M’Cheyne Bible Reading Plan
Orílẹ̀-èdè Israẹli bá àwọn ará Kenaani tókù jagun
1 Lẹ́yìn ikú Joṣua, ni orílẹ̀-èdè Israẹli béèrè lọ́wọ́ Olúwa pé “Èwo nínú ẹ̀yà wa ni yóò kọ́kọ́ gòkè lọ bá àwọn ará Kenaani jagun fún wa?”
2 Olúwa sì dáhùn pé, “Juda ni yóò lọ; nítorí pé èmi ti fi ilẹ̀ náà lé e lọ́wọ́.”
3 Nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà Juda béèrè ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ Simeoni arákùnrin wọn pé, “Ẹ wá bá wa gòkè lọ sí ilẹ̀ tí a ti fi fún wa, láti bá àwọn ará Kenaani jà kí a sì lé wọn kúrò, àwa pẹ̀lú yóò sì bá a yín lọ sí ilẹ̀ tiyín bákan náà láti ràn yín lọ́wọ́.” Àwọn ọmọ-ogun Simeoni sì bá àwọn ọmọ-ogun Juda lọ.
4 Nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Juda sì kọlu wọ́n, Olúwa sì fi àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi lé wọn lọ́wọ́, wọ́n sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọkùnrin ní Beseki. 5 Ní Beseki ni wọ́n ti rí Adoni-Beseki, wọ́n sì bá a jagun, wọ́n sì ṣẹ́gun àwọn ará Kenaani àti Peresi. 6 Ọba Adoni-Beseki sá àsálà, ṣùgbọ́n ogun Israẹli lépa rẹ̀ wọ́n sì bá a, wọ́n sì gé àwọn àtàǹpàkò ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀.
7 Nígbà náà ni Adoni-Beseki wí pé, “Àádọ́rin ọba ni èmi ti gé àtàǹpàkò wọn tí wọ́n sì ń ṣa èérún oúnjẹ jẹ lábẹ́ tábìlì mi. Báyìí Ọlọ́run ti san án fún mi gẹ́gẹ́ bí ohun tí mo ṣe sí wọn.” Wọ́n sì mú un wá sí Jerusalẹmu, ó sì kú síbẹ̀.
8 Àwọn ológun Juda sì ṣẹ́gun Jerusalẹmu, wọ́n sì kó o, wọ́n sì fi ojú idà kọlù ú, wọ́n sì dáná sun ìlú náà.
9 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni àwọn ogun Juda sọ̀kalẹ̀ lọ láti bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé ní àwọn ìlú orí òkè ní gúúsù àti ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ òkè lápá ìwọ̀-oòrùn Juda jagun. 10 (A)(B)Ogun Juda sì tún ṣígun tọ ará Kenaani tí ń gbé Hebroni (tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiriati-Arba) ó sì ṣẹ́gun Ṣeṣai, Ahimani àti Talmai. 11 Láti ibẹ̀, wọ́n sì wọ́de ogun láti ibẹ̀ lọ bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ní Debiri (tí à ń pè ní Kiriati-Seferi nígbà kan rí).
12 Kalebu sì wí pé, “Èmi yóò fi ọmọbìnrin mi Aksa fún ọkùnrin tí ó bá kọlu Kiriati-Seferi, tí ó sì gbà á ní ìgbéyàwó.” 13 Otnieli ọmọ Kenasi, àbúrò Kalebu sì gbà á, báyìí ni Kalebu sì fi ọmọbìnrin rẹ̀ Aksa fún un ní ìyàwó.
14 Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Aksa lọ sí ọ̀dọ̀ Otnieli, ó rọ̀ ọ́ kí ó béèrè ilẹ̀ oko lọ́wọ́ baba rẹ̀. Nígbà nàà ni Aksa sọ̀kalẹ̀ ní orí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, Kalebu sì béèrè pé, “Kí ni kí èmi ṣe fún ọ?”
15 Aksa sì dáhùn pé, “Mo ń fẹ́ kí o ṣe ojúrere kan fún mi, nígbà ti o ti fún mi ní ilẹ̀ ní gúúsù, fún mi ní ìsun omi náà pẹ̀lú.” Kalebu sì fún un ní ìsun òkè àti ìsun ìsàlẹ̀.
16 Àwọn ìran Keni tí wọ́n jẹ́ àna Mose bá àwọn ọmọ Juda gòkè láti ìlú ọ̀pẹ lọ sí aginjù Juda ní gúúsù Aradi; wọ́n sì lọ, orílẹ̀-èdè méjèèjì sì jùmọ̀ ń gbé pọ̀ láti ìgbà náà.
17 Ó sì ṣe, àwọn ológun Juda tẹ̀lé àwọn ológun Simeoni arákùnrin wọn, wọ́n sì lọ bá àwọn ará Kenaani tí ń gbé Sefati jagun, wọ́n sì run ìlú náà pátápátá, ní báyìí àwa yóò pe ìlú náà ní Horma (Horma èyí tí ń jẹ́ ìparun). 18 Àwọn ogun Juda sì ṣẹ́gun Gasa àti àwọn agbègbè rẹ̀, Aṣkeloni àti Ekroni pẹ̀lú àwọn ìlú tí ó yí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ká.
19 Olúwa sì wà pẹ̀lú ẹ̀yà Juda, wọ́n gba ilẹ̀ òkè, ṣùgbọ́n wọn kò le lé àwọn ènìyàn tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀, nítorí wọ́n ní kẹ̀kẹ́ ogun onírin. 20 Gẹ́gẹ́ bí Mose ti ṣèlérí, wọ́n fún Kalebu ní Hebroni, ó sì lé àwọn tí ń gbé ibẹ̀ kúrò; àwọn náà ni ìran àwọn ọmọ Anaki mẹ́ta. 21 Àwọn ẹ̀yà Benjamini ni wọn kò le lé àwọn Jebusi tí wọ́n ń gbé Jerusalẹmu, nítorí náà wọ́n ń gbé àárín àwọn Israẹli títí di òní.
22 Àwọn ẹ̀yà Josẹfu sì bá Beteli jagun, Olúwa síwájú pẹ̀lú wọn. 23 Nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu rán àwọn ènìyàn láti lọ yọ́ Beteli wò (orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀ rí ni Lusi). 24 Àwọn ayọ́lẹ̀wò náà rí ọkùnrin kan tí ń jáde láti inú ìlú náà wá, wọ́n sì wí fún un pé, “Fi ọ̀nà àtiwọ ìlú yìí hàn wá, àwa ó sì dá ẹ̀mí rẹ sí, a ó sì ṣe àánú fún ọ.” 25 Ó sì fi ọ̀nà ìlú náà hàn wọ́n, wọ́n sì fi ojú idà kọlu ìlú náà, ṣùgbọ́n wọ́n dá ọkùnrin náà àti gbogbo ìdílé rẹ̀ si. 26 Ọkùnrin náà sí lọ sí ilẹ̀ àwọn ará Hiti, ó sì tẹ ìlú kan dó, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Lusi, èyí sì ni orúkọ rẹ̀ títí di òní.
27 (C)Ṣùgbọ́n Manase kò lé àwọn ará Beti-Ṣeani àti ìlú rẹ̀ wọ̀n-ọn-nì jáde, tàbí àwọn ará Taanaki àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Dori àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Ibleamu àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, tàbí àwọn ará Megido àti àwọn ìgbèríko tí ó yí i ká, torí pé àwọn ará Kenaani ti pinnu láti máa gbé ìlú náà. 28 Nígbà tí àwọn ọmọ Israẹli di alágbára, wọ́n mú àwọn ará Kenaani sìn bí i ẹrú, ṣùgbọ́n wọn kò fi agbára lé wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ náà. 29 (D)Efraimu náà kò lé àwọn ará Kenaani tí ó ń gbé Geseri jáde, ṣùgbọ́n àwọn ará Kenaani sì ń gbé láàrín àwọn ẹ̀yà Efraimu. 30 Bẹ́ẹ̀ ni àwọn Sebuluni kò lé àwọn ará Kenaani tí ń gbé Kitironi jáde tàbí àwọn ará Nahalali, ṣùgbọ́n wọ́n sọ wọ́n di ẹrú. Wọ́n sì ń sin àwọn ará Sebuluni. 31 Bẹ́ẹ̀ ni Aṣeri kò lé àwọn tí ń gbé ní Akko tàbí ní Sidoni tàbí ní Ahlabu tàbí ní Aksibu tàbí ní Helba tàbí ní Afiki tàbí ní Rehobu. 32 Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà. 33 Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá. 34 Àwọn ará Amori fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dani dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀. 35 Àwọn ará Amori ti pinnu láti dúró lórí òkè Heresi àti òkè Aijaloni àti ti Ṣaalbimu, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu di alágbára wọ́n borí Amori wọ́n sì mú wọn sìn. 36 Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Akrabbimu kọjá lọ sí Sela àti síwájú sí i.
Anania àti Safira
5 Ṣùgbọ́n ọkùnrin kan ti a ń pè ni Anania, pẹ̀lú Safira aya rẹ̀, ta ilẹ̀ ìní kan, 2 Nípa ìmọ̀ aya rẹ̀ ó yan apá kan pamọ́ nínú owó náà, ó sì mú apá kan rẹ̀ wá, ó sì fi í lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ àwọn aposteli.
3 Ṣùgbọ́n Peteru wí pé, “Anania, Èéṣe ti Satani fi kún ọkàn rẹ láti ṣèké sí Ẹ̀mí Mímọ́, tí ìwọ sì fi yan apá kan pamọ́ nínú owó ilẹ̀ náà? 4 Nígbà tí ó wà níbẹ̀ tìrẹ kọ́ ní í ṣe? Nígbà tí a sì ta á tan, kò ha wà ní ìkáwọ́ rẹ̀? Èéha ti ṣe tí ìwọ fi rò nǹkan yìí lọ́kàn rẹ? Ènìyàn kọ́ ni ìwọ ṣèké sí bí kò ṣe sí Ọlọ́run?”
5 Nígbà tí Anania sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó ṣubú lulẹ̀, ó sì kú, ẹ̀rù ńlá sí ba gbogbo àwọn tí ó gbọ́. 6 Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sí dìde, wọ́n dì í, wọn sì gbé è jáde, wọn sì sin ín.
7 Ó sì tó bí ìwọ̀n wákàtí mẹ́ta, aya rẹ̀ láìmọ̀ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀, ó wọlé. 8 Peteru sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Wí fún mi, ṣé iye yìí ni ìwọ àti Anania gbà lórí ilẹ̀?”
Ó sì wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, iye rẹ̀ náà ni.”
9 Peteru sí wí fún un pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fohùn ṣọ̀kan láti dán Ẹ̀mí Olúwa wò? Wò ó, ẹsẹ̀ àwọn tí ó sìnkú ọkọ rẹ ń bẹ ní ẹnu-ọ̀nà, wọn ó sì gbe ìwọ náà jáde.”
10 Lójúkan náà ó sì ṣubú lulẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì kú; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin sì wọlé wọ́n bá a ní òkú, wọ́n sì gbé e jáde, wọ́n sín in lẹ́bàá ọkọ rẹ̀. 11 Ẹ̀rù ńlá sì bá gbogbo ìjọ àti gbogbo àwọn tí ó gbọ́ nǹkan wọ̀nyí.
Àwọn aposteli wo ọ̀pọ̀ sàn
12 A sì ti ọwọ́ àwọn aposteli ṣe iṣẹ́ ààmì àti iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Gbogbo wọn sì fi ọkàn kan wà ní ìloro Solomoni. 13 Kò sí nínú àwọn ìyókù tí ó jẹ́ gbìyànjú láti darapọ̀ mọ́ wọn, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ń fi ọ̀wọ̀ gíga fún wọn. 14 Ṣùgbọ́n síbẹ̀síbẹ̀, a sì ń yan àwọn ọkùnrin àti àwọn obìnrin tí ó gba Olúwa gbọ́ kún iye wọn sí i. 15 Tó bẹ́ẹ̀ tí wọn ń gbé àwọn abirùn jáde sí òpópónà, tí wọn ń tẹ́ wọn sí orí ibùsùn àti àkéte kí òjìji Peteru ba à le gba orí ẹlòmíràn nínú wọn bí ó bá ti ń kọjá lọ. 16 Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì kó ara wọn jọ láti àwọn ìlú tí ó yí Jerusalẹmu ká, wọn ń mú àwọn abirùn wá àti àwọn tí ara kan fún ẹ̀mí àìmọ́; a sì mu olúkúlùkù wọn ní ara dá.
Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn aposteli
17 Nígbà náà ni ẹ̀mí owú gbígbóná gbé olórí àlùfáà àti gbogbo àwọn tí wọn wà lọ́dọ̀ rẹ̀ tí ì ṣe ẹ̀yà tí àwọn Sadusi wọ̀. 18 Wọ́n sì nawọ́ mú àwọn aposteli wọn sì fi wọ́n sínú túbú. 19 Ṣùgbọ́n ní òru, angẹli Olúwa ṣí ìlẹ̀kùn túbú; ó sì mú wọn jáde. 20 Ó sì wí pé “Ẹ lọ dúró nínú tẹmpili kí ẹ sì máa ṣọ́ ọ̀rọ̀ ìyè yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ fún àwọn ènìyàn.”
21 Nígbà tí wọ́n sì gbọ́ èyí, wọ́n wọ tẹmpili lọ ní kùtùkùtù, wọ́n sì ń kọ́ni.
Nígbà tí olórí àlùfáà àti àwọn ti ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ dé, wọn sì pè àpéjọ ìgbìmọ̀, àti gbogbo àwọn àgbàgbà àwọn ọmọ Israẹli, wọn sì ránṣẹ́ sí ilé túbú láti mú àwọn aposteli wá. 22 Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn olùṣọ́ dé ibẹ̀ wọn kò sì rí wọn nínú túbú, wọn padà wá, wọn sísọ fún wọn pé, 23 “Àwa bá ilé túbú ni títí pinpin, àti àwọn olùṣọ́ dúró lóde níwájú ìlẹ̀kùn; ṣùgbọ́n nígbà tí àwa ṣí ìlẹ̀kùn, àwa kò bá ẹnìkan nínú túbú.” 24 Nígbà tí olórí ẹ̀ṣọ́ tẹmpili àti àwọn olórí àlùfáà sí gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n dààmú nítorí wọn kò mọ ibi tí ọ̀rọ̀ yìí yóò yọrí sí.
25 Nígbà náà ni ẹnìkan dé, ó wí fún wọn pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin tí ẹ̀yin fi sínú túbú wà ní tẹmpili, wọn dúró wọ́n sì ń kọ́ àwọn ènìyàn.” 26 Nígbà náà ni olórí ẹ̀ṣọ́ lọ pẹ̀lú àwọn olùṣọ́, ó sì mú àwọn aposteli wá. Wọn kò fi ipá mú wọn, nítorí tí wọn bẹ̀rù àwọn ènìyàn kí a má ba à sọ wọ́n ní òkúta.
27 Nígbà tí wọn sì mú àwọn aposteli dé, wọn mú wọn dúró níwájú àjọ ìgbìmọ̀; olórí àlùfáà sì bi wọ́n léèrè. 28 Ó wí pé, “Àwa kò ha ti kìlọ̀ fún un yín gidigidi pé, kí ẹ má ṣe fi orúkọ yìí kọ́ni, síbẹ̀ ẹ̀yin ti fi ìkọ́ni yín kún Jerusalẹmu, ẹ sì ń pète àti mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkùnrin yìí wá sí orí wá.”
29 Ṣùgbọ́n Peteru àti àwọn aposteli dáhùn, wọ́n sì wí pé, “Àwa kò gbọdọ̀ má gbọ́ tí Ọlọ́run ju ti ènìyàn lọ! 30 (A)Ọlọ́run àwọn baba wa jí Jesu dìde kúrò ní ipò òkú, ẹni tí ẹ̀yin pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. 31 Òun ni Ọlọ́run fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ gbé gẹ́gẹ́ bí Ọmọ-aládé àti Olùgbàlà láti fi ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún Israẹli. 32 Àwa sì ni ẹlẹ́rìí nǹkan wọ̀nyí, àti gẹ́gẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti ṣe ẹlẹ́rìí pẹ̀lú, tí Ọlọ́run fi fún àwọn tí ó gbà á gbọ́.”
33 Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ èyí, ọkàn wọn gbọgbẹ́ dé inú, wọ́n gbèrò láti pa wọ́n. 34 Ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àjọ ìgbìmọ̀, tí a ń pè ni Gamalieli, Farisi àti amòfin, tí ó ní ìyìn gidigidi lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn, ó dìde dúró, ó ni kí a mú àwọn aposteli bì sẹ́yìn díẹ̀. 35 Ó sì wí fún wọn pé “Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ kíyèsi ara yín lóhùn tí ẹ̀yin ń pète láti ṣe sí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí. 36 Nítorí ṣáájú ọjọ́ wọ̀nyí ni Teuda dìde, ó ń wí pé, ẹni ńlá kan ní òun; ẹni tí ìwọ̀n irínwó ọkùnrin dara wọn pọ̀ mọ́; ṣùgbọ́n a pa á; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ sì túká, tí wọn sí di asán. 37 Lẹ́yìn ọkùnrin yìí ni Judasi ti Galili dìde ni àkókò kíka àwọn ènìyàn, ó sì ni ẹni púpọ̀ lẹ́yìn rẹ̀; òun pẹ̀lú ṣègbé; àti gbogbo iye àwọn tí ó gba tirẹ̀ ni a fọ́nká. 38 Ǹjẹ́ èmi wí fún un yín nísinsin yìí, ṣọ́ra fún àwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí ẹ sí fi wọn sílẹ̀, nítorí bí ìmọ̀ tàbí iṣẹ́ yìí bá jẹ́ ti ènìyàn, a ó bì í ṣubú. 39 Ṣùgbọ́n bí ti Ọlọ́run bá ní, ẹ̀yin kì yóò lè bì í ṣubú; kí ó má ba à jẹ́ pé, a rí yín bí ẹni tí ń bá Ọlọ́run jà.”
40 Wọ́n sì gbà ìmọ̀ràn rẹ̀. Wọn pe àwọn aposteli wọlé, wọ́n si lù wọ́n. Wọn sí kìlọ̀ fún wọn pé kí wọn má ṣe sọ̀rọ̀ ni orúkọ Jesu mọ́, wọ́n sì jọ̀wọ́ wọn sílẹ̀ lọ.
41 Nítorí náà wọn sì lọ kúrò níwájú àjọ ìgbìmọ̀; wọn ń yọ̀ nítorí tí a kà wọ́n yẹ láti jìyà nítorí orúkọ rẹ̀. 42 Ní ojoojúmọ́ nínú tẹmpili àti ni ojúlé dé ojúlé, wọn kò dẹ́kun kíkọ́ni àti láti wàásù ìhìnrere náà pé Jesu ni Kristi.
Àjàkálẹ̀-ààrùn, ìyàn àti idà
14 Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Jeremiah nípa ti àjàkálẹ̀-ààrùn:
2 “Juda káàánú,
àwọn ìlú rẹ̀ kérora
wọ́n pohùnréré ẹkún fún ilẹ̀ wọn,
igbe wọn sì gòkè lọ láti Jerusalẹmu.
3 Àwọn ọlọ́lá ènìyàn rán àwọn ìránṣẹ́ wọn lọ bu omi,
wọ́n lọ sí ìdí àmù
ṣùgbọ́n wọn kò rí omi.
Wọ́n padà pẹ̀lú ìkòkò òfìfo;
ìrẹ̀wẹ̀sì àti àìnírètí bá wọn,
wọ́n sì bo orí wọn.
4 Ilẹ̀ náà sán
nítorí pé kò sí òjò ní ilẹ̀ náà;
ìrètí àwọn àgbẹ̀ di òfo,
wọ́n sì bo orí wọn.
5 Kódà, abo àgbọ̀nrín tí ó wà lórí pápá
fi ọmọ rẹ̀ tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí sílẹ̀,
torí pé kò sí koríko.
6 Àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó dúró lórí òkè òfìfo
wọ́n sì ń mí ẹ̀fúùfù bí ìkookò
ojú wọn kò ríran
nítorí pé kò sí koríko jíjẹ.”
7 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wa jẹ́rìí lòdì sí wa,
wá nǹkan kan ṣe sí i Olúwa, nítorí orúkọ rẹ.
Nítorí ìpadàsẹ́yìn wa ti pọ̀jù,
a ti ṣẹ̀ sí ọ.
8 Ìrètí Israẹli;
ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú,
èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà
bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?
9 Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú,
bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́?
Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa,
orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa;
má ṣe fi wá sílẹ̀.
10 Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí:
“Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri;
wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu.
Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n;
yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí,
yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”
11 Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí. 12 (A)Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”
13 Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”
14 Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn. 15 Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn. 16 Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
17 “Kí ìwọ kí ó sì sọ ọ̀rọ̀ yìí fún wọn pé:
“ ‘Jẹ́ kí ojú mi kí ó sun omijé
ní ọ̀sán àti ní òru láìdá;
nítorí tí a ti ṣá wúńdíá,
ọmọ ènìyàn mi ní ọgbẹ́ ńlá
pẹ̀lú lílù bolẹ̀.
18 Bí mo bá lọ sí orílẹ̀-èdè náà,
Èmi yóò rí àwọn tí wọ́n fi idà pa.
Bí mo bá lọ sí ìlú ńlá,
èmi rí àwọn tí ìyàn ti sọ di aláàrùn.
Wòlíì àti Àlùfáà
ti lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.’ ”
19 Ṣé o ti kọ Juda sílẹ̀ pátápátá ni?
Ṣé o ti ṣá Sioni tì?
Èéṣe tí o fi pọ́n wa lójú
tí a kò fi le wò wá sàn?
A ń retí àlàáfíà
ṣùgbọ́n ohun rere kan kò tí ì wá,
ní àsìkò ìwòsàn
ìpayà là ń rí.
20 Olúwa, a jẹ́wọ́ ìwà ibi wa
àti àìṣedéédéé àwọn baba wa;
lóòótọ́ ni a ti ṣẹ̀ sí ọ.
21 Nítorí orúkọ rẹ má ṣe kórìíra wa;
má ṣe sọ ìtẹ́ ògo rẹ di àìlọ́wọ̀.
Rántí májẹ̀mú tí o bá wa dá
kí o má ṣe dà á.
22 Ǹjẹ́ èyíkéyìí àwọn òrìṣà yẹ̀yẹ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè le ṣe kí òjò rọ̀?
Ǹjẹ́ àwọsánmọ̀ fúnrarẹ̀ rọ òjò bí?
Rárá, ìwọ ni, Olúwa Ọlọ́run wa.
Torí náà, ìrètí wa wà lọ́dọ̀ rẹ,
nítorí pé ìwọ lo ń ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.
Àjíǹde rẹ̀
28 (A)(B) Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, bí ilẹ̀ ti ń mọ́, Maria Magdalene àti Maria kejì lọ sí ibojì.
2 (C)Wọ́n rí i pé, ìṣẹ̀lẹ̀ ńlá ṣẹ̀ tí ó mú gbogbo ilẹ̀ mì tìtì. Nítorí angẹli Olúwa ti sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run. Ó ti yí òkúta ibojì kúrò. Ó sì jókòó lé e lórí. 3 Ojú rẹ̀ tàn bí mọ̀nàmọ́ná. Aṣọ rẹ̀ sì jẹ́ funfun bí ẹ̀gbọ̀n òwú. 4 (D)Ẹ̀rù ba àwọn olùṣọ́, wọ́n sì wárìrì wọn sì dàbí òkú.
5 Nígbà náà ni angẹli náà wí fún àwọn obìnrin náà pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Mo mọ̀ pé ẹ̀yin ń wá Jesu tí a kàn mọ́ àgbélébùú. 6 Ṣùgbọ́n kò sí níhìn-ín. Nítorí pé ó ti jíǹde, gẹ́gẹ́ bí òun ti wí. Ẹ wọlé wá wo ibi ti wọ́n tẹ́ ẹ sí. 7 (E)Nísinsin yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Galili síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóò gbé rí i,’ wò ó, o ti sọ fún yin.”
8 Àwọn obìnrin náà sáré kúrò ní ibojì pẹ̀lú ìbẹ̀rù àti ayọ̀ ńlá. Wọ́n sáré láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn nípa ìròyìn tí angẹli náà fi fún wọn. 9 (F)Bí wọ́n ti ń sáré lọ lójijì Jesu pàdé wọn. Ó wí pé, “Àlàáfíà” Wọ́n wólẹ̀ níwájú rẹ̀. Wọ́n gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Wọ́n sì foríbalẹ̀ fún un. 10 Nígbà náà, Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù. Ẹ lọ sọ fún àwọn arákùnrin mi pé, ‘Kí wọ́n lọ tààrà sí Galili níbẹ̀ ni wọn yóò gbé rí mi.’ ”
Àwọn olùṣọ́ ròyìn
11 (G)Bí àwọn obìnrin náà sì ti ń lọ sí ìlú, díẹ̀ nínú àwọn olùṣọ́ tí wọ́n ti ń ṣọ́ ibojì lọ sọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. 12 Wọ́n sì pe ìpàdé àwọn àgbàgbà Júù. Wọ́n sì fohùn ṣọ̀kan láti fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ fún àwọn olùṣọ́. 13 Wọ́n wí pé, “Ẹ sọ fún àwọn ènìyàn pé, ‘Gbogbo yín sùn nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu wá lóru láti jí òkú rẹ̀.’ 14 Bí Pilatu bá sì mọ̀ nípa rẹ̀, àwa yóò ṣe àlàyé tí yóò tẹ́ ẹ lọ́rùn fún un, tí ọ̀rọ̀ náà kì yóò fi lè kó bá yín.” 15 Àwọn olùṣọ́ sì gba owó náà. Wọ́n sì ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti darí wọn. Ìtàn yìí sì tàn ká kíákíá láàrín àwọn Júù. Wọ́n sì gba ìtàn náà gbọ́ títí di òní yìí.
Jesu pín iṣẹ́ ńlá fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀
16 (H)Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ́kànlá náà lọ sí Galili ní orí òkè níbi tí Jesu sọ pé wọn yóò ti rí òun. 17 Nígbà tí wọ́n sì rí i, wọ́n foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n díẹ̀ nínú wọn ṣe iyèméjì bóyá Jesu ni tàbí òun kọ́. 18 (I)Nígbà náà ni Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Gbogbo agbára ni ọ̀run àti ní ayé ni a ti fi fún mi. 19 Nítorí náà, Ẹ lọ, ẹ sọ wọ́n di ọmọ-ẹ̀yìn orílẹ̀-èdè gbogbo, ẹ máa bamitiisi wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti Ẹ̀mí Mímọ́. 20 Ẹ kọ́ wọn láti máa kíyèsi ohun gbogbo èyí tí mo ti pàṣẹ fún yín. Nítorí èmi wà pẹ̀lú yín ní ìgbà gbogbo títí tí ó fi dé òpin ayé.”
Copyright: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní Ẹ̀tọ́ àdàkọ © 2009, 2017 by Biblica, Inc. A lò ó nípa ìgbàyọ̀ǹda láti ọwọ́ Bíbílíkà Inc. Ààbò lórí ẹ̀tọ́ àdàkọ yìí múlẹ̀ jákèjádò àgbáyé. Yoruba Contemporary Bible Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc.® Used by permission of Biblica, Inc.® All rights reserved worldwide.