Add parallel Print Page Options

Ìṣẹ́gun Sihoni àti Ogu

21 (A)Israẹli rán oníṣẹ́ láti sọ fún Sihoni ọba àwọn ará Amori wí pé:

22 “Jẹ́ kí a kọjá ní orílẹ̀-èdè rẹ. A kò ní kọjá sí inú oko pápá tàbí ọgbà àjàrà àbí mu omi láti inú kànga. A máa gba òpópónà náà ti ọba títí tí a ó fi la ilẹ̀ rẹ kọjá.”

23 Ṣùgbọ́n Sihoni kò ní jẹ́ kí àwọn Israẹli kọjá ní ilẹ̀ wọn. Ó pe àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ jọ wọ́n sì wọ́de ogun lọ sí aginjù nítorí àwọn ọmọ Israẹli. Nígbà tí ó dé Jahasi, ó bá àwọn ọmọ Israẹli jà. 24 Àmọ́, Israẹli ṣẹ́gun, wọn fi ojú idà pa wọ́n, wọ́n sì gba ilẹ̀ láti ọwọ́ Arnoni lọ dé Jabbok, títí tí ó fi dé ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, nítorí pé ààlà wọn jẹ́ olódi. 25 Israẹli sì gba gbogbo ìlú Amori wọ́n sì ń gbé ibẹ̀ pẹ̀lú Heṣboni, àti gbogbo ibùgbé ìlú tó yí i ká. 26 Heṣboni ni ìlú Sihoni ọba àwọn ará Amori, ẹni tí ó bá ọba Moabu ti tẹ́lẹ̀ jà tí ó sì gba gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ ní ọwọ́ rẹ̀ títí dé Arnoni.

27 Ìdí nìyìí tí akọrin sọ wí pé:

“Wá sí Heṣboni kí ẹ jẹ́ kí a tún un kọ́;
    jẹ́ kí ìlú Sihoni padà bọ̀ sípò.

28 “Iná jáde láti Heṣboni,
    ọ̀wọ́-iná láti Sihoni.
Ó jó Ari àti Moabu run,
    àti ìlú àwọn olùgbé ibi gíga Arnoni.
29 Ègbé ní fún ọ, ìwọ Moabu!
    Ẹ ti parun, ẹ̀yin ènìyàn Kemoṣi!
Ó ti fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìsáǹsá
    àti ọmọ rẹ̀ obìnrin gẹ́gẹ́ bí ìgbèkùn
    fún Sihoni ọba àwọn Amori.

30 “Ṣùgbọ́n àti bì wọ́n ṣubú;
    A ti pa ìjẹgàba Heṣboni run, a pa wọ́n run títí dé Diboni.
A sì ti bì wọ́n lulẹ̀ títí dé Nofa,
    tí ó sì fi dé Medeba.”

31 Nígbà náà ni àwọn ọmọ Israẹli sì ń gbé ní ilẹ̀ Amori.

32 Lẹ́yìn ìgbà tí Mose rán ayọ́lẹ̀wò lọ sí Jaseri, àwọn ọmọ Israẹli sì gba àwọn agbègbè tó yí wọn ká wọ́n sì lé àwọn Amori tó wà níbẹ̀ jáde. 33 (B)Nígbà náà wọ́n pẹ̀yìndà wọ́n sì gòkè lọ sí Baṣani, Ogu ọba ti Baṣani àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wọ́de ogun jáde láti pàdé wọn ní ojú ogun ní Edrei.

34 Olúwa sọ fún Mose pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”

35 Wọ́n sì pa á, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, wọn kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè. Wọ́n sì gba ìní ilẹ̀ rẹ̀.

Read full chapter

26 Mo rán àwọn ìránṣẹ́ láti aginjù Kedemoti lọ́ sọ́dọ̀ Sihoni ọba Heṣboni pẹ̀lú ọ̀rọ̀ àlàáfíà wí pé, 27 “Jẹ́ kí a la ilẹ̀ ẹ yín kọjá. Àwa yóò gba ti òpópónà nìkan. A kò ní yà sọ́tùn tàbí sósì. 28 Ẹ ta oúnjẹ tí a ó jẹ àti omi tí a ó mu fún wa ní iye owó wọn. Kìkì kí ẹ sá à jẹ́ kí a rìn kọjá: 29 gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Esau tí ó ń gbé ní Seiri àti àwọn ará Moabu tí ó ń gbé ní Ari, ti gbà wá láààyè títí a fi la Jordani já dé ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò fún wa.” 30 Ṣùgbọ́n Sihoni ọba Heṣboni kò gbà fún wa láti kọjá. Torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti mú ọkàn rẹ̀ yigbì, àyà rẹ̀ sì kún fún agídí kí ó ba à le fi lé e yín lọ́wọ́, bí ó ti ṣe báyìí.

31 Olúwa sì bá mi sọ̀rọ̀ pé, “Kíyèsi i, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fi Sihoni àti ilẹ̀ rẹ̀ lé e yín lọ́wọ́. Báyìí, ẹ máa ṣẹ́gun rẹ̀, kí ẹ sì gba ilẹ̀ rẹ̀.”

32 Nígbà tí Sihoni àti gbogbo àwọn jagunjagun rẹ̀ jáde wá láti bá wa jagun ní Jahasi, 33 Olúwa Ọlọ́run wa fi lé wa lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ ni a ṣẹ́gun rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo ológun rẹ̀. 34 Nígbà náà, gbogbo ìlú wọn ni a kó tí a sì pa wọ́n run pátápátá tọkùnrin, tobìnrin àti gbogbo ọmọ wọn. A kò sì dá ẹnikẹ́ni sí. 35 Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú tí a ṣẹ́gun fún ara wa. 36 Láti Aroeri, létí odò Arnoni àti láti àwọn ìlú tí ó wà lẹ́bàá odò náà títí ó fi dé Gileadi, kò sí ìlú tí ó lágbára jù fún wa, Olúwa Ọlọ́run wa fi gbogbo wọn fún wa. 37 Ní ìbámu pẹ̀lú òfin Olúwa Ọlọ́run wa, ẹ kò súnmọ́ ọ̀kan nínú ilẹ̀ àwọn ará Ammoni, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò dé ilẹ̀ tí ó lọ sí Jabbok, tàbí ilẹ̀ tí ó yí àwọn ìlú òkè e nì ká.

Ìṣẹ́gun ogù ọba Baṣani

(A)Lẹ́yìn èyí ní a yípadà tí a sì kọrí sí ọ̀nà tí ó lọ sí Baṣani, Ogu ọba Baṣani àti gbogbo jagunjagun rẹ̀ ṣígun wá pàdé wa ní Edrei. Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe bẹ̀rù rẹ̀, nítorí tí mó tí fi òun lé ọ lọ́wọ́, àti àwọn ọmọ-ogun rẹ̀, àti ilẹ̀ rẹ̀. kí ìwọ kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti ṣe sí Sihoni ọba Amori ẹni tí ó ń jẹ ọba ní Heṣboni.”

Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa Ọlọ́run wa fi Ogu ọba Baṣani àti àwọn jagunjagun rẹ̀ lé wa lọ́wọ́. A kọlù wọ́n títí kò fi ku ẹnìkan fún un láàyè. Ní ìgbà náà ní a gba gbogbo àwọn ìlú rẹ̀. Kò sí ọ̀kankan tí a kò gbà nínú àwọn ọgọta (60) ìlú tí wọ́n ní: Gbogbo agbègbè Argobu, lábẹ́ ìjọba Ogu ní Baṣani. Gbogbo ìlú wọ̀nyí ní a mọ odi gíga yíká pẹ̀lú àwọn ìlẹ̀kùn àti irin. Ọ̀pọ̀ àwọn ìlú kéékèèkéé tí a kò mọ odi yíká sì tún wà pẹ̀lú. Gbogbo wọn ni a parun pátápátá gẹ́gẹ́ bí á ti ṣe sí Sihoni ọba Heṣboni, tí a pa gbogbo ìlú wọn run pátápátá: tọkùnrin tobìnrin àti àwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n a kó gbogbo ohun ọ̀sìn àti ìkógun àwọn ìlú wọn, fún ara wa.

Ní ìgbà náà ni a ti gba ilẹ̀ tí ó wà ní Jordani láti odò Arnoni, títí dé orí òkè Hermoni lọ́wọ́ àwọn ọba Amori méjèèjì wọ̀nyí. (Àwọn ará Sidoni ń pe Hermoni ní Sirioni: Àwọn Amori sì ń pè é ní Seniri) 10 Gbogbo àwọn ìlú tí ó wà ní orí òkè olórí títẹ́ náà ni a gbà àti gbogbo Gileadi, àti gbogbo Baṣani, títí dé Saleka, àti Edrei, ìlú àwọn ọba Ogu ní ilẹ̀ Baṣani. 11 (Ogu tí í ṣe ọba Baṣani nìkan ni ó ṣẹ́kù nínú àwọn ará Refaimu. Ibùsùn rẹ̀ ni a fi irin ṣe, ó sì gùn ju ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàlá lọ ní gígùn àti ẹsẹ̀ bàtà mẹ́fà ní ìbú. Èyí sì wà ní Rabba ti àwọn Ammoni.)