M’Cheyne Bible Reading Plan
Orúkọ àwọn ọba tí a ṣẹ́gun
12 (A)Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé Òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:
2 Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni.
Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín Àfonífojì náà dé Odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.
3 Ó sì ṣe àkóso ní orí ìlà-oòrùn aginjù láti Òkun Kinnereti sí ìhà Òkun ti aginjù (Òkun Iyọ̀), sí Beti-Jeṣimoti, àti láti gúúsù lọ dé ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè Pisga.
4 Àti agbègbè Ogu ọba Baṣani, ọ̀kan nínú àwọn tí ó kù nínú àwọn ará Refaimu, ẹni tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei.
5 Ó ṣe àkóso ní orí Òkè Hermoni, Saleka, Baṣani títí dé ààlà àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, àti ìdajì Gileadi dé ààlà Sihoni ọba Heṣboni.
6 Mose ìránṣẹ́ Olúwa àti àwọn ọmọ Israẹli sì borí wọn. Mose ìránṣẹ́ Olúwa sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Reubeni, àwọn ẹ̀yà Gadi àti ìdajì ẹ̀yà Manase kí ó jẹ́ ohun ìní wọn.
7 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí Joṣua àti àwọn ọmọ Israẹli ṣẹ́gun ní ìhà ìwọ̀-oòrùn Jordani, láti Baali-Gadi ní Àfonífojì Lebanoni sí Òkè Halaki, èyí tí O lọ sí ọ̀nà Seiri (Joṣua sì fi ilẹ̀ wọn fún àwọn ẹ̀yà Israẹli ní ilẹ̀ ìní gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn: 8 ilẹ̀ òkè, ní ẹsẹ̀ òkè ní ìhà ìwọ̀-oòrùn òkè aginjù, ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè, ní aginjù àti nì gúúsù ilẹ̀ àwọn ará: Hiti, Amori, Kenaani, Peresi, Hifi àti àwọn ará Jebusi):
9 Ọba Jeriko ọ̀kan
Ọba Ai (tí ó wà nítòsí Beteli) ọ̀kan
10 Ọba Jerusalẹmu ọ̀kan
ọba Hebroni ọ̀kan
11 Ọba Jarmatu ọ̀kan
ọba Lakiṣi ọ̀kan
12 Ọba Egloni ọ̀kan
ọba Geseri ọ̀kan
13 Ọba Debiri ọ̀kan
ọba Gederi ọ̀kan
14 Ọba Horma ọ̀kan
ọba Aradi ọ̀kan
15 Ọba Libina ọ̀kan
ọba Adullamu ọ̀kan
16 Ọba Makkeda ọ̀kan
ọba Beteli ọ̀kan
17 Ọba Tapua ọ̀kan
ọba Heferi ọ̀kan
18 Ọba Afeki ọ̀kan
ọba Laṣaroni ọ̀kan
19 Ọba Madoni ọ̀kan
ọba Hasori ọ̀kan
20 Ọba Ṣimroni-Meroni ọ̀kan
ọba Akṣafu ọ̀kan
21 Ọba Taanaki ọ̀kan
ọba Megido ọ̀kan
22 Ọba Kedeṣi ọ̀kan
ọba Jokneamu ni Karmeli ọ̀kan
23 Ọba Dori (ní Nafoti Dori) ọ̀kan
ọba Goyimu ní Gilgali ọ̀kan
24 Ọba Tirsa ọ̀kan
gbogbo àwọn ọba náà jẹ́ mọ́kànlélọ́gbọ̀n.
Ilẹ̀ tí ó kù láti gbà
13 Nígbà tí Joṣua sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.
2 “Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù:
“gbogbo àwọn agbègbè àwọn Filistini, àti ti ara Geṣuri: 3 láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni;
ti àwọn ará Affimu); 4 láti gúúsù;
gbogbo ilẹ̀ àwọn ará Kenaani, láti Arah ti àwọn ará Sidoni títí ó fi dé Afeki, agbègbè àwọn ará Amori;
5 Àti ilẹ̀ àwọn ará Gebali;
àti gbogbo àwọn Lebanoni dé ìlà-oòrùn, láti Baali-Gadi ní ìsàlẹ̀ Òkè Hermoni dé Lebo-Hamati.
6 “Ní ti gbogbo àwọn olùgbé agbègbè òkè, láti Lebanoni sí Misrefoti-Maimu, àní, gbogbo àwọn ará Sidoni, èmi fúnra mi ní yóò lé wọn jáde ní iwájú àwọn ará Israẹli. Kí o ri dájú pé o pín ilẹ̀ yí fún Israẹli ní ilẹ̀ ìní, gẹ́gẹ́ bí mo ṣe fi àṣẹ fún ọ, 7 pín ilẹ̀ yìí ní ilẹ̀ ìní fún àwọn ẹ̀yà mẹ́sàn-án àti ìdajì ẹ̀yà Manase.”
Pínpín ilẹ̀ ìhà ìlà-oòrùn Jordani
8 Àwọn ìdajì ẹ̀yà Manase tí ó kù, àti àwọn Reubeni àti àwọn Gadi ti gba ilẹ̀ ìní, tí Mose ti fún wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani bí Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.
9 Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí Àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín Àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni. 10 Gbogbo ìlú Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó ṣe àkóso ní Heṣboni, títí dé ààlà àwọn ará Ammoni.
11 Àti Gileadi, ní agbègbè àwọn ènìyàn Geṣuri àti Maakati, gbogbo Òkè Hermoni àti gbogbo Baṣani títí dé Saleka, 12 Ìyẹn, gbogbo ilẹ̀ ọba Ogu ní Baṣani, tí ó jẹ ọba ní Aṣtarotu àti Edrei, ẹni tí ó kù nínú àwọn Refaimu ìyókù. Mose ti ṣẹ́gun wọn, ó sì ti gba ilẹ̀ wọn. 13 Ṣùgbọ́n àwọn ará Israẹli kò lé àwọn ará Geṣuri àti Maakati jáde, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń gbé ní àárín àwọn ará Israẹli títí di òní yìí.
14 Ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Lefi ni kò fi ogún kankan fún, níwọ̀n ìgbà tí ó ti jẹ́ pé ọrẹ àfinásun sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ni ogún tiwọn, gẹ́gẹ́ bí o ti ṣèlérí fún wọn.
15 Èyí ni Mose fi fún ẹ̀yà Reubeni ni agbo ilé sí agbo ilé:
16 Láti agbègbè Aroeri ní etí Arnoni Jọ́ọ́jì àti láti ìlú tí ń bẹ láàrín Jọ́ọ́jì, àti gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ ní ìkọjá Medeba 17 sí Heṣboni àti gbogbo ìlú rẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, pẹ̀lú Diboni, Bamoti Baali, Beti-Baali-Mioni, 18 Jahisa, Kedemoti, Mefaati, 19 Kiriataimu, Sibma, Sereti Ṣahari lórí òkè ní àfonífojì. 20 Beti-Peori, gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Pisga, àti Beti-Jeṣimoti 21 gbogbo ìlú tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ àti gbogbo agbègbè Sihoni ọba Amori, tí ó ṣe àkóso Heṣboni. Mose sì ti ṣẹ́gun rẹ̀ àti àwọn ọmọ ìjòyè Midiani, Efi, Rekemu, Suri, Huri àti Reba, àwọn ọmọ ọba pawọ́pọ̀ pẹ̀lú Sihoni tí ó gbé ilẹ̀ náà. 22 Ní àfikún àwọn tí a pa ní ogun, àwọn ọmọ Israẹli fi idà pa Balaamu ọmọ Beori alásọtẹ́lẹ̀.
23 Ààlà àwọn ọmọ Reubeni ni etí odò Jordani. Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ ni ilẹ̀ ìní àwọn ọmọ Reubeni ní agbo ilé ní agbo ilé.
24 Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ẹ̀yà Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé:
25 Agbègbè ìlú Jaseri, gbogbo ìlú Gileadi àti ìdajì orílẹ̀-èdè àwọn ọmọ ará Ammoni títí dé Aroeri, ní ẹ̀bá Rabba; 26 àti láti Heṣboni lọ sí Ramati-Mispa àti Betonimu, àti láti Mahanaimu sí agbègbè ìlú Debiri, 27 àti ní Àfonífojì Beti-Haramu, Beti-Nimra, Sukkoti àti Safoni pẹ̀lú ìyókù agbègbè ilẹ̀ Sihoni ọba Heṣboni (ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani, agbègbè rẹ̀ títí dé òpin Òkun Kinnereti).
28 Àwọn ìlú wọ̀nyí àti abúlé rẹ̀ jẹ́ ogún àwọn ọmọ Gadi, ní agbo ilé ní agbo ilé.
29 Èyí ni ohun tí Mose ti fi fún ìdajì ẹ̀yà Manase, èyí ni pé, fún ìdajì ìdílé irú-ọmọ Manase, ní agbo ilé ní agbo ilé:
30 Ilẹ̀ náà fẹ̀ dé Mahanaimu àti gbogbo Baṣani, gbogbo agbègbè ilẹ̀ Ogu ọba Baṣani, èyí tí í ṣe ibùgbé Jairi ní Baṣani, ọgọ́ta ìlú, 31 ìdajì Gileadi, àti Aṣtarotu àti Edrei (àwọn ìlú ọba Ogu ní Baṣani).
Èyí ni fún irú àwọn ọmọ Makiri ọmọ Manase fún ààbọ̀ àwọn ọmọ Makiri, ní agbo ilé ní agbo ilé.
32 Èyí ni ogún tí Mose fi fún wọn nígbà tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu ní ìhà kejì Jordani ní ìlà-oòrùn Jeriko. 33 Ṣùgbọ́n fún ẹ̀yà Lefi, Mose kò fi ogún fún un; Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, ní ogún wọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.
Saamu ìyìn. Ti Dafidi.
145 Èmi yóò gbé ọ ga, Ọlọ́run ọba mi;
Èmi yóò yin orúkọ rẹ̀ láé àti láéláé
2 Ní ojoojúmọ́ èmi yóò yìn ọ́
èmi yóò sì pòkìkí orúkọ rẹ láé àti láéláé.
3 Títóbi ni Olúwa. Òun sì ni ó yẹ láti fi ìyìn fún púpọ̀púpọ̀:
kò sí ẹni tí ó lè wọn títóbi rẹ̀.
4 Ìran kan yóò máa yin iṣẹ́ rẹ dé ìran mìíràn;
wọn yóò máa sọ iṣẹ́ agbára rẹ
5 Wọn yóò máa sọ ìyìn ọláńlá rẹ tí ó lógo,
èmi yóò máa ṣe àṣàrò nínú iṣẹ́ ìyanu rẹ.
6 Wọn yóò sọ iṣẹ́ agbára rẹ tí ó ní ẹ̀rù
èmi yóò kéde iṣẹ́ ńlá rẹ̀.
7 Wọn yóò ṣe ìrántí ọ̀pọ̀lọpọ̀
ìwà rere rẹ àti orin ayọ̀ òdodo rẹ.
8 Olóore-ọ̀fẹ́ ni Olúwa àti aláàánú
ó lọ́ra láti bínú ó sì ní ìfẹ́ púpọ̀.
9 Olúwa dára sí ẹni gbogbo;
ó ní àánú lórí ohun gbogbo tí ó dá.
10 Gbogbo ohun tí ìwọ ti dá ni
yóò máa yìn ọ́ Olúwa;
àwọn ẹni mímọ́ yóò máa pòkìkí rẹ.
11 Wọn yóò sọ ògo ìjọba rẹ
wọn yóò sì sọ̀rọ̀ agbára rẹ,
12 Kí gbogbo ènìyàn le mọ iṣẹ́ agbára rẹ̀
àti ọláńlá ìjọba rẹ tí ó lógo.
13 Ìjọba rẹ ìjọba ayérayé ni,
àti ìjọba rẹ wà ní gbogbo ìrandíran.
14 Olúwa mú gbogbo àwọn tí ó ṣubú ró
ó sì gbé gbogbo àwọn tí ó tẹríba dìde.
15 Ojú gbogbo ènìyàn ń wò ọ́,
ó sì fún wọn ní oúnjẹ wọn ní àkókò tí ó yẹ
16 Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ
ìwọ sì tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.
17 Olúwa jẹ́ olódodo ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀
àti ìfẹ́ rẹ̀ sí gbogbo ohun tí o dá.
18 Olúwa wà ní tòsí gbogbo àwọn tí ń ké pè é,
sí gbogbo ẹni tí ń ké pè é ní òtítọ́.
19 Ó mú ìfẹ́ àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ṣẹ;
ó gbọ́ igbe wọn, ó sì gbà wọ́n.
20 Olúwa dá gbogbo àwọn tí ó ní ìfẹ́ sẹ sí
ṣùgbọ́n gbogbo àwọn ẹni
búburú ní yóò parun.
21 Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ìyìn Olúwa.
Jẹ́ kí gbogbo ẹ̀dá yín orúkọ rẹ̀ mímọ́ láé àti láéláé.
Jerusalẹmu lábẹ́ ìgbèkùn
6 “Ẹ̀yin ènìyàn Benjamini, sá sí ibi ààbò!
Ẹ sá kúrò ní Jerusalẹmu,
Ẹ fọn fèrè ní Tekoa!
Kí ẹ gbé ààmì sókè lórí Beti-Hakeremu!
Nítorí àjálù farahàn láti àríwá,
àní ìparun tí ó lágbára.
2 Èmi yóò pa ọmọbìnrin Sioni run,
tí ó jẹ́ arẹwà àti ẹlẹgẹ́.
3 Olùṣọ́-àgùntàn pẹ̀lú agbo wọn yóò gbóguntì wọ́n.
Wọn yóò pa àgọ́ yí wọn ká,
olúkúlùkù yóò máa jẹ ní ilé rẹ̀.”
4 “Ẹ ya ará yín sí mímọ́ láti bá a jagun!
Dìde, kí a kọlù ú ní ìgbà ọ̀sán!
Ṣùgbọ́n ó ṣe, nítorí ọjọ́ lọ tán,
ọjọ́ alẹ́ náà sì gùn sí i.
5 Nítorí náà, ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a kọlù ú ní àṣálẹ́
kí a sì ba odi alágbára rẹ̀ jẹ́.”
6 Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Àwọn ọmọ-ogun wí:
“Ẹ ké àwọn igi náà lulẹ̀
kí ẹ sì mọ odi ààbò yí Jerusalẹmu ká.
Èyí ni ìlú títóbi tí a ó bẹ̀wò,
nítorí pé ó kún fún ìninilára.
7 Gẹ́gẹ́ bí kànga ṣe ń da omi inú rẹ̀ sílẹ̀,
náà ni ó ń tú ìwà búburú rẹ̀ jáde.
Ìwà ipá àti ìparun ń tún pariwo nínú rẹ̀;
nígbà gbogbo ni àìsàn àti ọgbẹ́ rẹ̀ ń wà níwájú mi.
8 Ìwọ Jerusalẹmu, gba ìkìlọ̀
kí Èmi kí ó má ba à lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ rẹ,
kí n sì sọ ilẹ̀ rẹ di ahoro,
tí kò ní ní olùgbé.”
9 Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí:
“Jẹ́ kí wọn pèsè ìyókù Israẹli
ní tónítóní bí àjàrà;
na ọwọ́ rẹ sí àwọn ẹ̀ka nì lẹ́ẹ̀kan sí i
gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ti í kó èso àjàrà jọ.”
10 Ta ni ẹni tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti
tí mo lè fún ní ìmọ̀ràn? Ta ni
yóò tẹ́tí sílẹ̀ sí mi? Etí wọn
ti di, nítorí náà wọn kò lè gbọ́.
Ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ ohun búburú sí wọn,
wọn kò sì ní inú dídùn nínú rẹ̀.
11 Èmi kún fún ìbínú
Olúwa, èmi kò sì le è pa á mọ́ra.
“Tú u sí orí àwọn ọmọ ńigboro, àti
sórí àwọn ọmọkùnrin tí wọn kó ra
wọn jọ pọ̀, àti ọkọ àti aya ni a ò
mú sínú rẹ̀, àti àwọn arúgbó
tí ó ní ọjọ́ kíkún lórí.
12 Ilé wọn o sì di ti ẹlòmíràn,
oko wọn àti àwọn aya wọn,
nígbà tí èmi bá na ọwọ́ mi
sí àwọn olùgbé ilẹ̀ náà,”
ni Olúwa wí.
13 “Láti orí ẹni tí ó kéré sí orí
ẹni tí ó tóbi ju, gbogbo wọn
ni ó sì ní ojúkòkòrò fún èrè,
àwọn wòlíì àti àlùfáà lápapọ̀
sì kún fún ẹ̀tàn.
14 Wọ́n sì ń wo ọgbẹ́ àwọn ènìyàn
mi bí ẹni pé kò tó nǹkan.
Wọ́n ń wí pé, ‘Àlàáfíà, Àlàáfíà,’
nígbà tí kò sì sí àlàáfíà.
15 Ojú ha a tì wọ́n nítorí ìwà
ìríra wọn bí? Rárá, wọn kò
ní ìtìjú mọ́, wọn kò tilẹ̀ ní oorun ìtìjú
Nítorí náà, wọn ó ṣubú láàrín
àwọn tó ṣubú, a ó sì ké wọn
lulẹ̀ nígbà tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò,”
ni Olúwa wí.
16 Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Ẹ dúró sí ìkóríta, kí ẹ sì wò,
ẹ béèrè fún ọ̀nà àtijọ́, ẹ béèrè
ẹ béèrè ọ̀nà dáradára nì, kí ẹ rìn nínú rẹ,
ẹ̀yin yóò sì rí ìsinmi fún ọkàn yín.
Ṣùgbọ́n ẹ̀yin wí pé, ‘Àwa kì yóò rìn nínú rẹ̀.’
17 Èmi yan olùṣọ́ fún un yín,
mo sì wí pé:
‘Tẹ́tí sí dídún fèrè náà,’
ẹ̀yìn wí pé, ‘Àwa kì yóò tẹ́tí sílẹ̀.’
18 Nítorí náà, gbọ́ ẹ̀yin orílẹ̀-èdè
kíyèsi, kí ẹ sì jẹ́ ẹlẹ́rìí
ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ sí wọn.
19 Gbọ́, ìwọ ayé!
Mò ń mú ìparun bọ̀ sórí àwọn ènìyàn wọ̀nyí,
èso ìrò inú wọn,
nítorí wọn kò fi etí sí ọ̀rọ̀ mi,
wọ́n sì ti kọ òfin mi sílẹ̀.
20 Èrè wo ni ó wà fún mi nínú tùràrí láti Ṣeba wá,
tàbí èso dáradára láti ilẹ̀ jíjìn réré?
Ẹbọ sísun yín kò ṣe ìtẹ́wọ́gbà,
ọrẹ yín kò sì wù mí.”
21 Nítorí náà, èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Èmi yóò gbé ohun ìdènà síwájú
àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn baba
àti ọmọ yóò jùmọ̀ ṣubú lù wọ́n,
àwọn aládùúgbò àti ọ̀rẹ́ yóò ṣègbé.”
22 Báyìí ni Olúwa wí:
“Wò ó, àwọn ọmọ-ogun ń bọ̀ wá láti ilẹ̀ àríwá,
a ó sì gbé orílẹ̀-èdè ńlá dìde
láti òpin ayé wá.
23 Wọ́n sì dìmọ́ra pẹ̀lú ọrun àti ọ̀kọ̀,
Wọ́n jẹ́ ẹni ibi, wọn kò sì ní àánú
wọ́n ń hó bí omi Òkun, bí wọ́n
ti ṣe ń gun àwọn ẹṣin wọn lọ;
wọ́n sì wá bí ọkùnrin tí yóò
jà ọ́ lógun, ìwọ ọmọbìnrin Sioni.”
24 Àwa ti gbọ́ ìròyìn nípa wọn,
ọwọ́ wa sì di rírọ, ìrora sì mú wa
bí obìnrin tí ń rọbí.
25 Má ṣe jáde lọ sí orí pápá
tàbí kí o máa rìn ní àwọn
ojú ọ̀nà, nítorí ọ̀tá náà ní idà,
ìpayà sì wà níbi gbogbo.
26 Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbé aṣọ ọ̀fọ̀ wọ̀,
kí ẹ sì sùn nínú eérú,
ẹ ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú ìpohùnréré ẹkún
gẹ́gẹ́ bí i lórí ọmọkùnrin yín kan ṣoṣo
nítorí pé lójijì ni àwọn apanirun yóò kọlù wá.
27 “Èmi ti fi ẹ́ ṣe ẹni tí yóò máa yọ́
irú àwọn ènìyàn mi gẹ́gẹ́ bi irin
tútù, kí wọn kí ó lè ṣe àkíyèsí,
kí ó sì dán ọ̀nà wọn wò.
28 Ọlọ́tẹ̀ tí ọkàn rẹ̀ le ní gbogbo wọn.
Wọ́n ń lọ káàkiri láti sọ̀rọ̀-òdì.
Wọ́n jẹ́ idẹ àti irin,
wọ́n sì kún fún ìwà ìbàjẹ́.
29 Ewìrì a fẹ́ná kíkankíkan,
kí ó lè yọ́ òjé,
ẹni tí ń yọ́ ọ ń yọ́ ọ lásán;
a kò si ya ènìyàn búburú kúrò.
30 A pè wọ́n ní fàdákà tí a kọ̀sílẹ̀,
nítorí Olúwa ti kọ̀ wọ́n sílẹ̀.”
Òwe àwọn òṣìṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà
20 (A)“Nítorí ìjọba ọ̀run dàbí ọkùnrin tí ó jẹ́ baálé kan, tí ó jíjáde lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, tí ó gba àwọn alágbàṣe sínú ọgbà àjàrà rẹ̀. 2 Òun pinnu láti san dínárì kan fún iṣẹ́ òòjọ́ kan. Lẹ́yìn èyí ó sì rán wọn lọ sínú ọgbà àjàrà rẹ̀.
3 “Ní wákàtí kẹta ọjọ́ bí ó ti ń kọjá níwájú ilé ìgbanisíṣẹ́, ó rí díẹ̀ nínú àwọn aláìríṣẹ́ tí wọ́n dúró ní ọjà. 4 Ó wí fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin pàápàá, ẹ lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà mi, bí ó bá sì di òpin ọjọ́, èmi yóò san iye ti ó bá yẹ fún yín.’ 5 Wọ́n sì lọ.
“Ó tún jáde lọ́sàn án ní nǹkan bí wákàtí kẹfà àti wákàtí kẹsànán, ó túnṣe bákan náà. 6 Lọ́jọ́ kan náà ní wákàtí kọkànlá ọjọ́, ó tún jáde sí àárín ìlú, ó sì rí àwọn aláìríṣẹ́ mìíràn tí wọ́n dúró. Ó bi wọ́n pé, ‘Èéṣe tí ẹ̀yin kì í ṣiṣẹ́ ní gbogbo ọjọ́?’
7 “Wọ́n sì dáhùn pé, ‘Nítorí pé kò sí ẹni tí yóò fún wa ní iṣẹ́ ṣe.’
“Ó tún sọ fún wọn pé, ‘Ẹ̀yin náà ẹ jáde lọ ṣiṣẹ́ pẹ̀lú nínú ọgbà àjàrà mi.’
8 (B)“Nígbà tí ó di àṣálẹ́, ẹni tó ni ọgbà àjàrà sọ fún aṣojú rẹ̀ pé, ‘Pe àwọn òṣìṣẹ́ náà, kí ó san owó iṣẹ́ wọn fún wọn, bẹ̀rẹ̀ láti ẹni ìkẹyìn lọ sí ti ìṣáájú.’
9 “Nígbà tí àwọn ti a pè ní wákàtí kọkànlá ọjọ́ dé, ẹnìkọ̀ọ̀kan gba owó dínárì kan. 10 Nígbà tí àwọn tí a gbà ṣiṣẹ́ lákọ̀ọ́kọ́ fẹ́ gba owó tiwọn, èrò wọn ni pé àwọn yóò gba jù bẹ́ẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn gba owó dínárì kan. 11 Bí wọ́n ti ń gbà á, wọ́n ń kùn sí onílẹ̀ náà, 12 pé, ‘Wákàtí kan péré ni àwọn tí a gbà kẹ́yìn fi ṣiṣẹ́, ìwọ sì san iye kan náà fún wọn àti àwa náà ti a fi gbogbo ọjọ́ ṣiṣẹ́ nínú oòrùn gangan.’
13 (C)“Ṣùgbọ́n ó dá ọ̀kan nínú wọn lóhùn pé, ‘Ọ̀rẹ́, kò sí aburú nínú nǹkan tí èmi ṣe sí yín. Kì í ha ṣe pé ẹ̀yin gbà láti ṣiṣẹ́ fún owó dínárì kan. 14 Ó ní, Gba èyí tí í ṣé tìrẹ, ki ó sì máa lọ. Èmi fẹ́ láti fún ẹni ìkẹyìn gẹ́gẹ́ bí mo ti fi fún ọ. 15 Àbí ó lòdì sí òfin pé kí èmi fún ẹnikẹ́ni ní owó mi bí mo bá yàn láti ṣe bẹ́ẹ̀? Kí ni ìdí tí ìwọ ní láti bínú nítorí èmi ṣe ohun rere?’
16 (D)“Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹni ìkẹyìn yóò di ẹni ìṣáájú, ẹni ìṣáájú yóò sì di ẹni ìkẹyìn.”
Jesu tún sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀
17 (E)Bí Jesu ti ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu, ó pe àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá sí apá kan ó sì wí pé, 18 “Wò ó, àwa ń gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Ó sọ fún wọn pé, a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn olùkọ́ òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá mi lẹ́bi ikú. 19 Wọn yóò sì fà á lé àwọn kèfèrí lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà àti láti nàa án, àti láti kàn mi mọ́ àgbélébùú, ní ọjọ́ kẹta, yóò jí dìde.”
Ẹ̀bẹ̀ ìyá
20 (F)(G) Nígbà náà ni ìyá àwọn ọmọ Sebede bá àwọn ọmọ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Jesu, ó wólẹ̀ lórí eékún rẹ̀, o béèrè fún ojúrere rẹ̀.
21 (H)Jesu béèrè pé, “Kí ni ìwọ ń fẹ́?”
Ó sì dáhùn pé, “Jẹ́ kí àwọn ọmọ mi méjèèjì jókòó ní apá ọ̀tún àti apá òsì lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ?”
22 (I)Ṣùgbọ́n Jesu dáhùn ó sì wí pé, “Ẹ̀yin kò mọ ohun tí ẹ̀yin ń béèrè, ẹ̀yin ha le mu nínú ago tí èmi ó mu?”
Wọ́n dáhùn pé, “Àwa lè mu ún.”
23 (J)Jesu sì wí fún wọn pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin yóò mu nínú ago mi, ṣùgbọ́n èmi kò ní àṣẹ láti sọ irú ènìyàn tí yóò jókòó ní apá ọ̀tún tàbí apá òsì. Baba mi ti pèsè ààyè wọ̀n-ọn-nì sílẹ̀ fún kìkì àwọn tí ó yàn.”
24 Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́wàá ìyókù sì gbọ́ èyí, wọ́n bínú sí àwọn arákùnrin méjì yìí. 25 (K)Ṣùgbọ́n Jesu pé wọ́n papọ̀, ó wí pé, “Dájúdájú, ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọba aláìkọlà a máa lo agbára lórí wọn, àwọn ẹni ńlá láàrín wọn a sì máa fi ọlá tẹrí àwọn tí ó wà lábẹ́ wọn ba. 26 Ṣùgbọ́n èyí yàtọ̀ láàrín yín. Dípò bẹ́ẹ̀, ẹni tí ó bá ń fẹ́ ṣe olórí láàrín yín, ní láti ṣe bí ìránṣẹ́ fún yín ni, 27 Àti ẹni tí ó bá fẹ́ ṣe olórí nínú yín, ẹ jẹ́ kí ó máa ṣe ọmọ ọ̀dọ̀ yin. 28 Gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ènìyàn kò ṣe wá sí ayé, kí ẹ lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, ṣùgbọ́n láti ṣe ìránṣẹ́ fún yín, àti láti fi ẹ̀mí rẹ ṣe ìràpadà ọ̀pọ̀ ènìyàn.”
Afọ́jú méjì ríran
29 (L)Bí Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń fi ìlú Jeriko sílẹ̀, ọ̀pọ̀ ènìyàn sì wọ́ tẹ̀lé e lẹ́yìn. 30 Àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì sì jókòó lẹ́bàá ọ̀nà, nígbà tí wọ́n sí gbọ́ pé Jesu ń kọjá lọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kígbe pé, “Olúwa, Ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!”
31 Àwọn ènìyàn sí bá wọn wí pé kí wọn dákẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n kígbe sókè sí i. “Olúwa, ọmọ Dafidi, ṣàánú fún wa!”
32 Jesu dúró lójú ọ̀nà, ó sì pè wọ́n, Ó béèrè pé, “Kí ni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ṣe fún yín?”
33 Wọ́n dáhùn pé, “Olúwa, àwa fẹ́ kí a ríran.”
34 Àánú wọn sì ṣe Jesu, ó fi ọwọ́ kan ojú wọn. Lójúkan náà, wọ́n sì ríran, wọ́n sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.