Bí ẹnikẹ́ni bá sì bi yín pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tú u?’ Kí ẹ̀yin wí báyìí pé, ‘Olúwa ń fẹ́ lò ó.’ ”

32 (C)Àwọn tí a rán sì mú ọ̀nà wọn pọ̀n, wọ́n sì bá a gẹ́gẹ́ bí ó ti wí fún wọn. 33 Bí wọ́n sì ti ń tú ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, àwọn Olúwa rẹ̀ bi wọ́n pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń tu kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà?”

34 (D)Wọ́n sì wí pé, “Olúwa fẹ́ lò ó.”

35 Wọ́n sì fà á tọ Jesu wá, wọ́n sì tẹ́ aṣọ sí ẹ̀yìn ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ náà, wọ́n sì gbé Jesu kà á. 36 (E)Bí ó sì ti ń lọ wọ́n tẹ́ aṣọ wọn sí ọ̀nà.

37 Bí ó sì ti súnmọ́ etí ibẹ̀ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè olifi, gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ̀, wọ́n sì fi ohùn rara yin Ọlọ́run, nítorí iṣẹ́ ńlá gbogbo tí wọ́n ti rí;

38 (F)Wí pé, “Olùbùkún ni ọba tí ó ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!”

“Àlàáfíà ní ọ̀run, àti ògo ni òkè ọ̀run!”

39 (G)Àwọn kan nínú àwọn Farisi nínú àwùjọ náà sì wí fún un pé, “Olùkọ́ bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ wí.”

40 Ó sì dá wọn lóhùn, ó wí fún wọn pé, “Mo wí fún yín, Bí àwọn wọ̀nyí bá pa ẹnu wọn mọ́, àwọn òkúta yóò kígbe sókè.”

41 (H)Nígbà tí ó sì súnmọ́ etílé, ó ṣíjú wo ìlú náà, ó sọkún sí i lórí, 42 Ó ń wí pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ̀, lónìí yìí, àní ìwọ, ohun tí í ṣe tí Àlàáfíà rẹ! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí wọ́n pamọ́ kúrò lójú rẹ. 43 (I)Nítorí ọjọ́ ń bọ̀ fún ọ, tí àwọn ọ̀tá rẹ yóò mọ odi bèbè yí ọ ká, àní tí wọn yóò sì yí ọ ká, wọn ó sì ká ọ mọ́ níhà gbogbo. 44 (J)Wọn ó sì wó ọ palẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ pẹ̀lú rẹ; wọn kì yóò sì fi òkúta kan sílẹ̀ lórí ara wọn; nítorí ìwọ kò mọ ọjọ́ ìbẹ̀wò rẹ.”

Jesu nínú tẹmpili

45 (K)Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46 Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọsa.”

47 (L)Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, Ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48 Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn (BYO)

Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.