New Testament in a Year
Àwọn ìkìlọ̀ àti ọ̀rọ̀ ìyànjú
12 (A)Ó sì ṣe, nígbà tí àìníye ìjọ ènìyàn péjọpọ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń tẹ ara wọn mọ́lẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sísọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ máa ṣọ́ra yín nítorí ìwúkàrà àwọn Farisi tí í ṣe àgàbàgebè. 2 (B)Kò sí ohun tí a bò, tí a kì yóò sì fihàn; tàbí tí ó pamọ́, tí a kì yóò mọ̀. 3 Nítorí náà ohunkóhun tí ẹ̀yin sọ ní òkùnkùn, ní gbangba ni a ó ti gbọ́ ọ; àti ohun tí ẹ̀yin bá sọ sí etí ní iyàrá, lórí òrùlé ni a ó ti kéde rẹ̀.
4 (C)(D) “Èmi sì wí fún yín ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó ń pa ara ènìyàn kú, lẹ́yìn èyí, wọn kò sì ní èyí tí wọ́n lè ṣe mọ́. 5 (E)Ṣùgbọ́n èmi ó sì sọ ẹni tí ẹ̀yin ó bẹ̀rù fún yín: Ẹ bẹ̀rù ẹni tí ó lágbára lẹ́yìn tí ó bá pànìyàn tan, láti wọ́ ni lọ sí ọ̀run àpáàdì. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín òun ni kí ẹ bẹ̀rù. 6 Ológoṣẹ́ márùn-ún sá à ni a ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ méjì? A kò sì gbàgbé ọ̀kan nínú wọn níwájú Ọlọ́run? 7 (F)Ṣùgbọ́n gbogbo irun orí yín ni a kà pé ṣánṣán. Nítorí náà kí ẹ má ṣe bẹ̀rù: ẹ̀yin ní iye lórí ju ológoṣẹ́ púpọ̀ lọ.
8 “Mo sì wí fún yín pẹ̀lú, Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú àwọn ènìyàn. Ọmọ ènìyàn yóò sì jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run: 9 (G)Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mi níwájú ènìyàn, a ó sẹ́ ẹ níwájú àwọn angẹli Ọlọ́run. 10 (H)Àti ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí ọmọ ènìyàn, a ó dárí rẹ̀ jì í; ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀-òdì sí ẹ̀mí mímọ́, a kì yóò dárí rẹ̀ jì í.
11 (I)“Nígbà tí wọ́n bá sì mú yin wá sí Sinagọgu, àti síwájú àwọn olórí, àti àwọn aláṣẹ, ẹ má ṣe ṣàníyàn pé, báwo tàbí ohun kín ni ẹ̀yin yóò fèsì rẹ̀ tàbí kín ni ẹ̀yin ó wí: 12 Nítorí Ẹ̀mí mímọ́ yóò kọ́ yín ní wákàtí kan náà ní ohun tí ó yẹ kí ẹ sọ.”
Ìtàn òmùgọ̀ ọlọ́rọ̀
13 Ọ̀kan nínú àwùjọ wí fún un pé, “Olùkọ́, sọ fún arákùnrin mi kí ó pín mi ní ogún.”
14 Ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin yìí, ta ni ó fi mí jẹ onídàájọ́ tàbí olùpíngún fún yín?” 15 (J)Ó sì wí fún wọn pé, “Kíyèsára kí o sì máa ṣọ́ra nítorí ojúkòkòrò: nítorí ìgbésí ayé ènìyàn kò dúró lé ọ̀pọ̀ ohun tí ó ní.”
16 Ó sì pa òwe kan fún wọn pé, “Ilẹ̀ ọkùnrin ọlọ́rọ̀ so ọ̀pọ̀lọpọ̀ èso. 17 Ó sì rò nínú ara rẹ̀ pé, ‘Èmi ó ti ṣe, nítorí tí èmi kò ní ibi tí èmi ó gbé kó èso mi jọ sí.’
18 “Ó sì wí pé, ‘Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èso àti ọrọ̀ mi jọ sí. 19 Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, máa yọ̀.’
20 (K)“Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, ‘Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó béèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti ta ni nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?’
21 “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìṣúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”
Má ṣe ṣe àníyàn
22 (L) Jesu sì wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Nítorí náà mo wí fún yín pé, ẹ má ṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín pé, kín ni ẹ̀yin yóò jẹ tàbí nípa ara yin pe kín ni ẹyin o fi bora. 23 Ẹ̀mí sá à ju oúnjẹ lọ, ara sì ju aṣọ lọ. 24 (M)Ẹ kíyèsi àwọn ẹyẹ ìwò: wọn kì í fúnrúgbìn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì í kórè: wọn kò ní àká, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní abà, Ọlọ́run sá à ń bọ́ wọn: mélòó mélòó ni tí ẹ̀yin fi sàn ju ẹyẹ lọ! 25 Ta ni nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún ọjọ́ ayé rẹ̀? 26 Ǹjẹ́ bí ẹ̀yin kò ti lè ṣe èyí tí ó kéré bí eléyìí, èéṣe tí ẹ̀yin fi ń ṣàníyàn nítorí ìyókù?
27 (N)“Ẹ kíyèsi àwọn lílì bí wọ́n ti ń dàgbà; wọn kì í ṣiṣẹ́, wọn kì í rànwú; ṣùgbọ́n kí èmi wí fún yín, a kò ṣe Solomoni pàápàá lọ́ṣọ̀ọ́ ní gbogbo ògo rẹ̀ tó ọ̀kan nínú ìwọ̀nyí. 28 Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run bá wọ koríko igbó ní aṣọ tó bẹ́ẹ̀ èyí tí ó wà lónìí, tí a sì gbá a sínú iná lọ́la: mélòó mélòó ni yóò wọ̀ yín láṣọ, ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré. 29 Kí ẹ má sì ṣe lé ohun tí ẹ ó jẹ, tàbí ohun tí ẹ ó mu, kí ẹ má sì ṣe ṣe àníyàn nínú ọkàn. 30 (O)Nítorí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè ayé ń wá kiri: Baba yín sì mọ̀ pé, ẹ̀yin ń fẹ́ nǹkan wọ̀nyí. 31 Ṣùgbọ́n ẹ máa wá ìjọba Ọlọ́run, gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.