M’Cheyne Bible Reading Plan
Gideoni
6 Àwọn ọmọ Israẹli sì túnṣe ohun tí ó burú ní ojú Olúwa, Ó sì fi wọ́n lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́ fún ọdún méje. 2 Agbára àwọn ará Midiani sì pọ̀ púpọ̀ lórí àwọn Israẹli, wọ́n sì hùwà ipá sí wọn, nítorí ìdí èyí, àwọn Israẹli sálọ sí àwọn orí òkè, wọ́n sì kọ́ àgọ́ fún ara wọn nínú ihò àpáta, àti nínú ọ̀gbun àti ní ibi agbára nínú àpáta. 3 Ní ìgbàkúgbà tí àwọn ọmọ Israẹli bá ti gbin ọ̀gbìn wọn, àwọn ará Midiani, àwọn ará Amaleki àti àwọn ará ìlà-oòrùn mìíràn yóò wá láti bá wọn jà. 4 Wọn yóò tẹ̀dó sí orí ilẹ̀ náà, wọn a sì bá irúgbìn wọ̀nyí jẹ́ títí dé Gasa, wọn kì í sì í fi ohun alààyè kankan sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli, kì bá à ṣe àgùntàn, màlúù tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́. 5 Wọn a máa wá pẹ̀lú ohun ọ̀sìn wọn àti àwọn àgọ́ wọn, wọn a sì dàbí eṣú nítorí i púpọ̀ wọn. Ènìyàn kò sì lè ka iye àwọn ènìyàn náà bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìbákasẹ, wọ́n pọ̀ dé bi pé wọn kò ṣe é kà ní iye, wọn a bo ilẹ̀ náà wọn a sì jẹ ẹ́ run. 6 Àwọn ará Midiani sì pọ́n àwọn ọmọ Israẹli lójú, wọ́n sọ wọ́n di òtòṣì àti aláìní, fún ìdí èyí wọ́n ké pe Olúwa nínú àdúrà fún ìrànlọ́wọ́.
7 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli ké pe Olúwa nítorí àwọn ará Midiani. 8 Olúwa fi etí sí igbe wọn, ó sì rán wòlíì kan sí wọn, ẹni tí ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli wí: mo mú yín gòkè ti Ejibiti wá, láti oko ẹrú. 9 Mo gbà yín kúrò nínú agbára Ejibiti àti kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn aninilára yín. Mo lé wọn kúrò ní iwájú yín, mo sì fi ilẹ̀ wọn fún yín. 10 Mo wí fún un yín pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín: ẹ má ṣe sin àwọn òrìṣà àwọn ará Amori, ní ilẹ̀ ẹni tí ẹ̀yin ń gbé. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́rọ̀ sí ohun tí mo sọ.”
11 Ní ọjọ́ kan angẹli Olúwa wá, ó sì jókòó ní abẹ́ igi óákù ofira èyí ti ṣe ti Joaṣi ará Abieseri, níbi tí Gideoni ọmọ rẹ̀ ti ń lu ọkà jéró, níbi ìpọntí wáìnì láti fi pamọ́ kúrò níwájú àwọn ará Midiani. 12 Nígbà tí angẹli Olúwa fi ara han Gideoni, ó wí fún un pé, “Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, akọni ológun.”
13 Gideoni dáhùn pé, “Alàgbà, bí Olúwa bá wà pẹ̀lú wa, kí ló dé tí gbogbo ìwọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ sí wa? Níbi gbogbo àwọn iṣẹ́ ìyanu rẹ tí àwọn baba wa ròyìn rẹ̀ fún wa nígbà tí wọ́n wí pé, ‘Olúwa kò ha mú wa gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá?’ Ṣùgbọ́n nísinsin yìí Olúwa ti kọ̀ wá sílẹ̀, ó sì ti fi wá lé àwọn ará Midiani lọ́wọ́.”
14 Olúwa sì yípadà sí i, ó sì wí fún un pé, “Lọ nínú agbára tí o ní yìí, kí o sì gba àwọn ará Israẹli sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Midiani. Èmi ni ó ń rán ọ lọ.”
15 Gideoni sì dáhùn pé, “Yéè olúwa mi, ọ̀nà wo ni èmi yóò fi gba Israẹli là? Ìdílé mi ni ó jẹ́ aláìlera jù ní Manase, àti pé èmi ni ó sì kéré jù ní ìdílé baba mi.”
16 Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ, ìwọ yóò sì pa gbogbo àwọn ará Midiani láì ku ẹnìkankan.”
17 Gideoni sì dáhùn pé, nísinsin yìí tí mo bá bá ojúrere rẹ pàdé, fún mi ní ààmì pé ìwọ ni ń bá mi sọ̀rọ̀. 18 Jọ̀wọ́ má ṣe kúrò níbí títí èmi yóò fi mú ọrẹ wá fún ọ kí n sì gbé e sí iwájú rẹ.
Olúwa sì wí pé, “Èmi yóò dúró títí ìwọ yóò fi dé.”
19 Gideoni sì yára wọ ilé lọ, ó sì pa ọ̀dọ́ ewúrẹ́ kan, wọ́n sì sè é, ó sì mú ìyẹ̀fun efa kan, ó fi ṣe àkàrà aláìwú. Ó gbé ẹran náà sínú agbọ̀n, ṣùgbọ́n ó fi ọbẹ̀ rẹ̀ sínú ìkòkò, ó gbé wọn jáde tọ angẹli náà wá bí ọrẹ lábẹ́ igi óákù.
20 Angẹli Ọlọ́run náà sì wí fún un pé, “Gbé ẹran náà àti àkàrà àìwú náà, sí orí àpáta yìí, kí o sì da omi ọbẹ̀ rẹ̀ sí orí rẹ̀.” Gideoni sì ṣe bẹ́ẹ̀. 21 Angẹli Olúwa sì fi orí ọ̀pá tí ó wà ní ọwọ́ rẹ̀ kan ẹran àti àkàrà àìwú náà. Iná sì jáde láti inú àpáta, ó sì jó ẹran àti àkàrà náà, kò sì rí angẹli náà mọ́. 22 Nígbà tí Gideoni sì ti mọ̀ dájúdájú pé angẹli Olúwa ni, ó ké wí pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè! Mo ti rí angẹli Olúwa ní ojúkorojú!”
23 Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Àlàáfíà! Má ṣe bẹ̀rù, ìwọ kì yóò kùú.”
24 Báyìí ni Gideoni mọ pẹpẹ kan fún Olúwa níbẹ̀, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní “Àlàáfíà ni Olúwa.” Ó sì wà ní Ofira ti Abieseri títí di òní.
25 Ní òru ọjọ́ náà Olúwa wí fún un pé, mú akọ màlúù baba rẹ, àní akọ màlúù kejì ọlọ́dún méje. Wó pẹpẹ Baali baba rẹ lulẹ̀, kí o sì bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ lulẹ̀. 26 Lẹ́yìn èyí kí o wá mọ pẹpẹ èyí tí ó yẹ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ lórí òkè yìí. Kí o sì mú akọ màlúù kejì, kí o sì mú igi ère òrìṣà Aṣerah tí ìwọ bẹ́ lulẹ̀ rú ẹbọ sísun sí Olúwa.
27 Gideoni mú mẹ́wàá nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún un ṣùgbọ́n, nítorí ó bẹ̀rù àwọn ará ilé baba rẹ̀ àti àwọn ènìyàn ìlú náà kò ṣe é ní ọ̀sán, òru ni ó ṣe.
28 Nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ kejì mọ́, tí àwọn ènìyàn ìlú náà jí, wọ́n rí i pé àti fọ́ pẹpẹ Baali àti pé a ti bẹ́ igi ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, a sì ti fi akọ màlúù kejì rú ẹbọ lórí pẹpẹ tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ.
29 Àwọn ènìyàn ìlú náà bi ara wọn wí pé, “Ta ni ó ṣe èyí?”
Lẹ́yìn tí wọn fi ara balẹ̀ ṣe ìwádìí, wọ́n gbọ́ wí pé, “Gideoni ọmọ Joaṣi ni ó ṣe é.”
30 Àwọn ọkùnrin ìlú náà sì wí fún Joaṣi wí pé, “Mú ọmọ rẹ jáde wá. Ó ní láti kú nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali lulẹ̀ ó sì ti ké ère òrìṣà Aṣerah tí ó wà ní ẹ̀bá rẹ̀ lulẹ̀.”
31 Ṣùgbọ́n Joaṣi bi àwọn èrò tí wọ́n fi ìbínú dúró tì í wí pé, “Ẹ̀yin yóò ha gbìjà Baali bí? Ẹ̀yin yóò ha gbà á sílẹ̀ bí? Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbìjà rẹ̀ kíkú ni olúwa rẹ̀ yóò kú ní òwúrọ̀. Bí Baali bá ṣe Ọlọ́run nítòótọ́ yóò jà fún ara rẹ̀ bí ẹnikẹ́ni bá wó pẹpẹ rẹ̀ lulẹ̀.” 32 Fún ìdí èyí ní ọjọ́ náà wọ́n pe Gideoni ní “Jerubbaali” wí pé, “Jẹ́ kí Baali bá a jà,” nítorí pé ó ti wó pẹpẹ Baali.
33 Láìpẹ́ jọjọ, àwọn ogun àwọn Midiani, ti àwọn Amaleki àti ti àwọn ènìyàn ìhà ìlà-oòrùn yòókù kó ara wọn jọ pọ̀ ní ìṣọ̀kan, wọ́n sì kọjá Jordani wọ́n sì tẹ̀dó sí Àfonífojì Jesreeli. 34 Ẹ̀mí Olúwa sì bà lé Gideoni, ó sì fun fèrè ìpè, láti pe àwọn ará Abieseri láti tẹ̀lé òun. 35 Ó rán àwọn oníṣẹ́ la ilẹ̀ Manase já pé kí wọ́n dira ogun, àti sí Aṣeri, Sebuluni àti Naftali gbogbo pẹ̀lú sì lọ láti pàdé wọn.
36 Gideoni wí fún Ọlọ́run pé, “Bí ìwọ yóò bá gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti ṣe ìlérí— 37 kíyèsi, èmi yóò fi awọ irun àgùntàn lé ilẹ̀ ìpakà ní alẹ́ òní. Bí ìrì bá sẹ̀ sí orí awọ yìí nìkan tí gbogbo ilẹ̀ yòókù sì gbẹ, nígbà náà ni èmi yóò mọ̀ lóòótọ́ pé ìwọ yóò gba Israẹli là nípasẹ̀ mi bí ìwọ ti sọ.” 38 Èyí ni ó sì ṣẹlẹ̀. Nígbà tí Gideoni jí ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì fún irun àgùntàn náà, ọpọ́n omi kan sì kún.
39 Gideoni sì tún wí fún Ọlọ́run pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú sí mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí n tún wá ìdánilójú kan sí i, èmi bẹ̀ ọ́ jẹ́ kí n fi awọ irun yìí ṣe ìdánwò kan sí i. Ní àsìkò yìí, jẹ́ kí awọ irun yìí gbẹ kí gbogbo ilẹ̀ sì tutù pẹ̀lú ìrì.” 40 Ní òru náà Ọlọ́run ṣe bẹ́ẹ̀, awọ irun àgùntàn nìkan ni ó gbẹ; gbogbo ilẹ̀ yòókù sì tutù nítorí ìrì.
Àwọn ìpè Korneliu fún Peteru
10 (A)Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. 2 Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. 3 Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!”
4 Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?”
Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. 5 Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru. 6 Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.”
7 Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo. 8 Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa.
Ìran Peteru
9 Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́: 10 Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran. 11 Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀: 12 Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run. 13 Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.”
14 Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”
15 Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.”
16 Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run.
Korneliu ránṣẹ́ sí Peteru
17 Bí Peteru sì ti ń dààmú nínú ara rẹ̀ bí òun bá ti mọ̀ ìran tí òun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Korneliu dé. Wọ́n ń béèrè ilé Simoni, wọ́n dúró ní ẹnu-ọ̀nà. 18 Wọn nahùn béèrè bí Simoni tí a ń pè ní Peteru, wọ̀ níbẹ̀.
19 Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ. 20 Ǹjẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kó ara ró láti bá wọn lọ: nítorí èmi ni ó rán wọn.”
21 Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí rẹ̀ ti ẹ fi wá?”
22 Wọ́n sì wí pé, “Korneliu balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtítọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ angẹli mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” 23 Nígbà náà ni Peteru pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò.
Peteru ní ilé Korneliu
Ní ọjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, díẹ̀ nínú àwọn ti o ti gbàgbọ́ ní Joppa sì bá a lọ pẹ̀lú. 24 Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesarea, Korneliu sì ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. 25 Ó sì ṣe bí Peteru ti ń wọlé, Korneliu pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un. 26 Ṣùgbọ́n Peteru gbé e dìde, ó ni, “Dìde ènìyàn ni èmi tìkára mi pẹ̀lú.”
27 Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ. 28 Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́. 29 Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo béèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”
30 Korneliu sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹsànán ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi. 31 Ó sì wí pé, ‘Korneliu, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run. 32 Ǹjẹ́ ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru; ó wọ̀ ní ilé Simoni aláwọ létí Òkun.’ 33 Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsin yìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.”
34 Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. 35 Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀. 36 Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo 37 Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Judea, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Galili, lẹ́yìn bamitiisi ti Johanu wàásù rẹ̀. 38 Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
39 “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 40 Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. 41 Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú. 42 Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú. 43 Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”
44 Bí Peteru sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. 45 Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti a ti kọ nílà tí wọ́n bá Peteru wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú. 46 Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo.
Nígbà náà ni Peteru dáhùn wí pé, 47 “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin pe, kí a má bamitiisi àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?” 48 Ó sì pàṣẹ kí a bamitiisi wọn ni orúkọ Jesu Kristi. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ọjọ́ mélòó kan.
19 Èyí ní ohun tí Olúwa wí: “Lọ ra ìkòkò lọ́dọ̀ alámọ̀, mú dání lára àwọn àgbàgbà ọkùnrin àti wòlíì. 2 Kí o sì lọ sí Àfonífojì ọmọ Beni-Hinnomu, níwájú ẹnu ibodè Harsiti, níbẹ̀ ni kí o sì kéde gbogbo ọ̀rọ̀ tí èmi yóò sọ fún ọ. 3 Kí o sì wí pé ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọba àwọn Juda àti ẹ̀yin ará Jerusalẹmu. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya. 4 Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjèjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí ọba Juda kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kún ilẹ̀ yìí. 5 Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Baali láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sísun sí Baali—èyí tí èmi kò pàṣẹ láti ṣe, tí èmi kò sì sọ, tàbí tí kò sì ru sókè láti inú ọkàn mi. 6 Nítorí náà ṣọ́ra ọjọ́ ń bọ̀ ni Olúwa wí nígbà tí àwọn ènìyàn kì yóò pe ibí ní Tofeti mọ́ tàbí Àfonífojì ọmọ Hinnomu, ṣùgbọ́n Àfonífojì Ìpakúpa.
7 “ ‘Ní ibí yìí ni èmi yóò ti pa èrò Juda àti Jerusalẹmu run. Èmí yóò mú wọn ṣubú nípa idà níwájú àwọn ọ̀tá wọn, lọ́wọ́ àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn. Èmi yóò sì fi òkú wọn ṣe oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀. 8 Èmi yóò sọ ìlú yìí di ahoro àti ohun ẹ̀gàn, gbogbo àwọn tí ń kọjá yóò bẹ̀rù wọn yóò sì máa fòyà nítorí gbogbo ọgbẹ́ rẹ̀. 9 Èmi yóò mú kí wọ́n jẹ ẹran-ara ọmọ wọn ọkùnrin àti ẹran-ara ọmọ wọn obìnrin, ẹnìkínní yóò sì jẹ ẹran-ara ẹnìkejì, nígbà ìdótì àti ìhámọ́ láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, àti àwọn tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’
10 “Nígbà náà ni ìwọ yóò fọ́ ìkòkò náà ní ojú àwọn tí ó bá ọ lọ. 11 Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀-èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tofeti títí tí kò fi ní sí ààyè mọ́. 12 Èyí ni ohun tí èmi yóò ṣe sí ibí yìí àti àwọn tí ń gbé ní ibí yìí ni Olúwa wí. Èmi yóò mú ìlú yìí dàbí Tofeti. 13 (A)Àwọn ilé tí ó wà ní Jerusalẹmu àti ti ọba ìlú Juda ni a ó sọ di àìmọ́ bí Tofeti, gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí òrùlé sí gbogbo ogun ọ̀run, tí a sì ń rú ẹbọ mímu sí ọlọ́run mìíràn.’ ”
14 Jeremiah sì padà láti Tofeti níbi tí Olúwa rán an sí láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ ó sì dúró ní gbangba tẹmpili Olúwa, ó sì sọ fún gbogbo ènìyàn pé, 15 “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbèríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”
Ìwòsàn ọkùnrin ẹlẹ́mìí èṣù
5 (A)Wọ́n lọ sí apá kejì adágún ní ẹ̀bá ilẹ̀ àwọn ará Gadara. 2 Bí Jesu sì ti ń ti inú ọkọ̀ ojú omi jáde. Ọkùnrin kan tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́ jáde ti ibojì wá pàdé rẹ̀. 3 Ọkùnrin yìí ń gbé nínú ibojì, kò sí ẹni tí ó lè dè é mọ́, kódà ẹ̀wọ̀n kò le dè é. 4 Nítorí pé nígbà púpọ̀ ni wọ́n ti ń fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ dè é lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀, tí ó sì ń já a dànù kúrò ni ẹsẹ̀ rẹ̀. Kò sí ẹnìkan tí ó ní agbára láti káwọ́ rẹ̀. 5 Tọ̀sán tòru láàrín àwọn ibojì àti ní àwọn òkè ni ó máa ń kígbe rara tí ó sì ń fi òkúta ya ara rẹ̀.
6 Nígbà tí ó sì rí Jesu látòkèrè, ó sì sáré lọ láti pàdé rẹ̀. Ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 7 (B)Ó sì kígbe ní ohùn rara wí pé, “Kí ní ṣe tèmi tìrẹ, Jesu Ọmọ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo? Mo fi Ọlọ́run bẹ̀ ọ́ má ṣe dá mi lóró.” 8 Nítorí tí Ó wí fún un pé, “Jáde kúrò lára ọkùnrin náà, ìwọ ẹ̀mí àìmọ́!”
9 Jesu sì bi í léèrè pé, “Kí ni orúkọ rẹ?”
Ẹ̀mí àìmọ́ náà sì dáhùn wí pé, “Ligioni, nítorí àwa pọ̀.” 10 Nígbà náà ni ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ Jesu gidigidi, kí ó má ṣe rán àwọn jáde kúrò ní agbègbè náà.
11 Agbo ẹlẹ́dẹ̀ ńlá kan sì ń jẹ lẹ́bàá òkè. 12 Àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà bẹ Jesu pé, “Rán wa lọ sínú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ wọ̀n-ọn-nì kí àwa le è wọ inú wọn lọ.” 13 Jesu fún wọn láààyè, àwọn ẹ̀mí àìmọ́ náà sì jáde kúrò lára ọkùnrin náà, wọ́n sì wọ inú àwọn ẹlẹ́dẹ̀ náà lọ. Agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà tí ó tó ìwọ̀n ẹgbàá sì túká lọ́gán, wọ́n sì sáré lọ ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè rọ́ sínú Òkun, wọ́n sì ṣègbé.
14 Àwọn olùtọ́jú ẹran wọ̀nyí sì sálọ sí àwọn ìlú ńlá àti ìlú kéékèèkéé, wọ́n sì ń tan ìròyìn náà ká bí wọ́n ti ń sáré. Àwọn ènìyàn sì tú jáde láti fojú gán-án-ní ohun náà tí ó ṣẹlẹ̀. 15 Nígbà tí wọ́n péjọ sọ́dọ̀ Jesu, wọ́n rí ọkùnrin náà, ẹni tí ó ní ẹ̀mí èṣù, tí ó jókòó níbẹ̀, ó wọ aṣọ ìyè rẹ sì bọ̀ sípò, ẹ̀rù sì bà wọ́n. 16 Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣojú wọn sì ń ròyìn rẹ̀ fún àwọn ènìyàn ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin ẹlẹ́mìí àìmọ́, wọ́n si sọ nípa agbo ẹlẹ́dẹ̀ náà pẹ̀lú. 17 Nígbà náà, àwọn èrò bẹ̀rẹ̀ sí ní bẹ Jesu pé kí ó fi agbègbè àwọn sílẹ̀.
18 Bí Jesu ti ń wọ inú ọkọ̀ ojú omi lọ, ọkùnrin náà tí ó ti ní ẹ̀mí àìmọ́ tẹ́lẹ̀ bẹ̀ Ẹ́ pé kí òun lè bá a lọ. 19 Jesu kò gbà fún un, ṣùgbọ́n ó wí fún un pé, “Lọ sí ilé sí ọ̀dọ̀ àwọn ẹbí rẹ, kí o sì sọ fún wọn bí Ọlọ́run ti ṣe ohun ńlá fún ọ, àti bí ó sì ti ṣàánú fún ọ.” 20 (C)Nítorí naà, ọkùnrin yìí padà lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ròyìn ní Dekapoli nípa ohun ńlá tí Jesu ṣe fún un. Ẹnu sì ya gbogbo ènìyàn.
Òkú ọmọbìnrin kan àti obìnrin aláìsàn
21 (D)Nígbà tí Jesu sì ti inú ọkọ̀ rékọjá sí apá kejì Òkun, ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn péjọ yí i ká ní etí Òkun. 22 (E)Ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu tí à ń pè ni Jairu wá sọ́dọ̀ Jesu, nígbà tí ó sì rí i, ó wólẹ̀ níwájú rẹ̀. 23 (F)Ó sì bẹ̀ ẹ́ gidigidi pé, “Ọmọbìnrin mi wà lójú ikú, mo bẹ̀ ọ́, wá fi ọwọ́ rẹ lé e, kí ara rẹ̀ lè dá, kí ó sì yè.” 24 Jesu sì ń bá a lọ.
Ọ̀pọ̀ ìjọ ènìyàn sì ń tọ̀ Ọ́ lẹ́yìn. 25 Obìnrin kan sì wà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn náà, tí ó ti ní ìsun ẹ̀jẹ̀ fún odidi ọdún méjìlá. 26 Ẹni tí ojú rẹ̀ sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú lọ́dọ̀ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣègùn, tí ó sì ti ná gbogbo ohun tí ó ní, síbẹ̀ kàkà kí ó san, ó ń burú sí i. 27 Nígbà tí ó sì gbúròó iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe, ìdí nìyìí tí ó fi wá sẹ́yìn rẹ̀, láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì fọwọ́ kan aṣọ rẹ̀. 28 Nítorí ti ó rò ní ọkàn rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à lè fi ọwọ́ kan aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.” 29 Ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì gbẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, òun sì mọ̀ lára rẹ̀ pé, a mú òun láradá kúrò nínú ààrùn náà.
30 (G)Lọ́gán, Jesu sì mọ̀ nínú ara rẹ̀ pé agbára jáde lára òun. Ó yípadà láàrín ọ̀pọ̀ ènìyàn, ó sì béèrè, “Ta ni ó fi ọwọ́ kan aṣọ mi?”
31 Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé, “Ìwọ rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó rọ̀gbà yí ọ ká, ìwọ sì tún ń béèrè ẹni tí ó fi ọwọ́ kàn ọ́?”
32 Síbẹ̀, Jesu bẹ̀rẹ̀ sí wò yíká láti rí ẹni náà, tí ó fi ọwọ́ kan òun. 33 Nígbà náà, obìnrin náà kún fún ìbẹ̀rù àti ìwárìrì nítorí ó ti mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ lára òun. Ó sì kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ gbogbo òtítọ́ fún un. 34 (H)Jesu sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá: Máa lọ ní àlàáfíà, ìwọ sì ti sàn nínú ààrùn rẹ.”
35 Bí Jesu sì ti ń ba obìnrin náà sọ̀rọ̀, àwọn ìránṣẹ́ dé láti ilé Jairu olórí Sinagọgu wá, wọ́n wí fún un pé, ọmọbìnrin rẹ ti kú, àti pé kí wọn má ṣe yọ Jesu lẹ́nu láti wá, nítorí ó ti pẹ́ jù.
36 Ṣùgbọ́n bi Jesu ti gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ó wí fún Jairu pé, “Má bẹ̀rù, sá à gbàgbọ́ nìkan.”
37 (I)Nígbà náà, Jesu dá ọ̀pọ̀ ènìyàn náà dúró. Kò sì jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tẹ̀lé òun lẹ́yìn lọ ilé Jairu, bí kò ṣe Peteru, Jakọbu àti Johanu arákùnrin Jakọbu. 38 Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, Jesu rí i pé gbogbo nǹkan ti dàrú. Ilé kún fún àwọn tí ń sọkún, àti àwọn tí ń pohùnréré ẹkún. 39 Ó wọ inú ilé lọ, o sì bá àwọn ènìyàn sọ̀rọ̀, ó béèrè pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń sọkún tí ẹ sì ń pohùnréré ẹkún? Ọmọbìnrin náà kò kú, ó sùn lásán ni.” 40 Wọ́n sì fi í rẹ́rìn-ín.
Ṣùgbọ́n ó sọ fún gbogbo wọn láti bọ́ síta, ó mú baba àti ìyá ọmọ náà, àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ mẹ́ta. Ó sì wọ inú yàrá tí ọmọbìnrin náà gbé dùbúlẹ̀ sí. 41 (J)Ó gbá a ní ọwọ́ mú, ó sì wí pé, “Talita kuumi” (tí ó túmọ̀ sí, ọmọdébìnrin, dìde dúró). 42 Lẹ́sẹ̀kan náà, ọmọbìnrin náà sì dìde. Ó sì ń rìn, ẹ̀rù sì bà wọ́n, ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀ gidigidi. 43 (K)Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé kí wọn má ṣe sọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀. Ó sì wí fún wọn kí wọn fún ọmọbìnrin náà ní oúnjẹ.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.