Add parallel Print Page Options

Ọmọbìnrin tó kú àti obìnrin onísun-ẹ̀jẹ̀

18 Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsi i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsin yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.” 19 Jesu dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.

20 Sì kíyèsi i, obìnrin kan ti ó ní ìsun ẹ̀jẹ̀ ní ọdún méjìlá, ó wá lẹ́yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀. 21 Nítorí ó wí nínú ara rẹ̀ pé, “Bí mo bá sá à le fi ọwọ́ kan ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀, ara mi yóò dá.”

22 (A)Nígbà tí Jesu sì yí ara rẹ̀ padà tí ó rí i, ó wí pé, “Ọmọbìnrin, tújúká, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradà.” A sì mú obìnrin náà láradá ni wákàtí kan náà.

23 Nígbà tí Jesu sí i dé ilé ìjòyè náà, ó bá àwọn afunfèrè àti ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó ń pariwo. 24 Ó wí fún wọn pé, “Ẹ máa lọ; nítorí ọmọbìnrin náà kò kú, sísùn ni ó sùn.” Wọ́n sì fi i rín ẹ̀rín ẹlẹ́yà. 25 Ṣùgbọ́n nígbà tí a ti àwọn ènìyàn jáde, ó wọ ilé, ó sì fà ọmọbìnrin náà ní ọwọ́ sókè; bẹ́ẹ̀ ni ọmọbìnrin náà sì dìde. 26 Òkìkí èyí sì kàn ká gbogbo ilẹ̀ náà.

Read full chapter

Òkú obìnrin kan àti obìnrin aláìsàn kan

40 (A)Ó sì ṣe, nígbà tí Jesu padà lọ, àwọn ènìyàn tẹ́wọ́gbà á; nítorí tí gbogbo wọn ti ń retí rẹ̀. 41 Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jairu, ọ̀kan nínú àwọn olórí Sinagọgu wá; ó sì wólẹ̀ lẹ́bàá ẹsẹ̀ Jesu, ó bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó wá sí ilé òun: 42 Nítorí ó ní ọmọbìnrin kan ṣoṣo, ọmọ ìwọ̀n ọdún méjìlá, ti ó ń kú lọ.

Bí ó sì ti ń lọ àwọn ènìyàn ko fun ni ààyè. 43 Obìnrin kan tí ó sì ní ìsun ẹ̀jẹ̀ láti ìgbà ọdún méjìlá, tí ó ná ohun gbogbo tí ó ní fún àwọn oníṣègùn, tí kò sì sí ẹnìkan tí ó lè mú un láradá, 44 Ó wá sí ẹ̀yìn rẹ̀, ó fi ọwọ́ tọ́ ìṣẹ́tí aṣọ rẹ̀; lọ́gán ni ìsun ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sì ti gbẹ.

45 (B)Jesu sì wí pé, “Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mí?”

Nígbà tí gbogbo wọn sẹ́ Peteru àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ sọ pé, “Olùkọ́, àwọn ènìyàn ko ní ààyè, wọ́n sì ń kọlù ọ́, ìwọ sì wí pé, Ta ni ó fi ọwọ́ kàn mi?”

46 (C)Jesu sì wí pé, “Ẹnìkan fi ọwọ́ kàn mí: nítorí tí èmí mọ̀ pé, àṣẹ jáde lára mi.”

47 Nígbà tí obìnrin náà sì mọ̀ pé òun kò fi ara sin, ó wárìrì, ó wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó sì sọ fún un lójú àwọn ènìyàn gbogbo nítorí ohun tí ó ṣe, tí òun fi fi ọwọ́ kàn án, àti bí a ti mú òun láradá lójúkan náà. 48 (D)Ó sì wí fún un pé, “Ọmọbìnrin, ìgbàgbọ́ rẹ mú ọ láradá; máa lọ ní Àlàáfíà!”

49 Bí ó sì ti ń sọ̀rọ̀ lẹ́nu, ẹnìkan ti ilé olórí Sinagọgu wá, ó wí fún un pé, “Ọmọbìnrin rẹ kú; má yọ olùkọ́ni lẹ́nu mọ́.”

50 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu gbọ́, ó dá a lóhùn, pé, “Má bẹ̀rù: sá gbàgbọ́ nìkan, a ó sì mú un láradá.”

51 Ṣùgbọ́n nígbà tí Jesu sì wọ ilé, kò jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé, bí kò ṣe Peteru, àti Jakọbu, àti Johanu, àti baba àti ìyá ọmọbìnrin náà. 52 Gbogbo wọn sì sọkún, wọ́n pohùnréré ẹkún rẹ̀: ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ má sọkún mọ́; kò kú, sísùn ni ó sùn.”

53 Wọ́n sì fi í ṣẹ̀fẹ̀, wọ́n sá mọ̀ pé ó kú. 54 Nígbà tí ó sì sé gbogbo wọn mọ́ òde, ó mú un lọ́wọ́, ó sì wí pé, “Ọmọbìnrin, dìde!” 55 Ẹ̀mí rẹ̀ sì padà bọ̀, ó sì dìde lọ́gán: ó ní kí wọn fún un ní oúnjẹ. 56 (E)Ẹnu sì ya àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n ó kìlọ̀ fún wọn pé, kí wọn má ṣe wí fún ẹnìkan ohun tí a ṣe.

Read full chapter